Àwọn Ìwé Mímọ́
2 Nífáì 7


Ori 7

Isaiah sọ̀rọ̀ bí ti Messia—Messia nã yíò ní ahọ́n amòye—Òun yíò fi ẹ̀hìn rẹ̀ fún àwọn aluni—A kì yíò dãmú rẹ̀—Fi Isaiah 50 wé e. Ní ìwọ̀n ọdún 559 sí 545 kí á tó bí Olúwa wa.

1 Bẹ̃ni, nítorí báyĩ ni Olúwa wí: Èmi ti kọ̀ yín sílẹ̀ bí, tàbí èmi ti sọ yín nù kúrò títí láé bí? Nítorí báyĩ ni Olúwa wí: Níbo ni ìwé ìkọ̀sílẹ̀ ìyá yín gbé wà? Tani ẹni tí mo kọ̀ yín sílẹ̀ fún, tàbí tani nínú àwọn onígbèsè mi ni mo tà yín fún? Bẹ̃ni, tani ẹni tí mo tà yín fun? Kíyèsĩ i, nítorí àwọn àìṣe dẽdé yin ni ẹ̀yin ti ta ara yín, àti nítorí àwọn ìrékọjá yín ni a ṣe kọ ìyá yín sílẹ̀.

2 Nítorí-èyi, nígbàtí mo dé, kò sí ẹnìkan; nígbàtí mo pè, bẹ̃ni, kò sí ẹnìkan láti dáhùn. A! ará ilé Isráẹ́lì, ọwọ́ mi ha kúrú tóbẹ̃ tí kò fi lè ràpadà bí, tàbí èmi kò ha ní agbára láti gba ni bí? Kíyèsĩ i ní ìbáwí mi mo gbẹ òkun, mo sọ odò nlá wọn di ijù àti ẹja wọn láti rùn nítorí tí àwọn omi nì ti gbẹ, wọ́n sì kú nítorí ti òùngbẹ.

3 Mo fi ohun dúdú wọ àwọn ọ̀run, mo sì fi aṣọ ọ̀fọ̀ ṣe ìbora wọn.

4 Olúwa Ọlọ́run ti fi ahọ́n amòye fún mi, kí èmi kí ó lè mọ̀ bí a ti í sọ̀rọ̀ ní àkókò sí yín, A! ará ilé Isráẹ́lì. Nígbàtí ẹ̀yin bá ni ãrẹ̀ ó njí yin ní òròwúrọ̀. Ó ṣí mi ní etí láti gbọ́ bí amòye.

5 Olúwa Ọlọ́run ti ṣí mi ní etí, èmi kò sì ṣe àìgbọ́ràn, bẹ̃ni èmi kò yípadà.

6 Mo fi ẹ̀hìn mi fún aluni nã, àti ẹ̀rẹ̀kẹ́ mi fún àwọn tí ntu irun. Èmi kò pa ojú mi mọ́ kúrò nínú ìtìjú àti ìtutọ́ sí.

7 Nítorí Olúwa Ọlọ́run yíò ràn mí lọ́wọ́, nítorí-èyi èmi kì yíò dãmú. Nítorí-èyi ni mo ṣe gbé ojú mi ró bí òkúta líle, èmi sì mọ̀ pé ojú kì yíò ti mí.

8 Olúwa sì wà ní tòsí, ó sì dá mi láre. Tani yíò bá mi jà? Ẹ jẹ́ kí á dúró pọ̀. Tani í ṣe ẹlẹ́jọ́ mi? Jẹ́ kí ó súnmọ mi, èmi yíò sì lù ú pẹ̀lú agbára ẹnu mi.

9 Nítorí Olúwa Ọlọ́run yíò ràn mí lọ́wọ́. Gbogbo àwọn tí yíò sì dá mi ní ẹ̀bi, kíyèsĩ i, gbogbo wọn yíò di ogbó bí ẹ̀wù, kòkòrò yíò sì jẹ wọ́n run.

10 Tani nínú yín tí ó bẹ̀rù Olúwa, tí ó gba ohùn ìránṣẹ́ rẹ̀ gbọ́, tí nrìn nínú òkùnkùn tí kò sì ní ìmọ́lẹ̀?

11 Kíyèsĩ i gbogbo èyín tí ó dá iná, tí ẹ fi ẹta iná yí ara yín ká, ẹ máa rìn nínú ìmọ́lẹ̀ iná yín àti nínú ẹta iná tí ẹ ti dá. Èyí ni yíò jẹ́ ohun tí ó wá láti ọwọ́ mi—ẹ̀yin yíò dùbúlẹ̀ nínú ìrora-ọkàn.