Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ṣíṣe Ìrànlọ́wọ́ Fún Tálákà àti Olùpọ́njú
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2022


Ṣíṣe Ìrànlọ́wọ́ Fún Tálákà àti Olùpọ́njú

Ìjọ Jésù Krístì nifẹ láti sin àwọn wọnnì nínú àìní, àti bákannáà ó sì nifẹ láti jinlẹ̀ ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn míràn nínú ìtiraka náà.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, àyànfẹ́ Ààrẹ Russell M. Nelson wa yíò bá wa sọ̀rọ̀ lẹ́hìnwá nínú abala yí. Ó ti ní kí njẹ́ olùsọ̀rọ̀ àkọ́kọ́.

Kókó-ọ̀rọ̀ mi lóni dálé ohun tí Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn-Mímọ́ Ọjọ́-Ìkẹhìn àti àwọn ọmọ ìjọ nfúnni tí wọ́n sì nṣe fún àwọn aláìní àti olùpọ́njú. Èmi yíò tún sọ̀rọ̀ nípa irú fífúnni bẹ́ẹ̀ nípasẹ̀ àwọn ènìyàn rere miran. Fífún àwọn tí ó ṣe aláìní jẹ́ ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ kan nínú gbogbo àwọn ẹ̀sìn ti Ábráhámù àti nínú àwọn miran pẹ̀lú.

Ní oṣù díẹ̀ sẹ́hìn, Ìjọ ti Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́ Ìkẹhìn ròhìn fún ìgbà àkọ́kọ́ bí iṣẹ́ inúrere-ọmọ ènìyàn káàkiri ayé ṣe pọ̀ tó.1 Àwọn ìnáwó wa ti 2021 fún àwọn wọ̀nnì tó ṣe aláìní ní àwọn orílẹ̀-èdè 188 ní àgbáyé jẹ́ $906 míllìọ̀nù—ó fẹ́rẹ̀ tó bílíoọ́nù kan dọ́llàr. Ní àfikún, àwọn ọmọ ìjọ wa yọ̀ọ̀da rékọjá wákàtí mẹ́fà míllìọ̀nù iṣẹ́ nínú èrò kannáà.

Bẹ́ẹ̀ni, àwọn iye jẹ́, ìròhìn àìpé ti fífúnni àti rírànnilọ́wọ́ wa. Wọn kò pẹ̀lú awọn iṣẹ́ ti ara ẹni tí àwọn ọmọ ìjọ wa nfún olúkúlukú bí wọn ti nṣe iṣẹ́-ìránṣẹ́ fún ara wọn ní àwọn ipò tí a pè àti iṣẹ́ ìsìn àtinúwá ọmọ ìjọ-sí-ọmọ ìjọ. Àti pé ìròhìn 2021 wa kò mẹ́nuba ohun tí àwọn ọmọ ìjọ wa ṣe níkọ̀ọ̀kan nipasẹ àìlónkà àwọn ìṣètò àánú tí kò ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ìjọ wa níti ìṣe. Mo bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àwọn wọ̀nyí.

Ní 1831, ọdún méjì lẹ́hìn tí a ti ṣètò Ìjọ tí a mú padàbọ̀sípò, Olúwa fúnni ní ìfihàn yí láti darí àwọn ọmọ ìjọ rẹ̀ mo, sì gbàgbọ́, pé gbogbo àwọn ọmọ Rẹ̀ ní àgbáyé:

“Kíyèsíi, kò tọ́ pé kí èmí ó pàṣẹ nínú ohun gbogbo; nítorí ẹnití a bá mú ní dandan nínú ohun gbogbo, òun kannáà jẹ́ ọ̀lẹ àti pé kìí ṣe ọlọ́gbọ́n ọmọ ọ̀dọ̀. …

“Lòotọ́ ni mo wí, ènìyàn níláti lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ rere pẹ̀lú ìtara, àtí kí wọn ó ṣe ohun púpọ làti inú ìfẹ́ ọkàn wọn, kí wọn ó sí mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ òdodo ṣẹ;

“Nitori agbara náà wà nínú wọn, nípa èyí tí wọn jẹ́ aṣojú fún ara wọn. Àti pé níwọ̀nbí àwọn ènìyàn bá ṣe rere, wọn kì yíò pàdánù èrè wọn bí ó ti wù kí ó rí.”2

Kọjá ọdún méjìdínlógójì bí Àpóstélì kan àti ní jíju ọgbọ̀n ọdún ti iṣẹ́ amòye, mo ti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìtiraka onínúrere nípasẹ̀ àwọn ìṣètò àti irú ènìyàn tí irú ìfihàn yi ṣàpèjúwe bí “èrò rere kan” àti “mí[mú] òdodo púpọ̀ wá sí ìmúṣẹ.” Àwọn àìlóhúnkà àpẹrẹ iru iṣẹ́ ìsìn inúrere-ọmọ ènìyàn bẹ́ẹ̀ ló wà káàkiri àgbáyé, kọja àwọn ààlà tiwa àti lílọ kọja ìwọ́pọ̀ imọ wa. Ní ríronú lórí èyí, mo rò nípa wòlíì Ọba Bẹ́ńjámínì ti Ìwé ti Mọ́mọ́nì, ẹni tí ìwàásù rẹ̀ wà pẹ̀lú òtítọ́ ayérayé yìí: “Nígbà tí ẹ bá wà nínú iṣẹ́ ìsìn àwọn ẹ̀dá ẹlẹgbẹ́ yín ẹ wà nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run yín nìkan.”3

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìtọ́jú àti iṣẹ́ ìsìn inúrere-ọmọ ènìyàn sí àwọn ẹ̀dá akẹ́gbẹ́ wa ni a kọ́ tí a sì nlò nípasẹ̀ Ìjọ ti Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́ Ìkẹhìn àti nípasẹ̀ àwa gẹ́gẹ́ bí ọmọ ìjọ rẹ̀. Fún àpẹrẹ, a máa ngba ààwẹ ní àkọ́kọ́ oṣoòṣù àti láti dásí ó kéré jù ìbádọ́gba pẹ̀lú oúnjẹ tí a kò jẹ láti ran àwọn aláìní lọ́wọ́ nínú àwọn ìjọ tiwa. Ìjọ náà tún ṣe àwọn ìrànlọ́wọ́ lọ́pọ̀lọpọ̀ fún inúrere ọmọ ènìyàn àti àwọn iṣẹ́ ìsìn míràn káàkiri gbogbo àgbáyé.

Pẹ̀lú gbogbo ohun tí Ìjọ wa nṣe tààrà, ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ ìsìn inúrere-ọmọ ènìyàn sí àwọn ọmọ Ọlọ́run káàkiri ayé ni àwọn ènìyàn àti ìṣètò tí kò ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Ìjọ wa níti ìṣe. Gẹ́gẹ́bí ọ̀kan lára ​​àwọn àpọ́sítélì wa ti ṣe àfiyèsí: “Ọlọ́run nlo àwọn ènìyàn tí ó ju ẹyọ kan lọ fún àṣepé iṣẹ́ ńlá àti iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀. … Ó gbòòrò púpọ̀, ó nira púpọ̀, fún èyikeyi ènìyàn kanṣoṣo.”4 Gẹ́gẹ́bí ọmọ Ìjọ tí a múpadàbọ̀sípò, a níláti nífura síi kí a sì mọrírì iṣẹ́ ìsìn àwọn ẹlòmíràn.

Ìjọ Jésù Krístì fi jin sísin àwọn wọnnì nínú àìní, àti bákannáà kí a si jin rírẹ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn míràn nínú ìtiraka náà. Láìpẹ́ a ṣe ẹ̀bún títóbí kan lọ sí Ètò Oúnjẹ Ayé United Nations. Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ díkédì ti iṣẹ́ inúrere-ọmọ ènìyàn wa, àwọn ìṣètò dángájíá bí kókó olùbáraṣe: àwọn iṣẹ́ pẹ̀lú ilé-iṣẹ́ Red Cross àti Red Crescent nínú àwọn dọ́sìnì orílẹ̀-èdè ti pèsè ìrọ̀rùn pàtàkì fún àwọn ọmọ Ọlọ́run ní ìgbà àjálù àdánidá àti ìjà. Bákànnáà, a ní àkọsílẹ̀ gígùn ti ìrànlọ́wọ́ pẹ̀lú àwọn Iṣẹ́ ìsìn Ìrànnilọ́wọ̀ Catholic. Àwọn ìṣètò wọ̀nyí ti kọ́ wa ní púpọ̀ nípa ìdẹ̀rùn kílàsì-àgbáyé.

A tún ti ní àwọn ìfọwọ́sowọ́pọ̀ tó sèso-rere pẹ̀lú àwọn ìṣètò míràn, pẹ̀lú Ìrànlọ́wọ́ Mùsùlùmí, Omi fún àwọn Ènìyàn, àti IsraAID, láti dárúkọ díẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé olúkúlukú ìṣètò inúrere-ọmọ ènìyàn ní àwọn ibi àkànṣe tirẹ̀, àfojúsùn wíwọ́pọ̀ ni à npín láti mú ìjìyà dínkù ní àárín àwọn ọmọ Ọlọ́run. Gbogbo èyí jẹ́ ara iṣẹ́ Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Rẹ̀.

Ìfihàn òde òní kọ́ni pé Olùgbàlà wa, Jésù Krístì, ni “ìmọ́lẹ̀ tòótọ́ tí ntàn sí gbogbo ènìyàn tí ó wá sí ayé.” 5 Nípa bẹ́ẹ̀, gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run ní ìmòye láti sìn Ín àti ara wọn gẹ́gẹ́bí ìmọ̀ àti agbára wọn tó dárájùlọ.

Ìwé ti Mọ́mọ́nì kọ́ni pé “ohunkohun tí ó bá npe àti tí ó sì nfanimọ́ra láti ṣe rere, àti láti nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, àti láti sìn Ín, jẹ́ ìmísí láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.”6

Ntẹ̀síwájú:

“Nítorí ẹ kíyèsĩ, a fún olukúlùkù ènìyàn ní Ẹ̀mí Krístì, kí ó lè mọ̀ rere yàtọ̀ sí búburú; nítorí èyí, èmi yíò fihàn yin bí a ti í ṣè idájọ́; nítorítí ohun gbogbo tí í bá npè ènìyàn láti ṣe rére, àti láti yí ènìyàn lọ́kàn padà láti gbàgbọ́ nínú Krístì, ni a rán jáde nípa agbára àti ẹ̀bùn Krístì; …

“Àti nísisìyí, ẹ̀yin ará mi, … ẹ̀yin mọ̀ ìmọ́lẹ̀ tí ẹ̀yin lè fi ṣe ìdájọ́, ìmọ́lẹ̀ tí í ṣe ìmọ́lẹ̀ Krístì.”7

Nihin ni díẹ̀ nínú àwọn àpẹrẹ ti àwọn ọmọ Ọlọ́run tí ó nṣe ìrànlọ́wọ́ fún àwọn ọmọ Ọlọ́run míràn pẹ̀lú àwọn kókó ìnílò fún oúnjẹ, ìtọ́jú ètò-ìlera, àti ìkọ́ni:

Ní ọdún mẹ́wa sẹ́hìn, Kanhdaris, ọkọ àti ìyàwó Sikh kan ní United Arab Emirates, tìkálárarẹ̀ ṣe ìfilọ́lẹ̀ ìtiraka olókìkí kan láti bọ́ àwọn tí ebi npa. Nípasẹ̀ tẹ́mpìlì Guru Nanak Darbar Sikh, wọn nsin ó ju ẹgbẹ̀rún ọgbọ̀n lọ́wọ́lọ́wọ́ lórí oúnjẹ ewébẹ̀ ní gbogbo òpin ọ̀sẹ̀ sí ẹnikẹ́ni tí ó wọnú ìlẹ̀kùn wọn, láìka ẹ̀sìn tàbí ẹ̀yà sí. Dokita Kanhdari ṣàlàyé, “A gbàgbọ́ pé gbogbo wa jẹ́ ọ̀kan; ọmọ Ọlọ́run kan ni wá, a sì wà níhìn láti máa sìn aráyé.”8

Ìpèsè ètò-ìlera àti ìtọ́jù-eyín fún àwọn tí ó nílò jẹ́ àpẹẹrẹ míràn. Ni Chicago, Mo pàdé dókítà ìtọ́jú ara pàtàkì kan ní Siria-Amẹrika, Dokita Zaher Sahloul. Ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn olùdásílẹ̀ ti MedGlobal, èyítí ó ṣètò àwọn amòye elétò-ìlera láti yọ̀ọ̀da àkókò wọn, iṣẹ́, ìmọ̀, àti àwọn olórí láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún àwọn míràn nínú rògbòdìyàn, gẹ́gẹ́bí inú ogun Síríà, níbití Dókítà Sahloul ti fi ẹ̀mí rẹ̀ wéwu ní fífi ìtọ́jú ìlera fún àwọn ará ìlú. MedGlobal àti àwọn ìṣètò tó jọra (pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn amoye Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ikẹhìn) ṣe àfihàn pé Ọlọ́run nmú àwọn amòye ìgbàgbọ́ lọ síwájú láti mú ìrọ̀rùn wá fún àwọn talaka tó nílò rẹ̀ ní àgbaye.9

Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Ọlọ́run aláìmọtara-ẹni-nìkan ló nkópa nínú ìtiraka kíkọ́ni, bákannáà káàkiri ayé. Àpẹrẹ dídára kan, tí a mọ̀ nípasẹ̀ akitiyan inúrere-ọmọ ènìyàn wa, jẹ́ iṣẹ́-ṣíṣe ti ọkùnrìn kan tí a mọ̀ sí Mr. Gabriel, tí ó ti jẹ́ rẹfují láti oríṣiríṣi ìjà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà. Ó ṣàkíyèsí láìpẹ́ pé àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ọmọdé rẹfují ní Ìlà Oòrùn Áfíríkà nílò ìrànlọ́wọ́ láti mú kí ìrètí wọn wà láàyè àti kí ọkàn wọn lè ṣiṣẹ́. Ó ṣètò àwọn olùkọ́ mìràn nínú ìkani rẹfují sí ohun tí wọ́n pè ní “àwọn ilé ìwé igi,”níbi tí a ti kó àwọn ọmọdé jọ fún ẹ̀kọ́ lábẹ́ iboji igi kan. Kò dúró fún àwọn míràn láti ṣètò tàbí darí ṣùgbọ́n tìkáráarẹ̀ ṣe ìtiraka ìtọ́sọ́nà tí ó ti pèsè àwọn ànfàní ìkẹ́kọ fún ẹgbẹẹ̀gbẹ̀rún àwọn ọmọ ilé-ìwé alákọbẹ̀rẹ̀ lakoko àwọn ọdún aápọn ti ìṣípòpadà.

Bẹ́ẹ̀ni, àwọn àpẹrẹ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí kò túmọ̀ sí gbogbo ohun tí ìṣèto bá sọ tàbí ṣe tàbí àwọn olúkúlùkù tó nṣe bí ẹni dídára tàbí tí Ọlọ́run ti lò rí bẹ́ẹ̀ nítòòtọ́. Àwọn àpẹrẹ wọ̀nyí fi hàn pé Ọlọ́run mí sí ọ̀pọ̀ àwọn ìṣètò àti olúkúlukú láti ṣe rere púpọ̀ sí i. Ó tún fi hàn pé púpọ̀ sí i lára ​​wa níláti máa da rere tí àwọn ẹlòmíràn ṣe mọ̀ kí a sì máa tìí lẹ́hìn bí a ti ní àkókò àti ọ̀nà láti ṣe bẹ́ẹ̀.

Nihin ni díẹ̀ nínú àwọn àpẹrẹ nípa iṣẹ́ ìsìn tí Ìjọ nṣe àtìlẹhìn àti èyítí àwọn ọmọ ìjọ wa àti àwọn ènìyàn rere míràn àti àwọn ìṣètò pẹ̀lú nṣe àtìlẹhìn pẹ̀lú olúkúlukú àwọn ìdáwó àkókò àti owó:

Mo bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú òmìnira ẹ̀sìn. Ní àtìlẹhìn pé, à nṣe àwọn ìfẹ́ ti ara wa ṣùgbọ́n pẹ̀lú àwọn ìfẹ́ ti àwọn ẹ̀sìn miran. Gẹ́gẹ́bí Ààrẹ wa àkọ́kọ́, Joseph Smith, ti kọ̀ni, “A gba ànfàní jíjọ́sìn Ọlọ́run Olódùmarè ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà ẹ̀rí-ọkàn tiwa, a sì gba gbogbo ènìyàn ni ànfàní kannáà, kí wọn sì jọ́sìn báwo, níbo, tàbí ohun tí wọ́n lè ṣe.”10

Àwọn àpẹrẹ míràn tí ìmúpadàbọ̀sípò Ìjọ ti inúrere-ọmọ ènìyàn àti àwọn àtìlẹhìn tí à tún nfi ṣerànwọ́ ọ̀fẹ́ nípasẹ̀ àwọn ọmọ ìjọ ní àwọn ilé-ẹ̀kọ́ tí a mọ̀ dáradára, kọlẹ́ẹ̀jì, àti unifásítì àti tí a kò mọ̀ sí dáadáa ṣùgbọ́n nísisìyí tí a tẹ̀ àwọn ìdáwó nlá jáde fún ìrọ̀rùn àwọn tí ó njìyà látinú ìparun àti ìṣípòpadà ti àwọn àjálù àdánidá bíi àwọn ìjì líle àti àwọn ìṣẹ́lẹ̀.

Àwọn iṣe àánú míràn ti àwọn ọmọ ìjọ wa nṣe àtìlẹhìn nípa ìdáwó àtinúwá wọn àti ìtiraka tí ó jẹ́ onírurú jùlọ sí àkópọ̀, ṣùgbọ́n fífẹnuba díẹ̀ wọ̀nyí yíò dába oríṣiríṣi àti pàtàkì wọn: ní títako ẹlẹ́yàmẹ̀yà àti àwọn ìkórira miran, ìwádi lórí bí ó ṣe lè ṣe ìdíwọ́ àti láti wo àwọn àrùn, ṣíṣe ìrànlọ́wọ́ àwọn abirùn, àtìlẹhìn àwọn ìṣètò orin: àti ìmúdárasi ìwà àti àyíká rírí fún gbogbo ènìyàn.

Gbogbo ìtiraka inúrere-ọmọ ènìyàn ti Ìjọ ti Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn nwá láti tẹ̀lé àpẹrẹ àwọn olódodo ènìyàn tí a ṣàpèjúwe nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì: “Àti ní báyìí, nínú àwọn ipò ìṣe rere wọn, wọn kò rán ẹnikẹ́ni tí ó wà ní ìhòòhò lọ. , tàbí àwọn tí ebi npa, tàbí àwọn tí òùngbẹ ngbẹ, tàbí àwọn tí wọ́n nṣàìsàn,… wọ́n sì jẹ́ olómìnira fún gbogbo ènìyàn, àti àgbà àti ọ̀dọ́, àti ìdè àti òmìnira, àti lọ́kùnrin àti lóbìnrin, bóyá lóde ìjọ tàbí nínú ìjọ. ”11

Mo jẹ́ ẹ̀rí nípa Jésù Krístì, ẹnití ìmọ́lẹ̀ àti Ẹ̀mí rẹ̀ ntọ́ gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run sọ́nà ní ríran òtòṣì àti onírẹ̀wẹ̀sì lọ́wọ́ káàkiri ayé. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.