Àwọn Ìwé Mímọ́
Mórónì 10


Orí 10

Ẹ̀rí nípa Ìwé ti Mọ́mọ́nì wá nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́—Àwọn ẹ̀bùn ti Ẹ̀mí ni a fifún àwọn olótitọ́ ènìyàn—Àwọn ẹ̀bùn ti Ẹ̀mí a máa bá ìgbàgbọ́ rìn—Ọ̀rọ̀ Mórónì jáde wá láti inú erupẹ̀—Ẹ wá sí ọ̀dọ̀ Krístì, kí a sì sọ yín di pípé nínú rẹ̀, kí ẹ̀yin ó sì sọ ẹ̀mí yín di mímọ́. Ní ìwọ̀n ọdún 421 nínú ọjọ́ Olúwa wa.

1 Nísisìyí èmi, Mórónì, kọ àwọn ohun díẹ̀ bí ó ti dára lójú mi; èmi sì kọ̀we sí àwọn arákùnrin mi, àwọn ara Lámánì; èmi sì fẹ́ kí wọn ó mọ̀ pé irínwó àti ogún ọdún ti kọjá láti ìgbà tí a ti fúnni ní àmì nípa bíbọ̀ Krístì.

2 Èmí sì fi èdìdí dì àwọn àkọsílẹ̀ wọ̀nyí, lẹhìn tí mo ti sọ̀rọ̀ díẹ̀ láti gbà yín níyànjú.

3 Ẹ kíyèsĩ, ẹ̀mi yíò rọ̀ yín pé nígbàtí ẹ̀yin yio bá kà àwọn ohun wọ̀nyí, bí ó bá jẹ́ ọgbọ́n nínú Ọlọ́run pé kí ẹ̀yin ó kà wọ́n, pé ẹyin ó rántí bí Olúwa tí ní ãnu tó sí àwọn ọmọ ènìyàn, láti igbà dídá Ádámù àní títí dé ìgbà tí ẹ̀yin yíò rí àwọn ohun wọ̀nyí gbà, kí ẹ sì ṣe àsarò lórí rẹ̀ nínú ọkàn yín.

4 Àti nígbatí ẹ̀yin yíò sì rí àwọn ohun wọ̀nyí gbà, èmi gbà yín níyànjú pé kí ẹ bẽrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, Bàbá Ayérayé, ní orukọ Krístí, bí àwọn ohun wọ̀nyí kò bá íṣe òtítọ́; bí ẹ̀yin yíò bá sì bẽrè, tọkàn-tọkàn pẹ̀lú gbogbo ìfẹ́ inú yín, pẹ̀lú ìgbàgbọ́ nínú Krístì, yíò fi òtítọ́ inú rẹ̀ hàn sí yín, nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ̀.

5 Àti nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́ ẹ̀yin lé mọ̀ òtítọ́ ohun gbogbo.

6 Ohunkóhun tí ó bá sì jẹ́ rere jẹ èyítí ó tọ́ àti tí í ṣe òtítọ́; nítorí èyí, kò sì ohun tí ó jẹ rere tí í sẹ Krístì, ṣùgbọ́n a máa jẹ́wọ́ pé òun ni.

7 Ẹ̀yin sì lè mọ̀ pé òun ni, nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́; nítorí èyí èmi yíò gbà yín níyànjú, pé kí ẹ máṣe sẹ́ agbára Ọlọ́run; nítorítí ó nṣiṣẹ́ nípa agbara, gẹ́gẹ́bí ìgbàgbọ́ àwọn ọmọ ènìyàn, ọ̀kan nã ní òní àti ní ọ̀la, àti títí láé.

8 Àti pẹ̀lú, mo gbà yín níyànjú, ẹ̀yin arákùnrin mi, pé kí ẹ máṣe sẹ́ àwọn ẹ̀bùn Ọ́lọ́run, nítorítí wọ́n pọ̀; wọ́n sì wá láti ọwọ́ Ọlọ́run kannã. Óríṣiríṣi ọ̀nà sì ni a ngbà fi fún ni ní àwọn ẹ̀bùn wọ̀nyí; ṣùgbọ́n Ọlọ́run kannã ní ẹni tí nṣe ohun gbogbo nínú ohun gbogbo; wọn a sì máa fifún ni nípa ìfihàn Ẹmi Ọlọ́run sí àwọn ènìyàn, láti ṣe ànfàní fún wọn.

9 Nítorí ẹ kíyèsĩ, nípa Ẹ̀mi Ọlọ́run a fi fún ẹnìkan láti kọ́ni ní ọ̀rọ̀ ọgbọ́n;

10 Àti fún ẹlòmíràn, láti kọ́ni ní ọ̀rọ̀ ìmọ̀ nípa Ẹ̀mí kánnã;

11 Àti fún ẹlòmíràn, ìgbàgbọ́ nlá èyítí ó pọ̀; àti fún ẹlòmíràn, ẹ̀bùn ìmúláradá nípa Ẹ̀mí kannã;

12 Àti pẹ̀lú, fún ẹlòmíràn, láti lè ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu nlá;

13 Àti pẹ̀lú, fún ẹlòmíràn, láti lè sọtẹ́lẹ̀ nípa ohun gbogbo;

14 Àti pẹ̀lú, fún ẹlòmíràn, láti máa rí àwọn ángẹ́lì àti ẹ̀mí tí njíṣẹ́ iranṣẹ;

15 Àti pẹ̀lú, fún ẹlòmíràn, onírúurú èdè;

16 Àti pẹ̀lú, fún ẹlòmíràn, ìtumọ̀ èdè àti onírúurú èdè.

17 Gbogbo àwọn ẹ̀bùn yĩ sì wá nípa Ẹ̀mí Krístì; a sì nfi wọ́n fún olukúlùkù; gẹ́gẹ́bí ó ti wù ú.

18 Èmi sì gbà yín níyànjú, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, pé kí ẹ rántí pé láti ọwọ́ Krístì ni gbogbo ẹbun rere ti wá.

19 Èmi sì gbà yín níyànjú, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, pé kí ẹ rántí pé òun ni ọ̀kan nã ní àná, ní òní, àti títí láé, àti pé gbogbo àwọn ẹ̀bùn wọ̀nyí tí èmi ti sọ nípa wọn, èyítí í ṣe ti ẹ̀mí, kò lè parẹ́, àní ní ìwọ̀n ìgbà tí ayé yíò wà, àfí nípa àìgbàgbọ́ àwọn ọmọ ènìyàn nìkan.

20 Nítorí èyí, ó yẹ kí ìgbàgbọ́ ó wà; bí ó bá sì yẹ kí ìgbàgbọ́ ó wà ìrètí níláti wà pẹ̀lú; bí ó bà sì yẹ kí ìrètí ó wà ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ níláti wà.

21 Àti pé àfi bí ẹ̀yin bá ní ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ a kò lè gbà yín là nínú ìjọba Ọlọ́run; bẹ̃ni a kò lè gbà yín là nínú ìjọba Ọlọ́run bí ẹ kò bá ní ìgbagbọ́; bẹ̃ni a kò lè gbà yín la bí ẹ kò bá ní ìrètí.

22 Bí ẹ̀yin kò bá sì ní ìrètí ó di dandan ki ẹ̀yin wà láìnírètí, àìnírètí sì nwa nítorí àìṣedẽdé.

23 Krístì sì sọ nítõtọ́ fún àwọn baba wa pé: Bí ẹ̀yin bá ní ìgbàgbọ́ ẹ̀yin yíò ṣe ohun gbogbo tí ó tọ́ sí mi.

24 Àti nísisìyí èmi nbá gbogbo ìkangun ayé sọ̀rọ̀—pé bí ọjọ́ nã bá dé tí agbara àti àwọn ẹ̀bùn Ọlọ́run yíò dẹ́kun, yíò rí bẹ̃ nítorí àìgbàgbọ́.

25 Ègbé sì ní fún àwọn ọmọ ènìyàn bí ó bá rí báyĩ; nítorítí kì yíò sì ẹnikẹ́ni tí nṣe rere lãrín yín, rárá kòsí ẹnìkan. Nítorí bí ẹnikan bá wà lãrín yin tí nṣe rere, yíò ṣiṣẹ́ nípa agbára àti àwọn ẹ̀bùn Ọlọ́run.

26 Ègbé sì ni fún àwọn tí yíò mú àwọn ohun wọ̀nyí kúrò tí wọn sì kú, nítorítí wọ́n kú nínú ẹṣẹ wọn, a kò sì lè gbà wọ́n là nínú ìjọba Ọlọ́run; èmi sì nsọ ọ́ gẹ́gẹ́bí àwọn ọ̀rọ̀ Krístì; èmi kò sì purọ́.

27 Mo sì gbà yín níyànjú láti ranti àwọn ohun wọ̀nyí; nítorítí àkókò nã yíò dé kánkán tí ẹ̀yin yíò mọ̀ pé èmi kò purọ́, nítorítí ẹ̀yin ó rí mi níwájú ìtẹ́ ìdájọ́ Ọlọ́run; Olúwa Ọlọ́run yíò sì wí fún yín pe: Njẹ èmi kò ha kéde ọ̀rọ̀ mi fun yín bí, àwọn tí ọkùnrin yĩ kọ, bí ẹnití nkígbe jáde láti ipò òkú, bẹ̃ni, àní bí ẹnití nsọ̀rọ̀ jáde wá láti inú erùpẹ̀?

28 Mo sọ àwọn ohun wọ̀nyí sí ti ìmúṣẹ àwọn ìsọtẹ́lẹ̀. Ẹ sì kíyèsĩ, wọn yíò jáde lọ láti ẹnu Ọlọ́run tí ó wà títí ayé; ọ̀rọ̀ rẹ̀ yíò sì kọ jáde láti ìran dé ìran.

29 Ọlọ́run yíò sì fi hàn sí ọ, pé èyítí èmi ti kọ jẹ́ òtítọ́.

30 Àti pẹ̀lú èmi yíò gbà yín níyànjú pé kí ẹ wá sí ọ̀dọ̀ Krístì, kí ẹ sì dì ẹ̀bùn gbogbo èyí tí í ṣe rere mú, kí ẹ má sì ṣe fi ọwọ́ kàn ẹ̀bùn búburú, tàbí ohun àìmọ́.

31 Kí o sì jí, kí o sì dìde kúrò nínú erùpẹ̀, A! Jerúsálẹ́mù; bẹ̃ni, kí o sì gbé ẹ̀wù arẹwà rẹ wọ̀, A! ọmọbìnrin Síónì; kí o sì fí agbára kún àwọn àgọ́ rẹ kí o sì fẹ̀ ìpínlẹ̀ rẹ títí láé kí á má sì ṣe dàmú rẹ mọ́, kí àwọn májẹ̀mú Bàbá Ayérayé èyítí ó tí dá pẹ̀lú rẹ, A! ìdílè Isráẹ́lì ó lè di mìmúṣẹ.

32 Bẹ̃ni, ẹ wá sí ọ̀dọ̀ Krístì, kí a sì sọ yín di pípé nínú rẹ̀, kí ẹ sì sẹ́ ara yín ní ti gbogbo àìwà-bí-Ọlọ́run; bí ẹ̀yin bá sì sẹ́ ara yín ní ti gbogbo àìwà-bí-Ọlọ́run, àti kí ẹ sì fẹ Ọlọ́run pẹ̀lu gbogbo agbara, iyè àti ipá yín, nígbànã ni õre-ọ̀fẹ́ rẹ̀ sì tó fún yín, pé nípa õre-ọ̀fẹ́ rẹ̀ ẹ̀yin lè di pípé nínú Krístì; àti nípa õre-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run bí ẹ̀yin bá di pípé nínú Krístì, ẹ̀yin kò lè sẹ́ agbára Ọlọ́run.

33 Àti pẹ̀lú, bí ẹ̀yín bá jẹ́ pípé nínú Krístì nípa õre-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run, tí ẹ kò sì sẹ́ agbara rẹ̀, nígbànã ni a ó sọ yín di mímọ́ nínú Krístì nípa õre-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run, nípasẹ̀ títa ẹ̀jẹ̀ Krístì sílẹ̀, èyítí ó wà nínú májẹ̀mú ti Bàbá sí ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín, kí ẹ̀yin ó lè di mímọ́, láìní àbàwọ́n.

34 Àti nísisìyí mo kí yín, ó dìgbóṣe. Èmí yíò lọ sì párádísè Ọlọ́run láìpẹ́ yĩ, títí ìgbàtí ẹ̀mí àti ara mi yíò tún dàpọ̀, tí á ó sì mú mi jáde pẹ̀lú ayọ̀ ìṣẹ́gun nínú òfúrufú, láti pàdé yín níwájú ìtẹ́ ìdájọ́ aláyọ̀ ti Jèhófàh nlá, Onídàjọ́ Ayérayé tí ãye àti òkú. Àmín.

Ìparí