Àwọn Ìwé Mímọ́
2 Nífáì 2


Ori 2

Ìràpadà nwá nípasẹ̀ Messia Mímọ́—Òmìnira níti yíyàn (ìṣojúẹni) ṣe pàtàkì sí wíwà láyé àti ìlọ̀síwájú—Ádámù ṣubú kí àwọn ènìyàn lè wà—Àwọn ènìyàn ní òmìnira láti yan ìdásílẹ̀ àti ìyè àìnípẹ̀kun. Ní ìwọ̀n ọdún 588 sí 570 kí á tó bí Olúwa wa.

1 Àti nísisìyí, Jákọ́bù, èmi wí fún ọ: Ìwọ jẹ́ àkọ́bí mi ní àwọn ọjọ́ wàhálà mi nínú ijù. Sì kíyèsĩ i, ní ìgbà èwe rẹ ìwọ ti ní ìpọ́njú àti ìrora-ọkàn púpọ̀, nítorí ti ìwàkúwà àwọn arákùnrin rẹ.

2 Bíótilẹ̀ríbẹ̃, Jákọ́bù, àkọ́bí mi ní ijù, ìwọ mọ́ títóbi Ọlọ́run; òun yíò sì ya ípọ́njú rẹ sí mímọ́ fun èrè rẹ.

3 Nítorí-èyi, ọkàn rẹ ni a ó bùkún fún, ìwọ yíò sì gbé láìléwu pẹ̀lú arákùnrin rẹ, Nífáì; àwọn ọjọ́ rẹ ni ìwọ yíò sì lò nínú iṣẹ́-ìsìn Ọlọ́run rẹ. Nítorí-èyi èmi mọ̀ pé a ti rà ọ́ padà, nítorí ti òdodo Olùràpadà rẹ; nítorí ìwọ ti kíyèsĩ i pé ní kíkún àkókò ó mbọ̀wá láti mú ìgbàlà wá fún àwọn ènìyàn.

4 Ìwọ sì ti kíyèsĩ i ní èwe rẹ, ògo rẹ̀; nítorí-èyi, a bùkún fun ọ àní gẹ́gẹ́bí àwọn ẹni tí òun yíò ṣe ìránṣẹ sí nínú ara; nítorí Ẹ̀mí nã jẹ́ ọ̀kannã, ní àná, ní òní, àti títí láé. A sì pèsè ọ̀nà kúrò nínú ìṣubú ènìyàn, ìgbàlà sì jẹ́ ọ̀fẹ́.

5 Àwọn ènìyàn ni a sì kọ́ tó kí wọ́n mọ́ rere kúrò ní ibi. A sì fi òfin nã fún àwọn ènìyàn. Nípasẹ̀ òfin nã kò sì sí ẹran ara tí a dá láre; tàbí, nípasẹ̀ òfin nã ni a ké àwọn ènìyàn kúrò. Bẹ̃ni, nípasẹ̀ òfin ti ayé yí ni a fi ké wọn kúrò; àti pẹ̀lú, nípasẹ̀ òfin ti ẹ̀mí wọ́n parun kúrò nínú èyí tí ó jẹ́ rere, wọ́n sì di òtòṣì títí láé.

6 Nítorí-èyi, ìràpadà mbọ̀wá nínú àti nípasẹ̀ Messia Mímọ́ nã; nítorí ó kún fún õre-ọ̀fẹ́ àti òtítọ́.

7 Kíyèsĩ i, ó fi ara rẹ̀ silẹ bi ẹbọ fún ẹ̀sẹ̀, lati dahun àwọn ohun ti òfin bẽrè, fun gbogbo àwọn wọnnì tí ó ní ìrora ọkàn àti ẹ̀mí ìròbìnújẹ́; kò sì sí àwọn míràn tí o lè dáhùn àwọn ohun ti òfin bẽrè.

8 Nítorí-èyi, báwo ni pàtàkì látí sọ àwọn ohun wọ̀nyí di mímọ̀ sí àwọn olùgbé ayé ṣe tóbi tó, kí wọ́n lè mọ̀ wípé kò sí ẹran ara tí ó lè gbé níwájú Ọlọ́run, àfi tí ó bá jẹ́ nípa àṣepé, àti ãnú, àti ore ọ̀fẹ́ ti Messia Mímọ́, ẹni tí ó fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ gẹ́gẹ́bí ti ẹran ara, tí ó sì tún gbà á nípa agbára Ẹ̀mí, kí ó le mú àjínde òkú wá ṣẹ, tí ó jẹ́ ẹni èkíní tí yíò jínde.

9 Nítorí-èyi, òun jẹ́ èso àkọ́so fún Ọlọ́run, níwọ̀n bí òun yíò tí bẹ ẹ̀bẹ̀ fún gbogbo àwọn ọmọ ènìyàn; àwọn tí ó bá sì gbàgbọ nínú rẹ̀ ni a o gbàlà.

10 Àti nítorí ti ẹ̀bẹ̀ fun olúkúlùkù, gbogbo ènìyàn wá sọ́dọ̀ Ọlọ́run; nítorí-èyi, wọ́n dúró níwájú rẹ̀, kí á lè ṣe ìdájọ́ nípasẹ̀ rẹ̀ gẹ́gẹ́bí òtítọ́ àti ìwà mímọ́ èyítí ó wà nínú rẹ̀. Nítorí-èyi, àwọn òpin òfin èyí tí Ẹní Mímọ́ nã ti fún ni, sí fífi ìyà èyí tí a ti fi lélẹ̀, ìyà èyí tí a fi lélẹ̀ tí ó wà ní àtakò sí ti àlãfíà èyí tí a fi lélẹ̀, láti dáhùn òpin ètùtù—

11 Nítorí o di dandan, pé kí àtakò wà ní ohun gbogbo. Bí kò bá jẹ́ bẹ̃, àkọ́bí mi nínú ijù, a kò lè mú òdodo wá sí ṣíṣe, bẹ̃ni ìwà búburú, bẹ̃ni ìwà mímọ́ tàbí òṣì, bẹ̃ni rere tàbí búburú. Nítorí-èyi, ohun gbogbo di dandan ki wọ́n jẹ́ ìdàlù ní ọ̀kan; nítorí-èyi, bí yíò bá jẹ́ ara kan kò lè ṣe àìdúró bí ti òkú, tí kò ní ẹ̀mí bẹ̃ni ikú, tàbí ìdìbàjẹ́ tàbí àìdìbàjẹ́, àlãfíà tàbí òṣì, bẹ̃ni òye tàbí àìmọ̀.

12 Nítorí-èyi, a níláti da a fún ohun asán; nítorí-èyi ìbá má sí ète ní òpin ẹ̀dá rẹ̀. Nítorí-èyi, ohun yí níláti pa ọgbọ́n Ọlọ́run àti àwọn ète ayérayé rẹ̀ run, àti pẹ̀lú agbára, àti ãnú, àti àìṣègbè Ọlọ́run.

13 Bí ẹ̀yin bá sì wí pé kò sí òfin, ẹ̀yin yíò wí pẹ̀lú pé kò sí ẹ̀ṣẹ̀. Bí ẹ̀yin bá wí pé kò sí ẹ̀ṣẹ̀, ẹ̀yin yíò wí pẹ̀lú pé kò sí òdodo. Bí kò bá sì sí òdodo kò sí inúdídùn. Bí kò bá sì sí òdodo tàbí inúdídùn kò sí ibáwí tàbí òṣì. Bí àwọn ohun wọ̀nyí kò bá sì wà kò sí Ọlọ́run. Bí Ọlọ́run kò bá sì wà àwa kò sí, bẹ̃ni ayé; nítorí ìbá má sí ẹ̀dá àwọn ohun, bẹ̃ni láti ṣe tàbí láti lè ṣe sí; nítorí-èyi, ohun gbogbo níláti di òfo.

14 Àti nísisìyí, ẹ̀yin ọmọkùnrin mi, mo wí fún yín àwọn ohun wọ̀nyí fún èrè àti ẹ̀kọ́ yín; nítorí Ọlọ́run kan wà, ó sì ti dá ohun gbogbo, pẹ̀lú àwọn ọ̀run àti ayé, àti ohun gbogbo tí ó wà nínú wọn, pẹ̀lú àwọn ohun láti ṣe àti àwọn ohun láti lè ṣe iṣẹ́ lé lórí.

15 Láti sì mú ète ayérayé rẹ̀ ní òpin ènìyàn ṣẹ, lẹ́hìn tí ó ti dá àwọn òbí wa èkíní, àti àwọn ẹranko ìgbẹ́ àti àwọn ẹyẹ ojú sánmà, àti ní akotan, gbogbo ohun èyí tí a dá, ó di dandan kí àtakò wà; àní èso tí a kà lẽwọ̀ ní àtakò sí igi ìyè; tí ọ̀kan dùn tí èkejì sì korò.

16 Nítorí-èyi, Olúwa Ọlọ́run fi fún ènìyàn kí ó lè ṣe ohunkóhun fúnrarẹ̀. Nítorí-èyi, ènìyàn kò lè ṣe fúnrarẹ̀ àfi tí ó bá jẹ́ pé a tàn án nípasẹ̀ ọ̀kan tàbí èkejì.

17 Èmi, Léhì, gẹ́gẹ́bí àwọn ohun èyí tí mo ti kà, kò sì lè ṣe àì ṣèbí pé angẹ́lì Ọlọ́run kan, gẹ́gẹ́bí èyí tí a kọ, ti ṣubú láti ọ̀run wá; nítorí-èyi, ó di èṣù, nítorí tí ó ti wá ohun èyí tí ó burú níwájú Ọlọ́run.

18 Nítorí tí ó sì ti ṣubú láti ọ̀run wá, tí ó sì ti di òtòṣì títí láé, ó wá òṣì gbogbo aráyé pẹ̀lú. Nítorí-èyi, ó wí fún Éfà, bẹ̃ni, àní ejò láéláé nì, ẹni tí ó jẹ́ èṣù, ẹni tí ó jẹ́ bàbá gbogbo èké, nítorí-èyi ó wípé: Jẹ nínú èso tí a kà lẽwọ̀ nã, ìwọ kì yíò sì kú, ṣùgbọ́n ìwọ yíò dàbí Ọlọ́run, ní mímọ̀ rere àti búburú.

19 Lẹ́hìn tí Ádámù àti Éfà sì ti jẹ nínú èso tí a kà lẽwọ̀ nã, a lé wọn jáde kúrò ní ọgbà Édẹ́nì, láti ro ilẹ̀.

20 Wọ́n sì ti mú àwọn ọmọ jáde wá; bẹ̃ni, àní ìdílé gbogbo ayé.

21 Àwọn ọjọ́ àwọn ọmọ ènìyàn ni a sì fà gùn, gẹ́gẹ́bí ìfẹ́ Ọlọ́run, pé kí wọ́n lè ronúpìwàdà níwọ̀n ìgbà ti wọ́n bá wà nínú ẹran ara; nítorí-èyi, ipò wọn di ipò ìdánwò, a sì mú àkókò wọn pẹ́, gẹ́gẹ́bí àwọn òfin èyí tí Olúwa Ọlọ́run fi fún àwọn ọmọ ènìyàn. Nítorí ó fi òfin fún ni kí gbogbo ènìyàn lè ronúpìwàdà; nítorí tí ó fihàn sí gbogbo ènìyàn pé wọ́n ti sọnù, nítorí ìrékojá àwọn òbí wọn.

22 Àti nísisìyí, kíyèsĩ i, bí ó bá ṣe pé Ádámù kò ti rékọjá òun ìbá má ti ṣubú, ṣùgbọ́n òun ìbá ti wà nínú ọgbà Édẹ́nì. Gbogbo ohun èyí tí a dá ìbá sì tì wà ní ipò kannã nínú èyí tí wọ́n wà lẹ́hìn tí a dá wọn; wọn ìbá sì ti wà títí láé, tí wọn kò sì ní ní òpin.

23 Wọn ìbá má sì ti ní àwọn ọmọ; nítorí-èyi wọn ìbá ti dúró ní ipò àìlẹ́ṣẹ̀, tí wọn kò ní ayọ̀, nítorí wọn kò mọ́ òṣì; tí wọn kò ṣe rere, nítorí wọn kò mọ́ ẹ̀ṣẹ̀.

24 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ i, ohun gbogbo ni a ti ṣe ní ọgbọ́n rẹ̀ ẹni tí ó mọ́ ohun gbogbo.

25 Ádámù ṣubù kí àwọn ènìyàn lè wà; àwọn ènìyàn sì wà, kí wọ́n lè ní ayọ̀.

26 Messia sì mbọ̀wá ní kíkún àkókò, kí ó lè ra àwọn ọmọ ènìyàn padà kúrò ní ìṣubú nì. Àti nítorí tí a sì ti rà wọ́n padà kúrò ní ìṣubú nì wọ́n ti di òmìnira títí láé, ní mímọ́ rere kúrò ní búburú; láti ṣe fúnrawọn kì í ṣe kí á sì mú wọn ṣe, àfi tí ó bá jẹ́ nípasẹ̀ ìjìyà òfin ní ọjọ́ nlá àti ti ìkẹhìn, gẹ́gẹ́bí àwọn òfin èyí tí Ọlọ́run ti fi fún ni.

27 Nítorí-èyi, àwọn ènìyàn wà ní òmìnira nípa ti ara; ohun gbogbo ni a sì fi fún wọn tí ó jẹ́ yíyẹ fún ènìyàn. Wọ́n sì wà ní òmìnira láti yan ìdásílẹ̀ àti ìyè àìnípẹ̀kun, nípa Onílàjà nlá ti gbogbo ènìyàn, tàbí láti yan ìgbèkùn àti ikú, gẹ́gẹ́bí ìgbèkùn àti agbára ti èṣù; nítorí ó nwá kí gbogbo ènìyàn lè di òtòṣì bí ti ara rẹ̀.

28 Àti nísisìyí, ẹ̀yin ọmọkùnrin mi, èmi fẹ́ kí ẹ̀yin kí ó gbé ojú sókè sí Onílàjà nlá nã, kí ẹ sì fetísílẹ̀ sí àwọn òfin nlá rẹ̀; kí ẹ sì jẹ́ olóotọ́ sí àwọn ọ̀rọ̀ rẹ, kí ẹ sì yan ìyè àìnípẹ̀kun, gẹ́gẹ́bí ìfẹ́ Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ̀;

29 Kí ẹ má sì ṣe yan ikú ayérayé, gẹ́gẹ́bí ìfẹ́ ti ara àti búburú èyí tí mbẹ nínú rẹ̀, èyí tí ó fún ẹ̀mí èṣù ní agbára láti dì nígbèkùn, láti mú yin sọ̀kalẹ̀ sínú ọ̀run àpãdì, pe kí ó lè jọba lórí yín ní ìjọba tirẹ̀.

30 Èmi ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ díẹ̀ wọ̀nyí sí gbogbo yín, ẹyin ọmọkùnrin mi, ní àwọn ọjọ́ ìdánwò mi ìkẹhìn; èmi sì ti yan ipa-ọ̀nà rere, gẹ́gẹ́bí àwọn ọ̀rọ̀ wòlĩ nã. Èmi kò sì ní ohun míràn tí mo gbé ka iwájú bíkòṣe ti àlãfíà ọkàn yín títí ayé. Àmín.