Àwọn Ìwé Mímọ́
Étérì 12


Orí 12

Wòlĩ Étérì gbà àwọn ènìyàn nã níyànjú láti gbà Ọlọ́run gbọ́—Mórónì ṣe àtúnsọ lórí àwọn ìyanu ati ohun ìyanu tí a ṣe nípa ìgbàgbọ́—Ìgbàgbọ́ ní ó jẹ́ kí arákùnrin Járẹ́dì ó rí Krístì—Olúwa a máa fún àwọn ènìyàn ní àìlera kí wọn ó lè rẹ̀ ara wọn sílẹ̀—Arákùnrin Járẹ́dì ṣí Okè-giga Sérínì nípa ìgbàgbọ́—Ìgbàgbọ́, ìrètí, àti ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ jẹ àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì sí ìgbàlà—Mórónì rí Jésù lójúkojú.

1 Ó sì ṣe tí ìgbà ayé Étérì jẹ́ ìgbà ayé Kóríántúmúrì; Kóríántúmúrì sì jẹ́ ọba lórí gbogbo ilẹ̀ nã.

2 Étérì sì jẹ́ wòlĩ Olúwa; nítórí èyí Étérì jáde wá ní ìgbà ayé Kóríántúmúrì, ó sì bẹ̀rẹ̀sí sọ àsọtẹ́lẹ̀ sí àwọn ènìyàn nã, nítórítí wọn kò lè dá a lẹ́kun nítorí Ẹ̀mí Olúwa èyítí o wà nínú rẹ̀.

3 Nítorítí ó kígbe láti òwúrọ̀, àní títí di àṣalẹ́, tí ó ngbà àwọn ènìyàn nã níyànjú láti gbàgbọ́ nínú Olọ́run sí tí ìrònúpìwàdà kí wọn ó má bã parun, ó sì nwí fún wọn pé nípa ìgbàgbọ́ ohun gbogbo a má a di mímúṣẹ—

4 Nítorí èyí, ẹnikẹ́ni tí ó bá gbàgbọ́ nínú Ọlọ́run lè ní ìrètí dájúdájú fún ayé tí ó dára jù èyí, bẹ̃ni, àní àyè ní apá ọ̀tún Ọlọ́run, ìrètí èyítí nwá nípa ìgbàgbọ́, tí ó sì rọ̀ mọ́ ọkàn ènìyàn, típẹ́típẹ́, èyítí yíò mú wọn dúró gbọningbọnin àti ní ìdúróṣínṣin, tí wọn sì kún fún iṣẹ́ rere ní gbogbo ìgbà, tí a sì darí wọn láti yìn Ọlọ́run lógo.

5 Ó sì ṣe tí Étérì sì nsọ àsọtélẹ̀ níti àwọn ohun nlá èyítí ó yanilẹ́nu sí àwọn ènìyàn nã, èyítí wọn kò gbàgbọ́, nítorípé wọn kò rí wọn.

6 Àti nísisìyí, èmi Mórónì, yíò sọ̀rọ̀ díẹ̀ nípa àwọn ohun wọ̀nyí; èmi yíò fihàn sí aráyé pé ìgbàgbọ́ jẹ́ àwọn ohun tí a ní írètí fún tí a kò fi ojú rí; nítorí eyi, ẹ máṣe jiyàn nítorípé ẹ̀yin kò ríi, nítorítí ẹ̀yin kì yíò rí ẹ̀rí gbà títi di lẹ̀hìn tí a bá dán ìgbàgbọ́ yín wò.

7 Nitori nípa ìgbàgbọ́ ni Krístì fi ara rẹ hàn sí àwọn baba wa, lẹ́hìn tí ó ti jínde kúrò nínú òkú; kò sì fi ara rẹ̀ hàn sí wọn títí dí ní ẹ̀hìn ìgbà tí wọn ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀; nítorí èyí, ó dì dandan pé kí àwọn kan ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀, nítorítí kò fi ara rẹ̀ hàn sí aráyé.

8 Ṣùgbọ́n nítorí ìgbàgbọ́ ènìyàn ó ti fi ara rẹ̀ hàn sí aráyé, ó sì ṣe orúkọ Bàbá lógo, ó sì pèsè ọ̀nà kan sílẹ̀ nípasẹ̀ èyítí àwọn míràn yíò jẹ́ alábãpín nínú ẹ̀bùn ọ̀run nã, nípasẹ̀ èyítí wọn yíò ní ìrètí lórí àwọn ohun nã tí wọ́n kò tĩ rí.

9 Nítorí èyí, ẹ̀yin lè ní ìrètí pẹ̀lú, kí ẹ sì jẹ́ alábãpín nínú ẹ̀bùn nã, bí ẹ̀yin ó bá ní ìgbàgbọ́.

10 Ẹ kíyèsĩ nípa ìgbàgbọ́ ni a fi pè àwọn ará ìgbà àtijọ́ nípa ti àṣẹ mímọ́ ti Ọlọrun.

11 Nítorí èyí, nípa ìgbàgbọ́ ni a fi òfin Mósè fún ni. Sùgbọ́n nínú ẹ̀bùn tí í ṣe Ọ́mọ rẹ̀ ni Olọ́run pèsè ọ̀nà èyítí ó dára jù; àti nípa ìgbàgbọ́ ní a sì ti múu ṣẹ.

12 Nítorí bí kò básí ìgbàgbọ́ lãrín àwọn ọmọ ènìyàn Ọlọ́run kò lè ṣe iṣẹ́ ìyanu lãrín wọn; nítorínã, òun kò fi ara rẹ̀ hàn àfi ní ẹ́hìn ìgbàgbọ́ wọn.

13 Ẹ kíyèsĩ, ìgbàgbọ́ Álmà àti Ámúlẹ́kì ní ó mú kí tũbú wo lulẹ̀.

14 Ẹ kíyèsĩ, ìgbàgbọ́ Nífáì àti Léhì ní ó mú kí ìyípadà ó bá àwọn ara Lámánì, tí a fi ṣe ìrìbọmi wọn pẹ̀lú iná àti pẹ̀lú Ẹ̀mí Mímọ́.

15 Ẹ kíyèsĩ, ìgbàgbọ́ Ámọ́nì àti àwọn arákùnrin rẹ̀ ni ó mú kí a ṣe iṣẹ́ ìyanu nla lãrín àwọn ará Lámánì.

16 Bẹ̃ni, àní àti gbogbo àwọn tí wọ́n ṣe àwọn iṣẹ ìyanu ṣe wọ́n nípa ìgbàgbọ́, àní àwọn tí wọ́n wà ṣãju Krístì àti àwọn tí o wà lẹ́hìn rẹ̀.

17 Nípa ìgbàgbọ́ sì ní àwọn ọmọ ẹ̀hìn mẹta nã gbà ìlérí pé wọn kò ní tọ́ ikú wò; wọ́n kò sì gbá ìlérí nã àfi ní ẹ́hìn ìgbàgbọ́ wọn.

18 Kò sì sí ìgbà kan tí ẹnikẹ́ni ṣe iṣẹ́ ìyanu àfi ní ẹ́hìn ìgbàgbọ́ wọn; nítorí èyí wọ́n kọ́kọ́ gbàgbọ́ nínú Ọmọ Ọlọ́run.

19 Àwọn púpọ̀ ní ó sì wà tí ìgbàgbọ́ wọn lágbára púpọ̀, àní kí Krístì ó tó dé, àwọn tí a kò lè dènà mọ́ ní ibi ìkèlé, sùgbọ́n tí wọn rí i pẹ̀lú ojú ara wọn àwọn ohun tí wọn ti fi ojú ìgbàgbọ́ wò, tí inú wọn sì dùn.

20 Ẹ sì kíyèsĩ, àwa ti ríi nínú àkọsílẹ̀ yĩ pé ọ̀kan nínú wọn ní àrákurin Járẹ́dì; nítorítí ìgbàgbọ́ rẹ̀ nínú Ọlọ́run tóbi tóbẹ̃ tí Olọ́run kò lé fi ìka rẹ̀ pamọ́ kúrò lójú arákùnrin Járẹ́dì nígbàtí Ọlọ́run nà ìka rẹ̀ jáde, nítorí ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí ó ti sọ fún un, ọ̀rọ̀ èyítí ó tí rí gbà nípa ìgbàgbọ́.

21 Àtí lẹ́hìn tí arákùnrin Járẹ́dì ti ri ìka Olúwa, nítorí ìlérí tí arákùnrin Járẹ́dì ti rí gbà nípa ìgbàgbọ́, Olúwa kò lè dáwọ́ ohunkóhun dúró fún un láti rí; nítorí èyí ó fi ohun gbogbo hàn sí nítorítí a kò lè fí í sílẹ̀ ní àìsí ìkèlé.

22 Àti nípa ìgbàgbọ́ ni àwọn baba mi ti rí ìlérí nã gbà pé àwọn ohun wọ̀nyí yíò tọ̀ àwọn arákùnrin wọn wá nípasẹ̀ àwọn Kèfèrí; nítorí èyí Olúwa ti pàṣẹ fún mi, bẹ̃ni, àní Jésù Krístì.

23 Èmi sì wí fún un pé: Olúwa, àwọn Kèfèrí yíò fí àwọn ohun wọ̀nyí ṣe ẹlẹ́yà, nítorí àìpé wa nínú ohun kíkọ; nítorítí Olúwa ìwọ ní ó mú kí àwa ó tobi nínú ọ̀rọ̀ sísọ nípa ìgbàgbọ́, ṣùgbọ́n ìwọ kò mú kí àwa ó tóbi níti ohun kíkọ; nítorítí ìwọ ni ó mú kí gbogbo àwọn ènìyàn wọ̀nyí ó lè sọ̀rọ̀ púpọ̀ nítorí Ẹ̀mí Mímọ́ èyítí ìwọ tí fi fún wọn;

24 Ìwọ sì ti mú kí àwa ó lè kọ ṣùgbọ́n díẹ̀, nítorí ìnira ọwọ́ wa. Kíyèsĩ, ìwọ kò mú wa tóbi nínú ohun kíkọ bí ti arákùnrin Járẹ́dì, nítorítí ìwọ mú kí àwọn ohun tí ó kọ ó tóbi àní gẹ́gẹ́bí ìwọ ti rí, sí fífi ipá mú ènìyàn láti kà wọ́n.

25 Ìwọ sì ti mú kí àwọn ọ̀rọ̀ wa ó ní ágbára àti kí wọn ó tóbi, àní tó èyíti a kò lè kọ wọ́n; nítorí èyí, nígbàtí àwa nkọ àwa rí àìpé wa, àwa sì nṣe àṣìṣé níti bí a ṣe nkọ àwọn ọ̀rọ̀ wa; èmi sì bẹ̀rù kí àwọn Kèfèrí ó má fi àwọn ọ̀rọ̀ wa ṣe ẹlẹ́yà.

26 Nígbàtí èmí si ti sọ eleyĩ, Olúwa bá mi sọ̀rọ̀ wípé: Àwọn aṣiwèrè ènìyan a mã ṣe ẹlẹ́yà, ṣùgbọ́n wọn yíò ṣọ̀fọ̀; õre-ọ̀fẹ́ mí sì tó fún oniwàtútù ènìyàn, kí wọn ó má lè rí ọ mú nítí àìpé rẹ;

27 Bí àwọn ènìyàn bà sì tọ̀ mi wá emí yíò fi àìpé wọn hàn sí wọn. Mo fún àwọn ènìyàn ní àìpé kí wọn ó lè rẹ̀ ara wọn sílẹ̀; õre-ọ̀fẹ́ mi sì tó fún gbogbo ẹ̀nìti ó bá rẹ̀ ara rẹ sílẹ̀ níwájú mi; nítorí tí wọ́n bá rẹ̀ ara wọn sílẹ̀ níwájú mi, tí wọ́n sì ní ìgbàgbọ́ nínú mi nígbànã ni èmi yio mú àwọn ohun aláìlágbára dì èyíti ó lágbára fún wọn.

28 Ẹ kíyèsĩ, èmi yíò fi àìlera àwọn Kèfèrí hàn sí wọn, èmi yíò sì fi hàn sí wọn pé ìgbàgbọ́, ìrètí àti ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ a mã mú wá sí ọ́dọ̀ mi—orísun gbogbo òdodo.

29 Àti èmi Mórónì, lẹ́hìn tí mo ti gbọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ní ìtùnú, mo sì wípé: A! Olúwa, àwa yíò ṣe òdodo rẹ, nítorítí mo mọ̀ pé ìwọ nṣe fún àwọn ọmọ ènìyàn gẹgẹbí ìgbàgbọ́ wọn;

30 Nítorítí arákùnrin Járẹ́dì wí fún òkè gíga Sérínì pé, Ṣí ní ìdí—a sì ṣí i ní ìdí. Bí kò bá sì ní ìgbàgbọ́ kì bá tí ṣí ní ìdì; nítorí èyí ìwọ a máa ṣe fun àwọn ènìyàn lẹ́hìn tí wọn bá ní ìgbàgbọ́.

31 Nítorí báyĩ ní ìwọ fí ara rẹ hàn sí àwọn ọmọ ẹ̀hìn rẹ; lẹ́hìn tí wọn ní ìgbàgbọ́, tí wọn sì sọ̀rọ̀ ní orúkọ rẹ, ìwọ sì fi ara rẹ hàn sí wọn ninu agbára nlá.

32 Èmi sì rántí pẹ̀lú pé ìwọ ti wípé ìwọ ti pèsè ilé fún ènìyàn, bẹ̃ni, àní lãrín àwọn ibùgbé Baba rẹ, nínú èyítí èníyàn lè ni ìrètí tí ó dara púpọ̀; nítorí èyí ènìyàn gbọ́dọ̀ ní ìrètí, bí kò rí bẹ̃ kò lè rí ibi ìjogún nínú ibi èyíti ìwọ ti pèsè sílẹ̀.

33 Àti pẹ̀lú, mo rántí pé ìwọ ti wípé ìwọ ti ní ìfẹ́ sí ayé, àní sí fífi ẹ̀mí ara rẹ lélẹ̀ fún ayé, kí ìwọ ó tún padà mú u láti pèsè àyè sílẹ̀ fún àwọn ọmọ ènìyàn.

34 Àti nísisìyí èmi mọ̀ pé ìfẹ́ yì èyítí ìwọ ti ní fún àwọn ọmọ ènìyàn jẹ́ ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́; nítorí èyí, àfi bí àwọn ènìyàn bá ni ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ wọn kò lè jogún ibi èyítí ìwọ ti pèsè sílẹ̀ nínú àwọn íbùgbé Bàbá rẹ.

35 Nítorí èyí, èmi mọ̀ nípa ohun yĩ tí ìwọ ti wí, pé bí àwọn Kèfèrí kò bà ní ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́, nitori àìpé wa, pé ìwọ yíò dán wọn wò ìwọ ó sì gbà tálẹ́ntì nã lọ́wọ́ wọn, bẹ̃ni, eyi nnì ti wọ́n ti rí gbà, kí ó sì fifún àwọn ti yíò ní lọ́pọ̀lọpọ̀.

36 Ó sì ṣe tí mo gbàdúrà sí Olúwa kí ó lè fún àwọn Kèfèrí ní õre-òfẹ́, kí wọn ó lè ní ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́.

37 Ó sì ṣe tí Olúwa wí fún mi pe: Bí wọn kò bá ní ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ kò já mọ́ nkan fún ọ, ìwọ ti jẹ olótĩtọ́; nítorí èyí, á ó mú ẹ̀wu rẹ mọ́. Àti nítorípé ìwọ ti ri àìlera ara rẹ a ó mú kí ó ní ágbára, àní sí jíjókõ ní ãyè nã èyítí èmi ti pèsè sílẹ̀ nínú àwọn ibùgbé Bàbá mi.

38 Àti nísisìyí èmi, Mórónì, kí àwọn Kèfèrí pé o digbóṣe, bẹ̃ni, àti pẹ̀lú àwọn arákùnrin mi ti èmi ní ìfẹ́ sí, títí a ó fi pàdé níwájú ìtẹ́ ìdájọ́ Krístì, níbití gbogbo ènìyàn yíò mọ̀ pé ẹ̀jẹ̀ yín kò fi àbàwọ́n sí ẹ̀wù mi.

39 Nígbànã ni ẹ̀yin yíò mọ̀ pé emí ti ri Jésù, àti pé ó ti bá mi sọ̀rọ̀ lójúkojú, àti pé ó wí fún mi nínú ìwà-ìrẹ̀lẹ̀ tí ó hàn kedere, àní bí ẹnìkan ti í ba ekeji sọ̀rọ̀ ní èdè mi, nípa àwọn ohun wọ̀nyí;

40 Díẹ̀ nínú àwọn ohun wọ̀nyí ni èmi sì kọ, nítorí àìpé mí nínú ohun kíkọ.

41 Áti nísisìyí, èmi yíò gbà yín níyànjú láti wá Jésù yĩ kiri nípa ẹniti àwọn wòlĩ àti àwọn àpóstélì ti kọ, pé kí õre ọ̀fẹ́ Ọlọ́run Baba, àti pẹ̀lú Jésù Krístì Olúwa, àti Ẹ̀mí Mímọ́, ẹniti ó njẹ́rĩ sí wọn, ó wà, kí ó sì máa gbé nínú yín títí láé. Amín.