Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Wọ́n Sì Lépa láti Rí Ẹni Tí Jésù Í Ṣe
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2022


Wọ́n Sì Lépa láti Rí Ẹni Tí Jésù Í Ṣe

Mo jẹ́ ẹ̀rí pé Jésù wà láàyè, pé Òun mọ̀ wá, àti pé Òun ní agbára láti wòsàn. láti yípadà, àti láti dáríjì.

Ẹ̀yin arákùnrin, arábìnrin, àti ọ̀rẹ́, ní 2013 ìyàwó mi, Laurel, àti èmi ni a pè láti sìn bí olórí àwọn míṣọ̀n ní Míṣọ̀n Czech/Slovak. Àwọn ọmọ wa mẹ́rẹ̀ẹ̀rin sìn pẹ̀lú wa.1 A di alábùkúnfún bí ẹbí kan pẹ̀lú àwọn ọlọ́gbọ́n ìránṣẹ́-ìhìnrere àti nípasẹ̀ àwọn Ènìyàn Mímọ́ àrà ọ̀tọ̀ ti Czech àti Slovak. A fẹ́ràn wọn.

Bí àwọn ẹbí wa ṣe wọ pápá míṣọ̀n, ohun kan tí Alàgbà Joseph B. Wirthlin kọ́ni lọ pẹ̀lú wa. Nínú ọ̀rọ̀ tí àkọlé rẹ̀ jẹ́ “Òfin Nlá” Alàgbà Wirthlin bèèrè, “Ṣe ẹ nifẹ Olúwa?” Àmọ̀ràn rẹ̀ sí àwọn wọnnì lára wa tí yíò dáhùn “bẹ́ẹ̀ni” jẹ́ ìrọ̀rùn àti ìjìnlẹ̀: “Lo àkokò pẹ̀lú Rẹ̀. Jíròrò lórí àwọn ọ̀rọ̀ Rẹ̀. Ẹ gbé àjàgà Rẹ̀ lórí yín. Ẹ lépa láti ní òye kí ẹ sì gbọ́ran.”2 Alàgbà Wirthlin nígbànáà ṣe ìlérí àwọn ìbùkún ìyípadà sí àwọn wọnnì tí wọ́n nfẹ́ láti fi àkokò àti ààyè sílẹ̀ fún ìgbé ayé àti àwọn ìkọ́ni Jésù Krístì.3

A gba àmọ̀ràn Alàgbà Wirthlin àti ìlérí sí ọkàn. Papọ̀ pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́-ìhìnrere wa, a lo àkokò púpọ̀ síi pẹ̀lú ṣíṣe áṣárò Máttéù, Markù, Lúkù, àti Jòhánnù látinú Májẹ̀mú Titun àti 3 Néfì látinú Ìwé ti Mọ́mọ́nì. Ní ìparí gbogbo ìpàdé àpapọ̀ ẹ̀kùn, ìgbìmọ̀ àwọn olórí, tàbí ìpàdé ẹ̀kùn, a rí arawa padà nínú ohun tí a tọ́ka sí bí “Àwọn Ìhìnrere Marun”4 Kíkà, sísọ, jíjíròrò, àti kíkọ́ nípa Jésù.

Fún èmi, fún Laurel, àti fún àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere wa, lílo àkokò pẹ̀lú Jésù nínú àwọn ìwé mímọ́ yí ohun gbogbo padà. A jèrè ìmoore jíjinlẹ̀ fún ẹnití Òun í ṣe, àti ohun tí ó ṣe pàtàkì sí I. Lápapọ̀ a ronú bí Òun ti kọ́ni, ohun tí Ó kọ́ni, àwọn ọ̀nà tí Ó ti fi ìfẹ́ hàn, ohun tí Ó ṣe láti bùkún àti láti sìn, àwọn iṣẹ́ ìyanu, bí Òun ṣe fèsí sí elénìní, ohun tí Òun ṣe pẹ̀lú ìṣòrò ẹ̀dùn ọkàn ènìyàn, àwọn àkọlé àti orúkọ̀ Rẹ̀, bí Òun ti fetísílẹ̀, bí Òun ti yanjú ìjà, ayé nínú èyí tí Òun gbé, àwọn òwé Rẹ̀, bí Òun ṣe gba ìrẹ́pọ̀ àti inúrere níyànjú, okun Rẹ̀ láti dáríjì àti láti wòsàn, àwọn ìwàásù Rẹ̀, àwọn àdúra Rẹ̀, ìrúbọ ètùtù Rẹ̀, Àjínde Rẹ̀, ìhìnrere Rẹ̀.

À nfi ìgbà púpọ̀ dàbí “[ẹni] kúkurú” náà Zacchaeus tó nsáré láti gun igi síkámóré bí Jésù ti nkọjá ní Jericho nítorí, bí Lúkù ṣe júwe rẹ̀, a “nwá láti rí ẹni tí Jésù í ṣe.”5 Kìí ṣe Jésù bí a ti nifẹ tàbí fẹ́ kí Òun ó jẹ́, ṣùgbọ́n dípò Jésù bí Òun ti jẹ́ tẹ́lẹ̀ lotitọ àti bayi. Gẹ́gẹ́ bí Alàgbà Wirthlin ti ṣe ìlérí, a kọ́ ẹ̀kọ́ ní ọ̀nà òtítọ́ pé “ìhìnrere Jésù Krístì jẹ́ ìhìnrere ìyípadà. Ó gbà wá bí àwọn ọkùnrin àti obìnrin ilẹ̀ ayé ó sì tún wa ṣe sínú àwọn ọkùnrin àti obìnrin ayérayé.”7

Àwọn wọnnì ni àwọn ọjọ́ pàtàkì. A wá láti gbàgbọ́ pè “pẹ̀lú Ọlọ́run kò sí ohun tí yíò ṣòro.”8 Àwọn ìrántí mímọ́ ọ̀sán ní Prague, Bratislava, tàbí Brno, papọ̀ bí míṣọ̀n kan, ríronú àti níní ìrírí agbára àti ódodo Jésù, tẹ̀síwájú ní ìbámu sí gbogbo ìgbé ayé wa.

Wo Márkù 2:1-12. Ìtàn tí ó wà níbẹ̀ jẹ́ ọ̀rọ̀yàn. Mo fẹ́ ka apàkan rẹ̀ tààrà látinú Márkù, lẹ́hìnnáà kí a sì pín in bí mo ti wá láti ní òye rẹ̀ lẹ́hìn àṣàrò kíkún àti ìbánisọ̀rọ̀ pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere wa àti àwọn míràn.9

“Nígbàtí [Jésù] sì tún wọ Kápérnáúmù lọ lẹ́hìn ọjọ́ mélókan; òkìkí kàn yíká pé ó wà nínú ilé.

“Lójúkannáà ọ̀pọ̀ ènìyàn sì péjọ tóbẹ́ẹ̀ tí àyè kò sí fún wọn mọ́, kò sí, títí dé ẹnu-ọ̀nà: ó sì wàásù ọ̀rọ̀ náà fún wọn.

“Wọ́n sì wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n gbé ẹnìkan tí ó ní ẹ̀gbà tọ̀ọ́ wá, ẹnití mẹ́rin gbé.

“Nígbàtí wọn kò lè súnmọ́ ọ nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn, wọ́n sì ṣí òrùlé ilé nibití ó gbé wà: nígbàti wọ́n sì dá a lu tán, wọ́n sọ akéte náà kalẹ̀ lórí èyítí ẹlẹ́gbà dùbúlẹ̀.

“Nígbàtí Jésù rí ìgbàgbọ́ wọn, ó wí fún ẹlẹ́gbà náà pé, Ọmọ, a dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jì ọ́.”

Lẹ́hìn ìpàṣípàrọ̀ pẹ̀lú àwọn kan nínú ọ̀pọ̀ ènìyàn,10 Jésù wo ọkùnrin ẹlẹ́gbà ó sì wòó sàn níti-ara, ó wípé:

“Mo wí fún ọ, Dìde, gbé àkéte rẹ, kí o sì máa lọ ilé rẹ.

“Ó sì dìde lójúkannáà, ó sì gbé àkéte náà, ó sì jáde lọ ní ojú gbogbo wọn; wọ́n sì yin Ọlọ́run lógo, wípé, àwa kò rí irú èyí rí.”11

Nísisìyí iṣẹ́ ìránṣẹ́ Rẹ̀, Jésù padà sí Kápérnáúmù, ìletò apẹja kékeré tí ó wà ní gúsù etí Òkun Gálílì.12 Ó ti ṣe onírurú àwọn iṣẹ́ ìyanu nípa wíwo aláìsàn sàn àti lílé àwọn ẹ̀mí òkùnkùn jáde.12 Ní ìtara láti gbọ́ àti láti ní ìrírí ọkùnrin tí à npé ní Jésù, àwọn olùgbé ìletò kórajọ ní ilé níbití a ti gbọ́ kíkùn pé yíò dúró sí.13 Bí wọ́n ti ṣe é, Jésù bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ni.14

Àwọn ilé ní Kápérnáúmù nígbà náà jẹ́ òrulé-pẹrẹsẹ, ibùgbé ìdúró-kanṣoṣo, tí a kó papọ̀.15 Òrùlé náà àti ògiri ní ìdàpọ̀ òkúta, igi-nlá, amọ̀, àti igi-ìbolé, tí ó ní ààyè àwọn àtẹ̀gùn rírọrun tí a gbékalẹ̀ ní ẹ̀gbẹ́ ilé náà.16 Àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn dàgbà kíákíá ní ilé náà, tí ó kún yàrá náà níbi tí Jésù ti nkọ́ni, tí ó sì ntàn jáde sínú òpópónà.17

Ìtàn náà dojúkọ ọmọkùnrin kan “tí ó ní àrùn ẹ̀gbà” àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ mẹ́rin.18 Ẹ̀gbà jẹ́ irú ara rírọ kan, tí ó nbá àìlera àti ara-gbígbọ̀n wá nígbàkugbà.19 Mo ronú nípa ọ̀kan lára àwọn mẹ́rin náà tí ó nwí fún àwọn tókù pé, “Jésù wà ní ìletò wa. Gbogbo wa mọ̀ nípa àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Ó ṣe àti àwọn wọnnì tí Ó ti wòsàn. Bí a bá kàn lè mú ọ̀rẹ́ wa wá sọ́dọ̀ Jésù, bóyá òun náà lè di pípé.”

Nítorínáà, ẹnìkọ̀ọkan wọn mú igun ẹni tàbí ibùsùn ọ̀rẹ́ wọn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé e nínú àwọn òpópónà wọ́gọwọ̀gọ, híhá, àìtúnṣe ti Kápérnáúmù.21 Àwọn iṣan ní ríro, wọ́n yí igun tó kẹ́hìn ṣùgbọ́n láti ríi pé ọ̀pọ̀ ènìyàn tàbí, bí ìwé mímọ́ ti pè é, “ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀” àwọn ènìyàn tí wọ́n kórajọ láti fetísílẹ̀ pọ̀ gan tí gbígbé ọ̀rẹ́ wọn ní ẹnu-ọ̀nà sí ọ̀dọ̀ Jésù kò ṣeéṣe.22 Pẹ̀lú ìfẹ́ àti ìgbàgbọ́, àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin kò rẹ̀wẹ̀sì. Dípò bẹ́ẹ̀, wọ́n rá wọ àtẹ̀gùn sí orí òrùlé pẹrẹsẹ, fi pẹ̀lẹ̀pẹ̀lẹ́ gbé ọ̀rẹ́ wọn àti ìbùsùn rẹ̀ sókè pẹ̀lú wọn, wọ́n já òrùlé tàbí àjà yàrá níbití Jésù ti nkọ́ni, wọ́n sì gbé ọ̀rẹ́ wọn kalẹ̀.23

Ronú pé láàrín ohun tí ó gbọdọ̀ ti jẹ́ àkokò ìkọ́ni pàtàkì kan, Jésù ngbọ́ ariwo kékèké, ó wòkè, ó sì rí ihò tí ó ngbòòrò nínú òrùlé bí eruku àti àbà ṣe njábọ́ sínú yàrá náà. Ọkùnrin arọ kan lórí ibùsùn ni a ngbékalẹ̀ nígbànáà sórí ilẹ̀. Ní ìfiyèsí, Jésù ní òye pé èyí kìí ṣe ìdíwọ́ ṣùgbọ́n ó jẹ́ ohun kan tí ó ṣe dandan. Ó wo ọkùnrin náà ní orí ibùsùn, ní gbangba Ó dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jì, àti ní àfojúrí Ó wò ó sàn.24

Pẹ̀lú sísọ nípa Márkù 2 nínú iyè, àwọn onírurú òtitọ́ hàn kedere nípa Jésù bíi Krístì náà. Àkọ́kọ́, nígbàtí à ngbìyànjú láti ran ẹnìkan lọ́wọ́ a nní ìfẹ́ láti wá sọ́dọ̀ Krístì, a lè ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ìgbẹ́kẹ̀lé pé Òun ní okun láti gbé ẹrù wúwo ẹ̀ṣẹ̀ náà àti láti dáríjì. Èkejì. Nígbàtí a bá gbé ẹ̀dùn ọkàn, ti-ara, tàbí àwọn àìsàn míràn wá sọ́dọ̀ Krístì, a lè ṣe bẹ́ẹ̀ ní mímọ̀ pé Ó ní agbára láti wòsàn àti láti tuninínú. Ẹ̀kẹ́ta, nígbàtí a bá tiraka bíiti àwọn mẹ́rin láti mú àwọn míràn wá sọ́dọ̀ Krístì, a lè ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ìdánilójú pé Òun rí èrò òtítọ́ wa òun ó sì bù-ọlá fún wọn bí ó ṣe tọ́.

Ẹ rántí pé, ìkọ́ni Jésù ni a dílọ́wọ́ nípa ìfarahàn ihò nínú òrùlé. Dípò ìbáwí tàbí títú àwọn mẹ́rin tí wọ́n dá ihò sí òrùlé ká fún ìdíwọ́, ìwé mímọ́ wí fún wa pé “Jésù rí ìgbàgbọ́ wọn.”24 Àwọn wọnnì tí wọ́n rí iṣẹ́ ìyanu náà “ní ìyàlẹ́nu, wọ́n sì yin Ọlọ́run lógo, tí ó fi irú agbára bẹ́ẹ̀ [fún] ènìyàn.”26

Ẹ̀yin arákùnrin àti Arábìnrin, ẹ jẹ́ kí n parí pẹ̀lú àfikún àkiyèsí méjì. Bóyá bí àwọn iìránṣẹ́ ìhìnrere, òjíṣẹ́ ìránṣẹ́, ààrẹ Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́, bíṣọ́ọ̀pù, olùkọ́ni, òbí, arákùnrin tàbí arábìnrin, tàbí ọ̀rẹ́, a wà nínú iṣẹ́ bí ọmọẹ̀hìn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn ti mímú àwọn ẹlòmíràn wá sọ̀dọ̀ Krístì. Nípa báyìí, àwọn ìwà tí a fihàn láti ọwọ́ àwọn ọ̀rẹ́ mẹ́rin náà yẹ fún gbígbèrò àti fífarawé.27 Wọ́n ní ìgboyà, ìmúyẹ, ìforítì, ìdásílẹ̀, ìṣípòpadà, ìrètí, ìpinnu, òtítọ́, ìgbàgbọ́ fún rere, ìrẹ̀lẹ̀, àti fífaradà.

Ní àfikún, àwọn ọ̀rẹ́ mẹ́rin tẹnumọ́ pàtàkì ti-ẹ̀mí ìletò àti jíjọ́sìn.27 Ní èrò láti mú ọ̀rẹ́ wọn wá sọ́dọ̀ Krístì, ọ̀kọ̀ọ̀kan lára àwọn mẹ́rin gbúdọ̀ gbé igun ibùsùn. Bí ọ̀kan bá fi sílẹ̀, àwọn nkan a nira síi. Bí méjì bá pa ìtiraka ti, iṣẹ́ náà kò ní fi taratara ṣeéṣe. Olukúlùkù wa ní ipa láti ṣe nínú ìjọba Ọlọ́run.29 Bí a ti nkúnjú ojúṣe náà tí a sì nsa ipá wa, à ngbé igun wa. Bóya ní Argentina tàbí Vietnam, Accra tàbí Brisbane, ẹ̀ká kan tàbí wọ́ọ̀dù kan, ẹbí kan tàbí ojúgba ìránṣẹ́ ìhìnrere kan, ẹnìkọ̀ọ̀kan wa ní igun kan láti gbé. Bí a ti nṣe é, àti pé bí a yíò bá ṣe é, Olúwa yíò bùkún gbogbo wa lápapọ̀ bí ọmọ ìjọba Rẹ̀ nihin lórí ilẹ̀ ayé. Bí Ó ti rí ìgbàgbọ́ wọn, bẹ́ẹ̀ni Òun yíò rí tiwa yíò sì bùkún wa bí ènìyàn kan.

Ní àwọn àkokò tó yàtọ̀ mo ti gbé igun ibùsùn kan, àti ní àwọn ìgbà míràn mo ti jẹ́ ẹni tí a gbé. Ara agbára ìtàn olókìkí ti Jésù yí ni pé ó rán wá létí gẹ́gẹ́ bí a ṣe nílò ara wa tó, bí arákùnrin àti arábìnrin, ní èrò láti wá sọ́dọ̀ Krístì àti láti di yíyípadà.

Ìwọ̀nyí ni díẹ̀ lára àwọn ohun tí mo ti kọ́ ní lílo àkokò pẹ̀lú Jésù nínú Mark 2.

“Njẹ́ kí Ọlọ́run gbà kí a lè [gbé igun wa], kí a máṣe ṣakì, kí a máṣe bẹ̀rù, ṣùgbọ́n kí a lè lókun nínú ìgbàgbọ́ wa, kí a sì ní ìpinnu nínú iṣẹ́wa, láti ṣe àṣeyọrí àwọn èrò Olúwa.”29

Mo jẹ́ ẹ̀rí pé Jésù wà láàyè, pé Òun mọ̀ wá, àti pé Òun ní agbára láti wòsàn. Láti yípadà, àti láti dáríjì. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́

  1. Evie, Wilson, Hyrum, and George.

  2. Joseph B. Wirthlin, “Òfin Nlá,” Liahona, Nov. 2007, 30.

  3. Àwọn ìbùkún láti ọwọ́ Alàgbà Wirthlin pẹ̀lú a`níkún agbára fún ìfẹ́, ìfẹ́ inú láti ṣe rere, níní ìfẹ́ láti jẹ́ gbígbọ́ran àti olùfèsì sí àwọn òfin Ọlọ́run, ìfẹ́-inú kan láti sin àwọn ẹlòmíràn, àti ipò láti ṣe rere nígbagbogbo.

  4. “Àwọn ìhìnrere … jẹ́ àgbékalẹ̀ ipele-mẹ́rin lábẹ́ àwọn orúkọ mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ àwọn ẹniọ̀wọ̀ tàbí àwọn olùkọ̀wé Ìhìnrere nípa ìgbé-ayé àti ìkọ́ni Jésù, àti ìjìyà rẹ̀, ikú àti àjínde” (Anders Bergquist, “Bíbélì: Májẹ̀mú Titun,” in Encyclopedia of Christianity James Bowden, ed. [2005], 141). Ìtúmọ̀ Bíbélì fikun pé “ọ̀rọ̀ náà ìhìnrere túmọ̀sí ‘ìròhìn rere.’ Ìròhìn rere ni pé Jésù Krístì ti ṣe ètùtù pípé fún gbogbo ènìyàn tí yíò ra gbogbo ènìyàn padà. … Àwọn àkọsílẹ̀ i`gbé ayé ikú Rẹ̀ àti àwọn i`ṣẹ̀lẹ̀ tí ó rọ̀ mọ́ iṣẹ́ iṣẹ́ ìránṣẹ́ Rẹ̀ ni à npè ní àwọn Ìhìnrere” (Ìtumọ̀ Bíbélì, “Àwọn Ìhìnrere”). Ikẹ́ta Nefi, tí a kọ sílẹ̀ nípasẹ̀ Nefi, ọmọ-ọmọ Helaman, ní a`kọsílẹ̀ kan nípa wíwà a`ti ìkọ́ni Jésù Krístì olùjínde ní àwọn Amerika ní kété lẹ́hìn ìkànmọ́ àgbélèbú Rẹ̀ àti, bákannáà, a tún lè tọ́kasi bíi “Ìhìnrere.” Àwọn ìwé marun ti ìwé mímọ́ jẹ́ ọ̀rọ̀yàn pàtàkì nítorí wọ́n ṣe àkọsílẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àti ipò nínú èyí tí Jésù Fúnrarẹ̀ fi taratara kọ́ni tí ó sì kópa. Wọ́n jẹ́ àmì bíbẹ̀rẹ̀ líle fún níní òye Jésù gẹ́gẹ́bí Krístì, ìbáṣepọ̀ wa sí I, àti ìhìnrere Rẹ̀.

  5. Wo Luke 19:1–4; bákannáà wo Jacob 4:13 (ó ṣálàyé pé Ẹ̀mí “nsọ̀rọ̀ àwọn ohun bí wọ́n ti jẹ́ gan an, àti nípa ohun gbogbo bí wọn ó ti jẹ́ gan an”) àti Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 93:24 (títúmọ̀ òtítọ́ bí “ìmọ̀ àwọn ohun bíwọ́n ti jẹ́, àti bí wọ́n ti wà, àti bí wọ́n ó ti wá”).

  6. Ààrẹ J. Reuben Clark bákannáà gbaniníyànjú àṣàrò “ìgbé ayé Olùgbàlà bí ọlọ́lá tòótọ́.” Ó pe àwọn ẹlòmíràn láti wà nínú àwọn àkọsílẹ̀ ti-ìwé mímọ́ ìgbé ayé Jésù Krístì, láti gbìyànjú àti láti “lọ lẹgbẹ pẹ̀lú Olùgbàlà, gbé pẹ̀lú rẹ̀, jẹ́ kí ó jẹ́ ọkùnrin tòótọ́, ìlàjì tọ̀run, bẹ́ẹ̀ni, ṣùgbọ́n bíótiwù kí o´ rí nlọ bí ọkùnrin kan tí ó nlọ ní àwọn ọjọ́ wọnnì.” Síwájú síi Ó ṣe ìlérí pé irú ìtiraka kan “yíò fún yín ní irú ìwò kan nípa rẹ̀, irú àṣepọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ bí mo ti rò pé ẹ kò lè gbà ní ọ̀nà míràn. … Kọ́ ohun tí ó ṣe, ohun tí ó ro, ohun tí ó kọ́. Ṣe bí ó ti ṣe. Gbé bí ó ti gbé, bí a ti lè ṣe tó. Ó jẹ́ ẹni pípé” (J. Reuben Clark, Jr.,Kíyèsí Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run (1962], 8–11). Fún òye nípa iyì àti àwọn èrèdí fún ṣíṣe àṣàrò Jésù ní ọ̀ràn ti àkọọ́lẹ̀-ìtàn, wo N. T. Wright àti Michael F. Bird., The New Testament in Its World (2019), 172–87.

  7. Joseph B. Wirthlin, “Òfin Nlá,” 30.

  8. Lúkù 1:37.

  9. Ní àfikú sí ìbánisọ̀rọ̀ déédé àti gígùn ti Mark 2:1–12 pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere ti Míṣọ̀n Czech Slovak, bákannáà mo fi ìmoore hàn fún àwọn ẹ̀kọ́ tí a kọ́ ní ríro àtẹ̀kọ yí pẹ̀lú àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìrni ní ibi ìmúrasílẹ̀ kílásì àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere ní èèkàn Highland Salt Lake àti àwọn olórí àti àwọn ọmọ-ìjọ ti Olùlànà YSA Salt Lake.

  10. Wo Mark 2:6-10.

  11. Márkù 12:41–44

  12. Wo Bruce M. Metzger àti Michael D. Coogan, The Oxford Companion to the Bible (1998), 104; James Martin, Jesus: A Pilgrimage (2014), 183–84.

  13. Wo Márkù 1:21–45

  14. Wo Márkù 2:1-2

  15. Wo Mark 2:2

  16. Wo Metzger and Coogan, The Oxford Companion to the Bible, 104; William Barclay, The Gospel of Mark (2001), 53.

  17. Wo Barclay, The Gospel of Mark, 53; see also Martin, Jesus: A Pilgrimage, 184.

  18. Wo Mark 2:2, 4; Bákannáà wo Barclay, Ìhìnrere ti Markù, 52–53. Barclay ṣe àlàyé pé “Ìgbé ayé ní Palestine jẹ́ ti gbangban gan. Ní òwúrọ̀ ilẹ̀kùn ẹnu ọ̀ná ṣí ẹnikẹ́ni tí ó bá sì fẹ́ lè jáde àti wọlé. Ilẹ̀kùn kò tì àyàfi tí ẹnìkan bá mọ̀ọ́mọ̀ fẹ́ ìkọ̀kọ̀; ilẹ̀kùn ṣíṣí túmọ̀ sí ìpè fún gbogbo ènìyàn láti wọlé. Nínú àwọn ilé onírẹ̀lẹ̀ bí irú [tí a fihàn ní Mark 2gbúdọ̀ ti jẹ́, kò sí ìwọlé gbàgede; olẹ̀kùn ṣí tààrà sí òpópónà. Nítorínáà, ní àìgba àkokò, ọ̀pọ̀ ènìyàn ti kún ilé dé òkè wọ́n sì ti pa pepele àyíká ilẹ̀kùn dé; gbogbo wọ́n sì ní ìlọ́ra fífetísílẹ̀ sí ohun tí Jésù níláti sọ.”

  19. Markù 2:4

  20. Wo Medical Dictionary of Health Termsẹ̀gbà,” health.harvard.edu.

  21. Wo Martin, Jésù: Arìnrìnàjò kan,183–84.

  22. Markù 2:4

  23. Wo Mark 2:4Bákannáà wo Julie M. Smith, “Ìhìnrere Gẹ́gẹ́bí Mark,” BYU Studies (2018), 155–71.

  24. Wo Mark 2:5-12

  25. Mark 2:5àfikún àtẹnumọ́.

  26. Matthew 9:8bákannáà wo Mark 2:12; Luke 5:26

  27. Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 62:3 ṣe àlàyé pé àwọn ìránṣẹ́ Olúwa di “alábùkún, nítorí ẹ̀rí tí ẹ ti jẹ́ ni akọsílẹ̀ ní ọ̀run … a sì ti dárí àwọn ẹ`ṣẹ̀ yín jì.”

  28. Wo M. Russell Ballard, “Ìrètí nínu Krístì,” Liahona, May 2021, 55–56. Ààrẹ Ballard kíyèsi pé “ọgbọ́n wíwà pẹ̀lú” ṣe pàtàkì sí ìlera ẹ̀mí àti ara papọ̀, a sì nṣe àkíyèsí pé “gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ inú ìyèjú wa, ìṣètò, wọ́ọ̀dù, àti àwọn èèkàn ní àwọn ẹ̀bùn àti tálẹ́ntì tí Ọlọ́run-fúnni tí ó lè ṣèrànwọ́ láti gbé ìjọba Rẹ̀ ga nísisìyí.” Bákannáà wo David F. Holland, Moroni: Ọ̀rọ̀ Ìṣíwájú Ránpẹ́ Ti-ẹ̀sin (2020), 61–65. Holland sọ àwọn ọ̀rọ̀ Moroni 6 àti àwọn ọ̀nà nínú èyí tí kíkópa àti jíjọ́sìn nínú ìletò ìgbàgbọ́ ṣèrànwọ́ láti mú irú ìrírí ti-ẹ̀mí araẹni diṣíṣe tí ó nso wá pọ̀ típẹ́típẹ́ sí Ọ̀run.

  29. Wo Dieter F. Uchtdorf, “Gbé Ibití O ti Dúró,” Liahona, Nov. 2008, 56. Alàgbà Uchtdorf ṣe àlàyé pé “kò sí ẹnìkankan lára wa tí ó lè tàbí gbúdọ̀ dá ti iṣẹ́ Olúwa síwájú. Ṣùgbọ́n bí gbogbo wa bá dúró papọ̀ ní ibi tí Olúwa ti yàn àti láti gbéga níbi tí a dúró, kò sí ohun tí ó lè dá iṣẹ́ tọ̀run yí dúró ní lílọ sókè àti síwájú.” Bákannáà wo Hong Chi (Sam) Wong, “Gbàlà nínú Ìrẹ́pọ̀,” Liahona, Nov. 2014, 15. Àwọn ìtọ́kasí Alàgbà Wong Mark 2:1–5 àti àwọn ìkọ́ni pé “ní èrò láti ran Olùgbàlà lọ́wọ́, a ní láti ṣiṣẹ́ papọ̀ nínú ìrẹ́pọ̀ àti ní ìbámu. Gbogbo ènìyàn, gbogbo ipò, àti pé gbogbo ìpè ní ó ṣe pàtàkì.”

  30. Oscar W. McConkie, nínú Ìròhìn Ìpàdé Àpapọ̀ Oct. 1952, 57.