Àwọn Ìwé Mímọ́
2 Nífáì 11


Ori 11

Jákọ́bù rí Olùràpadà rẹ̀—Òfin Mósè ṣe àpẹrẹ Krístì ó sì ṣe ẹ̀rí pé yíò wá. Ní ìwọ̀n ọdún 559 sí 545 kí á tó bí Olúwa wa.

1 Àti nísisìyí, Jákọ́bù sọ àwọn ohun púpọ̀ si sí àwọn ènìyàn mi ní àkókò nã; bíótilẹ̀ríbẹ̃ àwọn ohun wọ̀nyí nìkan ni mo mú kí á kọ, nítorí àwọn ohun èyí tí mo ti kọ tó mi.

2 Àti nísisìyí èmi, Nífáì, kọ àwọn ọ̀rọ̀ Isaiah si, nítorí ọkàn mi yọ̀ nínú àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀. Nítorí èmi yíò fi àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ wé sí àwọn ènìyàn mi, èmi yíò sì rán wọn jáde lọ sí gbogbo àwọn ọmọ mi, nítorí nítõtọ́ ó rí Olùràpadà mi, àní bí èmi ti rí i.

3 Àti arákùnrin mi, Jákọ́bù, ti ríi bí èmi ti ríi pẹ̀lú; nítorí-èyi, èmi yíò rán àwọn ọ̀rọ̀ wọn jáde sí àwọn ọmọ̀ mi láti fi ìdi rẹ̀ múlẹ̀ sí wọn pé àwọn ọ̀rọ̀ mi jẹ́ òtítọ́. Nítorí-èyi, nípa ọ̀rọ̀ ẹni mẹ́ta, Ọlọ́run ti sọ ọ́, ni èmi yíò fi ìdí ọ̀rọ̀ mi mulẹ̀. Bíótilẹ̀ríbẹ̃, Ọlọ́run rán àwọn ẹlẹ́rĩ síi, ó sì fi ìdí gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ mulẹ̀.

4 Kíyèsĩ i, ọkàn mí yọ̀ ní síṣe ẹ̀rí sí àwọn ènìyàn mi òtítọ́ bíbọ̀ Krístì; nítorí, fún ìdí èyí ni a ti fi òfin Mósè fún ni; gbogbo àwọn ohun èyí tí a sì ti fi fún ni nípasẹ̀ Ọlọ́run láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé, sí ènìyàn, jẹ́ ṣíṣe àpẹrẹ rẹ̀.

5 Àti pẹ̀lú ọkàn mí yọ̀ nínú àwọn májẹ̀mú Olúwa èyí tí ó ti ba àwọn bàbá wa dá; bẹ̃ni, ọkàn mí yọ̀ nínú ore ọ̀fẹ́ rẹ̀, àti nínú àìṣègbè rẹ̀, àti agbára, àti ãnú nínú ìlànà nlá àti ti ayérayé fún ìdásílẹ̀ lọ́wọ́ ikú.

6 Ọkàn mi sì yọ̀ ní síṣe ẹ̀rí sí àwọn ènìyàn mi pé àfi tí Krístì bá wá gbogbo ènìyàn kò lè ṣe àì parun.

7 Nítorí bí kò bá sí Krístì kò sí Ọlọ́run; bí kò bá sì sí Ọlọ́run àwa kò sí, nítorí ìbá má ti sí ẹ̀dá. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run kan wà, òun sì ni Krístì, òun yíò sì wá ní kíkún àkókò tirẹ̀.

8 Àti nísisìyí mo kọ díẹ̀ nínú àwọn ọ̀rọ̀ Isaiah, kí ẹnikẹ́ni nínú àwọn ènìyàn mi tí yíò rí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí lè gbé ọkàn wọn sókè kí wọ́n sì yọ̀ fún gbogbo ènìyàn. Nísisìyí ìwọ̀nyí ni àwọn ọ̀rọ̀ nã, ẹ̀yin sì lè fi wọ́n wé sí yín àti sí gbogbo ènìyàn.