Àwọn Ìwé Mímọ́
Étérì 11


Orí 11

Àwọn ogun, iyapa, àtí ìwà búburú jọba láyé àwọn ara Járẹ́dì—Àwọn wòlĩ sọ àsọtẹ́lẹ̀ níti ìparun àwọn ará Járẹ́dì àfi bí wọ́n bá ronúpìwàdà—Àwọn ènìyàn nã kọ̀ ọ̀rọ̀ àwọn wòlĩ.

1 Àwọn wòlĩ púpọ̀ sì wá pẹ̀lú ní ìgbà ayé Kọ́mù, wọ́n sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ níti ìparun àwọn ènìyàn olókìkí nnì àfi bí wọ́n bá ronúpìwàdà, kí wọn ó sì yí sí ọ́dọ́ Olúwa, kí wọn sì kọ̀ ìpànìyàn àti ìwà búburú wọn sílẹ̀.

2 Ó sì ṣe tí àwọn ènìyàn nã ṣá àwọn wòlĩ nã tì, wọ́n sì sá lọ sí ọ̀dọ̀ Kọ́mù fún ãbò, nítorítí àwọn ènìyàn nã wá ọ̀nà láti pa wọ́n.

3 Wọ́n sì sọ àsọtẹ́lé ohun púpọ̀ fún Kọ́mù; a sì bùkúnfún un ní ìyókù ọjọ́ ayé rẹ̀.

4 Ó sì dàgbà púpọ̀, ó sì bí Ṣíblọ́mù; Ṣíblọ́mù sì jọba ní ìrọ́pò rẹ̀, Arákùnrin Ṣíblọ́mù sì ṣọ̀tẹ̀ sí i, ogun nla tí ó pọ̀ púpọ̀ sì bẹ́ sílẹ̀ ní gbogbo ilẹ̀ nã.

5 O sì ṣe tí arákùnrin Ṣíblọ́mù mú kí wọn ó pa gbogbo àwọn wòlĩ tí ó nsọ àsọtẹ́lẹ̀ ní ti ìparun àwọn ènìyàn nã;

6 Ìyọnu nlá sì wà ní gbogbo ilẹ̀ nã, nítorítí wọ́n ti jẹ̃rí síi pé ègún nlá kan nbọ̀ lórí ilẹ̀ nã, àti lórí àwọn ènìyàn nã, àti pé ìparun nlá kan yíò wà ní ãrín wọn, irú èyítí kò sí rí lórí ilẹ̀ ayé, àwọn egungun wọn yíò sì di òkítì erùpẹ̀ lórí ilẹ̀ nã àfi bí wọ́n bá ronúpìwàdà kúrò nínú ìwà búburú wọn.

7 Wọn kò sì gbọ́ ohùn Olúwa, nítorí àwọn ẹgbẹ́ buburu wọn; nítorí èyí, àwọn ogun àti ìgbóguntì bẹ́ sílẹ̀ ní gbogbo ilẹ̀ nã, àti pẹ̀lú àwọn ìyàn tí ó pọ̀ àti àwọn àjàkálẹ̀ àrùn, tóbẹ̃ ti ìparun nlá kan fi wà, irú èyítí ẹnikan kò mọ̀ rí lórí ilẹ̀ ayé; gbogbo èyí sì kọjá lọ ní ọjọ́ ayé Ṣíblọ́mù.

8 Àwọn ènìyàn nã sì bẹ̀rẹ̀sí ronúpìwàdà kúrò nínú àìṣedẽdé wọn; gẹ́gẹ́bí wọn sì ti ṣe èyí Olúwa sì ṣãnú fún wọn.

9 O sì ṣe ti wọ́n pa Ṣíblọ́mù, wọ́n sì mú Sétì ní ìgbèkùn, ó sì gbé nínú ìgbèkùn ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.

10 O sì ṣe tí Áháhì, ọmọ rẹ̀, sì gbà ijọba nã; ó sì jọba lórí àwọn ènìyàn nã ní gbogbo ayé rẹ̀. O sì ṣe onírúurú àìṣedẽdé ni ọjọ́ ayé rẹ̀, nípa èyítí ó mú kí wọn ó ta èjẹ̀ púpọ̀ sílẹ̀; ọjọ́ ayé rẹ̀ kò sì pọ̀.

11 Àti Étémù, ẹnití í ṣe ìran Áháhì, sì gbà ìjọba nã; òun nã sì ṣe èyítí ó burú ní ojọ́ ayé rè.

12 Ó sì ṣe ní ọjọ́ ayé Étémù tí àwọn wòlĩ púpọ̀ wá, wọ́n sì tún sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún àwọn ènìyàn nã; bẹ̃ni, wọ́n sì sọ àsọtẹ́lẹ́ pé Olúwa yíò pa wọ́n run pátápátá kúrò lórí ilẹ̀ ayé àfi bí wọ́n bá ronúpìwàdà àwọn àìṣedẽdé wọn.

13 Ó sì ṣe tí àwọn ènìyàn nã sé ọkàn wọn le, tí wọn kò sì gbọ́ràn sí wọn lẹ́nu; àwọn wòlĩ nã sì binújẹ́ wọ́n sì kúrò lãrín wọn.

14 Ó sì ṣe tí Étémù sì ṣe ìdájọ́ nínú ìwà búburú ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀; ó sì bí Mórọ̀n. Ó sì ṣe tí Mórọ̀n sì jọba ní ìrọ́pò rẹ̀; Mórọ̀n sì ṣe èyítí ó burú níwájú Olúwa.

15 Ó sì ṣé tí ọ̀tẹ̀ sì dìde lãrín àwọn ènìyàn nã, nítorí ẹgbẹ́ òkùnkùn nnì èyítí wọn gbe dide láti ni agbara àti èrè; ènìyàn kan sì dìde lãrín wọn ẹnití ó lágbára nínú àìṣedẽdé, ó sì gbé ogun tì Mórọ̀n, nínú èyítí ó bì ìdajì ìjọba nã ṣubú; ó sì fi ọwọ́ mú ìdajì ìjọba nã fún ọpọ̀lọpọ̀ ọdún.

16 Ó sì ṣe tí Mórọ̀n sì bì í ṣubú, ó sì gbà ìjọba nã padà.

17 Ó sì ṣe tí ọkùnrin alágbára míràn dìde; ó sì jẹ́ ìran arákùnrin Járẹ́dì.

18 Ó sì ṣe tí ó bì Mórọ̀n ṣubú ó sì gbà ìjọba nã; nítorí èyí Mórọ̀n gbé nínú ìgbèkùn ní gbogbo ìyókù ọjọ́ ayé rẹ̀; ó sì bí Koriántórì.

19 Ó sì ṣe tí Koriántórì gbé nínú ìgbèkùn ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.

20 Àti ní ọjọ́ ayé Koriántórì àwọn wòlĩ púpọ̀ wá pẹ̀lú, wọ́n sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípà àwọn ohun nlá èyítí ó yanilẹ́nu, wọ́n sì nkígbe ìrònúpìwàdà sí àwọn ènìyàn nã, àti pé àfi bí wọn bá ronúpìwàdà Olúwa Olọ́run yíò ṣe ìdájọ́ fún wọn sí ìparun wọn pátápátá;

21 Àti pé Olúwa Olọ́run yíò rán tàbí mú àwọn ènìyàn míràn jáde láti ní ilẹ̀ nã ní ìní, nípa agbára rẹ̀, ní ọ̀na èyítí o gbà mú àwọn baba wọn jáde.

22 Wọ́n sì kọ̀ gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ àwọn wòlĩ nã, nítorí àwọn ẹgbẹ́ òkùnkùn àti àwọn ìwà ìkà ìríra wọn.

23 O sì ṣe tí Koriántórì bí Étérì, ó sì kú, nígbàtí ó tí gbé nínú ìgbékùn ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.