Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Tọkàn-tọkàn
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2022


Tọkàn-tọkàn

A níláti jẹ́ àtẹ̀lé Jésù tí ó jẹ́ aláyọ̀ àti tí ó ní ọkàn kàn nínú ìrìnàjò ti jíjẹ́ ọmọ-ẹ̀hìn araẹni wa.

Nígbàmíràn, ó máa nṣèrànwọ́ láti mọ ohun tí a nretí

Sísúnmọ́ ìparí iṣẹ́ ìránṣẹ́ Rẹ̀, Jésù sọ fún àwọn Àpóstélì Rẹ̀ pé àwọn àkókò líle yío wá. Ṣùgbọ́n Ó sọ bákannáà pé, “Ẹ ríi pé kí ẹ máse dààmú.”1 Bẹ́ẹ̀ni, Òun yío lọ, ṣùgbọ́n Òun kì yío fi wọ́n sílẹ̀.2 Òun yío rán Ẹmí Rẹ̀ láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti rántí, láti dúró ṣinṣin, àti láti rí àlàáfíà. Èyí ṣe àpèjúwe pé Olùgbàlà mú ìlérí Rẹ̀ ṣẹ láti wà pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀hìn Rẹ̀, ṣùgbọ́n a gbọ́dọ̀ máa wò Ó láìsinmi láti rànwa lọ́wọ́ dá A mọ̀ kí a sì gbádùn ìwàníbẹ̀ Rẹ̀

Àwọn ọmọ-ẹ̀hìn Krístì ti fi ìgbà gbogbo dojúkọ àwọn àkókò líle.

Ọrẹ́ mi ọ̀wọ́n kan fi ọ̀rọ̀ kíkọ́ àtijọ́ kan ránṣẹ́ sími láti inú Nebraska Advertiser, ìwé ìròhìn kan láti Midwestern United States, ti Oṣù Keje, 1857. Ó kà pé: “Ní òwùrọ̀ yí ní kùtùkùtù ẹgbẹ́ àwọn Mọ́mọ́nì kan kọjá níhĩn nínú ìrìn àjò wọn lọ sí Salt Lake. Àwọn obìnrin (tí kò jẹ́ ẹlẹ́gẹ́ láti dáni lójú) nyí ọmọlánke bíiti ẹrànkò, obìnrin [kan] ṣubú sílẹ̀ nínú ẹrọ̀fọ̀ dúdú yí èyí tí ó mú ìdádúró díẹ̀ ní títòlọ wá, àwọn ọmọdé nlọ lẹgẹ nínú aṣọ [àjèjì] wọn tí wọ́n nípinnu bíiti àwọn ìyá wọn.”3

Mo ti ronú púpọ̀ nípa obìnrin tí ẹrọ̀fọ̀ ti mù tán yi. Kínní ṣe tí ó ndá nìkan fà? Njẹ́ ànìkanwà ìyá ni bí? Kinni ó fún un ní okun àtinúwá, ìgboyà, ìfaradà láti rin irú ìrìnàjò ríronilára bẹ́ẹ̀ la ẹ̀rọ̀fọ̀ já, ní fífa gbogbo ohun tí ó ní nínú ọmọlanke kan lọ sí ibùgbé inú aginjù àìmọ̀ kan—ní ṣíṣe yẹ̀yẹ́ wọn nípasẹ̀ àwọn olùwòràn ní ìgbà míràn?4

Ààrẹ Joseph F. Smith sọ nípa okun àwọn obìnrin aṣaájú wọ̀nyí, ó wípé: “Njẹ́ ẹ le yí ọ̀kan ẹnìkan nínú àwọn obìnrin wọ̀nyí kúrò nínú ìgbàgbọ́ wọn nínú Ìjọ Jésù Krístì ti awọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn bí? Njẹ́ ẹ le mú iyè inú wọn dúdú sí iṣẹ́ ìhìnrere ti Wòlíì Joseph Smith? Njẹ́ ẹ le fọ́ wọn lójú pẹ̀lú ìtọ́ka sí iṣẹ́ ìhìnrere àtọ̀runwá ti Jésù Krístì, Ọmọ Ọlọ́run. Rárá, láe ní ayé yi ẹ kò le ṣe é. Kínìdí? Nítorípé wọ́n mọ̀ ọ́n. Ọlọ́run fi hàn sí wọn, ó sì yé wọn, kò sì sí agbára kan ní orí ilẹ̀ ayé tí ó le yí wọ̀n kúrò nínú ohun tí wọ́n mọ̀ sí òtítọ́ náà.”5

Ẹyin arákùnrin àti arábìnrin, láti jẹ́ irú ọkùnrin àti obìnrin bẹ́ẹ̀ ni ìpè ọjọ́ wa—àwa ọmọ-ẹ̀hìn tí ó nṣe ìwádi jinlẹ̀ láti rí okun láti máa fà á nígbàtí a bá pè láti rìn nínú aginjù, àwa ọmọ-ẹ̀hìn pẹ̀lú ìgbàgbọ́ tí a ti fi hàn sí wa láti ọwọ́ Ọlọ́run, àwa atẹ̀lé Jésù tí ó kún fún ayọ̀ àti ọkàn-kan nínú ìrìnàjò ti araẹni wa ní jíjẹ́ ọmọ-ẹ̀hìn. Àwa bí ọmọ ẹ̀hìn Jésù Krístì, à gbàgbọ́ a sì le dàgbà nínú àwọn òtítọ́ pàtàkì mẹ́ta.

Ìkínní, A Le Tẹramọ́ Pípa Àwọn Májẹ̀mú Wa Mọ́, Àní Nígbàtí Kò Tilẹ̀ Rọrùn.

Nígbàtí ìgbàgbọ́ yín, ẹbí yín, tàbí ọjọ́ ọ̀la yín bá ní ìpèníjà—nígbàtí ó bá nyà yín lẹ́nu ìdí tí ìgbé ayé fi le tóbẹ́ẹ̀ nígbàtí ẹ nsa gbogbo ipá láti gbé ìgbé ayé ìhìnrere—ẹ rántí pé Olúwa sọ fúnwa láti retí àwọn ìdààmú. Àwọn ìdààmú jẹ́ ara ètò náà, kò sì túmọ̀ sí pé a ti kọ̀ yín sílẹ̀; wọ́n jẹ́ ara ohun tí ó tùmọ̀ sí láti jẹ́ Tirẹ̀.6 Lẹ́hìn ohun gbogbo, Òun jẹ́, “ẹni ọ̀pọ̀ ìrora-ọkàn, tí ó sì mọ́ ìbànújẹ́.”7

Mo nkọ́ ẹ̀kọ́ pé Baba Ọ̀run ní ìfẹ́ nínú ìdàgbàsókè mi bí ọmọ-ẹ̀hìn Jésù Krístì kan ju bí Ó ti ṣe pẹ̀lú ìtura mi lọ. Mo lè má tilẹ̀ fi gbogbo ìgbà fẹ́ kí ó wà báyí—ṣùgbọ́n ó nrí bẹ́ẹ̀!

Gbígbé ìgbé ayé ìrọ̀rùn kò mú agbára wá. Agbára tí a nílò láti le tako ooru ọjọ́ wa ni agbára Olúwa, agbára Rẹ̀ sì nṣàn nípasẹ̀ àwọn májẹ̀mú wa pẹ̀lú Rẹ̀.8 Láti fi ara tìí nínú pẹ̀lú ìgbàgbọ́ wa nígbàtí a bá ndojúkọ àwọn ẹ̀fúùfù líle—láti fi òtítọ́ tiraka ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan láti ṣe ohun tí a dá májẹ̀mú pẹ̀lú Olùgbàlà pé a ó ṣe, pàápàá àti nípàtàkì jùlọ nígbàtí a bá kãrẹ̀, tí a nṣe àníyàn, àti tí a ní ìjàkadì pẹ̀lú àwọn ìbéèrè àti àwọn ọ̀rọ̀ tó ndààmú ẹni—ni láti gba ìmọ́lẹ̀ Rẹ̀, okun Rẹ̀, ifẹ́ Rẹ̀, Ẹmí Rẹ̀, àlàáfíà Rẹ̀ díẹ̀díẹ̀.

Kókó rírìn ní ipá ọ̀nà májẹ̀mú ni láti dé ọ̀dọ̀ Olùgbàlà. Òun ni kókó náà, kìí ṣe ìtẹ̀síwájú pípé wa. Kìí ṣe eré ìje kan, a kò sì gbọdọ̀ fi ìrìn àjò wa wé ti àwọn ẹlòmíràn. Àní nígbàtí a bá ṣubú gan, Òun wà níbẹ̀.

Ìkejì, A Le Ṣe Ìṣe Nínú Ìgbàgbọ́.

Bíi ọmọ-ẹ̀hìn Jésù Krístì, a ní òye pé ìgbàgbọ́ nínú Rẹ̀ gba ìgbésẹ̀—pàápàá ní àwọn àkókò líle.9

Ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́hìn, àwọn òbí mi pinnu láti pààrọ̀ ẹní àtẹ́ìká ilé. Ní òru ṣaájú kí ẹní àtẹ́ìká titun tó dé, mama mi sọ fún àwọn arákùnrin mi láti gbé àwọn ohun èlò ilé kí wọn ó sì yọ àwọn ẹní àtẹ́ìká inú yàrá kúrò kí a lè tẹ́ ẹní àtẹ́ìká titún. Arábìnrin mi ẹni ọdún méje nígbànáà, Emily, ti sùn. Nítorínáà, bí ó ti sùn, wọ́n rọra kó gbogbo àwọn nkan kúrò ní yàrá rẹ̀, yàtọ̀ sí ibùsùn, wọ́n sì fa ẹní àtẹ́ẹ̀ìká ya jáde. Ó dára, bí àwọn arákùnrin àgba ti máa nṣe nígbàmíràn, wọ́n pinnu láti ṣe eré kan. Wọ́n kó gbogbo àwọn nkan rẹ̀ tó kù kúrò níbi ìkópamọ́ sí, àti lára àwọn ògiri, ní fífi yàrá náà sílẹ̀ lófo. Lẹ́hìnnáà wọ́n kọ ìwé kan wọ́n sì lẹ̀ ẹ́ mọ́ ògiri: “Emily ọ̀wọ́n, a ti lọ. A ó kọ̀wé ní ààrin ọjọ́ díẹ̀ a ó sì sọ ibití a wà. Pẹ̀lú ìfẹ́, ẹbí rẹ.”

Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì nígbàtí Emily kò wá fún oúnjẹ àárọ̀, àwọn arákùnrin mi wá a lọ—níbẹ̀ ló wà, nínú ìbànújẹ́ àti ní òun nìkan lẹ́hìn ìlẹ̀kùn pípadé. Emily ronú lórí ìrírí yí lẹ́hìnwá: “Inú bí mi. Ṣùgbọ́n kínni ìbá ṣẹlẹ̀ kání mo kàn ti ṣílẹ̀kùn? Kínni nbá ti gbọ́? Kínni nbá ti gbóòrùn? Èmi ìbá ti mọ̀ pé nkò nìkan wà. Èmi ìbá ti mọ̀ pé a fẹ́ràn mi gan an. Ìrònú náà kò tilẹ̀ wá sí ọkàn mi rárá láti ṣe ohun kan nípa ipò mi. Mo kàn juwọ́ lẹ̀ mo sì dúró nínú yàrá mi mo nsunkún. Àti síbẹ̀síbẹ̀ ká ní mo ti fi ìrọ̀rùn ṣí ìlẹ̀kùn.”10

Arábìnrin mi ti fi ìrònú rẹ̀ dá lé ohun tí ó rí, ṣùgbọ́n kìí ṣe àwòrán bí àwọn nkan ti rí gan an. Njẹ́ kò pani lẹ́rĩn pé àwa, bíi Emily, le di kikáríjọ nínú ìbànújẹ́ tàbí ìpalára tàbí ìrẹ̀wẹ̀sì tàbí àníyàn tàbí ìdánìkanwà tàbí ìbínú tàbí ìdààmú tí kò tilẹ̀ ní wá sí ọkàn wa láti ṣe nkankan, láti ṣílẹ̀kùn jẹ́jẹ́, láti ṣe ìṣe pẹ̀lú ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì?

Awọn ìwé mímọ́ kún fún àwọn àpẹrẹ àwọn ọkùnrin àti àwọn obìnrin, àwọn ọmọ-ẹ̀hìn Krístì, ẹni tí, nígbàtí wọ́n ndojúkọ àìṣeéṣe, wọ́n gbé ìgbésẹ̀—wọ́n dìde sókè nínú ìgbàgbọ́ wọ́n sì rìn.11

Sí àwọn adẹ́tẹ̀ tí ó nwá ìwòsàn, Krístì wí pé, “Ẹ lọ fi ara yín hàn fún àwọn àlùfáà. O sì ṣe, pé, bí wọ́n ti lọ, wọ́n di wíwẹ̀mọ́.”12

Wọ́n lọ láti fi ara wọn hàn sí àwọn àlùfáà bí ẹnipé a ti wò wọ́n sàn tẹ́lẹ̀, àti pé nínú ìlànà ṣíṣe ìṣe, wọ́n ṣeé.

Bákannáà mo fẹ́ sọ pé bí èrò ṣíṣe ìṣe láàrin ìrora yín bá dàbí àìṣeéṣe, ẹ jọ̀wọ́ ẹ jẹ́kí ìṣe yín jẹ́ láti nawọ́ síta fún ìrànlọ́wọ́—sí ọ̀rẹ́ kan, ọmọlẹ́bí kan, olùdarí Ijọ kan, akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ kan. Èyí le jẹ́ ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ sí ìrètí.

Ìkẹta, A Le Wà Tọkàn-Tọkàn Kí A Sì Kún Fún Ayọ̀ Nínú ìfọkànsìn Wa13

Nígbàtí àwọn àkóko líle bá wá, mo máa ngbìyànjú láti rántí pé mo yàn láti tẹ̀lé Krístì kí ntó wá sí ilẹ̀ ayé àti pé àwọn ìpèníjà sí ìgbàgbọ́ mi, ìlera mi, àti ìpamọ́ra mi gbogbo jẹ́ ara ìdí tí mo fi wà níhĩn. Àti pé dájúdájú èmi kò gbọdọ̀ rò láe pé àdánwò mi ó pe ìfẹ́ Ọlọ́run fúnmi sí ìbéèré tàbí kí ó yí ìgbàgbọ́ mi nínú Rẹ̀ sí iyèméjì. Àwọn àdánwò kò túmọ̀ sí pé ètò ti nkùnà; wọ́n jẹ́ ara ètò tí ó wà láti rànmí lọ́wọ́ wá Ọlọ́run. Mo ndàbí Rẹ̀ síi nígbàtí mo bá faradà pẹ̀lú sùúrù, àti pẹ̀lú ìrètí, bíi Òun, nígbàtí mo bá wà nínú ìrora, mo ngbàdúrà síi taratara.13

Jésù Krístì ni àpẹrẹ pípé ti fífẹ́ràn Baba wa pẹ̀lú gbogbo ọkàn Rẹ̀—ní ṣíṣe ìfẹ́ Rẹ̀, láìka ohun tó gbà sí.15 Mo fẹ́ tẹ̀lé àpẹrẹ Rẹ̀ nípa ṣíṣe ohun kannáà.

Mo ní ìmisí nípa jíjẹ́ ọmọ-ẹ̀hìn tọkàn-tọkàn, tinú-tinú ti opó náà tí ó ju owó idẹ wẹ́wẹ́ méjì sínú iṣúra tẹ́mpìlì. Ó fi gbogbo ohun tó ní sílẹ̀.14

Jésù Krístì rí ọ̀pọ̀ ti gbogbo ohun tó ní níbití àwọn ẹlòmíràn ti rí àìní rẹ̀ nìkan. Èyí kannáà jẹ́ òtítọ́ pẹ̀lú ẹnìkọ̀ọ̀kan wa. Òun kìí rí àìní wa bíi ìjákulẹ̀ ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀ bíi ànfàní láti lo ìgbàgbọ́ àti láti dàgbà.

Íparí

Ẹyin akẹgbẹ́ mi ọmọ-ẹ̀hìn Jésù Krístì, pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi, mo yàn láti dúro pẹ̀lú Olúwa. Mo yàn láti dúró pẹ̀lú àwọn àṣàyàn ìránṣẹ́ Rẹ̀—Ààrẹ Russell M. Nelson àti àwọn Àpostélì akẹgbẹ́ rẹ̀—nítorí wọ́n nsọ̀rọ̀ fún Un wọ́n sì jẹ́ olùtọ́jú ti àwọn ìlànà àti àwọn májẹ̀mú tí ó so mí pọ̀ mọ́ Olùgbàlà.

Nígbàtí mo bá ṣubú, èmi ó tẹramọ́ dídìde, ní fífi ara ti oore ọ̀fẹ́ àti agbára ìleṣe ti Jésù Krístì. Èmi ó dúró nínú májẹ̀mú mi pẹ̀lú Rẹ̀ èmi ó sì ṣiṣẹ́ la àwọn ìbéèrè mi já nípa ṣíṣe àṣàrò ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, nípa ìgbàgbọ́, àti pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ẹmí Mímọ́, ìtọ́ni ẹni tí èmi gbẹ́kẹ̀lé. Emi yío wá Ẹmí Rẹ̀ lójoojúmọ́ nípa ṣíṣe àwọn ohun kékeré tí ó sì rọrùn.

Èyí ni ipa ọ̀nà jíjẹ́ ọmọ-ẹ̀hìn.

Àti títí ọjọ́ náà tí àwọn ọgbẹ́ ayé ikú ojoojúmọ́ yío di wíwòsàn, èmi ó dúró de Olúwa èmi ó sì gbẹ́kẹ̀ lé E—àkókò Rẹ̀, ọgbọ́n Rẹ̀, ètò Rẹ̀.13

Apá nínú apá pẹ́lú yín, mo fẹ́ dúró pẹ̀lú Rẹ̀ títíláé. Tọkàn-tọkàn. Ní mímọ̀ pé nígbàtí a bá fẹ́ràn Jésù Krístì pẹ̀lú gbogbo ọkàn wa, Ó nfún wa ní ohun gbogbo ní ìdápadà.15 Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.