Àwọn Ìwé Mímọ́
2 Nífáì 30


Ori 30

A ó ka àwọn Kèfèrí tí a yí lọ́kàn padà pẹ̀lú àwọn ènìyàn májẹ̀mú—Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ará Lámánì àti àwọn Jũ yíò gba ọ̀rọ̀ nã gbọ́ wọn yíò sì di wíwuni—A ó mú Isráẹ́lì padà sípò a ó sì pa ènìyàn búburú run. Ní ìwọ̀n ọdún 559 sí 545 kí á tó bí Olúwa wa.

1 Àti nísisìyí kíyèsĩ i, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, èmi yíò sọ̀rọ̀ sí yín; nítorí èmi, Nífáì, kì yíò yọ̃da kí ẹ̀yin kí ó ṣebí pé ẹ̀yin jẹ́ olódodo ju bí àwọn Kèfèrí yíò ṣe jẹ́. Nítorí kíyèsĩ i, àfi bí ẹ̀yin yíò bá pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́ gbogbo yín yíò parun bẹ̃gẹ́gẹ́; àti nítorí ti àwọn ọ̀rọ̀ èyí tí a ti sọ kò yẹ kí ẹ̀yin ṣèbí pé a ti pa àwọn Kèfèrí run pátápátá.

2 Nítorí kíyèsĩ i, mo wí fún yín pé ọ̀pọ̀ iye àwọn Kèfèrí tí ó bá ronúpìwàdà ni ènìyàn májẹ̀mú ti Olúwa; ọ̀pọ̀ iye àwọn Jũ tí kò bá sì ronúpìwàdà ni a ó ké kúrò; nítorí Olúwa kò dá májẹ̀mú pẹ̀lú ẹnikẹ́ni bíkòṣe pẹ̀lú àwọn tí ó bá ronúpìwàdà tí ó sì gbàgbọ́ nínú Ọmọ rẹ̀, ẹni tí i ṣe Ẹní Mímọ́ Isráẹ́lì.

3 Àti nísisìyí, èmi yíò sọ-tẹ́lẹ̀ díẹ̀ sĩ nípa àwọn Jũ àti àwọn Kèfèrí. Nítorí lẹ́hìn tí ìwé èyí tí mo ti sọrọ nípa rẹ̀ yíò jáde wá, tí a ó sì kọ sí àwọn Kèfèrí, tí a ó sì tún fi èdídì dì í sókè sí Olúwa, ọ̀pọ̀ ni yíò wà tí yíò gba àwọn ọ̀rọ̀ èyí tí a kọ gbọ́; wọn yíò sì gbé wọn jáde sí ìyókù irú-ọmọ wa.

4 Nígbànã sì ni ìyòkù irú-ọmọ wa yíò mọ̀ nípa wa, bí a ṣe jáde wá láti Jerúsálẹ́mù, àti pé àwọn jẹ́ àtẹ̀lé àwọn Jũ.

5 Ìhìn-rere Jésù Krístì ni a ó sì kéde lãrín wọn; nítorí-èyi, a ó mú wọn padà sípò sí ìmọ̀ àwọn bàbá wọn, àti pẹ̀lú sí ìmọ̀ Jésù Krístì, èyí tí a ní lãrín àwọn bàbá wọn.

6 Nígbànã sì ni wọn yíò yọ̀; nítorí wọn yíò mọ̀ pé ó jẹ́ ìbùkún fún wọn láti ọwọ́ Ọlọ́run; ìpẹ́ òkùnkùn wọn yíò sì bẹ̀rẹ̀sí jábọ́ kúrò ní ojú wọn; ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìran kì yíò sì kọjá kúrò lãrín wọn, àfi tí wọn bá jẹ́ ènìyàn tí ó mọ́ tí ó sì wuni.

7 Yíò sì ṣe tí àwọn Jũ èyí tí a túká yíò bẹ̀rẹ̀sí gbàgbọ́ nínú Krístì pẹ̀lú; wọn yíò sì bẹ̀rẹ̀sí péjọ sí ori ilẹ̀ ayé; ọ̀pọ̀ iye àwọn tí yíò sì gbàgbọ́ nínú Krístì yíò di ènìyàn wíwuni pẹ̀lú.

8 Yíò sì ṣe tí Olúwa Ọlọ́run yíò bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ lãrín gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè, ìbátan, èdè, àti ènìyàn, láti mú mímú padà sípò àwọn ènìyàn rẹ̀ wá sí órí ayé.

9 Àti pẹ̀lú òdodo ni Olúwa Ọlọ́run yíò ṣe ìdájọ́ àwọn tálákà, yíò sì báni wí pẹ̀lú ìṣòtítọ́ fún àwọn ọlọ́kàn tútù ayé. Òun yíò sì lu ayé pẹ̀lú ọ̀gọ ẹnu rẹ̀; àti pẹ̀lú ẽmí àwọn ètè rẹ̀ ni yíò sì pa àwọn ènìyàn búburú.

10 Nítorí àkókò nã nbọ̀wá kíákíá tí Olúwa Ọlọ́run yíò mú ìpín nlá kan ṣẹ lãrín àwọn ènìyàn, àwọn ènìyàn búburú ni òun yíò sì parun; òun yíò sì dá àwọn ènìyàn rẹ̀ sí, bẹ̃ni, àní bí ó ṣe pé òun yíò pa àwọn ènìyàn búburú run nípasẹ̀ iná.

11 Òdodo yíò sì jẹ́ àmùrè ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, àti ìṣòtítọ́ àmùrè inú rẹ̀.

12 Àti nígbànã ni ìkõkò yíò gbé pẹ̀lú ọ̀dọ́-àgùtàn; ẹkùn yíò sì dùbúlẹ̀ pẹ̀lú ọmọ ewúrẹ́, àti ọmọ màlũ, àti ọmọ kìnìún, àti ẹgbọ̀rọ̀ ẹran àbọ́pa, papọ̀; ọmọ kékeré kan yíò sì má dà wọ́n.

13 Àti màlũ àti béárì yíò sì ma jẹ; àwọn ọmọ wọn yíò dùbúlẹ̀ pọ̀; kìnìún yíò sì jẹ koríko bí màlũ.

14 Ọmọ ẹnu-ọmú yíò sì ṣiré ní ihò pãmọ́lè, ọmọ tí a já lẹ́nu ọmú yíò sì fi ọwọ́ rẹ̀ sí ihò gùnte.

15 Wọn kì yíò panilára bẹ̃ni wọn kì yíò panirun ní gbogbo òkè mímọ́ mi; nítorí ayé yíò kún fún ìmọ̀ Olúwa gẹ́gẹ́bí omi ti bò ojú òkun.

16 Nítorí-èyi, àwọn ohun gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ni a ó sọ di mímọ̀; bẹ̃ni, àwọn ohun gbogbo ni a ó sọ di mímọ̀ fún àwọn ọmọ ènìyàn.

17 Kò sí nkan tí ó jẹ́ ohun ìkọ̀kọ̀ tí a kò ní fi hàn; kò sí iṣẹ́ òkùnkùn tí a kò ní fi han ní ìmọ́lẹ̀; kò sì sí nkan tí a fi èdídì dì lórí ilẹ̀ ayé tí a kò ní tú sílẹ̀.

18 Nítorí-èyi, gbogbo àwọn ohun tí a ti fihàn sí àwọn ọmọ ènìyàn ni a ó fihàn ní ọjọ́ nã; Sátánì kì yíò sì ní agbára lórí ọkàn àwọn ọmọ ènìyàn mọ́, fún ìgbà pípẹ́. Àti nísisìyí, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, mo fi òpin sí àwọn ọ̀rọ̀ sísọ mi.