Àwọn Ìwé Mímọ́
Étérì 15


Orì 15

Ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̃gbẹ̀rún àwọn ara Jarẹ́dì ni wọ́n pa nínú ogun—Ṣísì àti Kóríántúmúrì kó gbógbo àwọn ènìyàn nã jọ sí ìjà àjàkú—Ẹ̀mí Olúwa dẹ́kun láti mã bá wọn jà—Ọrilẹ̀ èdè àwọn ará Járẹ́dì ni a parun pátápátá—Kóríántúmúrì nìkan ní ó kù lẹ́hìn.

1 Ó sì ṣe nígbàtí Kóríántúmúrì ti bọ̀sípò ní ti àwọn ọgbẹ́ rẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀sí rántí àwọn ọrọ̀ tí Étérì ti sọ fún un.

2 Ó rí í pé wọ́n ti fi idà pa àwọn tí ó fẹ́rẹ́ tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀rún méjì nínú àwọn ènìyàn rẹ̀, ó si bẹ̀rẹ̀sí ní irora ọkàn nínú ọkàn rẹ̀; bẹ̃ni, wọ́n ti pa ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀rún méjì àwọn ọkùnrin alágbára, àti pẹlú àwọn aya wọn àti àwọn ọmọ wọn.

3 O sì bẹ̀rẹ̀sí ronúpìwàdà kúrò nínú ohun búburú tí ó ti ṣe; ó bẹ̀rẹ̀sí rántí àwọn ọ̀rọ̀ tí a ti sọ fún un láti ẹnu gbogbo àwọn wòlĩ, ó sì rí i pé, wọ́n ti dì mímúṣẹ títí di àkókò yĩ, títí dé èyítí ó kéré jùlọ; ọkàn rẹ̀ sì sọ̀fọ̀ ó sì kọ̀ láti gbà itùnú.

4 Ó sì ṣe tí ó kọ èpístélì kan sí Ṣísì, pé òun fẹ́ kí ó dá àwọn ènìyàn nã sí, àti pe òun yíò gbé ìjọba nã lélẹ̀ nítorí ẹ̀mi àwọn ènìyàn nã.

5 O sì ṣe nígbàtí Ṣísì tí rí èpístélì rẹ̀ gbà ó kọ èpístẹ́lì kan sí Kóríántúmúrì, pé bí yíò bá fi ara rẹ̀ lélẹ̀, kí òun ó lè pa pẹ̀lú idà rẹ̀, pé òun yíò dá ẹ̀mí àwọn ènìyàn nã sí.

6 Ó sì ṣe tí àwọn ènìyan nã kò ronúpìwàdà kúrò nínú àìṣedẽdé wọn; àwọn ènìyàn Kóríántúmúrì sì ru ara wọn sókè ní ìbínú sí àwọn ènìyàn Ṣísì; àwọn ènìyàn Ṣísì sì rú ara wọn sókè ní ìbínú sí àwọn ènìyan Kóríántúmúri; nítorí èyí, àwọn ènìyàn Ṣísì sì gbé ogun tì àwọn ènìyàn Kóríántúmúrì.

7 Nígbàtí Kóríántúmúrì sì ríi pé wọ́n fẹ́rẹ̀ borí òun ó tún sá níwájú àwọn ènìyàn Ṣísì.

8 Ó sì ṣe tí ó dé ibi omi Ríplíákúmì, ní ìtúmọ̀sí èyítí ó jẹ́ títóbi, tàbí jù gbogbo wọn; nítorí èyí, nígbàtí wọ́n dé ibi omi yĩ wọ́n pàgọ́ wọn; Ṣísì pẹ̀lú pàgọ́ rẹ̀ nítòsí ibẹ̀; àti nitorinã ní ọjọ́ kejì wọ́n tún bẹ̀rẹ̀ ogun jíjà.

9 O sì ṣe ti wọn jà ogun tí ó gbóná gidigidi, nínú èyítí wọ́n tún ṣa Kóríántúmúrì lọ́gbẹ́, ó sì dákú nítorítí ó pádánù ẹ̀jẹ̀.

10 Ó sì ṣe tí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Kóríántúmúrì sì dojúkọ àwọn egbẹ́ ọmọ ogun Ṣísì tí wọn bòrí wọn, tí wọ́n sì mú kí wọn ó sálọ níwájú wọn, wọ́n sì sálọ sí apá gũsù, wọ́n sì pàgọ́ wọn sí ibìkan tí wọn npè ní Ógátì.

11 Ó sì ṣe tí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Kóríántúmúrì sì pàgọ́ wọn sí ẹ̀bá òkè Rámà; òun sì ni òkè kannã níbití baba mi Mọ́mọ́nì gbé àwọn àkọsílẹ̀ pamọ́ sí Olúwa, tí wọ́n jẹ́ mímọ́.

12 Ó sì ṣe tí wọ́n sì kó gbogbo àwọn ènìyàn nã jọ papọ̀ sí gbogbo orí ilẹ̀ nã, àwọn tí wọn kò ì pa àfi Étérì.

13 O sì ṣe ti Étérì sì rí gbogbo ìṣe àwọn ènìyàn nã; ó sì ríi pé àwọn ènìyàn tí ó jẹ́ ti Kóríántúmúrì kójọpọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ ọmọ ogun Kóríántúmúrì; àwọn ènìyàn ti ó sì jẹ́ ti Ṣísì kójọpọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ ọmọ ogun Ṣísì.

14 Nítorí èyí, wọ́n fi ìwọ̀n ọdún mẹ́rin kó àwọn ènìyàn nã jọ, kí wọn ó lè rí gbogbo àwọn tí ó wà lórí ilẹ̀ nã, àti kí wọn ó lè gbà gbogbo agbára tí ó ṣẽṣe fún wọn láti rí gbà.

15 Ó sì ṣe nígbàtí gbogbo wọn ti kójọ pọ̀ tán, olukúlùkù mọ́ ẹgbẹ ọmọ ogun èyítí ó bá fẹ́, pẹ̀lú àwọn aya wọn àti àwọn ọmọ wọn—àti àwọn ọkùnrin, àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé wọn sì dì ìhámóra ogun pẹ̀lú àwọn ohun ìjà ogun, wọn sì ní àwọn àpáta, àti awo ìgbàyà, ati àwọn àwo àsíborí, wọ́n sì wọ̀ ẹ̀wù ogun—wọ́n sì jáde lọ ní ogun ọkan sí èkejì; wọ́n sì jà ní gbogbo ọjọ́ nã, kò sì sí ẹniti ó borí.

16 Ó sì ṣe nígbàtí ó dí àṣálẹ́, ó rẹ̀ wọ́n, wọ́n sì padà sí ibùdó wọn; lẹ́hìn tí wọ́n sì padà sí ibùdó wọn wọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí hu wọn sì npohùnréré ẹkún fún àdánù àwọn tí a pa nínú àwọn ènìyàn wọn; ìgbè wọn, híhu wọn àti ìpohùnrere ẹkún wọn sì pọ̀ tóbẹ̃ tí wọn wọ̀ inú afẹ́fẹ́ lọ púpọ̀púpọ̀.

17 Ó si ṣé ní ọjọ́ kejì wọ́n tún lọ jagun, ojọ́ nla èyítí ó burú sì ni ojọ́ nã; bíótilẹ̀ríbẹ̃, wọn kò borí, nígbàtí ó sì di àṣãlẹ́ wọ́n tún fi igbe wọn wọ inú afẹ́fẹ́, àti àwọn híhu wọn, àti àwọn ìkẹ́dùn ọkàn wọn, fún àdánù áwọn tí a pa nínú àwọn ènìyàn wọn.

18 Ó sì ṣe tí Kóríántúmúrì tún kọ èpistélì kan sí Ṣísì, nínú èyítí ó ní oun kò fẹ́ kí ó wa sí ogun mọ́, ṣùgbọ́n kí ó gbà ìjọba nã, kí ó sì dá ẹ̀mí àwọn ènìyàn nã sí.

19 Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, Ẹ́mí Olúwa ti dẹ́kun láti bá wọn gbé, Sátánì sì ni agbara lórí ọkàn àwọn ènìyàn nã pátápátá; nítorítí wọ́n ti jọ̀wọ́ ara wọn sílẹ̀ fún síséle ọkàn wọn, àti ọkàn wọn tí o fọ́jú kí wọn ó lè parun; nítorí èyí wọn tún lọ sí ogun.

20 Ó sì ṣe tí wọ́n jà ní gbogbo ọjọ nã, nígbàtí alẹ́ sì lẹ wọ́n sùn lórí àwọn idà wọn.

21 Àti ni ọjọ́ tí ó tẹ̀lẽ wọn jà titi ilẹ̀ fi sú.

22 Nígbàtí alẹ si lẹ́ wọn yó fún ìbínú, àní bí ẹnití ó yó pẹ̀lú wáìnì; wọ́n sì tún sùn lórí àwọn idà wọn.

23 Àti ní ọjọ́ tí ó tẹ̀lẽ wọ́n tún jà; nígbàtí alẹ́ sì lẹ́ gbogbo wọn ti ṣubú nípa idà, àfi àwọn méjìlélãdọ́ta nínú àwọn ènìyàn Kóríántúmúrì, àti àwọn mọ̀kàndínlãdọ́rin nínú àwọn ènìyàn Ṣísì.

24 Ó sì ṣe ti wọn sùn lori àwọn idà wọn ni alẹ́ ọjọ́ nã, àti ní ọjọ́ tí ó tẹ̀lẽ wọn tún jà, wọn sì jà pẹ̀lú gbogbo agbára wọn pẹ̀lú àwọn idà wọn ati pẹ̀lú àwọn àpáta wọn ní gbogbo ọjọ́ nã.

25 Nígbàtí ó sì di àsálẹ́ àwọn mẹ́jìlélọ́gbọ̀n àwọn ènìyàn Ṣísì ní ó wà, àti àwọn mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n àwọn ènìyàn Kóríántúmúrì.

26 Ó sì ṣe tí wọn jẹun wọ́n sì sùn, wọ́n sì múrasílẹ̀ dè ikú ní ọjọ́ tí ó tẹ̀lẽ. Wọ́n sì jẹ́ ènìyàn ti ó tóbi tí ó sì lágbára ni ti agbára ènìyàn.

27 Ó sì ṣe tí wọ́n jà fún ìwọ̀n wákàtí mẹ́ta, wọ́n sì dákú nítorípé wọ́n pàdánù ẹ̀jẹ̀.

28 Ó sì ṣe nígbàtí àwọn ọmọ ogun Kóríántúmúrì ti tún gbà agbára tó tí wọn lè rìn, wọ́n Ṣetán láti sá fún ẹ̀mí ara wọn; ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, Ṣísì dìde, àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ pẹ̀lú, ó sì búra nínú ìbínu rẹ̀ pé òun yíò pa Kóríántúmúrì tàbí kí òun kú nípasẹ̀ idà.

29 Nítorí èyí, ó sá tẹ̀lé wọn, ní ọjọ́ tí ó tẹ̀lẽ ó sì bá wọn; wọ́n sì tún jà pẹ̀lú idà. Ó sì ṣe nígbàtí gbogbo wọn sì ti ṣubú nípa idà, àfi Kóríántúmúrì àti Ṣísì, ẹ kíyèsĩ Ṣísì dákú nítorípé ó ti pàdánù ẹ̀jẹ̀.

30 Ó sì ṣe nígbàtí Kóríántúmúrì ti faratì idà rẹ̀, tí ó si simi díẹ̀, ó bẹ́ orí Ṣísì kúrò.

31 Ó sì ṣe Lẹ́hìn tí ó ti bẹ́ orí Ṣísì, tí Ṣísì gbé ọwọ́ rè sókè ó sì ṣubúlulẹ̀; lẹ́hìn tí ó sì ti jà fún ẽmí, ó kù.

32 Ó sì ṣe tí Kóríántúmúrì ṣubúlulẹ̀, ó sì rí bí i pé kò ní ẹ̀mí.

33 Olúwa sì bá Étérì sọ̀rọ̀, ó sì wí fún un pe: Lọ jáde. Ó sì lọ jáde, o sì ríi pé àwọn ọ̀rọ̀ Olúwa gbogbo ní a ti múṣẹ; ó sì pari àkọsílẹ̀ rẹ̀; (apá kán nínú ọgọ́run rẹ̀ ni èmi kò sì tĩ kọ) ó sì gbé wọn pamọ́ lọ́nà tí àwọn ènìyàn Límháì fi rí wọn.

34 Nísisìyí àwọn ọ̀rọ̀ tí ó kẹ́hìn tí Étérì kọ ni ìwọ̀nyĩ: Bóyà Olúwa yíò sí mi nípò padà láìkú, tàbí kí èmi ó faradà ìfẹ́ Olúwa ní ti ara, kò jámọ́ nkankan, bí ó bá ri bẹ̃ tí a gbà mí là nínú ìjọba Olọ́run. Àmín.