Àwọn Ìwé Mímọ́
Étérì 5


Orí 5

Àwọn ẹlẹ̃rí mẹta àti iṣẹ́ nã fúnrarẹ̀ yíò duro gégẹ́bí ẹ̀rí otitọ Ìwé ti Mọ́mọ́nì.

1 Àti nísisìyí emí, Mórónì, ti kọ àwọn òrọ̀ tí a pa laṣẹ fún mi láti kọ, gẹ́gẹ́bí èmi ti rántí; èmi sì ti sọ fún ọ níti àwọn ohun ti emí ti dì ní èdìdí; nítorínã máṣe fọwọ́kàn wọ́n fún kí ìwọ ó ṣe ìtúmọ̀ wọn; nítorítí a ti ka ṣíṣe eleyĩ sí ẽwọ̀ fún ọ, bíkòṣe ní àkókò tí yíò jẹ́ ọgbọ́n nínú Ọlọ́run.

2 Àti kíyèsĩ, ìwọ lè ní ànfànì láti fi àwọn àwo nã hàn sí àwọn tí yíò ṣe ìrànlọ́wọ́ láti mú iṣẹ́ yì í jáde wá;

3 Sí àwọn mẹ́ta ni a ó sì fihàn nípa agbára Ọlọ́run; nítorí eyi wọn yíò mọ̀ dájúdájú pé àwọn ohún wọ̀nyí jẹ òtítọ́.

4 Àti láti ẹnu àwọn ẹlẹ́èrí mẹ́ta ni á ó fi àwọn ohún wọ̀nyí lélẹ̀; àti ẹ̀rí àwọn mẹta, àti iṣẹ́ yĩ, nínú èyítí a ó fi agbára Ọlọ́run hàn àti ọ̀rọ̀ rẹ̀, nípa àwọn èyítí Baba, àti Omọ, àti Ẹ̀mí Mímọ́ yíò ṣe àkọsílẹ̀—gbogbo èyĩ ní yìò sì dúró ní ìjẹ̃ri si ayé ní ọjọ́ ìkẹhìn.

5 Bí wọ́n bá sì ronúpìwàdà tí wọ́n sì wá sí ọ̀dọ̀ Bàbá ní orúkọ Jésù, a ó gbà wọ́n sínú ìjọba Ọlọ́run.

6 Àti nísisìyí, bí èmi kò bá ní àṣẹ ní ti àwọn ohun wọ̀nyí, ẹ dajọ; nítorí ẹ̀yin yíò mọ̀ pé mo ní àṣẹ nígbàtí ẹ̀yin yíò rí mi, àwa yíò sì dúró níwájú Ọlọ́run ni ọjọ́ ìkẹhìn. Àmín.