Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Òni Yí
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2022


Òní Yí

Wòlíì alààyè wa nsa ipá rẹ̀ láti kún ilẹ̀ ayé pẹ̀lú Ìwé ti Mọ́mọ́nì. A gbọ́dọ̀ tẹ̀lé ìdarí rẹ̀.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì gbólóhùn náà “òní yí”1 ni a lò léraléra láti pe àkíyèsí sí ìmọ̀ràn, àwọn ìlérí, àti àwọn ìkọ́ni. Ọba Bẹ́njámínì, nínú ọ̀rọ̀ ìparí rẹ̀, kìlọ̀ fún àwọn ènìyàn náà pé, “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi èyí tí èmi yíò wí fún yín ní òní yí; … kí ẹ ṣí etí yín àti ọkàn yín kí ẹ lè ní òye, àti inú yín, kí ohùn ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run lè di kedere ní iwájú yin.”2 Ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò jẹ́ àgbékalẹ̀ irúkannáà. A wá láti gbọ́ ìmọ̀ràn fún “òní yí,” pé kí a lè jẹ́ “olotitọ ní gbogbo ìgbà”3 sí Olúwa àti ìhìnrere Rẹ̀. Títẹ̀ mọ́ mi ní “òní yí” ni pàtàkì títún ìfarasìn wa ṣe sí Ìwé ti Mọ́mọ́nì, èyí tí Joseph Smith pè ní “ìwé pípé jùlọ nínú eyikeyi lórí ilẹ̀ ayé.”4

Àwòrán
Ẹdà Ìwé ti Mọ́mọ́nì ti Alàgbà Rasband

Mo di ẹ̀dà Ìwé ti Mọ́mọ́nì kan mú ní ọwọ́ mi. Èyí ni àtẹ̀jáde 1970 ọjọ́un, ó sí níyelórí sí mi. Nípa ìwò rẹ̀ ó ti gbó ó sì ti já, ṣùgbọ́n kò sí ìwé míràn tí ó ṣe pàtàkì sí ayé mi àti ẹ̀rí mi bí èyí yìí. Ní kíkà á mo jèrè ẹ̀rí kan nípa Ẹ̀mí pé Jésù Krístì ni Ọmọ Ọlọ́run,5 pé Òun ni Olùgbàlà mi,6 pé àwọn ìwé mímọ́ wọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run,7 àti pé ìhìnrere ni a múpadàbòsípò.8 Àwọn òtítọ́ wọnnì jinlẹ gidi nínú mi. Bí wòlíì Nefi ti wí pé, “Ọkàn mi yọ nínú àwọn ohun Olúwa.”9

Àwòrán
Alàgbà Rasband pẹ̀lú ààrẹ míṣọ̀n rẹ̀ àti Alàgbà Hanks

Òsì sí ọ̀tún: Alàgbà Ronald A. Rasband, ìránṣẹ́ ìhìnrere ọ̀dọ́; Ààrẹ Harold Wilkinson, ààrẹ ti Míṣọ̀n a`wọn Ìpínlẹ̀ Ìlà-oòrùn; àti Alàgbà Marion D. Hanks, Aláṣẹ Gbogbo Àádọ́rin.

Nihin ni ìtàn àtẹ̀hìnwá. Gẹ́gẹ́bí ọ̀dọ́ ìránṣẹ́ ìhìnrere kan, mo gba ìmọ̀ràn Alàgbà Marion D. Hanks,10ẹnití ó bẹ̀ wá wò ní Míṣọ̀n àwọn Ìpínlẹ̀ Ìlà-oòrùn. Òun ni ààrẹ Tẹ́lẹ̀ ti Míṣọ̀n British, àwọn méjì lára àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere rẹ̀ sì wà nijoko ní òní yí: àwọn arákùnrin mi ọ̀wọ́n Alàgbà Jeffrey R. Holland àti Alàgbà Quentin L. Cook.11 Gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere ní England, ó pè wá níjà láti ka ẹ̀dà Ìwé ti Mọ́mọ́nì tí kò ní àmìn ní ìgbà méjì ó kéréjù. Mo gbá iṣẹ́ náà. Ní kíkà àkọ́kọ́ mo níláti fàmì tàbí ìlà sí ohun gbogbo tí ó nawọ́ sí tàbí tí ó jẹ́ ẹ̀rí nípa Jésù Krístì. Mo lo lẹ́ẹ̀dì pupa kan, mo sì fa ìlà sí àwọn ẹsẹ púpọ̀. Ní ìgbà kejì, Alàgbà Hanks wípé kí nsàmì sí àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ àti ẹ̀kọ́ ìhìnrere, àti pé ní àkokò yí mo lo àwọ̀ rẹ́súrẹ́sú láti fi àmi sí àwọn ìwè mímọ́. Mo ka Ìwé ti Mọ́mọ́nì lẹ́ẹ̀mejì, bí a ti gbàmọ̀ràn, àti pé lẹ́hìnnáà ìgbà méjì síi ní lílo yẹ́lò àti dúdú láti fi àmì sí àwọn ẹsẹ tí ó farahàn sí mi.12 Bí ẹ ti ri, mo ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìfàmisí.

Àwòrán
Agbára ti Ìwé Mọ́mọ́nì

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì wà ní kíkà mi ju fífi àmì sí àwọn ìwé mímọ́. Pẹ̀lú kíká kọ̀ọ̀kan nípa Ìwé ti Mọ́mọ́nì, ní iwájú sí ẹ̀hìn, mo kún fún ìfẹ́ ìjìnlẹ̀ fún Olúwa. Mo ní ìmọ̀lára ìjìnlẹ̀ tí ó wọnú òtítọ́ àwọn ìkọ́ni Rẹ̀ àti bí a ṣe nlò wọ́n di “òní yí.” Ìwé yí bá àkọlé rẹ̀ mu, “Ẹ̀rí Míràn ti Jésù Krístì.”13 Pẹ̀lú àṣàrò náà àti ẹ̀rí ti ẹ̀mí tí mo gbà, mo di ìránṣẹ́ ìhìnrere Ìwé ti Mọ́mọ́nì àti ọmọẹ̀hìn Jésù Krístì.14

“Òní yí,” ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere títóbijùlọ ti Ìwé ti Mọ́mọ́nì ni Ààrẹ Russell M. Nelson. Nígbàtí a ṣẹ̀ṣẹ̀ pè é bí Àpóstélì titun, ó nfúnni ní ẹ̀kọ́ ní Accra, Ghana.15 Ní ijoko ni àwọn ọlọ́lá, pẹ̀lú ọba ọ̀kọlà Áfríkà kan, pẹ̀lú ẹnití ó sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ onítumọ̀ kan. Ọba náà jẹ́ akẹkọ pàtàkì ti Bíbélì ó sì nifẹ Olúwa. Títẹ̀lé àwọn ọ̀rọ̀, ọba náà dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, ẹnití ó sì bèèrè ní èdè Òyìnbó pípé, pé “Tani ìwọ jẹ́?” Ààrẹ Nelson ṣàlàyé pé òun jẹ́ “Àpóstélì Jésù Krístì kan tí a yàn.”16 Ìbèèrè ọba tó kan ni “kíni o lè kọ́ mi nípa Jésù Krístì?”17

Ààrẹ Nelson nawọ́ sí Ìwé ti Mọ́mọ́nì ó sì ṣí i lọ sí 3 Nefi 11. Lápapọ̀ Ààrẹ Nelson àti ọba ka ìwàásù Olùgbàlà sí àwọn ará Néfì: “Kíyèsi, Èmi ni Jésù Krístì, ẹnití àwọn wòlíì jẹri pe yíò wá sínú ayé. … Èmi ni ìmọ́lẹ̀ àti ìyè ayé.”18

Ààrẹ Nelson fi ẹ̀bún fún ọba náà pẹ̀lú ẹ̀dà Ìwé ti Mọ́mọ́nì ọba náà si fèsì, “O lè ti fún mi ni idẹ tàbí iyùn, ṣùgbọ́n kò sí ohun tí ó níyelórí sí mi ju àfikún ìmọ̀ yí nípa Olúwa Jésù Krístì.”19

Èyí kìí ṣe àpẹrẹ kanṣoṣo ti bí olólùfẹ́ wòlíì wa ti pín Ìwé ti Mọ́mọ́nì. Òun ti fi àwọn ẹ̀dà Ìwé ti Mọ́mọ́nì fún ọgọọgọrun àwọn ènìyàn, tí wọ́n njẹ̀rí rẹ̀ nípa Jésù Krístì nígbàgbogbo. Nígbàtí Ààrẹ Nelson pàdé àwọn àlejò, ààrẹ, ọba, ààrẹ orílẹ̀-èdè, olórí ìṣòwò àti àwọn ìṣètò àti onírurú onígbàgbọ́, bóyá ní olú-ìlú Ìjọ tàbí nínú ibùgbé ti arawọn, ó fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ fi ẹ̀bùn iwé ti ìwé mímọ́ ti a fihàn yí fúnni. Ó lè ti fún wọn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ohun tí a wé ní ríbọ̀n tí ó lè joko lórí tábìlì tàbí àga tàbí nínú àpótí bí ìrántí ìbẹ̀wò rẹ̀. Dípò bẹ́ẹ̀, ó fi ohun tí ó níyelórí sí i fún un, tí ó kọjá iyùn àti idẹ, bí ọba ọ̀kọlà ti júwe.

“Àwọn òtítọ́ Ìwé ti Mọ́mọ́nì,” Ààrẹ Nelson ti wípé, “ó ní agbára láti wòsàn, tùnínú, múpadàbọ̀sípò, tùlára, fúnlókun, pẹ̀tùsí, àti mú ìyárí bá ẹ̀mí wa.”20 Mo ti wòó bí àwọn ẹ̀dà Ìwé ti Mọ́mọ́nì wọ̀nyí ti wà nínú ọwọ́ àwọn ẹnití ó gbà wọ́n láti ọwọ́ wòlíì Ọlọ́run wa. Kò sí ẹ̀bùn tí ó tòbí ju èyí lọ.

Àwòrán
Ààrẹ Nelson pẹ̀lú ìyàwó àarẹ ti Gambíà

Ní àìpẹ́ jọjọ ó pàdé pẹ̀lú obìnrin àkọ́kọ́ ti Gambia ní ibi-iṣẹ́ rẹ̀ ó sì fi ìrẹ̀lẹ̀ fún un ní Ìwé ti Mọ́mọ́nì kan. Kò dúró níbẹ̀. Ó ṣí àwọn ojú-ewé láti kà pẹ̀lú rẹ̀, láti kọ́ àti láti jẹri nípa Jésù Krístì, Ètùtù Rẹ̀, àti ìfẹ́ Rẹ̀ fún gbogbo àwọn ọmọ Rẹ̀—níbigbogbo.

Wòlíì alààyè wa nsa ipá rẹ̀ láti kún ilẹ̀ ayé pẹ̀lú Ìwé ti Mọ́mọ́nì.21 Ṣùgbọ́n òun kò lè dá ṣí ṣíṣàn ọ̀nà náà. A gbọ́dọ̀ tẹ̀lé ìdarí rẹ̀.

Níní ìmísí nípa àpẹrẹ rẹ̀, mo ti gbìyànjú láti fi ìrẹ̀lẹ̀ àti ìtara sí pín Ìwé ti Mọ́mọ́nì síi.

Àwòrán
Alàgbà Rasband pẹ̀lú ààrẹ ti Mozambique

Láìpẹ́ mo wà nínú ìfúni-níṣẹ́ ṣe ní Mozambique. Àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè rírẹwà yí tí wọ́n ntiraka pẹ̀lú, ìṣẹ́, ìlera àìdáa, àìníṣẹ́, ìjì, àti ìjà òṣèlú. Èmi ní iyì pípàdé pẹ̀lú ààrẹ orílẹ̀-èdè náà, Filipe Nyusi. Ní ìbèèrè rẹ̀, mo gbàdúrà fún un àti orílẹ̀-èdè rẹ̀; mo wí fun pé a nkọ́ tẹ́mpìlì Jésù Krístì kan22 ní orílẹ̀-èdè yí. Ní òpin ìbẹ̀wò wa, mo fun ní ẹ̀dà Ìwé ti Mọ́mọ́nì kan ní Portuguese, èdè àbínibí rẹ̀. Bí a ṣe nfi ìmoore tẹ́wọ́gba ìwé náà, mo jẹri ìrètí àti ìlérí fún àwọn ènìyàn rẹ̀, tí a rí nínú àwọn ọ̀rọ̀ Olúwa ní àwọn ojú-ewé rẹ̀.23

Àwòrán
Alàgbà Rasband pẹ̀lú ọba àti ayaba ti Lesotho

Ní ìgbà míràn, ìyàwó mi, Melanie, àti èmi pàdé Ọba àti Olorì Letsie III ti Lesotho ní ilé wọn.24 Fún wa, àmìn ìbẹ̀wò wa ni fífún wọn ní ẹ̀dà Ìwé ti Mọ́mọ́nì nígbànáà kí a sì pín ẹ̀rí wa. Nígbàtí mo bá wo ẹ̀hìn lórí ìrírí náà àti àwọn míràn, ẹsẹ kan ti ìwé mímọ́ ọjọ́-ìkẹhìn wá sí ọkàn mi: “Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhìnrere mi ni a lè kéde nípa àwọn ohun àìlera àti ìrọ̀rùn sí àwọn òpin ayé, àti níwájú àwọn ọba àti alakoso.”25

Àwòrán
Alàgbà Rasband pẹ̀lú Aṣojú-orílẹ̀ èdè Pandey
Àwòrán
Àwọn olùdarí Ijọ pẹ̀lú Pátríákì Mímọ́ Bartolóméù

Mo ti pín Ìwé ti Mọ́mọ́nì pẹ̀lú Aṣojú Ìjọba ti India Pandey26; sí United Nations ní Geneva àti pẹ̀lú Ẹnimímọ́ Nnì Patriarch Bartholomew27 ti Ìjọ Ìlà-oòrùn Àtijọ́ àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn míràn. Mo ti ní ìmọ̀lára Ẹ̀mí Olúwa pẹ̀lú wa bí mo ti fúnra mi fi “òkúta-ìṣíkà ẹ̀sìn wa”28 ó sì jẹ́ ẹ̀rí mi nípa Jésù Krístì, òkúta igun ìgbàgbọ́ wa.29

Ẹ kò ní láti lọ sí Mozambique tàbí India tàbí pàdé pẹ̀lú àwọn ọba àti alakoso láti fún ẹnìkan ní ìwé yí ti àwọn ìkọ́ni àti ìlérí mímọ́. Mo pè yín, ní òní yí, láti fi Ìwé ti Mọ́mọ́nì kan fún àwọn ọ̀rẹ́ àti ẹbí yín, àwọn ará ibi iṣẹ́, olùdarí bọ́ọ̀lù yín, tàbí ọkùnrin olùdákòwò ní ọjà yín. Wọ́n nílò àwọn ọ̀rọ̀ Olúwa tí a rí nínú ìwé yí. Wọ́n nílò àwọn ìdáhùn sí ìbèèrè ìgbé ayé ojojúmọ́ àti ìyè ayérayé tí ó nbọ̀. Wọ́n nílò láti mọ̀ nípa ipa ọ̀nà májẹ̀mú tí a gbẹ́kalẹ̀ níwájú wọn àti ìfẹ́ ìbánigbé Olúwa fún wọn. Gbogbo rẹ̀ wà nihin nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì.

Nígbàtí ẹ bá fún wọn ní Ìwé ti Mọ́mọ́nì kan, ẹ̀ nṣí ọkàn àti inú wọn sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ẹ kò ní láti gbé àwọn ẹ̀dà títẹ́ ìwé náà pẹ̀lú yín. Ẹ lè pín in nírọ̀rùn látinú fóònù àgbéká látinú ibi titun áàpù Ìkàwé Ìhìnrere.30

Ẹ ronú nípa gbogbo ẹni tí ó lè di alábùkún nípa ìhìnrere nínú ayé wọn, kí ẹ sì fi ẹ̀dà ránṣẹ́ sí wọ́n nígbànáà látinú fóònù yín. Ẹ rántí láti fi ẹ̀rí yín pẹ̀lú àti bí ìwé náà ti bùkún ìgbé ayé yín.

Ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n, bí Àpóstélì Olúwa kan, mo nawọ́ ìpè mi lẹ́ẹ̀kansíi láti tẹ̀lé olólùfẹ́ wòlíì wa, Ààrẹ Nelson, ní kíkún ilẹ̀ ayé pẹ̀lú Ìwé ti Mọ́mọ́nì. Àìní náà pọ̀ gidi; a nílò láti gbé ìgbẹ́sẹ̀ yí nísisìyí. Mo ṣe ìlérí fún yín pé ẹ ó kópa nínú “iṣẹ́ títóbijùlọ lórí ilẹ̀ ayé,” Kíkójọ Ísráẹ́lì,31bí ẹ ti nní ìmísí láti nawọ́ jáde sí àwọn tí a ti “pa òtítọ́ mọ́ kúrò fún nítorí wọn kò mọ ibi tí wọ́n ó ti ríi.”32 Wọ́n nílò ijẹri àti ẹ̀rí yín nípa bí ìwé yí ti yí ìgbé ayé yín padà àti láti fà yín súnmọ́ Ọlọ́run síi,33 àtì “ìròhìn ayọ̀ nlá rẹ̀.”34

Mo jẹ́ ẹ̀rí pé nípa àwòṣe tọ̀run Ìwé ti Mọ́mọ́nì ni a múra rẹ̀ sílẹ̀ ní Amẹ́ríkà àtijọ́ láti jáde wá láti kéde ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, láti mú àwọn ẹ̀mí wá sọ́dọ̀ Jésù Krístì àti ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere Rẹ̀ ní “òní yí.” Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́

  1. Wo Jacob 2:2–3; Mosiah 2:14, 30; 5:7; Alma 7:15; àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹsẹ míràn nínú Ìwe ti Mọ́mọ́nì.

  2. Mòsíàh 2:9.

  3. Álmà 53:20.

  4. Àwọn Ìkọ́ni ti Àwọn Ààre Ìjọ: Joseph Smith (2007), 284. Ìsọ̀rọ̀ kíkún tí a fúnni nípasẹ̀ Joseph Smith November 28, 1841, nínú ìgbìmọ̀ pẹ̀lú àwọn Àpóstélì Méjìlá: “Mo wí fún àawọn arákùnrin pé Ìwé ti Mọ́mọ́nì ni ó péye ju ìwé kankan lórí ilẹ̀ ayé, òun sì ni okúta ìpìlẹ̀ ti ẹ̀sìn wa, àti pé ènìyàn yíò súnmọ́ Ọlọ́run si nípa ìlànà rẹ̀, ju ìwé eyikeyi lọ” (wo Àkọọ́lẹ̀-ìtàn Ìjọ4:461). Kókó ìtọ́kasí “títọ́” ni a lè kà sí ìfihàn tí a gbà nínú ìtumọ̀ rẹ̀ àti ẹ̀kọ́ tí a kọ́ni nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì tí ó ṣe àgbékalẹ̀ ju ìwé kankan míràn “kedere àti iyebíye” àwọn òtítọ̀ ìhìnrere (wo 1 Néfì 13:40

  5. Wo “Krístì Alààyè: Ẹ̀rí àwọn Àpóstélììkéde kan láti ọwọ́ Àjọ Ààrẹ Ìkínní àti Iyejú àwọn Àpóstélì Méjìlá, January 1, 2000: “A jẹ́ ẹ̀rí, bí àwọn Àpóstélì tí a yàn tòótọ́—pé Jésù ni Krístì Alààyè, Ọmọ àìkú Ọlọ́run. Òun ni Ọba nlá Ìmmánúẹ́lì, ẹni ti ó dúró ni òní ní ọwọ́ ọ̀tún Baba Rẹ̀. Òun ni ìmọ́lẹ̀, ìyè, àti ìrẹ̀tí ti ayé. Ọ̀nà Rẹ̀ ni ipa ọ̀nà tí ó darí sí ìdùnnú nínú ayé yí àti ìyè ayérayé ní ayé tó nbọ̀. Kí a dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún ẹ̀bùn àìláfiwé ti Ọmọ Àtọ̀runwá Rẹ̀” (ChurchofJesusChrist.org).

  6. Wo Isaiah 49:26; 1 Nefi 21:26; 22:12; Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 66:1.

  7. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni a rí nínú àwọn ìwé mímọ́. Fún àpẹrẹ, nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì, Lámánì àti Lẹ́múẹ́lì bèèrè, “Kíni ohun tí ọ̀pá irin túmọ̀ sí?” ní títọ́ka sí àlá Léhì. Néfì fèsì, “Ó jẹ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run; ẹnikẹ́ni tí ó bá sì fetísílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí ó sì dì í mú, kì yíò ṣègbé láé; bẹ̃ni ìdánwò àti àwọn ọfà iná èṣù kò lè borí wọn sí ìfọ́jù, láti tọ́ wọn kúrò sí ìparun” (1 Nefi 15:23–24).

  8. Wo “Ìmúpadàbọ̀sípò Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Ìhìnrere Jésù Krístì: Ìkédé Igba Ọdún Kan sí Àgbáyé,” èyí pẹ̀lú ìwọ̀nyí: “A kéde pé Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, tí a ṣètò ní April 6, 1830, Ìjọ Májẹ̀mú Titun Krístì tí a mú padàbọ̀sípò. Ìjọ yí ni ó rọ̀mọ́ ìgbé ayé pípé ti olórí igun-òkúta, Jésù Krístì, àti Ètùtù Àìlópin Rẹ̀ àti bí ọ̀rọ̀ Àjíìnde. Jésù Krístì ti pe àwọn Àpọ́stélì lẹ́ẹ̀kansi ó sì ti fún wọn ní àṣẹ oyèàlùfáà. O pe gbogbo wa láti wá sọ́dọ̀ Rẹ̀ àti Ìjọ Rẹ̀, láti gba Ẹ̀mí Mímọ́, àwọn ìlànà ìgbàlà, àti láti jèrè ayọ pípẹ́. A fi tayọ̀-tayọ̀ kéde pé ìlérí Ìmúpadàbọ̀sípò nlọ síwájú nípasẹ̀ ìtẹ̀síwájú ìfihàn. Ilẹ̀ ayé kò ní rí bákannáà mọ́ láé, bí ó ti jẹ́ pé Ọlọ́run yíò ‘kó ohun gbogbo papọ̀ ní ọ̀kan nínú Krístì’ (Ephesians 1:10)” (ChurchofJesusChrist.org).

  9. 2 Nefi 4:16.

  10. Wo Quentin L. Cook, “Ẹ Máṣe Jẹ́ Kí Ó Rẹ̀ Yín ní Ṣíṣe RereBrigham Young University devotional, Aug. 24, 2020), speeches.byu.edu; “Ọ̀sẹ̀ Yí Lórí Àwùjọ: Bí a ó ṣe Gbèrú Ìfẹ́ fún Olúwa, Arayín àti àwọn Míràn,” Ìròhìn ÌjọJuly 17, 2020.

  11. Kíka kẹ́ta, yẹ́lò: ìmọ̀ inú ilẹ̀ tàbí ìmọ̀ ayé; kíkà kẹ́rin, dúdú: ìlà-ìtàn Ìwé ti Mọ́mọ́nì.

  12. “Ẹ̀rí Míràn Ti Jésù Krístì” ni a fi kún bí àkọlé àtúnkọ sí gbogbo àtẹ̀jáde Ìwé ti Mọ́mọ́nì. Àwọn olórí Ìjọ ṣe orúkọ yíyípadà láti tẹnumọ èrò ti ìwé náà bí a ti sọ síwájúsi ní àkọlé ewé: “Àti bákannáà láti pàrọwà sí Jew àti Gentile pé Jésù ni Krístì, Ọlọ́run Ayérayé, ní fífi ararẹ̀ hàn sí gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè.”

  13. Jíjẹ́ ọmọẹ̀hìn Jésù Krístì ni ìfihàn ìfẹ́ wa fún Un. Àwọn ọmọẹ̀hìn ni a ti rìbọmi; wọ́n gbé orúkọ Jésù Krístì lé ara wọn; wọ́n tiraka láti tẹ̀lé E nípa rírọ̀mọ́ àwọn ìwà Rẹ̀ bí a ti júwe nípasẹ̀ Àpóstélì Pétérù: “Ẹ máṣe àìsimi, ẹ fi ìwà rere kún ìgbàgbọ́; àti ìmọ̀ kún ìwà rere; àti àìrékọjá kún ìmọ̀; àti sùúrù kún àìrékọjá; àti sùúrù kún ìwà bí Ọlọ́run; àti ìwa bí Ọlọ́run kún ìfẹ́; àti ìfẹ́ kún ìfẹ́ ọmọnìkejì” (2 Peter 1:5–7; bákannáà wo Wàásù Ìhìnrere Mi: Atọ́nà kan sí Iṣẹ́-ìsìn Ìránṣẹ́ Ìhìnrere [2019], 121–32).

  14. Ààrẹ Russell M. Nelson, internationally known heart surgeon before his call to the Quorum of the Twelve Apostles in 1984, gave a lecture at a medical school in Accra, Ghana, in 1986 on the history of heart surgery. Interviewed later by the media, he explained he was there as a ”servant of the Lord to help [the people] become better citizens, to build strong families, to gain true happiness, and prosper in the land.” He returned to Accra, Ghana, November 16, 2001, for the groundbreaking of the Accra Ghana Temple (Wo“Ground Broken for First Temple in West Africa,” Church NewsNov. 24, 2001).

  15. Wo Ìwé Ìléwọ́ Gbogbogbò: Sísìn nínú Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, 5.1.1.1In our day, the Lord calls men through the President of the Church to be ordained as Apostles and to serve in the Quorum of the Twelve Apostles (wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 18:26–28ChurchofJesusChrist.org).

  16. Wo Russell M. Nelson, “Ìwé ti Mọ́mọ́nì: Kíni Ìgbé Ayé Rẹ̀ Yíò Jẹ́ Láìsí Rẹ̀?,” LiahonaNov. 2017, 60.

  17. 3 Néfì 11:10–11

  18. Russell M. Nelson, “Ìwé ti Mọ́mọ́nì: Kíni Ìgbé Ayé Rẹ̀ Yíò Jẹ́ Láìsí Rẹ̀?61.

  19. Russell M. Nelson, “Ìwé ti Mọ́mọ́nì: Kíni Ìgbé Ayé Rẹ̀ Yíò Jẹ́ Láìsí Rẹ̀62.

  20. Wo Mose 7:62

  21. The Beira Mozambique Temple was announced April 4, 2021, by President Russell M. Nelson. More than half a million people live in Beira, which lies on the coast of the Indian Ocean.

  22. Àwọn Àpẹrẹ ìrètí àti ìlérí tí a rí nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì pẹ̀lú 2 Nefi 31:20; Jacob 4:4–6; Alma 13:28–29; 22:16; 34:41; Ether 12:32; Moroni 7:41; 8:26

  23. Alàgbà àti arábìnrin Rasband pàdé pẹ̀lú ẹbí ọba ní February 10, 2020, when on assignment in Africa to dedicate the Durban South Africa Temple.

  24. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 1:19

  25. Alàgbà Rasband met with Ambassador Indra Mani Pandey, Permanent Representative of India to the United Nations and Other International Organizations in Geneva, while on assignment to the Interfaith Forum in Bologna, Italy, on September 17, 2021.

  26. Alàgbà Rasband met with His All Holiness Ecumenical Patriarch Bartholomew of the Eastern Orthodox Church while on assignment to the Interfaith Forum in Bologna, Italy, on September 13, 2021.

  27. Àwọn Ìkọ́ni: Joseph Smith, 64. A keystone is a wedge-shaped piece of masonry that sits at the crown of an arch holding the other pieces in place. The Prophet Joseph described the Book of Mormon as “the keystone of our religion” because of its importance in uniting the Church through principles and ordinances. Ìwé ti Mọ́mọ́nì dúró bí “keystone” for the lives of members, helping them stay firmly on the covenant path.

  28. Wo Éfésù 4:11–14. Jesus Christ is the chief cornerstone of our Church, which bears His name. Just as the laying of a cornerstone at the temple is symbolic of the main stone forming the corner of the foundation of God’s house, Jesus Christ is the cornerstone of our faith and our salvation. He gave His life that we might live; there is none equal to Him in strength, in purpose, or in love.

  29. You can share it from your mobile phone. One way is by opening the Gospel Library app, going to the Scriptures collection, and then tapping “Share Now” at the top. Or from within the Book of Mormon app, you can tap the “Share” icon, which displays a QR code that a friend can easily scan using his or her phone.

  30. Russell M. Nelson, “Ìrètí of Israelì” worldwide youth devotional, June 3, 2018), HopeofIsrael.ChurchofJesusChrist.org. “On June 3, 2018, President Russell M. Nelson and his wife, Wendy W. Nelson, invited the youth to ‘enlist in the youth battalion of the Lord’ and take part in ‘the greatest challenge, the greatest cause, and the greatest work on earth.’ Kíni ohun tí ó sì jẹ́ ìpènija tí ó tóbijùlọ? The gathering of Israel” (Charlotte Larcabal, “A Call to Enlist and Gather Israel,” New Era, Mar. 2019, 24).

  31. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 123:12

  32. Wo 2 Nephi 4:27; Mosiah 4:3; 15:18; Alma 46:12

  33. 1 Néfì 13:37