Àwọn Ìwé Mímọ́
Étérì 7


Orí 7

Òríhà jọba nínú òdodo—Nínú ìfipágbà ìjọba àti ìjà, a gbé àwọn orogún ìjọba ti Ṣúlè, àti ti Kóhọ̀ kalẹ̀—Àwọn wòlĩ dá àwọn ènìyàn nã lẹ́bí fun ìwà búburú àti ìwà ìbọ̀rìṣà wọn, tí wọ́n sì ronúpìwàdà.

1 Ó sì ṣe tí Òríhà sì ṣe ìdájọ́ lórí ilẹ̀ nã nínú òdodo ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀, ẹ̀nítí ọjọ́ ayé rẹ̀ pọ̀ púpọ̀.

2 Ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin; bẹ̃ni, ó bí mọ̀kànlélọ́gbọ̀n, nínú èyítí àwọn mẹ́tàlélógún jẹ́ ọmọkùnrin.

3 Ó sì ṣe tí ó bí Kíbù pẹ̀lú nínú ọjọ́ ogbó rẹ̀. Ó sì ṣe tí Kíbù jọba ní ìrọ́pọ̀ rẹ̀; Kíbù sì bí Kóríhọ̀.

4 Nígbàtí Kóríhọ̀ sì jẹ́ ọmọ ọdún méjìlélọ́gbòn, ó ṣọ̀tẹ̀sí bàbá rẹ̀, ó sì kọjá lọ ó sì ngbé inú ilẹ̀ Néhọ́rì; ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin, wọ́n sì di arẹwà ènìyàn púpọ̀, nítorí eyi Kóríhọ̀ fà ènìyàn púpọ̀ lọ pẹ̀lú rẹ̀.

5 Nígbàtí ó sì ti kó ẹgbẹ́ ogun kán jọ́ ó gòké wá sínú ílẹ̀ Mórọ̀n níbití ọba ngbé, ó sì múu ní ìgbèkùn, èyítí ó mú ọ̀rọ̀ arákùnrin Járẹ́dì sẹ pé a ó mú wọn ní ìgbèkùn.

6 Nísisìyí ilẹ̀ Mórọ̀n, níbití ọba ngbé, súnmọ́ ilẹ̀ tí àwọn ará Nífáì ńpè ní Ibi-Ahoro.

7 Ó sì ṣe tí Kíbù ngbé inú ìgbèkùn, àti àwọn ènìyàn rẹ̀ lábẹ́ Kóríhọ̀ ọmọ rẹ̀, titi ó fi di arúgbó púpọ̀púpọ̀; bíótilẹ̀ríbẹ̃ Kíbù bí Ṣúlè nínú ọ́jọ́ ogbó rẹ̀, nígbàtí ó wà nínú ìgbekùn síbẹ̀.

8 Ó sì ṣe tí Ṣúlè bínú sí arákùnrin rẹ; Ṣúlè sì nlágbára sí i, ó sì di alágbára níti ipá ènìyàn; ó sì lágbára pẹ̀lú níti ìdájọ́.

9 Nítorí èyí, ó lọ sínú òké Efráímù, ó sì yọ́ irin tútù jáde láti inú oke nã, ó sì rọ àwọn idà fún àwọn tí ó ti fà lọ pẹ̀lú rẹ́; nígbàtí ó sí ti dì wọ́n ní ìhámọ́ra pẹ̀lú àwọn idà, ó padà sí ìlú-ńlá Néhórì, ó sí dojú ogun kọ arákùnrin rẹ̀ Kóríhọ̀, nípa èyítí ó gbà ìjọba nã o sì dáa padà fún bàbá rẹ̀ Kíbù.

10 Àti nísisìyí nítorí ohun tí Ṣúlè ti ṣe, bàbá rẹ̀ fi ìjọba nã fún un; nítori èyí ó bẹ̀rẹ̀sí jọba ní ìrọ́pò bàbá rẹ̀.

11 O sì ṣe tí ó ṣe ìdájọ́ pẹ̀lú òdodo; ó sì tàn ìjọba rẹ̀ ká gbogbo òrí ilẹ̀ nã, nítorítí àwọn ènìyàn nã ti pọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀.

12 O sì ṣe tí Ṣúlè pẹ̀lú bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin púpọ̀.

13 Kóríhọ̀ sì ronúpìwàdà kúrò nínú àwọn ohun ibi tí ó ti ṣe; nítorí eyi Ṣúlè fún un ní agbára nínú ìjọba rẹ̀.

14 Ó sì ṣe tí Kóríhọ̀ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin. Ẹnìkan tí orukọ rẹ í ṣe Nóà sì wà nínú àwọn ọmọkùnrin Kóríhọ̀.

15 Ó sì se tí Nóà ṣọ̀tẹ̀ sí Ṣúlè, ọba, àti sí bàbá rẹ̀ Kóríhọ̀, ó sì fà Kohọ̀ arákùnrin rẹ̀, àti gbogbo àwọn arákùnrin rẹ̀ àti púpọ̀ nínú àwọn ènìyàn nã.

16 O sì dojú ogun kọ Ṣúlè, ọba, nínú èyítí ó sì gbà ilẹ̀ ìní akọ́kọ́ wọn; ó sì di ọba lórí ílẹ tí ó wà ní apá ibẹ̀.

17 O sì ṣe tí ó tún dojú ogun kọ Ṣúlè, ọba; ó sì mú Ṣúlè, ọba, ó sì gbé e lọ ní ìgbèkùn sínú Mórọ̀n.

18 Ó sì ṣe bí ó ti múra tán láti pa á, àwọn ọmọ Ṣúlè yọ́kẹ́lẹ́ wọ̀ ínú ilé Nóà ní òru wọ́n sì pa, wọ́n sì fọ́ ilẹ̀kùn tũbú nã wọ́n sì mú bàbà wọn jáde, wọ́n sì dáa padà sórí ìtẹ́ rẹ̀ nínú ìjọba ara rẹ̀.

19 Nítorí èyí, ọmọkùnrin Nóà sì ńṣe ìjọba rẹ̀ dípò rẹ̀; bíótilẹ̀ríbẹ̃ wọn kò ri agbára gbà lé Ṣúlè ọba lórí, àwọn ènìyàn tí ó sì wà lábẹ́ ìjọba Ṣúlè ọba sì ni ìlọsíwájú púpọ̀púpọ̀ wọ́n sì di alágbára ènìyàn.

20 Ìpínyà sì wà ní orílẹ̀èdè nã; ìjọba méjì ní ó sì wà, ìjọba Ṣúlè, àti ìjọba Kohọ̀, ọmọ Nóà.

21 Kohọ̀, ọmọ Nóà sì mú kí àwọn ènìyàn rẹ̀ ó dojú ogun kọ Ṣúlè, nínú èyítí Ṣúlè borí wọn tí ó si pa Kohọ̀.

22 Àti nísisìyí Kohọ̀ ní ọmọkunrin kan tí a npè ní Nímrọ́dù; Nímrọ́dù sì fi ìjọba Kóhọ̀ lélẹ̀ fún Ṣúlè, ó sì rí ojú rere Ṣúlè; nítorí eyi Ṣúlè sì ńfí àwọn ohun púpọ̀ jínkí rẹ̀, ó sì nṣe ìjọba Ṣúlè gẹ́gẹ́bí ó ti wũ.

23 Àti pẹ̀lú nínú ìjọba Ṣúlè àwọn wòlĩ sì dé sí ãrín àwọn ènìyàn nã, awọn ẹni tí a rán láti ọ̀dọ̀ Olúwa, tí wọ́n sì ńsọ àsọtẹ́lẹ́ pé ìwà búburú àti ìwà ìbọ̀rìṣà àwọn ènìyàn nã ní ó nmú ègún wa sí orí ilẹ̀ nã, pé a ó sì pa wọ́n run bí wọn kò bà ronúpìwàdà.

24 Ó sì ṣe tí àwọn ènìyan nã sì ńkẹ́gàn àwọn wòlĩ nã, tí wọ́n sì ńfi wọ́n ṣe ẹlẹ́yà. Ó sì ṣe tí ọba Ṣúlè sì ṣe ìdájọ́ fún gbogbo àwọn tí nkẹ́gàn àwọn wòlĩ nã.

25 O sì ṣe òfin kan jákè-jádò ilẹ̀ nã, èyítí ó fún àwọn wòlĩ nã ní agbára láti lè lọ sí ibikíbi tí ó bá wù wọ́n; nítorínã a sì mú àwọn ènìyàn nã wá sí ìrònúpìwàdà.

26 Àti nítorípé àwọn ènìyàn nã ronúpìwàdà kúrò nínú àwọn àìṣedẽdé àti àwọn ìwà ìbọ̀rìṣà wọn Olúwa sì dá wọn sí, wọ́n sì tún bẹ̀rẹ̀sí ní ìlọsíwájú nínú ilẹ̀ nã. Ó sì ṣe tí Ṣúlè bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin ní ọjọ́ ogbó rẹ̀.

27 Àwọn ogun kò sì sí mọ́ ní gbogbo ọjọ́ ayé Ṣúlè; ó sì rántí àwọn ohun nlá tí Olúwa tí ṣe fún àwọn baba rẹ̀ ní mímú wọn kọjá lórí òkun ńlá sínú ilẹ̀ ìlérí; nítorí eyi ó ṣe ìdájọ́ nínú òdodo ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.