Àwọn Ìwé Mímọ́
Mórónì 9


Èpístélì kejì tí Mọ́mọ́nì sí ọmọ rẹ̀, Mórónì.

Èyítí a kọ sí orí 9.

Orí 9

Àwọn ará Nífáì àti àwọn ara Lámánì di búburú, wọn sì fàsẹ́hìn—Wọn dá ara wọn lóró wọn sì pa ara wọn—Mọ́mọ́nì gbàdúrà kí õre-ọ̀fẹ́ àti ire ó wà pẹ̀lú Mórónì títí láé. Ní ìwọ̀n ọdún 401 sí 421 nínú ojọ́ Olúwa wa.

1 Ọmọ mi àyànfẹ́, mo tún kọ̀wé sí ọ kí ìwọ ó lè mọ̀ pé mo sì wà lãyè; ṣùgbọ́n èmi yíò kọ nípa ohun tí o bani nínú jẹ́.

2 Nítorí kíyèsĩ, mo ti jà ogun tí ó gbóná gidigidi pẹ̀lú àwọn ará Lámánì, nínú èyítí àwa kò ṣẹ́gun; Ákíantúsì sì ti ṣubú nípasẹ̀ idà, àti Lúrámù pẹ̀lú àti Ẹ́mrọ́mù; bẹ̃ni, àwa sì ti pàdánù púpọ̀ nínú àwọn ènìyàn wa tí ó jẹ́ àṣàyàn.

3 Àti nísisìyí kíyèsĩ, ọmọ mi, mo bẹ̀rù pé àwọn ará Lámánì yíò pa àwọn ènìyàn yĩ run; nítorítí wọn kò ronúpìwàdà, Sátánì sì nrú wọn sókè títí ní ìbínú sí ara wọn.

4 Kíyèsĩ, èmi nṣiṣẹ́ pẹ̀lú wọn títí; nígbàtí mo bá sì sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pẹ̀lú ìjáfáfá wọn a máa wárìrì wọn a sì máa bínú sí mi; nígbàtí èmi kò bá sì sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ìjáfáfá wọn a sé ọkàn wọn le sí i; nítorí èyí, èmi bẹ̀rù pé Ẹ̀mi Olúwa ti dẹ́kun láti máa bá wọn gbé.

5 Nítorítí wọn bínú gidigidi tóbẹ̃ tí mo wòye pé wọn kò ní bẹ̀rù fún ikú; wọ́n sì ti pàdánù ìfẹ́ tí wọ́n, ní ọ̀kan sí ẹlòmíràn; wọn a sì máa pòùngbẹ ẹ̀jẹ̀ àti ìgbẹ̀san títí.

6 Àti nísisìyí, ọmọ mi àyànfẹ́, l’áìṣírò sísé le ọkàn wọn, jẹ́ kí àwa ó ṣiṣẹ́ tọkàn-tọkàn; nítorí bí àwa bá dẹ́kun láti máa ṣiṣẹ́, a ó gbà ìdálẹ́bi; nítorítí a ní iṣẹ́ láti ṣe nígbàtí a wà nínú àgọ ara yĩ, kí àwa ó lè ṣẹ́gun ẹnití ó jẹ́ ọ̀tá sí gbogbo ohun tí í ṣe òdodo, kí a sì fún ẹ̀mí wa ni ìsimi nínú ìjọba Olọ́run.

7 Àti nísisìyí mo kọ̀wé díẹ̀ sí ọ nípa ìjìyà àwọn ènìyàn yĩ. Nítorí gẹ́gẹ́bí ìmọ̀ tí mo ti gbà láti ọwọ́ Ámórónì, kíyèsĩ, àwọn ará Làmánì ní àwọn òndè tí ó pọ̀, àwọn tí wọn mú láti ilé-ìṣọ́ Ṣẹrísáhì; wọ́n sì jẹ́ ọkùnrin, obìnrin àti ọmọdé.

8 Àwọn ọkọ àti àwọn bàbá àwọn obìnrin àti àwọn omọde nã ní wọ́n sì ti pa; wọ́n sì nbọ́ àwọn obìnrin nã pẹ̀lú ẹran ara àwọn ọkọ wọ̀n, àti àwọn ọmọ pẹ̀lú ẹran-ara àwọn bàbá wọn; wọn kòsì fún wọn ní omi, àfi díẹ̀.

9 Àti l’áìṣírò àwọn ìwa ìríra púpọ̀ ti àwọn ara Lámánì yĩ, kò tàyọ tí àwọn ènìyàn wa ní Móríántúmù. Nítorí kíyèsĩ, wọn ti mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọbìnrin àwọn ará Lámánì ní ìgbèkùn; àti lẹ́hìn tí wọ́n ti gbà èyítí ó ṣe ọ̀wọ́n jùlọ àti tí ó níye lórí jù ohun gbogbo, èyítí í ṣe wíwà ní mímọ́ àti ìwá-rere—

10 Àti lẹ́hìn tí wọ́n ti ṣe eleyĩ, wọ́n pa wọn ní ọ̀nà tí ó rorò jùlọ, tí wọ́n ndá wọn lóró títí wọ́n fi kú; àti lẹ́hìn tí wọ́n ti ṣe eleyĩ, wọ́n a jẹ ẹran ara wọn bĩ ti àwọn ẹranko búburú, nítorí síséle ọkàn wọn; wọn á sì ṣe é gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí sí ìgboyà.

11 A! ọmọ mí àyànfẹ́, báwo ni irú àwọn ènìyàn báyĩ, tí wọn kò ní ọ̀làjú—

12 (Ọdún díẹ̀ ní ó sì ti kọjá lọ, láti ìgbàti wọ́n jẹ́ ọ̀làjú ènìyàn àti ẹnití ó wuni)

13 Ṣùgbọ́n A! ọmọ mi, báwo ni irú àwọn ènìyàn báyĩ, tí ìdùnnú wọn wà nínú ìwà ìríra púpọ̀—

14 Báwo ní àwa ó ṣe retí kí Ọlọ́run o dá ọwọ́ ìdájọ́ rẹ̀ sí wa duro?

15 Kíyèsĩ, ọkàn mí nkígbe pé: Ègbé ni fun àwọn ènìyàn yĩ. Jáde wá nínú ìdájọ́, A! Ọlọ́run, kí o sì fi ẹ̀ṣẹ̀ wọn pamọ́, àti ìwà íkà, àti àwọn ohun ìríra kúrò níwájú rẹ!

16 Àti pẹ̀lú, ọmọ mi, àwọn opó púpọ̀ àti àwọn ọmọbìnrin wọn ni ó kù sẹ́hìn ní Ṣẹrísáhì; àti àwọn ohun ìpèsè tí àwọn ará Lámánì kò kó lọ, kíyèsĩ, ẹgbẹ́ ọmọ ogun Sénífáì ti kó wọn lọ, wọ́n sì fi wọ́n sílẹ̀ láti máa rìn kiri lọ sí ibikíbi tí wọn lè lọ láti wá oúnjẹ kiri; àwọn arugbó obìnrin púpò ní ãrẹ̀ mú ní ọ̀nà tí wọ́n sì kú.

17 Ẹgbẹ́ ọmọ ogun tí ó wà lọ́dọ̀ mi sì ṣe àìlera; àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Lámánì sì wà lãrín èmi àti Ṣẹ́rísáhì; gbogbo àwọn tí ó sì ti sá lọ sínu ẹgbẹ́ ọmọ ogun Áárọ́nì ní ó ti bọ́ sọ́wọ́ ìrorò búburú wọn.

18 A! wọ́n ti sọ àwọn ènìyàn mi di búburú tó! Wọ́n wà láìní ètò àti láìní ãnú. Kíyèsĩ, ènìyàn lásán ni mo jẹ́, agbara ènìyàn nìkan ni èmi sì ní, èmi kò sì lè pàṣẹ mọ́.

19 Wọ́n sì ti di alágbára nínú ìwa àrekérekè wọn; wọ́n sì rorò bákannã, wọn kò sì dá ènìkan sí, ní arúgbó ni tàbí ọmọdé; wọ́n sì ndùnnú sí ohun gbogbo àfi èyítí ó jẹ́ rere; ìjìyà àwọn obìnrin wa àti àwọn ọmọ wa lórí ilẹ̀ yĩ sì tayọ ohun gbogbo, bẹ̃ni, ahọ́n kò lè sọ, bẹ̃ni a kò lè kọ ọ́.

20 Àti nísisìyí, ọmọ mi, èmi kò sọ nípa ohun ìṣẹ̀lẹ̀ búburú yĩ mọ. Kíyèsĩ, ìwọ mọ̀ ìwà búburú àwọn ènìyàn yĩ; ìwọ mọ̀ pé wọn kò ní òfin, àyà wọn sì le rékọjá; ìwà búburú wọn sì tayọ tí àwọn ará Lámánì.

21 Kíyèsĩ, ọmọ mi, èmi kò lè sọ̀rọ̀ wọn ní réré fún Ọlọ́run kí ó má bã bá mi jà.

22 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, ọmọ mi, èmi sọrọ rẹ ní rere fun Ọlọ́run, èmi sì ní ìgbẹ́kẹ̀lè nínú Krístì pé a ó gbà ọ́ là; mo sì gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kí ó dá ẹ̀mí rẹ sí, láti lè rí pípadà àwọn ènìyàn rẹ̀ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, tàbí ìparun wọn pátápátá; nítorítí mo mọ̀ pé wọ́n níláti parun àfi bí wọ́n bá ronúpìwàdà kí wọ́n sì padà wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀.

23 Bí wọ́n bá sì parun yíò rí bĩ ti àwọn ará Járẹ́dì, nítorí ìfẹ inú ọkàn wọn láti mã lépa ìtàjẹ̀sílẹ́ àti ìgbẹ̀san.

24 Bí ó bá sì rí bẹ̃ tí wọ́n parun, àwa mọ̀ pé púpọ̀ nínú àwọn arákùnrin wa ni o ti fi wá sílẹ̀ láti lọ darapọ̀ mọ́ àwọn ará Lámánì, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ní yíò sì fi wá sílẹ̀ síi láti lọ darapọ̀ mọ́ wọn; nítorí èyí, kọ àwọn ohun díẹ̀, bí a bá sì dá ọ sí tí èmi sì parun tí èmi kò sì rí ọ mọ́; ṣùgbọ́n emi ní ìdánilójú pé èmi yíò rí ọ ní àìpẹ́; nítorí èmi ní àwọn àkọsílẹ̀ mímọ́ tí èmi fẹ́ láti gbé fún ọ.

25 Ọmọ mi, jẹ olótĩtọ́ nínú Krístì; njẹ́ kí àwọn ohun tí èmi ti kọ ó máṣe bà ọ́ nínú jẹ́, kí ó sì rìn ọ́ mọ́lẹ̀ dé ojú ikú; ṣùgbọ́n kí Krístì ó gbé ọ sókè, àti kí ìjìyà àti ikú rẹ̀, àti fifi ara rẹ̀ hàn sí àwọn baba wa, àti ãnú àti irọ́jú rẹ̀, àti ìrètí fún ògo rẹ̀ àti fún ìyè àìnípẹ̀kun, wọ̀ ínú ọkàn rẹ lọ títí láé.

26 Àti kí õre-òfẹ́ Ọlọ́run Baba, ẹnití ìtẹ́ rẹ̀ ga sókè nínú àwọn ọ̀run, àti Olúwa wa Jésù Krístì, ẹnití ó jóko ní ọwọ́ ọ̀tún agbára rẹ̀, títí ohun gbogbo yíò wà lábẹ́ àṣẹ rẹ̀, kí ó wà, kí ó sì máa bá ọ gbé títí láé. Àmín.