Àwọn Ìwé Mímọ́
Étérì 8


Orí 8

Ijà àti asọ̀ wà lórí ilẹ̀ nã—Ákíṣì kó àwọn ẹgbẹ́ òkùnkùn kàn jọ ti wọn darapọ̀mọ́ra pẹ̀lú ìbúra láti pa ọba—Àwọn ẹgbẹ òkùnkùn jẹ́ ti èṣù wọn a sì máa jẹ́ ki orílẹ̀ èdè ó parun—Àwọn Kèfèrí òde oni gbà ìkìlọ̀ lórí ẹgbẹ òkùnkùn tí yíò lépa láti bì òmìnira ilẹ̀ gbogbo, orílẹ̀-èdè, àti àwọn ìlú ṣubú.

1 Ó sì ṣe tí ó bí Ómérì, Ómérì sì jọba ní ìrọ́pò rẹ̀. Ómérì sì bí Járẹ́dì; Járẹ́dì sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin.

2 Járẹ́dì sì ṣọ̀tẹ̀ sí bàbá rẹ̀, ó sì wá ó sì ngbé inú ilẹ̀ Hẹ́tì. Ó sì ṣe tí ó ntàn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, nitori ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn rẹ̀, títí ó fi gbà ìdajì ìjọba nã.

3 Nígbàtí o sì ti gbà ìdajì ijọba nã ó dojú ogun kọ bàbá rẹ̀, ó sì gbé bàbá rẹ̀ lọ ní ìgbèkùn, ó sì jẹ́ ki o sìn nínú oko ẹrú;

4 Àti nísisìyí, ní gbogbo ọjọ́ tí Ómérì fi jọba ó wà nínú ìgbèkùn ní ilàjì ọjọ́ ayé rẹ̀. Ó sì ṣe tí ó bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin, nínú wọn ni Ésrómù àti Kóríántúmúrì gbé wà;

5 Wọ́n sì bínú gidigidi nítorí àwọn ìṣe Járẹ́dì arákùnrin wọn, tóbẹ̃ tí wọ́n kó ẹgbẹ́ ogun jọ tí wọ́n sì dojú ogun kọ Járẹ́dì. Ó sì ṣe tí wọn dojú ogun kọ ọ́ ní òru.

6 Ó sì ṣe nígbàtí wọn ti pa ẹgbẹ́ omọ ọgun Járẹ́dì wọn ṣetán láti pa òun nã; ó sì ṣìpẹ̀ sí wọn kí wọn ó máṣe pa òun, pé òun yíò fi ijọba nã lé bàbá òun lọ́wọ́. Ó sì ṣe tí wọ́n jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀ sílẹ̀ fún un.

7 Àti nísisìyí ìrora ọkàn nla sì bá Járẹ́dì nítorítí ó sọ ìjọba nã nù, nítorítí ó ti gbé ọkàn rẹ̀ lérí ìjọba nã àti lérí ògo ayé.

8 Nísisìyí ọmọbìnrin Járẹ́dì jẹ́ ọlọgbọ́n àrekérekè ènìyàn, nígbàtí ó sì rí ìrora ọkàn bàbá rẹ̀, o ronú láti pa ète ọ̀nà tí òun yíò fi dá ìjọ́bá padà fún bàbá òun.

9 Nísisìyí ọmọbìnrin Járẹ́dì rẹwà púpọ̀. Ó sì ṣe tí ó bá bàbá rẹ̀ sọ̀rọ̀, ó sì wí fún un pé: Kíni ìdí ti bàbá mi fi ní ìrora ọkàn tó báyĩ? Njẹ́ òun kò ha kà àkọsílẹ̀ nnì èyítí àwọn bàbá wa mú kọjá lórí òkun nlá nnì bí? Kíyèsĩ, njẹ́ kò ha sí àkọsílẹ̀ nípa àwọn ará ìgbà àtijọ́, pé nípa àwọn ìlànà òkùnkùn, wọn wọ́n ngbà àwọn ìjọba àti ògo nlá?

10 Àti nísisìyí, nítorínã, kí bàbá mi ó ránṣẹ́ pè Ákíṣì, ọmọ Kímnórì; sì kíyèsĩ, mo lẹ́wà, èmi yíò sì jó níwájú rẹ̀, èmi yíò sì mú inú rẹ̀ dùn, tí yíò fẹ́ láti fi mi ṣe aya; nítorí eyi bí ó bá bí ọ́ pé kí o fi mí fún oun ní aya, nígbànã ni ìwọ yíò wípé: Èmi yíò fi í fún ọ bí ìwọ ó bá mú orí bàbá mi ọba, wá fún mi.

11 Àti nísisìyí Ómérì sì jẹ́ òrẹ́ sí Ákíṣì; nítorí èyí, nígbàtí Járẹ́dì ránṣẹ́ pè Ákíṣì, ọmọbìnrin Járẹ́dì jó níwájú rẹ̀ tí ó sì mú inú rẹ̀ dùn, tóbẹ̃ tí ó fẹ́ ẹ fún aya. Ó sì ṣe tí ó wí fún Járẹ́dì pé: Fi í fún mi fún aya.

12 Járẹ́dì sì wí fún un pe: Èmi yíò fi í fún ọ, bí ìwọ ó bá mú ori baba mi, ọba, wá fún mi.

13 O sì ṣe tí Ákíṣì kó gbógbo àwọn ará-ilé rẹ̀ jọ sínú ilé Járẹ́dì, ó sì wí fún wọn pé: Njẹ́ ẹ̀yin ha lè búra fún mi pé ẹ̀yin yíò ṣe òtítọ́ pẹ̀lú mi nínú ohun èyítí èmi fẹ kí ẹ̀yin ó ṣe?

14 Ó sì ṣe tí gbogbo wọn búra fún un, ní ti Ọlọ́run ọ̀run, àti pẹ̀lú ní ti àwọn ọ̀run, àti pẹ̀lú ní ti ayé, àti ní ti orí ara wọn, pé ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe èyítí ó yàtọ̀ sí ìrànlọ́wọ́ ti Ákíṣì fẹ́ yíò pàdánù orí ara rẹ̀; ẹnikẹ́ni tí ó bà sì fí ohunkóhun tí Ákíṣì yíò sọ di mímọ̀ fún wọn hàn, ẹni nã yíò pàdánù ẹ̀mí rẹ̀.

15 Ó sì ṣe ti wọn fohùnṣọ̀kan pẹ̀lú Ákíṣì. Ákíṣì sì ṣe ìbúra nã pẹ̀lú wọn èyítí àwọn ará ìgbà àtijọ́ tí nwá agbára a máa ṣe, èyítí a ti gbé fún wọn láti ọwọ́ Káìnì, ẹnití í ṣe apànìyàn láti ìbẹ̀rẹ̀ wá.

16 Agbára èṣù ní ó sì gbe wọn ró láti mã ṣe ìbúra yĩ sí àwọn ènìyàn, láti fi wọn sínú òkùnkùn, láti ràn àwọn tí nwá agbára lọ́wọ́ láti ní agbára, àti láti pànìyàn, àti láti kógun, àti láti purọ́, àti láti hù onírúurú ìwà búburú àti ìwà àgbèrè.

17 Ọmọbìnrin Járẹ́dì sì ni ẹnití ó fi í sínú ọkàn rẹ̀ láti gbé àwọn ohun àtijọ́ wọ̀nyí yẹ̀ wò; Járẹ́dì sì fi í sínú ọkàn Ákíṣì; nítorí eyi, Ákíṣì ṣe wọn fún àwọn ìbátan àti àwọn òrẹ́ rẹ̀, tí ó sì darí wọn lọ nípa àwọn ìlérí dídùn láti ṣe ohunkóhun tí óun bá fẹ́ kí wọn ó ṣe.

18 O sì ṣe tí wọn dá ẹgbẹ́ òkùnkùn kan sílẹ̀, àní bí ti àwọn ará àtijọ́; ẹgbẹ́ èyítí o rínilára àti tí ó níkà jùlọ, ni ojú Ọlọ́run;

19 Nítorítí Olúwa kì í ṣíṣẹ́ nínú àwọn ẹgbẹ́ òkùnkùn, bẹ̃ni kò sì fẹ́ kí àwọn ènìyàn ó tàjẹ̀sílẹ̀, ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo ni ó ti kã-lẽwọ̀, láti ìbẹ̀rẹ̀ ènìyàn.

20 Àti nísisìyí emí, Mórónì, kò kọ nípa irú àwọn ìbúra àti àwọn ẹgbẹ́ wọn, nítorítí a ti sọ ọ́ di mímọ̀ fún mi pé gbogbo ènìyàn ni ó ní wọn, àti pé gbogbo àwọn ará Lámánì ni ó ní wọn.

21 Wọ́n sì ti fa ìparun àwọn ènìyàn yĩ tí èmí nsọ̀rọ̀ nipa wọn nísisìyí, àti ìparun àwọn ènìyàn Nífáì.

22 Orílẹ̀èdè èyíówù tí ó bà sì tì ìrú àwọn egbẹ́ òkùnkùn bẹ̃ lẹ́hìn, láti ní agbára àti èrè, títí wọn yíò fi tàn ká gbogbo orílẹ̀-èdè nã, ẹ́ kíyèsĩ, á ó pa wọ́n run; nítorítí Olúwa kò ní gbà kí ẹ̀jẹ̀ àwọn ènìyàn mímọ́, ti wọn yíò ta silẹ, máa kígbe pè é láti inú ilẹ̀ wá fún ìgbẹ̀san lórí wọn, àti síbẹ̀síbẹ̀ kí ó má gbẹ̀san fún wọn.

23 Nítorí èyí, A! ẹ̀yín Kèfèrí, ó jẹ ohun ọgbọ́n nínú Ọlọ́run kí a fi àwọn ohun wọ̀nyí hàn yín, pé nípasẹ̀ wọn ẹ̀yin ó lè ronúpìwàdà kúrò nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín, kí ẹ́ má sì jẹ́ kí àwọn ẹgbẹ́ apànìyàn wọ̀nyí ó bò yín mọ́lẹ̀, èyítí wọ́n kójọ láti ni agbára àti èrè—àti iṣẹ́ nã, bẹ̃ni, àní kí iṣẹ́ ìparun nã sì wà sí órí yín, bẹ̃ni, àní idà àìṣègbè ti Ọlọ́run Ayérayé yíò sì ṣubú lù yín, sí ìṣúbu àti ìparun yín bí ẹyin bá gbà àwọn ohun wọ̀nyí lãyè.

24 Nítorí èyí, Olúwa pa a láṣẹ fún yín, nígbàtí ẹ̀yin ó bá ri àwọn ohun wọ̀nyí tí ó dé sí ãrín yín pé kí ẹ̀yin ó tají sí ipò búburú tí ẹ̀yin wa nínú rẹ̀, nítorí ẹgbẹ́ òkùnkùn yĩ èyítí yíò wà ní ãrín yín; tabi ègbé ni fún un, nitorí ẹ̀jẹ̀ àwọn tí wọ́n ti pa; nítorítí wọ́n nkigbe láti inú erùpẹ̀ wá fún ẹ̀san lórí rẹ̀, àti pẹ̀lú lórí àwọn tí ó dáa sílẹ̀.

25 Nítoriti yíò sì ṣe tí ẹnikẹ́ni tí ó bá dá a silẹ̀ nlépa láti gbé òmìnira ilẹ̀ gbogbo, orílẹ̀-èdè, àti àwọn ìlú ṣubú; ó sì nmú ìparun bá ènìyàn gbogbo, nítorítí èṣù ní ó dáa sílẹ̀, ẹnití í ṣe bàbá irọ́ gbogbo; àní òpùrọ́ nnì ẹnití ó tàn àwọn òbí wa àkọ́kọ́, bẹ̃ni, àní òpùrọ́ kannã ẹnití ó mú kí àwọn ènìyàn ó ṣe ìpànìyàn láti ìbẹ̀rẹ̀ wá; ẹnití ó ti sé ọkàn àwọn ènìyàn le tí wọ́n sì ti pa àwọn wòlĩ, tí wọn sì sọ wọ́n lókùta, tí wọ́n sì sọ wọ́n sóde láti ìbẹ̀rẹ̀ wá.

26 Nítorí èyí, emí, Mórónì, ni Olúwa pàṣẹ fún láti kọ àwọn ohun wọ̀nyí kí a lè mú ohun búburú kúrò, àti kí àkókò nã ó lè dé tí Sátánì kì yíò ní agbára mọ́ lórí ọkàn àwọn ọmọ ènìyàn, ṣùgbọ́n pé a ó yí wọn lọ́kàn padà láti ṣe réré títí, kí wọn ó lè wá sí ọ̀dọ̀ orísun gbogbo òdodo kí a sì gbà wọn là.