Àwọn Ìwé Mímọ́
2 Nífáì 19


Ori 19

Isaiah sọ̀rọ̀ bí i Messia—Àwọn ènìyàn inú òkùnkùn yíò rí ìmọ́lẹ̀ nlá—A bí ọmọ kan fún wa—Òun yíò jẹ́ Ọmọ-Aládé Àlãfíà yíò sì jọba lórí ìtẹ́-ọba Dáfídì—Fi Isaiah 9 wé e. Ní ìwọ̀n ọdún 559 sí 545 kí á tó bí Olúwa wa.

1 Bíótilẹ̀ríbẹ̃, ìṣújú nã kì yíò rí gẹ́gẹ́bí ó tí wà ní ìbínú rẹ̀, nígbàtí ní ìṣãjú ó mú ìpọ́njú wá sí ilẹ̀ Sébúlónì jẹ́jẹ́, àti ilẹ̀ Náftálì, àti lẹ́hìnnã o mu ìpọ́njú wá tí ó mú ni kẹ́dùn jùlọ nípa ọ̀nà Òkun Pupa níhà ẹkùn Jordánì ní Gálílì àwọn orílẹ̀-èdè.

2 Àwọm ènìyàn tí wọn rìn ní òkùnkùn ti rí ìmọ́lẹ̀ nlá; àwọn tí ngbé ilẹ̀ òjìji ikú, lórí wọn ni ìmọ́lẹ̀ mọ́ sí.

3 Ìwọ ti mú orílẹ̀-èdè nì bí sí i púpọ̀-púpọ̀, ìwọ sì sọ ayọ̀ di púpọ̀—wọ́n nyọ̀ níwájú rẹ gẹ́gẹ́bí ayọ̀ ìkórè, àti bí ènìyán ti í yọ̀ nígbàtí wọ́n bá pín ìkógun.

4 Nítorí ìwọ ṣẹ́ àjàgà ìnira rẹ̀, àti ọ̀pá èjìká rẹ̀, ọ̀gọ aninilára rẹ̀.

5 Nítorí gbogbo ìjà àwọn ológun ni ó wà pẹ̀lú ariwo rúdurùdu, àti aṣọ tí a yí nínú ẹ̀jẹ̀; ṣùgbọ́n èyí yíò jẹ́ fún ìjóná àti igi iná.

6 Nítorí a bí ọmọ kan fún wa, a fi ọmọkùnrin kan fún wa; ìjọba yíò sì wà ní èjìká rẹ̀; a ó sì ma pe orúkọ rẹ̀ ní, Ìyanu, Olùdámọ̀ràn, Ọlọ́run Alágbára, Bàbá Ayérayé, Ọmọ-Aládé Àlãfíà.

7 Níti ìbísí ìjọba rẹ̀ àti àlãfíà kò sí òpin, lórí ìtẹ́ Dáfídì, àti lórí ìjọba rẹ̀ láti má a tọ́ ọ, àti láti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pẹ̀lú ìdájọ́ àti pẹ̀lú àìsègbè láti ìsisìyí lọ, àní títí láé. Ìtara Olúwa àwọn Ọmọ-ogun yíò ṣe èyí.

8 Olúwa rán ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí Jákọ́bù ó sì ti bà lé Isráẹ́lì.

9 Gbogbo ènìyàn yíò sì mọ̀, àní Efráímù àti àwọn olùgbé Samáríà, tí nwí nínú ìgbéraga àti líle àyà pé:

10 Awọn bíríkì ṣubù lu ilẹ̀, ṣùgbọ́n àwa ó fi òkúta gbígbẹ́ mọ́ ọ́; a gé igi síkámórè lu ilẹ̀, ṣùgbọ́n a ó fi igi kédárì pãrọ̀ wọn.

11 Nítorínã ni Olúwa yíò gbé àwọn aninilára Résínì dìde sí i, yíò sì da àwọn ọ̀tá rẹ̀ pọ̀;

12 Àwọn ará Síríà níwájú àti àwọn Filístínì lẹ́hìn; wọn yíò sì jẹ Isráẹ́lì run pẹ̀lú ẹnu ṣíṣí. Fún gbogbo èyí ìbínú rẹ̀ kò yí kúrò, ṣùgbọ́n ọwọ́ rẹ̀ nà jáde síbẹ̀.

13 Nítorí àwọn ènìyàn nã kò yípadà sí ẹni tí ó lù wọ́n, bẹ̃ni wọn kò wá Olúwa àwọn Ọmọ-ogun.

14 Nítorínã ni Olúwa yíò gé kúrò ní Isráẹ́lì orí àti ìrú, ẹ̀ka igi àti koríko-odò ní ọjọ́ kan.

15 Àgbà, òun ni orí; àti wòlĩ tí nkọ́ ni ní èké, òun ni ìrù.

16 Nítorí àwọn olórí ènìyàn yí mú wọn ṣìnà; àwọn tí a sì tọ́ sí ọ̀nà nípa àwọn wọ̀nyí ni a parun.

17 Nítorínã ni Olúwa kì yíò ṣe ní ayọ̀ nínú àwọn ọ̀dọ́-ọmọkùnrin wọn, bẹ̃ni kì yíò ṣãnú fún àwọn aláìníbaba àti opó wọn; nítorí olúkúlùkù wọn jẹ́ àgàbàgebè àti olùṣe búburú, olúkúlùkù ẹnu sì nsọ wèrè. Fún gbogbo èyí ìbínú rẹ̀ kò yí kúrò, ṣùgbọ́n ọwọ́ rẹ̀ nà jáde síbẹ̀.

18 Nítorí ìwà-búburú njó bí iná; yíò jó ẹ̀wọ̀n àti ẹ̀gún run, yíò sì ràn nínú pàntírí igbó, wọn yíò sì gòkè lọ bí gbígbé sókè ẽfín.

19 Nípa ìbínú Olúwa àwọn Ọmọ-ogun ni ilẹ̀ fi ṣókùnkùn, àwọn ènìyàn yíò dàbí igi iná; ẹnìkan kì yíò dá arákùnrin rẹ̀ sí.

20 Òun yíò sì jájẹ ní ọwọ́ ọ̀tún ebi yíò sì pa á; òun yíò sì jẹ ní ọwọ́ òsì wọn kì yíò sì yó; wọn yíò jẹ olúkúlùkù ènìyàn ẹran-ara apá rẹ̀—

21 Mánássè, Efráímù; àti Efráímù, Mánássè; àwọn méjẽjì yíò dojúkọ Júdà. Fún gbogbo èyí ìbínú rẹ̀ kò yí kúrò, ṣùgbọ́n ọwọ́ rẹ̀ nà jáde síbẹ̀.