Àwọn Ìwé Mímọ́
2 Nífáì 27


Ori 27

Òkùnkùn àti ìṣubú-kuro nínú òtítọ́ yíò bò ayé ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn—Ìwé ti Mọ́mọ́nì yíò jáde wá—Àwọn ẹlẹ́rĩ mẹ́ta yíò jẹ́rĩ ìwé nã—Amòye ènìyàn yíò wípé òun kò lè ka ìwé tí a fi èdídì dì—Olúwa yíò ṣe iṣẹ́ ìyanu àti àjèjì—Fi Isaiah 29 wé e. Ní ìwọ̀n ọdún 559 sí 545 kí á tó bí Olúwa wa.

1 Ṣùgbọ́n, kíyèsĩ i, ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn, tàbí ní àwọn ọjọ́ àwọn Kèfèrí—bẹ̃ni, kíyèsĩ i gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ti àwọn Kèfèrí àti pẹ̀lú àwọn Jũ, àti àwọn tí yíò wá sórí ilẹ̀ yí àti àwọn tí yíò wà lórí àwọn ilẹ̀ míràn, bẹ̃ni, àní lórí gbogbo ilẹ̀ ayé, kíyèsĩ i, wọn yíò mọtípara pẹ̀lú àìṣedẽdé àti irú ohun ìríra gbogbo—

2 Nígbàtí ọjọ́ nã yíò de a ó bẹ̀ wọ́n wò láti ọ̀dọ̀ Olúwa àwọn Ọmọ-ogun, pẹ̀lú ãrá àti pẹ̀lú ilẹ̀ ríri, àti pẹ̀lú ìró nlá, àti pẹ̀lú ìjì, àti pẹ̀lú ẹ̀fũfù, àti pẹ̀lú ọ̀wọ́ ajónirun iná.

3 Gbogbo orílẹ̀-èdè tí sì nbá Síónì jà, tí wọ́n sì pọ́n ọn lójú, yíò dàbí àlá ìran òru; bẹ̃ni, yíò rí bẹ̃ fún wọn, àní bí ẹni ebi npa tí ó nlá àlá, sì kíyèsĩ i ó jẹun ṣùgbọ́n ó jí ọkàn rẹ̀ sì di òfo; tàbí bí ẹni tí òùngbẹ ngbẹ tí nlá àlá, sì kíyèsĩ i ó nmu omi ṣùgbọ́n ó jí sì kíyèsĩ i ó dákú, òùngbẹ sì ngbẹ ọkàn rẹ̀; bẹ̃ni, gẹ́gẹ́ bẹ̃ ni gbogbo ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè yíò rí tí nbá òkè Síónì jà.

4 Nítorí kíyèsĩ i, gbogbo ẹ̀yin tí nṣe àìṣedẽdé, ẹ mú ara dúró kí ẹnu sì yà yín, nítorí ẹ̀yin yíò kígbe sóde, ẹ ó sì kígbe; bẹ̃ni, ẹ̀yin yíò mu àmupara ṣùgbọ́n kì í ṣe pẹ̀lú ọtí-wáínì, ẹ̀yin yíò ta gbọ̀ngbọ́n ṣùgbọ́n kí ì ṣe pẹ̀lú ohun mímú líle.

5 Nítorí kíyèsĩ i, Olúwa ti da ẹ̀mí orun jíjìn lù yín. Nítorí kíyèsĩ i, ẹ̀yin ti pa ojú yín dé, ẹ sì ti kọ àwọn wòlĩ sílẹ̀; àti àwọn olórí yín, àti àwọn aríran ni ó ti bò ní ojú nítorí ti àìṣedẽdé yín.

6 Yíò sì ṣe tí Olúwa Ọlọ́run yíò mú jáde sí yín àwọn ọ̀rọ̀ ìwé kan, wọn yíò sì jẹ́ àwọn ọ̀rọ̀ àwọn wọnnì tí ó ti tõgbé.

7 Sì kíyèsĩ i a ó fi èdídì di ìwé nã; nínú ìwé nã sì ni ìfihan láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run yíò wà, láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé titi de òpin rẹ̀.

8 Nítorí-èyi, nítorí ti àwọn ohun tí a fi èdídì dì pọ̀, a kì yíò jọ̀wọ́ àwọn ohun tí a fi èdídì dì ní ọjọ́ ìwà búburú àti ẹ̀gbin àwọn ènìyàn. Nítorí-èyi a ó pa ìwé nã mọ́ kúrò lọ́dọ̀ wọn.

9 Ṣùgbọ́n a ó jọ̀wọ́ ìwé nã fún ọkùnrin kan, òun yíò sì fún ni ní àwọn ọ̀rọ̀ ìwé nã, èyí tí nṣe àwọn ọ̀rọ̀ àwọn ẹni tí ó ti tõgbé nínú eruku, òun yíò sì fi àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún òmíràn.

10 Ṣùgbọ́n àwọn ọ̀rọ̀ èyí tí a fi èdídì dì òun kì yíò fi fún ni, bẹ̃ni kì yíò fi ìwé nã fún ni. Nítorí a ó fi èdídì di ìwé nã nípasẹ̀ agbára Ọlọ́run, ìfihàn èyí tí a sì fi èdídì dì ni a ó pamọ́ sínú ìwé nã títí di àkókò títọ́ ti Olúwa, kí wọ́n lè jáde wá; nítorí kíyèsĩ i, wọ́n fi ohun gbogbo hàn láti ìpìlẹ̀ ayé dé òpin rẹ̀.

11 Ọjọ́ nã sì mbọ̀wá tí a ó ka àwọn ọ̀rọ̀ ìwé èyí tí a fi èdídì dì lórí àwọn òkè ilé; a ó sì kà wọ́n nípa agbára Krístì; a ó sì fi ohun gbogbo hàn sí àwọn ọmọ ènìyàn tí ó ti wà lãrín àwọn ọmọ ènìyàn, àti tí yíò wà láé àní dé òpin ayé.

12 Nítorí-èyi, ní ọjọ́ nã nígbàtí a ó fi ìwé nã fún ọkùnrin nã nípa ẹni tí mo ti sọ̀, a ó fi ìwé nã pamọ́ kúrò ní ojú ayé, tí ojú ẹnikẹ́ni kì yíò ríi àfi pé àwọn ẹlẹ́rĩ mẹ́ta yíò ríi, nípa agbára Ọlọ́run, pẹ̀lú ẹni tí a ó fi ìwé nã fún; wọn yíò sì jẹ́rĩ sí òtítọ́ ìwé nã àti àwọn ohun inú rẹ̀.

13 Kò sì sí ẹnikẹ́ni míràn tí yíò wò ó, àfi àwọn díẹ̀ gẹ́gẹ́bí ìfẹ́ Ọlọ́run, láti sọ ẹ̀rí nípa ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí àwọn ọmọ ènìyán; nítorí Olúwa Ọlọ́run ti sọ pé kí àwọn ọ̀rọ̀ olóotọ́ kí ó sọ̀rọ̀ bí ẹni pé ó wá láti òkú.

14 Nítorí-èyi, Olúwa Ọlọ́run yíò tẹ̀ síwájú láti mú àwọn ọ̀rọ̀ iwé nã jáde wá; ní ẹnu ọ̀pọ̀ àwọn ẹlẹ́rĩ tí ó básì ṣe bí ẹnipé ó dára ni yíò ti fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ múlẹ̀; ègbé sì ni fún ẹni nã tí yíò kọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílẹ̀!

15 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ i, yíò ṣe tí Olúwa Ọlọ́run yíò wí fún ẹni tí oun yíò fi ìwé nã fun: Mú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tí a kò fi èdídì dì kí o sì fi wọ́n fún ẹlòmíràn, kí ó lè fi wọ́n hàn fún amòye, wípé: Ka èyí, èmi bẹ̀ ọ́. Amòye nã yíò sì wípé: Mú ìwé nã wá síhín, èmi yíò sì kà wọ́n.

16 Àti nísisìyí, nítorí ògo ti ayé àti láti rí èrè gbà ni wọn yíò fi sọ èyí, kì í sì ṣe fún ògó Ọlọ́run.

17 Ọkùnrin nã yíò sì wípé: Èmi kò lè mú ìwé nã wá, nítorí a fi èdídì dì í.

18 Nígbànã ni amòye nã yíò wípé: Èmi kò lè kà á.

19 Nítorí-èyi yíò ṣe, tí Olúwa Ọlọ́run yíò tún fi ìwé nã àti àwọn ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ fún ẹni tí ki i ṣe amòye; ẹni tí ki i ṣe amòye nã yíò wípé: Èmi ki i ṣe amòye.

20 Nígbànã ni Olúwa Ọlọ́run yíò wí fún un: Àwọn amòye kì yíò kà wọ́n, nítorí wọ́n ti kọ̀ wọ́n sílẹ̀, èmi sì lè ṣe iṣẹ́ tèmi; nítorí-èyi ìwọ yíò ka àwọn ọ̀rọ̀ nã tí èmi yíò fi fún ọ.

21 Máṣe fi ọwọ́ kan àwọn ohun èyí tí a fi èdídì dì, nítorí èmi yíò mú wọn jáde wá ní àkókò tí ó tọ́ ní tèmi; nítorí èmi yíò fihàn sí àwọn ọmọ ènìyàn pé èmi lè ṣe iṣẹ́ tèmi.

22 Nítorí-èyi, nígbàtí ìwọ bá ti ka àwọn ọ̀rọ̀ tí mo ti pàṣẹ fún ọ, tí o sì gba àwọn ẹlẹ́rĩ èyí tí mo ti ṣe ìlérí fún yín, nígbànã ni ìwọ yíò tún fi èdídì di ìwé nã, ìwọ yíò sì fi pamọ́ fún mi, kí èmi lè pa àwọn ọ̀rọ̀ tí ìwọ kò tí ì kà mọ, títí èmi yíò ri pé ó tọ́ ní ọgbọ́n tèmi láti fi ohun gbogbo hàn sí àwọn ọmọ ènìyàn.

23 Nítorí kíyèsĩ i, èmi ni Ọlọ́run; èmi sì jẹ́ Ọlọ́run àwọn iṣẹ́-ìyanu; èmi yíò fi hàn sí ayé pé èmi jẹ́ ọ̀kannã ní àná, ní òní, àti títí láé; èmi kì yíò sì ṣe iṣẹ́ lãrín àwọn ọmọ ènìyàn àfi tí ó bá jẹ́ gẹ́gẹ́bí ìgbàgbọ́ wọn.

24 Yíò sì tún ṣe tí Olúwa yíò wí fún ẹni tí yíò ka àwọn ọ̀rọ̀ nã tí a ó fi fún un:

25 Níwọ̀n bí àwọn ènìyàn yí ti nfi ẹnu wọn fà mọ́ mi, tí wọ́n sì nfi ètè wọn yìn mí, ṣùgbọ́n tí ọkàn wọn jìnà sí mi, tí wọ́n sì bẹ̀rù mi nípa ìlànà ènìyàn—

26 Nítorí-èyi, èmi yíò tẹ̀síwájú láti ṣe iṣẹ́ ìyanu lãrín àwọn ènìyàn, bẹ̃ni, iṣẹ́ ìyanu àti àjèjì, nítorí ọgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n àti tí amòye wọn yíò parun, òye àwọn amero wọn yíò sì lùmọ́.

27 Ègbé sì ni fún àwọn tí nwá ọ̀nà láti fi ìmọ̀ràn wọn pamọ́ kúrò lójú Olúwa! Iṣẹ́ wọn sì wà ní òkùnkùn; wọ́n sì wípé: Tani ó rí wa, taní ó sì mọ̀ wá? Wọ́n sì wí pẹ̀lú pé: Dájúdájú, yíyí àwọn ohun po ní a ó kà sí bí amọ̀ amọ̀kòkò. Ṣugbọn kíyèsĩ i, èmi yíò fí hàn wọ́n, ní Olúwa àwọn Ọmọ-ogun wí, pé èmi mọ́ gbogbo iṣẹ́ wọn. Nítorí iṣẹ́ yíò ha wí fún ẹni tí ó ṣe é pé, òun kò ṣe mí? Tàbí ohun tí a mọ́ yíò ha wí fún ẹni tí ó mọ́ ọ́ pé, òun kò mòye?

28 Sùgbọ́n kíyèsĩ i, ni Olúwa àwọn Ọmọ-ogun wí: Èmi yíò fi hàn sí àwọn ọmọ ènìyàn pé ó ku ìgbà díẹ̀ kíún síi Lébánọ́nì yíò sì di pápá eléso; pápá eléso nã ni a ó sì kà sí bí igbó.

29 Ní ọjọ́ nã sì ni odi yíò gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ ìwé nã, ojú afọ́jú yíò sì rí láti inú ìfarasin àti láti inú òkùnkùn.

30 Àti ọlọ́kàn tútù pẹ̀lú yíò pọ̀si, ayọ̀ wọn yíò sì wà nínú Olúwa, àwọn tálákà lãrín àwọn ènìyàn yíò sì yọ̀ nínú Ẹní Mímọ́ Isráẹ́lì.

31 Nítorí dájúdájú bí Olúwa ti wà lãyè, wọ́n yíò ri pé a sọ ẹni búburú nã di asán, àwọn ẹlẹ́gàn ni a ó sì jẹ run, gbogbo àwọn tí nwá àìṣedẽdé ni a ó sì gé kúrò;

32 Àti àwọn tí ó nsọ ènìyàn di òdaràn nípa ọ̀rọ̀, tí wọn sì tọ́ èbìtì fún ẹni tí ó báni wí ní ẹnu ọ̀nà òde, tí wọ́n sì yí èyítí ó tọ́ sí ápákan fún ohun asán.

33 Nítorí-èyi, báyĩ ni Olúwa wí, ẹni tí ó ra Ábráhámù padà, nípa ilé Jákọ́bù: Jákọ́bù kì yíò tijú báyĩ, bẹ̃ni ojú rẹ̀ kì yíò di funfun.

34 Ṣùgbọ́n nígbàtí òun yíò rí àwọn ọmọ rẹ̀, iṣẹ́ ọwọ́ mi, ní ãrin rẹ̀, wọn yíò ya orúkọ mi sí mímọ́, wọn yíò sì ya Ẹní Mímọ́ Jákọ́bù sí mímọ́, wọn yíò sì bẹ̀rù Ọlọ́run Isráẹ́lì.

35 Àwọn nã pẹ̀lú tí o ṣìnà ní ẹ̀mí yíò wá sí ìmọ̀, àwọn tí ó nkùn sínú yíò kọ́ ẹ̀kọ́.