Àwọn Ìwé Mímọ́
2 Nífáì 24


Ori 24

A ó ko Isráẹ́lì jọ yíò sì gbádùn ìsimi ẹgbẹ̀rún ọdún—A sọ Lúsíférì sóde kúrò ní ọ̀run fún ìṣọ̀tẹ̀—Isráẹ́lì yíò yọ ayọ̀ ìṣẹ́gun lórí Bábílọ́nì (ayé)—Fi Isaiah 14 wé e. Ní ìwọ̀n ọdún 559 sí 545 kí á tó bí Olúwa wa.

1 Nítorí Olúwa yíò ṣãnú fún Jákọ́bù, yíò sì tún yan Isráẹ́lì, yíò sì mú wọn gbé ilẹ̀ wọn; àwọn àlejò yíò sì dàpọ̀ mọ́ wọn, wọn yíò sì faramọ́ ilé Jákọ́bù.

2 Àwọn ènìyàn yíò sì mú wọn, wọn yíò sì mú wọn wá sí ãyè wọn; bẹ̃ni, láti ona jijin títí de ìkangun ayé; wọn yíò sì padà sí àwọn ilẹ̀ ìlérí wọn. Ará ilé Isráẹ́lì yíò sì ní wọn, ilẹ̀ Olúwa yíò sì wà fún àwọn ìránṣẹ́-kùnrin àti àwọn ìránṣẹ́-bìnrin; àwọn tí ó ti kó wọn ní ìgbèkun ni wọn yíò kó ní ìgbèkun; wọn yíò sì ṣe àkóso aninilára wọn.

3 Yíò sì ṣe ní ọjọ́ nã tí Olúwa yíò fún ọ ní ìsimi, kúrò nínú ìrora-ọkàn rẹ, àti kúrò nínú ìjáyà rẹ, àti kúrò nínú oko-ẹrú líle níbi tí a ti mú ọ sìn.

4 Yíò sì ṣe ní ọjọ́ nã, ni ìwọ, yio fi ọba Bábílọ́nì ṣe ẹ̀fẹ̀ yí, tí ìwọ yíò sì wípé: Aninilára nì ha ti ṣe dákẹ́, ìlú nlá wúrà dákẹ́!

5 Olúwa ti ṣẹ́ ọ̀pá olùṣebúburú, ọ̀pá-aládé àwọn alákõso.

6 Ẹni tí ó fi ìbínú lu àwọn ènìyàn láì dáwọ́ duró, ẹni tí ó fi ìbínú ṣe àkóso àwọn orílẹ̀-èdè, ni à nṣe inúnibíni sí, láé dẹ́kun.

7 Gbogbo ayé wà ní isimi, wọ́n sì gbé jẹ́; wọ́n bú jáde nínú orin kíkọ.

8 Bẹ̃ni, àwọn igi fírì nyọ̀ sí ọ, àti igi kédárì ti Lébánọ́nì pẹ̀lú, wípé: Láti ìgbà tí ìwọ ti dùbúlẹ̀ kò sí agégi tí ó tọ̀ wá wá.

9 Ọ̀run àpãdì láti ìsàlẹ̀ wá mì fún ọ láti pàdé rẹ ní àbọ̀ rẹ; ó rú àwọn òkú dìde fún ọ, àní gbogbo àwọn alákõso ayé; ó ti gbé gbogbo ọba àwọn orílẹ̀-èdè dìde kúrò lórí ìtẹ́ wọn.

10 Gbogbo wọn yíò dáhùn wọn ó sì wí fún ọ pé: Ìwọ pẹ̀lú ti di àìlera gẹ́gẹ́bí àwa bí? Ìwọ ha dàbí àwa bí?

11 Ògo rẹ ni a ti sọ̀kalẹ̀ sí ibójì; a kò gbọ́ ariwo dùrù rẹ; ekòló ti tàn sí ábẹ́ rẹ, ìdin sì bò ọ́ mọ́ ilẹ̀.

12 Báwo ni ìwọ ti ṣe ṣubú láti ọ̀run wá, A! Lúsíférì, ìràwọ̀ òwúrọ̀! A gé ọ lu ilẹ̀, èyí tí ó sọ àwọn orílẹ̀-èdè di aláìlágbára!

13 Nítorí ìwọ ti wí ní ọkàn rẹ: Èmi yíò gòkè lọ sí ọ̀run, èmi yíò gbé ìtẹ́ mi ga kọjá àwọn ìràwọ̀ Ọlọ́run; èmi yíò jòkó pẹ̀lú lórí òkè ìjọ ènìyàn, ní ìhà àríwá;

14 Èmi yíò gòkè kọjá àwọ̀sánmà gíga; èmi yíò dàbí Ọ̀gá-ògo Jùlọ.

15 Síbẹ̀ a ó mú ọ sọ̀kalẹ̀ sí ọ̀run àpãdì, sí awọn ìhà ihò nã.

16 Àwọn tí ó rí ọ yíò tẹjúmọ́ ọ, wọn yíò sì ronú rẹ, wọn yíò sì wípé: Èyí ha nì ọkùnrin nã tí ó mú ayé wárìrì, tí ó mi àwọn ìjọba tìtì?

17 Tí ó sọ ayé dàbí ijù, tí ó sì pa ìlú rẹ̀ run, tí kò sì ṣí ilé àwọn òndè rẹ̀?

18 Gbogbo ọba àwọn orílẹ̀-èdè, bẹ̃ni, gbogbo wọn, dùbúlẹ̀ nínú ògo, olúkúlùkù nínú ilé rẹ̀.

19 Ṣùgbọ́n ìwọ ni a gbé sọnù kúrò níbi ibojì rẹ bí ẹ̀ka ìríra, àti ìyókù àwọn tí a pa, tí a fi idà gún ní àgúnyọ, tí nsọ̀kalẹ̀ lọ sí ihò òkúta; bí òkú tí a tẹ̀ mọ́lẹ̀.

20 A kì yíò sin ọ́ pọ̀ pẹ̀lú wọn, nítorí tí ìwọ ti pa ilẹ̀ rẹ run o sì ti pa àwọn ènìyàn rẹ; irú-ọmọ àwọn olùṣe búburú ni a kì yíò dárúkọ láéláé.

21 Múra ibi pípa fún àwọn ọmọ rẹ̀ nítorí àìṣedẽdé àwọn bàbá wọn, kí wọn kí ó má bá dìde, tàbí kí wọ́n ní ilẹ̀ nã, tàbí kí wọ́n fi ìlú-nlá kún ojú ayé.

22 Nítorí èmi yíò dìde sí wọn, ni Olúwa àwọn Ọmọ-ogun wí, èmi yíò sì gé orúkọ kúrò ní Bábílọ́nì, àti ìyókù, àti ọmọkùnrin, àti ọmọ dé ọmọ, ni Olúwa wí.

23 Èmi yíò sì ṣe é ní ilẹ̀níní fún õrẹ̀, àti àbàtà omi; èmi yíò sì fi ọwọ̀ ìparun gbá a, ni Olúwa àwọn Ọmọ-ogun wí.

24 Olúwa àwọn Ọmọ-ogun ti búra, wípé: Dájúdájú gẹ́gẹ́bí mo ti gbèrò, bẹ̃ni yíò rí; gẹ́gẹ́bí mo ti pinnu, bẹ̃ni yíò sì dúró—

25 Pé èmi ó mú àwọn ará Assíríà ní ilẹ̀ mi wá, àti lórí òkè mi ni èmi yíò tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀ lábẹ́ àtẹ́lẹsẹ̀; nígbànã ni àjàgà rẹ̀ yíò kúrò lára wọn, àti ẹrù rẹ̀ kúrò ní èjìká wọn.

26 Èyí ni ìpinnu tí a pinnu lórí gbogbo ayé; èyí sì ni ọwọ́ tí a nà jáde lórí gbogbo orílẹ̀-èdè.

27 Nítorí Olúwa àwọn Ọmọ-ogun ti pinnu, tani yíò sì sọ ọ́ dí asán? Ọwọ́ rẹ̀ sì nà jáde, tani yíò sì dá a padà?

28 Ní ọdún tí ọba Áhásì kú ni ìnira yí.

29 Ìwọ máṣe yọ̀, gbogbo Filistia, nítorí pàṣán ẹnití ó nà ọ́ ti ṣẹ́; nítorí láti inú gbòngbò ejò ni gùnte kan yíò jáde wá, irú-ọmọ rẹ̀ yíò sì jẹ́ ejò iná tí nfò.

30 Àkọ́bí àwọn tálákà yíò sì jẹ, àwọn aláìní yíò sì dùbúlẹ̀ láìléwu; èmi yíò sì pa gbòngbò rẹ pẹ̀lú ìyàn, òun yíò sì pa ìyókù rẹ.

31 Hu, A! ẹnu-odi; kígbe, A! ílú; ìwọ, gbogbo Filistia, ti di yíyọ́; nítorí ẽfín yíò ti àríwá jáde wá, ẹnìkan kì yíò sì dá wà ní àkókò yíyàn rẹ̀.

32 Èsì wo ni a ó fi fún àwọn ìránṣẹ́ àwọn orílẹ̀-èdè? Pé Olúwa ti tẹ Síónì dó, tálákà nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ yíò sì gbàgbọ́ nínú rẹ̀.