Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ní Ìdojúkọ Sí Tẹ́mpìlì
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2022


Ní Ìdojúkọ Sí Tẹ́mpìlì

Mo ṣe ìlérí pé àníkún àkokò nínú tẹ́mpìlì yíò bùkún ìgbé ayé yín ní àwọn ọ̀nà tí ohun míràn kò lè ṣe.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin ọ̀wọ́n, nínú àwọn abala marun títóbi ti ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò wọ̀nyí, a ti ní ìrírí pé ọ̀rùn ti ṣí lẹ́ẹ̀kansi! Mo gbàdúrà pé kí ẹ ṣe àkọsílẹ̀ àwọn ìtẹ̀mọ́ra yín kí ẹ sì mú wọn lò. Baba wa Ọ̀run àti Olólùfẹ́ Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì, dúró ní ṣíṣetán láti ràn yín lọ́wọ́. Mo rọ̀ yín láti mú ìtiraka yín pọ̀ si láti wá ìrànlọ́wọ́ Wọn.

Láìpẹ́, Arábìnrin Nelson àti èmi ní ànfàní láti tún àwọn ìràn àkokò titun kẹ́rin ti Fídíò Ìwé ti Mọ́mọ́nì wò.1 A ní ìmísí nípa wọn! Njẹ́ kí nfi díẹ̀ àyọsọ látinú ìran tí ó fi ìfarahàn Olùgbàlà sí àwọn ará Néfì hàn hàn yín.

O ṣe pàtàkì pé Olùgbàlà yàn láti farahàn sí àwọn ènìyàn ní tẹ́mpìlì. Ilé Rẹ̀ ni íṣe. Ó kún fún agbára Rẹ̀. Ẹ máṣe jẹ́ kí a sọ ìràn ohun tí Olúwa nṣe fún wa nísisìyí nù. Ó nmú àwọn tẹ́mpìlì Rẹ̀ wá sí àrọ́wọ́tó. Ó nyára àyè nínú èyítí à nkọ́ àwọn tẹ́mpìlì. Ó nṣe àníkún ìlèṣè wa láti ṣèrànwọ́ ní kíkójọ Isráẹ́lì. Bákannáà Ó nmu rọrùn fún ọ̀kọ̀ọ̀kan wa láti di títúnṣe níti ẹ̀mí. Mo ṣe ìlérí pé àníkún àkokò nínú tẹ́mpìlì yíò bùkún ìgbé ayé yín ní àwọn ọ̀nà tí ohun míràn kò lè ṣe.

A ní àwọn tẹ́mpìlì 168 tí ó nṣiṣẹ́ lọ́wọ́lọ́wọ́ àti àádọ́talémẹ́ta tẹ́mpìlì titun lábẹ́ kíkọ́ àti àádọ́talémẹ́rin míràn ní ipò àwòrán mímúra-kíkọ́!2 Inú mi dùn láti kéde awọn ètò wa láti kọ́ tẹ̀mpìlì titun kan ní ibì kọ̀ọ̀kan ìwọ̀nyí: Busan, Korea; Naga, Philippines; Santiago, Philippines; Eket, Nigeria; Chiclayo, Peru; Buenos Aires City Center, Argentina; Londrina, Brazil; Ribeirão Prêto, Brazil; Huehuetenango, Guatemala; Jacksonville, Florida; Grand Rapids, Michigan; Prosper, Texas; Lone Mountain, Nevada; àti Tacoma, Washington.

Bákannáà à nṣètò kíkọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tẹ́mpìlì ní àwọn agbègbè títóbí ìlú-nlá níbití àkokò rínrin ìrìnàjò sí tẹ́mpìlì tí ó nṣiṣẹ́ ti jẹ́ kókó ìpènijà. Nítorínáà, inú mi dùn láti kéde àfikún àwọn ibi mẹ́rin nítòsí Ìlú México níbití a ó kọ́ tẹ́mpìlì titun sí ní Cuernavaca, Pachuca, Toluca, àti Tula.

Ẹ̀yin arákùnrin ati aràbìnrin mi ọ̀wọ́n, njẹ́ kí ẹ ní ìdojúkọ sí tẹ́mpìlì ní àwọn ọ̀nà tí ẹ kò ní rí. Mo bùkún yín láti súnmọ́ Ọlọ́run àti Jésù Krístì ní dídàgbà ojojúmọ́. Mo nifẹ yín. Njẹ́ kí Ọlọ́run wà pẹ̀lú yín títí a ó tún pàdé lẹ́ẹ̀kansi, ni mo gbàdúrà ní orúkọ mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́

  1. Àwọn Fídíò titun wọ̀nyí wà nínú onírurú èdè lórí Ìkàwé Ìhìnrere àti àwọn ọ̀nà míràn. Àwọn ìràn ni a ó tẹ̀jáde ní ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ní òní lẹ́hìn ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò.

  2. Ní bíi Ọjọ́ Ìkínní Oṣù Kẹwa, 2022, àwọn tẹ́mpìlì mẹ́rin míràn ni a ti túnṣe (St. George Utah, Manti Utah, Salt Lake, àti Columbus Ohio), àwọn mẹ́ta sì ndúrò de ìyàsímímọ́ (Hamilton New Zealand, Quito Ecuador, àti Belém Brazil).