Àwọn Ìwé Mímọ́
Mórónì 1


Ìwé ti Mórónì

Orí 1

Mórónì kọ̀wé fún ànfàní àwọn ara Lámánì—Àwọn ara Nífáì tí kò sẹ́ Krístì ni wọ́n pa. Ní ìwọ̀n ọdún 401 sí 421 nínú ọjọ́ Olúwa wa.

1 Nísisìyí èmi, Mórónì, lẹ́hìn tí mó ti pari ṣíṣe ìkékúrú ọ̀rọ̀ nípa àwọn ènìyàn Járẹ́dì, mo lérò láti má kọ ohunkóhun mọ́, sùgbọn èmi kò ṣá tĩ kú; èmi kò sì fí ara mi hàn sí àwọn ara Lámánì ní ìbẹ̀rù pé wọn yíò pa mi run.

2 Sì kíyèsĩ, àwọn ogun wọn gbóná lọ́pọ̀lọpọ̀ lãrín ara wọn; àti nítorí ìkórira wọn, wọ́n pa gbogbo ará Nífáì tí kò sẹ́ Krístì.

3 Emí, Mórónì, kò sì ní sẹ́ Krístì; nítorí èyí, mo nrìn kiri sí ibikíbi tí mo bá lè lọ fún ãbò ẹ̀mí mi.

4 Nítorí èyí, mo kọ ohun díẹ̀ sí i, ní ìyàtọ̀ sí ohun tí èmi rò láti ṣe tẹ́lẹ̀; nítorítí èmi lérò láti má kọ ohunkóhun mọ; ṣùgbọn mo kọ ohun díẹ̀ síi, pé bóyá wọ́n lè wúlò fún àwọn arákùnrin mi, àwọn ara Lámánì, ní ọjọ́ iwájú, ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Olúwa.