Àwọn Ìwé Mímọ́
2 Nífáì 23


Ori 23

Ìparun Bábílọ́nì jẹ́ irú ìparun ní ìgbà Bíbọ̀ Èkejì—Yíò jẹ́ ọjọ́ ìbínú àti ẹ̀san—Bábílọ́nì (ayé) yíò ṣubú títí láé—Fi Isaiah 13 wé e. Ní ìwọ̀n ọdún 559 sí 545 kí á tó bí Olúwa wa.

1 Àjàgà Bábílọ́nì, èyí tí Isaiah ọmọ Ámósì ọkùnrin rí.

2 Ẹ gbé ọ̀págun sókè lórí òkè gíga, ẹ gbé ohùn ga sí wọn, ẹ ju ọwọ́, kí wọ́n bá lè lọ sínú ẹnu-odi àwọn ọlọ́lá.

3 Èmi ti pàṣẹ fún àwọn tèmi tí a yà sí mímọ́, èmi ti pe àwọn alágbára mi pẹ̀lú, nítorí ìbínú mi kò sí lórí àwọn tí nyọ̀ nínú ọlánlá mi.

4 Ariwo ọ̀pọ̀lọpọ̀ lórí òkè gíga gẹ́gẹ́bí ti ènìyàn púpọ̀, ariwo rúdurùdu ti ìjọba àwọn orílẹ̀-èdè tí a kójọ pọ̀, Olúwa àwọn Ọmọ-ogun gbá ogun àwọn ọmọ ogun jọ.

5 Wọ́n ti orílẹ̀ èdè òkèrè wá, láti ìpẹ̀kun ọ̀run, bẹ̃ni, Olúwa, àti ohun-èlò ìbínú rẹ̀, láti pa gbogbo ilẹ̀ run.

6 Ẹ hó, nítorí ọjọ́ Olúwa kù sí dẹ̀dẹ̀; yíò dé bí ìparun láti ọ̀dọ̀ Olódùmarè wá.

7 Nítorínã gbogbo ọwọ́ yíò rọ, àyà olúkúlùkù ènìyàn yíò já;

8 Wọn ó sì bẹ̀rù; ìrora àti ìrora-ọkàn yíò dì wọ́n mú; ẹnu yíò yà ẹnìkan sí ẹnìkejì rẹ̀; ojú wọn yíò dàbí ọ̀wọ́-iná.

9 Kíyèsĩ i, ọjọ́ Olúwa mbọ̀wá, ó ní ibi àti pẹ̀lú ìkọnnú àti ìbínú gbígbóná, láti sọ ilẹ̀ nã di ahoro; òun yíò sì pa àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ run kúrò nínú rẹ̀.

10 Nítorí àwọn ìràwọ̀ ọ̀run àti ìṣùpọ̀-ìràwọ̀ inú rẹ̀ kì yíò tan ìmọ́lẹ̀ wọn; õrùn yíò ṣòkùnkùn ní ìjádelọ rẹ̀, òṣùpá kì yíò sì mú kì ìmọ́lè rẹ̀ tàn.

11 Èmi ó sì fi ayé jìyà fún ibi, àti àwọn ènìyàn búburú fún àìṣedẽdé wọn; èmi ó mú kí ìgbéraga àwọn agbéraga kí ó mọ, èmi ó sì rẹ ìréra àwọn ènìyàn tí ó banilẹ́rù sílẹ̀.

12 Èmi yíò mú kí ènìyàn kan ṣọ̀wọ́n ju wúrà dídára; àní ènìyàn kan ju wúrà Ófírì dáradára.

13 Nítorínã, èmi ó mú àwọn ọ̀run mì-tìtì, ilẹ̀ ayé yíò sì ṣípò rẹ̀ padà, nínú ìbínú Olúwa àwọn Ọmọ-ogun, àti ní ọjọ́ ìbínú gbígbóná rẹ̀.

14 Yíò sì dàbí abo àgbọ̀nrín tí à nlépa, àti bí àgùntàn tí ẹnìkan kò gbájọ; olúkúlùkù wọn yíò sì yípadà sí ènìyàn rẹ̀, olúkúlùkù yíò sì sálọ sí ilẹ̀ rẹ̀.

15 Gbogbo ẹni tí ó bá gbéraga ni a ó tanù; bẹ̃ni, gbogbo ẹni tí ó bá da ara pọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn búburú ni yíò sì ṣubú nípa idà.

16 Àwọn ọmọ wọn, ni a ó fọ́ tũtú ní ójú ara wọn pẹ̀lú; a ó sì kó wọn ní ilé, a ó sì fi agbára mú àwọn aya wọn.

17 Kíyèsĩ i, èmi ó gbé àwọn ará Médíà dìde sí wọn, tí kì yíò ka fàdákà àti wúrà sí, tí kì yíò sì ní inú dídùn sí i.

18 Ọrún wọn pẹ̀lú yíò fọ́ àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin tũtú; wọn kì yíò sì ṣe ãnú fún èso inú; ojú wọn kì yíò dá ọmọdé sí.

19 Àti Bábílọ́nì, ògo ìjọba gbogbo, ẹwà ìtayọ Káldéà, yíò dàbí ìgbà tí Ọlọ́run bí Sódómù àti Gòmórrà ṣubú.

20 A kì yíò tẹ̀ ẹ́ dó mọ, bẹ̃ni a kì yíò sì gbé ibẹ̀ mọ́ láti ìran dé ìran: bẹ̃ni àwọn ará Arábíà kì yíò pàgọ́ níbẹ̀ mọ; bẹ̃ni àwọn olùṣọ́-àgùntàn kì yíò kọ́ agbo wọn níbẹ̀ mọ́.

21 Ṣùgbọ́n ẹranko ìgbẹ yíò dùbúlẹ̀ níbẹ̀; ilé wọn yíò sì kún fún àwọn ẹ̀dá tí nké; àwọn òwìwí yíò sì ma gbé ibẹ̀, àwọn ọ̀rọ̀ yíò sì ma jó níbẹ̀.

22 Àwọn ẹranko ìgbẹ́ ti àwọn érékùṣù yíò sì kígbe ní àwọn ilé ahoro wọn, àti drágónì nínú àwọn ãfin wọn tí ó jọjú; ìgbà rẹ̀ sì súnmọ́ etílé, a kì yíò sì fa ọjọ́ rẹ̀ gún. Nítorí èmi yíò pa á run kíákíá; bẹ̃ni, nítorí èmi yíò ní ãnú sí àwọn ènìyàn mi, ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn búburú yíò parun.