Àwọn Ìwé Mímọ́
2 Nífáì 20


Ori 20

Íparun Assíríà jẹ́ àpẹrẹ ìparun ti àwọn ènìyàn búburú ní ìgbà Bíbọ̀ Èkejì—Àwọn ènìyàn díẹ̀ ni a ó fi sílẹ̀ lẹ́hìn tí Olúwa bá tún wá—Ìyókù Jákọ́bù yíò padà ní ọjọ́ nã—Fi Isaiah 10 wé e. Ní ìwọ̀n ọdún 559 sí 545 kí á tó bí Olúwa wa.

1 Ègbé ni fún àwọn tí npàṣẹ àìṣòdodo, àti tí wọn nkọ ìbànújẹ́ tí wọn ti lànà;

2 Láti yí aláìní kúrò ní ìdájọ́, àti láti mú ohun ẹ̀tọ́ kúrò lọ́wọ́ tálákà ènìyàn mi, kí àwọn opó lè di ìjẹ wọn, àti kí wọ́n bá lè ja aláìníbaba ní olè!

3 Kíni ẹ̀yin yíò sì ṣe lọ́jọ́ ìbẹ̀wò, àti ní ìdáhóró tí yíò ti òkèrè wá? Tani ẹ̀yin yíò sá tọ̀ fún ìrànlọ́wọ́? Níbo ni ẹ̀yin yíò sì fi ògo yín sí?

4 Láìsí èmi wọn yíò tẹ̀ríba lábẹ́ àwọn ẹlẹ́wọ̀n, wọn yíò sì ṣubú lábẹ́ àwọn tí a pa. Fún gbogbo èyí ìbínú rẹ̀ kò yí kúrò, ṣùgbọ́n ọwọ́ rẹ̀ nà jáde síbẹ̀.

5 A! Ássíríà, ọ̀gọ́ ìbínú mi, àti ọ̀pá ọwọ́ wọn ni ìrúnú wọn.

6 Èmi ó rán an sí orílẹ-èdè àgàbàgebè, àti sí àwọn ènìyàn ìbínú mi ni èmi ó pàṣẹ kan láti ko ìkógun, àti láti mú ohun ọdẹ, àti láti tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ bí ẹrẹ̀ ní ìgboro.

7 Ṣùgbọ́n òun kò rò bẹ̃, bẹ̃ni ọkàn rẹ̀ kò rò bẹ̃; ṣùgbọ́n ó wà ní ọkàn láti parun àti láti gé orílẹ̀-èdè kúrò kĩ ṣe díẹ̀.

8 Nítorí ó wípé: Ọba kọ́ ni àwọn ọmọ-aládé mi ha jẹ́ pátápátá bí?

9 Kálnò kò ha dàbí Karkemíṣì? Hámátì kò ha dàbí Arpádì? Samáríà kò ha dàbí Damáskù?

10 Gẹ́gẹ́bí ọwọ́ mi ti dá àwọn ìjọba àwọn ère nì, ère èyí tí ó ju ti Jerúsálẹ́mù àti ti Samáríà lọ;

11 Èmi kì yíò ha, bí èmi ti ṣe sí Samáríà àti àwọn ère rẹ̀, ṣe bẹ̃ sí Jerúsálẹ́mù àti àwọn ère rẹ̀ bí?

12 Nítorí-èyi yíò sì ṣe pé nígbàtí Olúwa ti ṣe gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ lórí Òkè Síónì àti lórí Jerúsálẹ́mù, èmi yíò bá èso àyà líle ọba Assíríà wí, àti ògo ìwọ gíga rẹ̀.

13 Nítorí ó wípé: Nípa agbára ọwọ́ mi àti nípa ọgbọ́n mi ni èmi ti ṣe àwọn ohun wọ̀nyí; nítorí èmi mòye; èmi sì ti mú àlà àwọn ènìyàn kúrò, èmi sì ti jí ìṣura wọn, èmi sì ti sọ àwọn olùgbé nã kalẹ̀ bí alágbára ọkùnrin;

14 Ọwọ́ mi sì ti rí bí ìtẹ́ ẹyẹ kan ọrọ̀ àwọn ènìyàn; àti gẹgẹbí ẹní pé ẹnìkan nkó ẹyin tí ó kù jọ ní èmi ti kó gbogbo ayé jọ; kò sí ẹni tí ó gbọn ìyẹ́, tàbí tí ó ya ẹnu, tàbí tí ó dún.

15 Àáké ha lè fọ́nnu sí ẹni tí nfi í la igi? Ayùn ha lè gbé ara rẹ̀ ga sí ẹni tí nmì í? Bí ẹni pé ọ̀gọ lè mi ara rẹ̀ sí àwọn tí ó gbé e sókè, tàbí bí ẹni pé ọ̀pá lè gbé ara rẹ̀ sókè bí ẹni pé kì í ṣe igi!

16 Nítorínã ni Olúwa, Olúwa àwọn Ọmọ-ogun, yíò rán sí ãrin àwọn tirẹ̀ tí ó sanra, rírù; àti lábẹ́ ògo rẹ̀ yíò dá jíjó kan bí jíjó iná.

17 Ìmọ́lẹ̀ Isráẹ́lì yíò sì jẹ́ iná, àti Ẹní Mímọ́ rẹ̀ yíò jẹ́ ọ̀wọ́-iná, yíò sì jò yíò sì jẹ ẹ̀gún rẹ̀ àti ẹwọn rẹ̀ run ní ọjọ́ kan;

18 Yíò sì jó ògo igbó rẹ̀ run, àti pápá oko eleso rẹ̀, àti ọkàn àti ara; wọn yíò sì dàbí ìgbà tí ọlọ́págún bá dákú.

19 Ìyókù igi igbó rẹ̀ yíò sì jẹ́ díẹ̀, tí ọmọdé yíò lè kọ̀wé wọn.

20 Yíò sì ṣe ní ọjọ́ nã, tí ìyókù Isráẹ́lì, àti irú àwọn tí ó sálà ní ilé Jákọ́bù, kì yíò tún dúró ti ẹni tí ó lù wọ́n mọ́, ṣùgbọ́n wọn yíò duro ti Olúwa, Ẹní Mímọ́ Isráẹ́lì, ní òtítọ́.

21 Àwọn ìyókù yíò padà, bẹ̃ni, àní àwọn ìyókù ti Jákọ́bù, sí Ọlọ́run alágbára.

22 Nítorí bí ènìyàn rẹ Isráẹ́lì bá dàbí iyanrìn òkun, síbẹ̀ ìyókù nínú wọn yíò padà; àṣẹ ìparun nã yíò kún àkúnwọ́-sìlẹ̀ nínú òdodo.

23 Nítorí Olúwa Ọlọ́run àwọn Ọmọ-ogun yíò ṣe ìparun, àní ìpinnu ní ilẹ̀ gbogbo.

24 Nítorínã, báyĩ ni Olúwa Ọlọ́run àwọn Ọmọ-ogun wí: A! ẹ̀yin ènìyàn mi tí ngbé Síónì, ẹ má bẹ̀rù àwọn ará Assíríà; òun yíò lù ọ́ pẹ̀lú ọ̀gọ, yíò sì gbé ọ̀pá rẹ̀ sókè sí ọ, gẹ́gẹ́bí irú ti Égíptì.

25 Nítorí níwọ̀n ìgbà díẹ̀ kíún, ìrunú yíò sì tan, àti ìbínú mi nínú ìparun wọn.

26 Olúwa àwọn Ọmọ-ogun yíò sì gbé pàṣán kan sókè fún un gẹ́gẹ́bí ìpakúpa ti Mídíánì ní àpáta Órébù; àti gẹ́gẹ́bí ọ̀gọ rẹ̀ sójú òkun, bẹ̃ni yíò gbé e sókè gẹ́gẹ́bí irú ti Égíptì.

27 Yíò sì ṣe ní ọjọ́ nã tí a ó gbé ẹrù rẹ̀ kúrò ní èjìká rẹ, àti àjàgà rẹ̀ kúrò ní ọrùn rẹ, a ó sì pa àjàgà nã run nítorí yíyàn ní àmì òróró.

28 Òun ti dé sí Aíátì, òun ti kọjá sí Mígrónì; ní Míkmaṣì ni òun ti ko ẹrù-ogun rẹ̀ jọ sí.

29 Wọ́n ti rékọjá ọ̀nà nã; wọ́n ti gba ibùwọ̀ wọn ní Gébà; Rámà bẹ̀rù; Gíbéà ti Saulù ti sá.

30 Gbé ohùn rẹ sókè, A! ọmọbìnrin Gállímù; mú kí á gbọ́ ọ de Láíṣì, A! òtòṣì Anatótì.

31 A yọ Madménà nípò; àwọn olùgbé Gébímù kó ara wọn jọ láti sá.

32 Yíò dúró síbẹ̀ ní Nóbù ní ọjọ́ nã; òun yíò sì mi ọwọ́ rẹ̀ sí òkè gíga ọmọbìnrin Síónì, òkè kékeré Jerúsálẹ́mù.

33 Kíyèsĩ i, Olúwa, Olúwa àwọn Ọmọ-ogun yíò wọ́n ẹ̀ka pẹ̀lú ẹ̀rù; àti àwọn tí ó ga ní ìnà ni ó gé kúrò; àti àwọn agbéraga ni a ó rẹ̀ sílẹ̀.

34 Òun yíò sì gé pàntírí igbó lu ilẹ̀ pẹ̀lú irin, Lẹ́bánọ́nì yíò sì ṣubú nípa alágbára kan.