Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ìgboyà láti Kéde Òtítọ́
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2022


Ìgboyà láti Kéde Òtítọ́

Nígbà tí a bá ti kọ́ òtítọ́, Olúwa nfún wa ní ànfàní láti ṣe ohun tí Òun yíò ṣe bí Ó bá wà nihin ní òní.

Ní 1982, mo nparí akẹ́gbẹ́ ipò ní topógíráfì ní ilé ìwé ẹ̀kọ́ṣẹ́.

Ní òpin ọdún, ẹlẹgbẹ́ akẹkọ kan pè mí láti ní ìbánisọ̀rọ̀. Mo rántí pé a fi àwọn ọmọ kílásì míràn sílẹ̀ a sì lọ sí agbègbè kan ní ẹ̀gbẹ́ ibi ìṣeré. Nígbàtí a dé ibẹ̀, ó sọ̀rọ̀ sí mi nípa ìdánilójú ẹ̀sìn rẹ̀, kìí ṣe pé ó fi ìwé kan hàn mi nìkan, ṣùgbọ́n ó fún mi ní ìwé náà. Ní òtítọ́, èmi kò rántí gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ náà tí ó sọ, ṣùgbọ́n mo rántí àkokò náà dáadáa àti ọ̀nà tí mo fi nímọ̀lára nígbàtí ó wípé, “Mo fẹ́ láti jẹ́ ẹ̀rí mi sí ọ pé ìwé yí jẹ́ òtítọ́, àti pé ìhìnrere Jésù Krístì ni a ti múpadàbọ̀sípò.”

Lẹ́hìn ìbárasọ̀rọ̀ wa, mo lọ sílé, mo ṣí àwọn ojú-ewé nínú ìwé náà, mo sì fi sí orí àkàbà. Nítorí a wà ní òpin ọdún ó sì jẹ́ ọdún tí ó kẹ́hìn ti ìgboyè topógíráfì mi, èmi kò fi ojú sí ìwé náà dáadáa, tàbí sí àwọn akẹkọ ẹlẹgbẹ́ mi tí wọ́n pín in pẹ̀lú mi. Orúkọ ìwé tí ẹ lè rò tẹ́lẹ̀ ni. Bẹ́ẹ̀ni, Ìwé ti Mọ́mọ́nì ni.

Oṣù marun lẹ́hìnnáà, àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere wá sí ilé mi; wọ́n nlọ bí mo ti nbọ̀ ní ilé láti ibi iṣẹ́. Mo pè wọ́n wọlé padà. A joko sílẹ̀ nínú pátíò kékeré ní iwájú ilé mi, wọ́n sì kọ́ mi.

Nínú iwákiri fún òtítọ́ mi, mo bèèrè lọ́wọ́ wọn ìjọ èyí tí ó jẹ́ òtítọ́ àti bí mo ti lè ri. Àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere kọ́ mi pé mo lè gba ìdáhùn náà fún ara mi. Pẹ̀lú ìrètí àti ìfẹ́ nlá, mo tẹ́wọ́gba ìpènijà wọn láti ka ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn orí látinú Ìwé ti Mọ́mọ́nì. Mo gbàdúrà pẹ̀lú ọkàn òdodo àti pẹ̀lú èrò òtítọ́ (wo Mórónì 10:4–5). Ìdáhùn sí ìbèèrè mi hàn kedere, àti pé àwọn ọjọ́ díẹ̀ lẹ́hìnnáà, rẹ́gí-rẹ́gí ní Ọjọ́ Kínní Oṣù Karun, 1983, mo ṣe ìrìbọmi a sì fi ẹsẹ̀ mi múlẹ̀ bí ọmọ Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn.

Ní òní, nígbàtí mo bá ronú nípa ṣísẹ̀ntẹ̀lé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ṣẹlẹ̀, mo ri kedere bí ìgboyà ẹlẹgbẹ́ akẹkọ mi ti ṣe pàtàkì tó nígbàtí ó jẹ́ ẹ̀rí nípa ìmúpadàbọ̀sípò òtítọ́ ó sì fún mi ní ẹ̀rí gidi nípa Ìmúpadàbọ̀sípò ti ìhìnrere Jésù Krístì, àní Ìwé ti Mọ́mọ́nì. Ìṣe ìrọ̀rùn náà, ṣùgbọ́n tí ó jinlẹ̀ ṣe pàtàkì sí mi, ó dá ìsopọ̀ ní àárín mi àti àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere nígbàtí mo kọ́ pàdé wọn.

Òtítọ́ tí a ti fún mi, àti pé lẹ́hìn ìrìbọmi mi, mo di ọmọẹ̀hìn Jésù Krístì. Ní àwọn ọdún tó tẹ̀le, àti pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn ènìyàn pàtàkì gan bíi àwọn olórí, olùkọ́, ọ̀rẹ́, àti bákannáà nípasẹ̀ àṣàrò ti araẹni mi, mo kọ́ pé nígbàtí mo pinnu láti jẹ́ ọmọẹ̀hìn Jésù Krístì, mo ti tẹ́wọ́gba iṣẹ́ tí kìí ṣe láti dá ààbò bo òtítọ́ nìkan ṣùgbọ́n bákannáà ti kíkéde rẹ̀.

Nígbàtí mo faramọ láti gbàgbọ́ nínú òtítọ́ láti tẹ̀lé e, àti pé nígbàtí a bá ṣe ìtiraka kan láti di ọmọẹ̀hìn Jésù Krístì tòótọ́, a kò ní gba ìwé-ẹ̀rí pẹ̀lú ìmúdájú pé a kò ní ṣe àṣìṣe, pé a kò sì ní ṣe ọ̀fíntótó wa, pé a kò ní gba àdánwò láti rìn kúrò nínú òtítọ́, tí a kò ní gba òfíntótó, àní tàbí pé a kò ní ní ìrírí àwọn ìpọ́njú. Ṣùgbọ́n ìmọ̀ òtítọ́ kọ́ wa pé nígbàtí a bá wọ inú ipa ọ̀nà tààrà àti híhá tí yíò mú wa padà sí ọ̀dọ̀ Baba Ọ̀run, ọ̀nà sísá kúrò nínú àwọn wàhálà wọ̀nyí yíò wa nígbàgbogbo (wo 1 Corinthians 10:13); ìṣeéṣe ṣíṣe iyèméjì àwọn iyèméjì wa síwájú ṣíṣiyèméjì ìgbàgbọ́ wa yíò wá nígbàgbogbo (wo Dieter F. Uchtdorf, “Wá, Darapọ̀ pẹ̀lú Wa,” Liahona, Nov. 2013, 21); àti ní òpin, a ní ìmúdájú pé a kì yíò dá wà láéláé nígbàtí a bá nlọ nínú ìpọ́njú, nítorí Ọlọ́run nbẹ àwọn ènìyàn Rẹ̀ wò ní àárín àwọn ìpọ́njú wọn (wo Mosiah 24:14).

Nígbà tí a bá ti kọ́ òtítọ́, Olúwa nfún wa ní ànfàní láti ṣe ohun tí Òun yíò ṣe bí Ó bá wà nihin ní òní. Nítòótọ́, Ó fi àwọn ohun tí a gbọ́dọ̀ ṣe hàn wá nípa àwọn ìkọ̀ni Rẹ̀: “Ẹ̀yin yíò sì jáde lọ nínú agbára Ẹ̀mí Mímọ́, ní wíwàásù ìhìnrere mi, ní méjì méjì, ní orúkọ mi, ní gbígbé ohùn yín sókè bíi ìró fèrè, ní kíkéde ọ̀rọ̀ mi bíi ti àwọn àngẹ́lì” (Ẹkọ àti Àwọn Májẹmú 42:6). Ànfàní fún iṣẹ́-ìsìn ìránṣẹ́ ìhìnrere nínú àwọn ọ̀dọ́ wa kò láfiwé!

Ẹ jọ̀wọ́, ẹ̀yin ọ̀dọ́mọkùnrin, ẹ máṣe sún ìmúrasílẹ̀ yín láti sin Olúwa bí ìránṣẹ́ ìhìnrere síwájú. Bí ẹ ti ndojúkọ àwọn ipò tí ó lè mú kí ìpinnu yín láti sìn ní míṣọ̀n jẹ́ ìṣòro kan—irú èyí tí ó lè dá àwọn ẹ̀kọ́ yín dúró fún igbà kan, sísọ ó dàbọ̀ sí ọ̀rẹ́bìnrin yín láìsí imúdájú pé ẹ ó barìn mọ́ láé, àní tàbí níní láti rìn kúrò nínú iṣẹ́ tó tayọ—ẹ rántí àpẹrẹ Olùgbàlà Jésù Krístì. Ní ìgbà iṣẹ́ ìránṣẹ́ Rẹ̀, Òun bákannáà dojúkọ ìṣòro, pẹ̀lú ọ̀fíntótó, ìnilára, àti nígbẹ̀hìn ago ìkorò ti ìrúbọ ètùtù Rẹ̀. Síbẹ̀síbẹ̀ nínú gbogbo ipò Ó nwá láti ṣe ìfẹ́ Baba Rẹ̀ ó sì fi ògo fún Un. (Wo Jòh´nù 5:30; 6:38–39; 3 Nefi 11:11; Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 19:18–19.)

Awọn Ọ̀dọ́mọbìnrin, a kíi yín káàbọ̀ sí iṣẹ́ nínú ọgbà àjàrà Olúwa, àti pé nígbàtí ẹ bá pinnu láti sìn Ín, a kò ní yọ yín kúrò nínú irú àwọn ìpènijà kannáà.

Mo ṣe ìlérí pé oṣù mẹ́rìnlélógún tàbí méjìdínlógún iṣẹ́-ìsìn a kọjá ní pàpà míṣọ̀n gẹ́gẹ́ bí wọn yíò ti kọjá bí ẹ bá dúró sílé, ṣùgbọ́n àwọn ànfàní tí ó dúró dé àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin yíyẹ ti Ìjọ yí nínú pápá míṣọ̀n kò láfiwé. Ànfàní ti ṣíṣaṣojú Olùgbàlà Jésù Krístì àti Ìjọ Rẹ̀ kò ṣe é patì. Kíkópa nínú àwọn àdúrà àìlónkà, gbígbèrú àti jíjẹ́ ẹ̀rí yín ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ní ọjọ́, ọ̀pọ̀lọpọ̀ wákàtí àṣàrò ìwé mímọ́, pípàdé àwọn ènìyàn tí ẹ kò ní pàdé láé kání ẹ ti dúró sílé, jẹ́ àwọn ìrírí àìlèjúwe. Irú ipele ìrírí kannáà ni a fi pamọ́ fún àwọn ọ̀dọ́ tí Olúwa ti pè sí sísìn lórí iṣẹ́-ìsìn míṣọ̀n. A pè yín kí ẹ wá gan an ó sì ṣeéṣe. Ẹ jọ̀wọ́ ẹ máṣedín pàtàkì iṣẹ́ iṣẹ́-ìsìn iṣẹ́ ìránṣẹ́ tì, fún iṣẹ́-ìsìn àwọn míṣọ̀n ti ìrírí àìlèjúwe ti a pèsè bákannáà. “Iye ẹ̀mí tóbí ní ojú Ọlọ́run” (Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 18:10), pẹ̀lú iye ẹ̀mí yín.

Ní pípadà dé láti iṣẹ́-ìsìn yín, bóyá ọ̀rẹ́bìnrin yín tàbí ọ̀rẹ́kùnrin kò dúró dè yín mọ́, ṣùgbọ́n ẹ ò ti kẹkọ dáadáa láti ṣe ìpeni tí ó láápọn. Àwọn ẹ̀kọ́ ilé-ìwé yín yíò mú ọgbọ́n wá pẹ̀lú ìwò tí ẹ ti ní nípa mímúrasílẹ̀ déédé síi fún ibi-iṣẹ́, àti ní ìparí, ẹ ó ní ìdánilójú kíkún ti kíkéde ìhìnrere àláfíà pẹ̀lú ìgboyà, ní jíjẹ́ ẹ̀rí ìmúpadàbọ̀sípò òtítọ́.

Fún àwọn wọnnì lára yín tí wọ́n ti ṣe ìgbeyàwó àti ní àwọn ipele ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ayé, ẹ jẹ́ pàtàkì gan nínú iṣẹ́ Olúwa. Ẹ múra arayín sílẹ̀. Ẹ gbé ìgbé ayé ti-ìlera, ẹ wá ìgbẹ́kẹ̀lé-araẹni ti ara àti ti ẹ̀mí, nítorí àwọn ànfàní láti ṣe ohun tí Olúwa fẹ́ kí a ṣe fún àwọn ọmọ Rẹ̀ kò dínkù sí ẹgbẹ́ ọjọ́ orí kan. Àwọn ìrírí tí ó dídárajulọ tí ìyàwó mi àti èmi ti ní ní àwọn ọdún àìpẹ́ ti wá nígbàtí à nsìn lẹgbẹ àwọn lọ́kọláya pàtàkì, ní àwọn ibi pàtàkì, àti sínsin àwọn ènìyàn pàtàkì gan.

Ìrírí tí mo ní ní òpin ipò topógíráfì mi kọ́ mi pé à ndà ààbò bo òtítọ́ nígbàtí a bá nkéde rẹ̀ àti pé dídá ààbò bo òtítọ́ ni ohun ìtara. A kò níláti ṣe ààbò òtítọ́ ní ọ̀nà ìfinràn ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú fífẹ́ àtinúwá láti fẹ́ràn, pín, àti pe àwọn ènìyàn tí a njẹ́ ẹ̀rí sí nípa òtítọ́, ríronú nípa àláfíà ti ara àti ti ẹ̀mí àwọn ọmọ olùfẹ́ni Baba Ọ̀run nìkan. (wo Mosiah 2:41).

Nínú ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò ti Oṣù Kẹwa 2021, Ààrẹ Russell M. Nelson, olùfẹ́ wòlíì wa, kọ́ni pé ní ìlòdì sí ohun tí àwọn kan rò, ohun tí à npè ní títọ́ àti àṣìṣe wà lódodo. Òtítọ́ pátápátá wà lódodo—òtítọ́ ayérayé. (Wo Russell M. Nelson, “Òtítọ́ Àìléèrí, Ẹkọ́ Àìléèrí, àti Ìfihàn Àìléèrí,” Liahona, Nov. 2021, 6.)

Ìwé-mímọ́ kọ́ni pé, “Òtítọ́ ni ìmọ àwọn nkan bí wọ́n ṣe wà, àti bí wọ́n ṣe ti wà rí, àti bí wọn yíó ṣe wá” (Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 93:24).

Ìmọ̀ òtítọ́ kìí mú wa dáraju àwọn ènìyàn míràn lọ. Ṣùgbọ́n ó nkọ́ wa ní ohun tí a gbọ́dọ̀ ṣe láti padà sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.

Bí ẹ ti ntẹ̀síwájú gbọingbọin nínú Krístì àti pẹ̀lú ìgboyà kìí ṣe láti kéde òtítọ́ nìkan ṣùgbọ́n láti gbé ìgbé ayé òtítọ́, ẹ ó rí ìtùnú àti àláfíà nínú ìrúkèrúdò tí ẹ ó bápàdé ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyí.

Àwọn ìpènijà ayé lè jù wa sílẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ mọ̀ pé nígbàtí a bá lo ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì, àwọn ìpọ́njú, “[wa] kò ní dúró ju àkókò díẹ̀ lọ” (Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 121:7) ní ààyè ọlọ́lá ayérayé . Ẹ jọ̀wọ́ ẹ máṣe dá òpin fún ìparí àwọn ìṣòro àti ìpènijà yín sílẹ̀. Ẹ gbẹ́kẹ̀lé Baba Ọ̀run kí ẹ má sì ṣe jáwọ́, nítorí tí a kò bá jáwọ́, a kò ní mọ̀ bí òpin ìrìnàjò wa ìbá ti jẹ́ nínú ìjoba Ọlọ́run.

Rọ́ mọ́ òtítọ́, kẹkọ látinú àwọn orísun òtítọ́:

Mo jẹ́ ẹ̀rí mi nípa Jésù Krístì àti pé èyí ni Ìjọ Rẹ̀. A ní wòlíì alààyè, a ó sì nímọ̀lára ominira nígbàgbogbo tí a bá nkéde òtítọ́ pẹ̀lú ìgboyà. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.