Àwọn Ìwé Mímọ́
Mórónì 8


Orí 8

Ìrìbọmi àwọn ọmọdé jẹ́ ohun ìríra búburú—Àwọn ọmọdé wà lãyè nínú Krístì nítorí Etùtù nã—Ìgbàgbọ́, ìrònúpìwàdà, ìwà tútù àti ọkàn-ìrẹ̀lẹ̀, gbígbà Ẹ̀mí Mímọ́, àti ìfọkànrán dé opin ntọ́ni sí ìgbàlà. Ní ìwọ̀n ọdún 401 sí 421 nínú ọjọ́ Olúwa wa.

1 Èpístélì bàbá mi Mọ́mọ́nì, èyítí ó kọ sí èmi, Mórónì; o sì kọ ọ́ sí mi ní kété lẹhìn ìpè mi sínú iṣẹ́ ìránṣẹ́. Ní ọ̀nà yĩ ní ó sì fi kọ̀wé sí mi wípé:

2 Àyànfẹ́ ọmọ mí, Mórónì, inú mi dùn lọ́pọ̀lọpọ̀ pé Olúwa rẹ Jésù Krístì ti fi ọ si ọkàn, ó sì ti pè ọ́ sínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀, àti sínú iṣẹ́ mímọ́ rẹ̀.

3 Mo nfi ọ si ọkan ní ìgbàgbogbo nínú àdúrà mi, tí mo sì ngbàdúrà títí sí Ọlọ́run Bàbá ní orukọ Ọmọ rẹ̀ Mímọ́, Jésù, pé òun, nípasẹ̀ ìwà rere àti õre-ọ̀fẹ́ rẹ̀ aláìlópin, yíò pa ọ́ mọ́ nípa ìfọkànrán nínú ìgbàgbọ́ nínú orúkọ rẹ̀ titi dé òpin.

4 Àti nísisìyí, ọmọ mi, mo nbá ọ sọ̀rọ̀ nípa ohun tí ó nbá mí nínújẹ́ gidigidi; nítorítí ó nbá mí nínújẹ́ pé àríyànjiyàn wà lãrín yín.

5 Nítorí, bí èmi bá tí mọ̀ èyítí í ṣe òtítọ́, àríyànjiyàn ti wà lãrín yín nípa ìrìbọmi àwọn ọmọde yín.

6 Àti nísisìyí, ọmọ mi, mo fẹ́ kí ó ṣiṣẹ́ tọkàn-tọkàn, pé kí o mú àṣìṣe búburú yĩ kúrò lãrín yín; nítorípé, fún ìdí yĩ ni èmi ṣe kọ èpístélì yĩ.

7 Ní kété lẹhìn tí mó tí gbọ́ nípa àwọn ohun yĩ nípa yín mó ṣe ìwádi lọdọ̀ Olúwa nípa ọ̀rọ̀ nã. Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ mí wá nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́, wípé:

8 Fetísílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ Krístì, Olùràpadà rẹ, Olúwa rẹ àti Ọlọ́run rẹ. Kíyèsĩ, èmi kò wá sínú ayé láti pè àwọn olódodo bíkòṣe àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ sí ìrònúpìwàdà; àwọn tí ara wọn le kì í wá oníṣègùn, bíkòṣe àwọn tí ara wọn kò dá; nítorí èyí, àwọn ọmọdé wà ní aláìlẹ́ṣẹ̀, nítorítí wọn kò lè dẹ́ṣẹ̀; nítorí èyí ni a ṣe mú ègún Ádámù kúrò lórí wọn nítorí mi, pé kò lágbára lórí wọn; òfin ti ìkọlà ní a sì ti mú kúrò nítorí mi.

9 Ní ọ̀nà yĩ sì ni Ẹ̀mí Mímọ́ fí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run hàn sí mi; nítorí èyí, ọmọ mi àyànfẹ́, èmi mọ̀ pé ẹ̀tàn ni èyí jẹ́ níwájú Ọlọ́run, pé kí ẹ̀yin ó ṣe ìrìbọmi fún àwọn ọmọdé.

10 Kíyèsĩ mo wí fún ọ pé ohun yĩ ni ìwọ yíò kọ́ni—ìronúpìwàdà àti ìrìbọmi fún àwọn tí ó ti tó ójú bọ́ àti tí ó ti gbọ́n láti dẹ́ṣẹ̀; bẹ̃ni, kọ́ àwọn òbí pé wọ́n gbọdọ̀ ronupiwada kí a sì ṣe ìrìbọmi fun wọn, kí wọn ó sì rẹ̀ ara wọn sílẹ̀ bí ọmọdé, a ó sì gbà gbogbo wọn là pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn—

11 Àwọn ọmọde wọn kò níláti ṣe ìrònúpìwàdà, tabi ìrìbọmi. Kíyèsĩ ìrìbọmi wà fun ìrònúpìwàdà sí pípa àwọn òfin mọ́ fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀.

12 Ṣùgbọ́n àwọn ọmọdé wà lãyè nínú Krístì, àní láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé; bí kò bá rí bẹ̃, Ọlọ́run jẹ́ Ọlọ́run tí i ṣe ojúṣãjú, àti Ọlọ́run tí í yípadà, àti tí í bẹ̀rù ènìyàn; nítorí àwọn ọmọde mélo ni ó ha ti kú láìṣe ìrìbọmi!

13 Nítorí èyí, bí àwọn ọmọdé kò bá lè ní ìgbàlà láìṣe ìrìbọmi, èyi já sí pé wọ́n ti lọ sí ọ̀run àpãdì tí kò lópin.

14 Kíyèsĩ mo wí fun ọ, pé ẹnití ó bà rò pé àwọn ọmọdé yẹ fún ìrìbọmi òun ni ó wà nínú ìkorò òrõró àti ìdè aisedede; nítorítí kò ní èyítí í ṣe ìgbàgbọ́, ìrètí tàbí ìfẹ́ aláìlegbẹ́; nítorí èyí bí a bá ké e kúrò nígbàtí ó wà nínú èrò nnì, ọ̀run àpãdì ní yíò lọ.

15 Nítorí búburú rẹ̀ pọ̀ jùlọ láti rò pé Olọ́run yíò gbà ọmọ kan là nítorí ìrìbọmi, tí òmíràn yíò sì ṣègbé nítorípé kò ní ìrìbọmi.

16 Ègbé ni fun àwọn ẹniti yíò yí ọ̀nà Olúwa pó ní ọ̀nà yĩ, nítorítí wọn yíò ṣègbé àfi bí wọn bá ronúpìwàdà. Kíyèsĩ mo nsọ̀rọ̀ pẹ̀lú ìgboyà, nítorípé mó ní àṣẹ láti ọwọ́ Ọlọ́run; èmi kò sì bẹ̀rù ohun tí ènìyàn lè ṣe; nítorí ìfẹ́ tí ó pé a máa lé ìbẹ̀rù jáde.

17 Èmi si kún fún ìfẹ́ aláìlẹgbẹ́, èyítí í ṣe ìfẹ́ títí ayé; nítorí èyí, gbogbo ọmọdé ní ó jẹ́ bákannã sí mi; nítorí èyí, mo ní ìfẹ́ àwọn ọmọdé pẹ̀lú ìfẹ́ pípé; gbogbo wọn sì jẹ́ bákannã wọ́n sì jẹ́ alábãpín nínú ìgbàlà.

18 Nítorípé mo mọ̀ pé Olọ́run kì í ṣe Ọlọ́run tí í ṣe ojúṣãjú, bẹ̃ní kì í ṣe ẹ̀dá tí í yípada ṣùgbọ́n ó wà ní àìyípadà láti gbogbo ayérayé dé gbogbo ayérayé.

19 Àwọn ọmọdé kò lè ronúpìwàdà; nítorí èyí ohun búburú pupọ̀ jùlọ ni ó jẹ́ láti sẹ́ ọ̀pọ̀ ãnú Ọlọ́run tí ó wà lórí wọn, nítorítí wọ́n wà lãyè nínú rẹ̀ nítorí ãnú rẹ̀.

20 Ẹnití ó bà sì sọ wípé àwọn ọmọdé yẹ fún ìrìbọmi ní ó sẹ́ ãnú Krístì, tí ó sì kà ètùtù rẹ̀ àti agbára ìràpadà rẹ̀ kún asán.

21 Ègbé ni fún irú ẹni bẹ̃, nítorítí wọ́n wà nínú ewu ikú, ọrun àpãdì, àti oró àìnípẹ̀kún. Mo sọ ọ́ pẹ̀lú ìgboyà; Ọlọ́run ní ó pã laṣẹ fún mi. Fetí sílẹ̀ sí wọn àti kí ó ṣe àkíyèsí wọn, bíkòṣe bẹ̃ wọn yíò dúró ni ìtakò yín ní ìtẹ́ ìdájọ́ Krístì.

22 Nítorí kíyèsĩ pé gbogbo ọmọdé ni ó wà lãyè nínú Krístì, àti pẹ̀lú gbogbo àwọn tí ó wà láìní òfin. Nítorítí agbara ìràpadà wà fún gbogbo àwọn tí kò ní òfin; nítorí èyí, ẹnití a kò bá dálẹ́bi, tàbí írú ẹnití kò sí lábẹ́ ìdálẹ́bi rárá, kò lè ronúpìwàdà; irú ẹni bẹ̃ ìrìbọmi kò jámọ́ nkan fún un—

23 Sùgbọ́n ẹ̀tàn ní èyí níwájú Ọlọ́run, sísẹ́ ãnú Krístì, àti agbára Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ̀, ó sì nfi ìgbẹ́kẹ̀lé sínú òkú iṣẹ́.

24 Kíyèsĩ, ọmọ mi, èyí kò yẹ kí ó rí bẹ̃; nítorítí ìrònúpìwàdà wà fún ẹnití ó wà ní abẹ́ ìdálẹ́bi àti ní abẹ́ ègún òfin rírú.

25 Eso àkọ́kọ́ ìrònúpìwàdà sì ni ìrìbọmi; ìrìbọmi a sì máa wá nípa ìgbàgbọ́ sí pípa àwọn òfin mọ́; pípa àwọn òfin mọ́ a sì máa mú ìdárijì ẹ̀ṣẹ̀ wá;

26 Ìdárijì a sì máa mú ìwà-tútù wá, àti ìrẹ̀lẹ̀ ọkàn; àti nítorí ìwàtútù àti ìrẹ̀lẹ̀ ọkàn ìbẹ̀wò Ẹ̀mí Mímọ́ a máa wá, Olùtùnú èyítí fún ni ní ìrètí àti ìfẹ pípé, ìfẹ́ èyítí ífàyàrán ohun nípa ìtẹramọ́ nínú àdúrà gbígbà, títí òpin yíò dé, nígbàtí gbogbo ènìyàn mímọ́ yíò bá Ọlọ́run gbé.

27 Kíyèsĩ, ọmọ mi, èmi yíò tún kọ̀wé sí ọ bí èmi kò bá tún tĩ lọ́ kọlũ àwọn ará Lámánì. Kíyèsĩ, ìgbéraga orílẹ̀-èdè yĩ, tàbí àwọn ènìyàn ará Nífáì tí jẹ́ ohun ìparun fún wọn àfi bí wọn bá ronúpìwàdà.

28 Gbàdúrà fún wọn, ọmọ mi, kí ìrònúpìwàdà ó lè bá wọn. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ mo bẹ̀rù pé Ẹ̀mí Mímọ́ ti dẹ́kun láti bá wọn gbé; àti ní apá ilẹ̀ ibí yĩ wọn nwa ọ̀nà pẹ̀lú láti bì gbogbo agbára àti àṣẹ tí ó wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ṣubú; wọ́n sì nsẹ́ Ẹ̀mí Mímọ́.

29 Àti lẹ́hìn tí wọ́n ti kọ̀ ìmọ̀ nlá nã, ọmọ mi, wọ́n gbọ́dọ̀ ṣègbé ní kánkán, sí ti ìmúṣẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ èyítí àwọn wòlĩ ti sọ, àti ọ̀rọ̀ Olùgbàlà wa fúnrarẹ̀ pẹ̀lú.

30 Ó dìgbóṣe, ọmọ mi, títí èmi yíò kọ̀wé sí ọ, tàbí tún bá ọ pàdé. Àmín.