Àwọn Ìwé Mímọ́
Mórónì 6


Orí 6

Àwọn ẹnití ó ronúpìwàdà ní a rìbọmi àti tí a nì ìdàpọ̀ pẹ̀lú—Àwọn ọmọ ìjọ́ tí ó ronúpìwàdà ni a dáríjì—A darí àwọn ìpàdé nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́. Ní ìwọ̀n ọdún 401 sí 421 nínú ọjọ́ Olúwa wa.

1 Àti nísisìyí èmi sọ̀rọ̀ nípa ìrìbọmi. Ẹ kíyèsĩ, àwọn àgbàgbà, àwọn àlùfã, àti àwọn olùkọ́ni ni a rìbọmi; a kò sì rì wọ́n bọmi bíkòṣepé wọ́n so èso èyítí ó yẹ tí o sì fi hàn pé ó tọ́ sí wọn.

2 Bẹ̃ní wọn kò gbà kí ẹnikẹ́ni ó ṣe ìrìbọmi àfi bí wọ́n bá jáde wá pẹ̀lú ìròbìnújẹ́ àti ìrora ọkan àti ẹ̀mí ìròbínújé, tí wọ́n sì jẹrì sí ìjọ nã pé wọ́n ronúpìwàdà nítõtọ́ kúrò nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

3 Kò sì sí àwọn ènìyàn tí a gbà sínú ìrìbọmi bíkòṣepé wọ́n gbà orúkọ Krístì, tí wọn sì ni ìpinnu láti sìn ín títí dé òpin ayé wọn.

4 Àti lẹ́hìn tí wọ́n sì ti gbà wọ́n sínú ìrìbọmi, tí a tún wọn ṣe tí a sì ti wẹ̀ wọ́n mọ́ nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́, a kà wọ́n mọ́ àwọn ènìyàn ìjọ Krístì; a sì gbà orúkọ wọn, kí wọn ó lè máa rántí wọ́n àti kí wọn ó lè máa bọ́ wọn pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti o dara, láti pa wọ́n mọ́ nínú ọ̀nà tí o tọ́, láti pa wọn mọ́ pẹ̀lú ìṣọ́ra nínú àdúrà títí, ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ìtóye Krístì nìkan, ẹnití í ṣe olùpilẹ̀ṣẹ̀ àti aláṣepé ìgbàgbọ́ wọn.

5 Ìjọ́ nã a sì máa bá ara wọn péjọpọ̀ nígbàkũgbà, láti gbãwẹ̀ àti láti gbàdúrà, àti láti bá ara wọn sọ̀rọ̀ nípa àlãfíà ọkàn wọn.

6 Wọn a sì máa bá ara wọn péjọpọ̀ ni gbàkũgbà láti jẹ́ nínú àkàrà àti wáìnì, ní ìrántí Jésù Olúwa.

7 Wọ́n sì ṣọ́ra láti ríi pé kò sí aiṣedẽdé lãrín wọn; àti pé ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá rí tí ó nṣe àìṣedẽdé, tí àwọn ẹlẹ̃rí mẹ́ta nínú ìjọ, bá dá wọn lẹ́bi níwájú àwọn àgbàgbà, bí wọn kò bá sì ronúpìwàdà, tí wọn kò sì jẹ́wọ́, a ó pa orukọ wọn rẹ́, a kò sì ní kà wọ́n mọ́ àwọn ènìyàn Krístì.

8 Sùgbọ́n nigbakũgbà tí wọ́n bá ronúpìwàdà, tí wọ́n sì tọrọ ìdáríjì, pẹ̀lú ìronújinlẹ̀, a dárí jì wọ́n.

9 Ìjọ sì ní ó ndari àwọn ìpéjọpọ̀ wọn ní ìbámu pẹ̀lú iṣẹ́ Ẹ̀mí, àti nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́; nítorípé bí agbára Ẹ̀mí Mímọ́ bá ti darí wọn yálà láti wãsù ní, tabì láti gbani niyanju, tàbi láti gbàdúrà, tàbí láti bẹ̀bẹ̀, tàbi láti kọrin, àní bẹ̃ ní wọ́n ṣe.