Àwọn Ìwé Mímọ́
Étérì 9


Orí 9

Ijọba nti ọwọ́ ẹnìkan bọ́ sí ọwọ ẹlòmíràn ní tí àjogúnbá, rìkíṣí, àti ìpànìyàn—Émérì rí Ọmọ Òdodo nnì—Àwọn wòlĩ púpọ̀ nkígbe ìrònúpìwàdà—Ìyàn kan àti àwọn ejò oloro bá àwọn ènìyàn nã jà.

1 Àti nísisìyí èmi, Mórónì, tẹ̀síwájú pẹ̀lú àwọn àkọsílẹ̀ mí. Nítorínã, ẹ kíyèsĩ, ó sì ṣe tí ó jẹ́ wípé nitori àwọn ẹgbẹ́ òkùnkùn Ákíṣì áti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, ẹ kíyèsĩ, wọ́n sì gbé ìjọba Ómérì ṣubú.

2 Bíólitẹ̀ríbẹ̃, Olúwa ṣãnú fún Ómérì, àti fún àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ àti àwọn ọmọbìnrín rẹ̀ tí kò wá ìparun rẹ̀.

3 Ọlọ́run sì kìlọ̀ fun Ómérì lójú àlá pé kí ó jáde kúrò nínú ilẹ̀ nã; nítorí èyí Ómérì jáde kuro nínú ilẹ̀ nã pẹ̀lú ìdílé rẹ̀, wọ́n sì rìn ìrìn àjò fun ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́, wọ́n sì dé sí ibi òkè Ṣímù, wọ́n sì kọjá rẹ̀, wọ́n sì dé ibiti a ti pa àwọn ara Nífáì run, wọ́n sì lọ láti íbẹ̀ sí apá ìlà-oòrùn, wọ́n sì dé ibì kan tí wọ́n npè ní Ablómù, lẹba etí bèbè òkun, níbẹ̀ ni ó sì pàgọ́ rẹ̀ sí, àti pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin àti àwọn ọmọ rẹ̀ obìnrin, àti gbogbo agbo-ilé rẹ̀, àfi Járẹ́dì àti ìdílé rẹ̀.

4 O sì ṣe tí a fi àmì òróró yàn Járẹ́dì ní ọ́ba lórí àwọn ènìyàn nã, nípa ọ̀nà ìwà búburú; ó sì fún Ákíṣì ní ọmọ rẹ̀ obìnrin láti fi ṣe aya.

5 O sì ṣe tí Ákíṣì lépa ẹ̀mí bàbá ìyàwó rẹ̀; ó sì bẽrè ìrànlọ́wọ́ àwọn tí ó ti mú kí wọn ó búra pẹ̀lú ìbúra àwọn ará àtijọ́, wọn sì bẹ́ orí bàbá ìyàwò rẹ̀, bí ó ti jóko lórí ìtẹ́ rẹ̀, bí ó tí ngbọ ti àwọn ènìyàn rẹ̀.

6 Nítorítí ìtànkálẹ̀ ẹgbẹ́ òkùnkùn tí ó ní ìkà yì í pọ̀ púpọ̀ tí ó ti mú ọkàn gbogbo àwọn ènìyàn nã díbàjẹ́; nítorínã wọn pa Járẹ́dì lórí ìtẹ́ rẹ̀, Ákíṣì sì jọba ní ìrọ́pò rẹ̀.

7 Ó sì ṣe tí Ákíṣì bẹ̀rẹ̀sí ṣe ìlara ọmọkùnrin rẹ̀, nitorinã ó tĩ mọ́ inú tũbú, ó sì nfún un ni onjẹ díẹ̀ tabi kí ó ma fún un rárá titi ó fi kú.

8 Àti nísisìyí arákùnrin ẹnití ó kú, (orúkọ rẹ̀ sì ni Nímrà) bínú sì bàbá rẹ̀ nítorí ohun tí bàbá rẹ ti ṣe sí arákùnrin rẹ̀.

9 O sì ṣe tí Nímrà kó àwọn ọkùnrin díẹ̀ jọ, tí wọn sì sá kúrò ní ilẹ̀ nã, wọ́n sì de ọ̀dọ̀ Ómérì wọ́n sì ngbé pẹ̀lú rẹ̀.

10 O sì ṣe tí Ákíṣì bí àwọn ọmọkùnrin míràn, wọ́n sì rí ojú rere àwọn èniyàn nã, bí ó tilẹ̀ rí bẹ̃ wọ́n ti pinnu pẹ̀lú rẹ̀ láti ṣe onírúurú àìṣedẽdé ní ìbámu pẹ̀lú èyítí ó fẹ́.

11 Nísisìyí àwọn ènìyàn Ákíṣì fẹ́ èrè, àní bí Ákíṣì ti fẹ agbara; nítori èyí, àwọn ọmọ Ákíṣì fí owó fún wọn, nípa èyítí wọn fa èyítí ó pọ̀ jù nínú àwọn ènìyàn nã sí ọ̀dọ̀ wọn.

12 Ogún kan sì bẹ́ sílẹ̀ lãrín àwọn ọ́mọ Ákíṣì àti Ákíṣì, tí ó pẹ́ fún ìwọ̀n ọdún púpọ̀, bẹ̃ni, tí ó fẹrẹ pa gbogbo àwọn ènìyàn inú ìjọba nã run tán, bẹ̃ni, àní gbogbo wọn, afi àwọn ọgbọ̀n ènìyàn, àti àwọn tí ó sa pẹ̀lú ìdílé Ómérì.

13 Nítorí eyi, wọ́n sì tún dá Ómérì padà sí órí ilẹ̀ ìní rẹ̀.

14 O sì ṣe tí Ómérì bẹ̀rẹ̀sí darúgbó; bíótilẹ̀ríbẹ̃, ní ọjọ́ ogbó rẹ̀ ó bí Émérì, ó sì fi àmì òróró yàn Émérì láti jọba ní ìrọ́pò rẹ̀.

15 Lẹ́hìn tí ó sì ti fí àmì òróró yàn Émérì láti jọba ó rí àlãfíà nínú ilẹ̀ nã fún ìwọ̀n ọdún méjì, ó sì kú, lẹ́hìn tí ó ti rí òpọ̀lọpọ̀ ọjọ, èyítí ó kún fún ìrora-ọkàn. O sì ṣe tí Émérì jọba ní ìrọpò rẹ̀, ó sì rìn nínú ipaṣẹ̀ bàbá rẹ̀.

16 Olúwa sì tún bẹ̀rẹ̀sí mú ègun kúrò lórí ilẹ̀ nã, ìdílé Émérì sì ní ìlọsíwájú tí ó pọ̀ púpọ̀ ní abẹ ìjọba Émérì; àti nínú ìwọ̀n ọdun méjìlélọ́gọ́ta ní wọ́n sì ti di álágbára púpọ̀, tóbẹ̃ tí wọ́n di ọlọ́rọ̀ púpọ̀—

17 Tí wọn sì ni onírúurú èso, àti ti ọkà, àti tí àwọn aṣọ ṣẹ́dà, àti ti àwọn aṣọ ọ̀gbọ̀ dáradára, àti tí wúrà, àti tí fàdákà, àti tí àwọn ohun oníyebíye;

18 Àti pẹ̀lú àwọn onírúurú màlũ, àti àwọn abo màlũ, àti ti àgùtàn, àti ti ẹlẹ́dè, àti ti ewúrẹ́, àti pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ irú àwọn ẹranko miràn tí ó wúlò fún onjẹ ènìyàn.

19 Wọn sì ní àwọn ẹṣin pẹ̀lú, àti àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àwọn erin sì wà níbẹ̀ àti àwọn kúrílọ́mù àti àwọn kúmọ́mù; tí gbogbo wọn wúlò fún ènìyàn, àti pãpã àwọn erin àti àwọn kúrílọ́mù àti àwọn kúmọ́mù.

20 Bayĩ sì ni Olúwa dà ìbùkún rẹ̀ sí ori ilẹ̀ yí, èyítí ó jẹ́ àsàyàn ju gbogbo ilẹ míràn lọ; ó sì pàṣẹ pé ẹnikẹ́ni tí yíò bá ní ilẹ̀ nã ní ìní níláti ní i sí Olúwa, tàbí kí a pa wọ́n run nígbàtí wọn bá ti gbó nínú àìṣedẽdé; pé ni orí irú èyí nì, ni Olúwa wí: Èmi yíò da ẹ̀kún ìbínú mi lé.

21 Émérì sì ṣe ìdájọ́ nínú òdodo ní gbogbo ayé rẹ̀, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin púpọ̀; ó sì bí Koríántúmù, ó sì fi àmì òróró yàn Koríántúmù láti jọba ní ìrọ́pò rẹ̀.

22 Lẹ́hìn tí ó sì ti fi àmì òróró yàn Koríántúmù láti jọba ní ìrọ́pọ̀ rẹ̀ ó gbé fún ọdún mẹ́rin, ó sì rí àlãfíà nínú ilẹ̀ nã; bẹ̃ni, àní ó sì ri Ọmọ Òdodo nã, ó sì yọ̀ ó sì ṣògo nínú ọjọ ayé rẹ̀; ó sì kú ní àlãfíà.

23 Ó sì ṣe tí Koríántúmù sì nrìn nínú ipàsẹ̀ bàbá rẹ̀, ó sì kọ́ àwọn ilu nla nla, ó sì nfí èyítí ó dára fún àwọn ènìyàn rẹ̀ ní gbogbo ọjọ ayé rẹ̀. Ó sì ṣe tí kò ní àwọn ọmọ àní títí ó fi darúgbó púpọ̀púpọ̀.

24 O sì ṣe tí aya rẹ̀ kú, nígbàtí ó pé ẹni ọdún méjì le lọ́gọ́run. O sì ṣe ti Koríántúmù gbé ọmọdebinrin kan ní ìyàwó, nínú ọjọ́ ogbó rẹ, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin; nítorí eyi ó gbé ayé títí ó fi pé ẹni ọdùn méjìlélógóje.

25 O sì ṣe tí ó bí Kọ́mù, Kọ́mù sì jọba ní írọ́pò rẹ̀; ó jọba fún ọdun mọ́kàndínlógojì, ó sì bí Hẹ́tì; ó sí bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin míràn pẹ̀lú.

26 Àwọn ènìyàn nã sì ti tún tàn ká gbogbo orí ilẹ̀ nã, ìwà búburú tí ó pọ̀ púpọ̀ sì tún bẹ̀rẹ̀sí wà lórí ilẹ̀ nã, Hẹ́tì sì tún bẹ̀rẹ̀sí gbà àwọn ète okùnkùn tí ìgbà àtijọ́, láti pa bàbá rẹ̀ run.

27 O sì ṣe tí ó sì rọ̀ bàbá rẹ̀ lórí oyè, nítorítí ó pa á pẹ̀lú idà ara rẹ̀; ó sì jọba ní ìrọ́pò rẹ̀.

28 Àwọn wòlĩ sì tún wá sí ilẹ̀ nã, tí wọn si nkigbe ìrònúpìwàdà sí wọn—pé wọn gbọdọ̀ tún ọ̀nà Olúwa ṣe tàbí kí ègún ó wá sí órí ilẹ̀ nã; àní ìyàn nla yíò wà, nínú èyítí a ò pà wọ́n run bí wọn kò bá ronúpìwàdà.

29 Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn nã kò gbà ọ̀rọ̀ àwọn wòlĩ nã gbọ́, ṣùgbọ́n, wọ́n le wọ́n jade; wọ́n sì jù àwọn míràn nínú wọn sínú kòtò tí wọ́n fi wọn sílẹ̀ láti ṣègbé. Ó sì ṣe tí wọ́n ṣe ohun gbogbo ní ìbámu pẹ̀lú àṣẹ ọba, Hẹ́tì.

30 O sì ṣe tí ìyàn nlá kan mú lórí ilẹ̀ nã, àwọn olùgbé inú ilẹ̀ nã sì bẹ̀rẹ̀sí parun ní kíakía nítorí òjò kò rọ̀ lórí ilẹ̀ ayé.

31 Àwọn ejò olóró sì jáde wá pẹ̀lú lórí ilẹ̀ nã, wọ́n sì bù ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ṣán. O sì ṣe tí àwọn ọ̀wọ́ ẹran wọn bẹ̀rẹ̀sí sálọ kúrò níwájú àwọn ejò olóró nã, lọ sí apá ilẹ̀ tí ó wà ní apá gũsù, èyítí àwọn ará Nífáì npè ní Sarahẹ́múlà.

32 O sì ṣe tí ó pọ̀ nínú wọn tí ó ṣègbé lọ́nà; bíótilẹ̀ríbẹ̃, àwọn kan wà tí wọ́n salọ sínú ilẹ̀ tí ó wà ní apá gũsù.

33 O sì ṣe tí Olúwa mú kí àwọn ejò nã ó má lé wọn mọ́, ṣùgbọ́n kí wọn dí ọna kí àwọn ènìyàn nã ó má lè kọjá, pé kí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbìdanwò láti kọjá lè ṣubú nípasẹ̀ àwọn ejò olóró nã.

34 O si ṣe tí àwọn ènìyàn nã sì ntẹ̀lé ipa ọ̀nà àwọn ẹranko wọn, wọ́n sì njẹ okú àwọn tí ó ṣègbé lọ́nà, titi wọn fi jẹ gbogbo wọn tán. Nísisìyí nígbàtí àwọn ènìyàn nã rĩ pé wọn yíò ṣegbé wọn bẹ̀rẹ̀sí ronúpìwàdà kúrò nínú àìṣedẽdé wọn, wọ́n sì ké pè Olúwa.

35 Ó sì ṣe nígbàtí wọn ti rẹ̀ ara wọn sílẹ̀ tó níwájú Olúwa ó sì rán òjò sí órí ilẹ̀ ayé; àwọn ènìyàn nã sì tún bẹ̀rẹ̀sí ní ókun lára, èso sì bẹ̀rẹ̀sí wà ní àwọn orílẹ̀-èdè apá àríwá, àti nínú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí o wà ní àyíká. Olúwa sì fi agbara rẹ̀ hàn sí wọn ni ti dídá wọn sí kúrò lọ́wọ́ ìyàn.