Àwọn Ìwé Mímọ́
Étérì 10


Orí 10

Ọba kan rọ́pò òmíràn—Àwọn kan nínú àwọn ọba nã jẹ olódodo; àwọn míràn jẹ oníwá búburú—Nígbàtí ìwà òdódo bá borí, Olúwa yíò bùkún yíò sì mú àwọn ènìyàn ṣe rere.

1 O sì ṣe tí Ṣẹ́sì tí ó jẹ ìran Hẹ́tì—nítorítí Hẹ́tí ti ṣègbé nínú ìyàn, àti gbogbo ilé rẹ̀, àfi Ṣẹ́sì—nítorí eyi, Ṣẹ́sì bẹ̀rẹ̀sí mú àwọn ènìyàn nã lọ́kàn le.

2 Ó sì ṣe tí Ṣẹ́sì rántí ìparun àwọn bàbá rẹ̀, ó sì kọ́ ijọba òdodo; nítorítí ó rántí ohun tí Olúwa ti ṣe ní mímú Járẹ́dì àti arákùnrin rẹ̀ kọjá nínú òkun jíjìn nã; ó sì nrìn nínú ọ̀nà Olúwa; ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin.

3 Ọmọkùnrin rẹ̀ tí ó dàgbà jù, tí orúkọ rẹ̀ í ṣe Ṣẹ́sì, sì ṣọ̀tẹ̀ sí i; bíótilẹ̀ríbẹ̃ a pa Ṣẹ́sì láti ọwọ ọlọ́ṣà kan, nitori ọrọ̀ púpọ̀ tí ó ní, èyítí ó sì mú kí àlãfíà ó tún padà bá bàbá rẹ̀.

4 Ó sì ṣe tí bàbá rẹ̀ sì kọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìlú nlá lórí ilẹ̀ nã, àwọn ènìyàn nã sì tún bẹ̀rẹ̀sí tàn ká lórí gbogbo ilẹ̀ nã. Ṣẹ́sì sì wà lãyè títí di ọjọ́ ogbó tí ó pẹ́ púpọ̀; ó sì bí Ríplákíṣì. O sì kú, Ríplákíṣì sì jọba ní ìrọ́pò rẹ̀.

5 O sì ṣe tí Ríplákíṣì kò sì ṣe èyítí ó tọ́ ní ojú Olúwa, nítorití ó ní àwọn aya púpọ̀ àti àwọn àlè, ó sì nfún àwọn ènìyàn nã ní ohun tí ó ṣòró fún wọn láti ṣe; bẹ̃ni, ó mú wọn san owo ode tí ó pọ̀ púpọ̀; pẹ̀lú àwọn owo òde wọ̀nyí ni ó sì nkọ àwọn ilé nlá-nlá.

6 Ó sì kọ́ ìtẹ́-ọba tí ó dára púpọ̀ fún ara rẹ̀; ó sì kọ àwọn tũbú púpọ̀, ẹnikẹ́ni tí kò bá sì san owó òde ní ó jù sínú tũbú; àti ẹnikẹ́ni tí kò bá lè san owó orí ní ó sì jù sínú tũbú, ó sì mú kí wọn ó máa ṣe lãlã títí fún ìtìlẹ́hìn wọn; àti ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ̀ láti ṣe lãlã ní ó mú kí wọn ó pa.

7 Nítorí eyi ni ó fi rí gbogbo àwọn iṣẹ́ dáradára rẹ̀, àní àwọn wura rẹ̀ dáradára pàapã ní ó mú kí wọ́n ó tún dà nínú tũbú; àti gbogbo onírũrú iṣẹ́ ọwọ́ ni ó mú kí wọ́n ṣe ní ọ̀ṣọ́ nínú túbú. Ó sì ṣe tí ó pọ́n àwọn ènìyàn nã lójú pẹ̀lú ìwà àgbèrè àti àwọn ohun ìríra.

8 Àti nígbàtí ó sì ti jọba fún ìwọ̀n ọdun meji le logójì, àwọn ènìyan nã dìdé ní ìṣọ̀tẹ̀ sí i; ogun sì bẹ̀rẹ̀sí tún wà ní ilẹ̀ nã, tóbẹ̃ tí wọ́n pa Ríplakíṣì, àwọn ìran rẹ̀ ní wọ́n sì lé jáde kúrò nínú ilẹ̀ nã.

9 O sì ṣe lẹ́hìn ìwọ̀n ọdún tí ó pọ̀, Moríántónì, (ẹnití ó jẹ ìran Ríplákíṣì) kó ẹgbẹ́ ọmọ ogún kàn jọ lára áwọn àṣátì ènìyàn, ó sì kọjá lọ ó sì gbé ogun kọlũ àwọn ènìyàn nã; ó sì gbà agbára lórí àwọn ìlú nlá púpọ̀; ogun nã sì dí èyití ó gbóná púpọ̀púpọ̀; ó sì wà fun ìwọ̀n ọdún tí ó pọ̀; ó sì gbà agbára lórí gbogbo ilẹ̀ nã, ó sì fí ara rẹ̀ múlẹ̀ gẹ́gẹ́bí ọ́ba lórí gbogbo ilẹ̀ nã.

10 Lẹ́hìn tí ó sì ti fí ẹsẹ̀ ara rẹ̀ mulẹ̀ gẹ́gẹ́bí ọba ó sì dẹ̀ àjàgà ọrùn àwọn ènìyàn nã, nípa èyítí ó rí ojú rere lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn nã, wọ́n sì fi àmì òróró yàn án láti jẹ́ ọba wọn.

11 O sì ṣe àìṣègbè si àwọn ènìyàn nã, láìṣe sí ara rẹ̀ nitori ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwà àgbèrè rẹ̀; nítorí eyi á ké e kúrò níwájú Olúwa.

12 O sì ṣe tí Moriántónì kọ́ ìlú nlá tí ó pọ̀, àwọn ènìyàn nã sì di ọlọ́rọ̀ púpọ̀púpọ̀ lábẹ́ ìjọba rẹ̀, àti ní ti àwọn ilé, àti ni wúrà àti fàdákà, àti ní kíkó ọkà jọ, àti ní agbo ẹran, àti ọ̀wọ́ ẹran, àti nínú àwọn ohun tí a ti dá padà fún wọn.

13 Moriántónì sì dàgbà púpọ̀, lẹ́hìnnã ní ó sì bí Kímù; Kímù sì jọba ní ìrọ́pò bàbá rẹ̀; ó sì jọba fún ọdún mẹ́jọ, bàbá rẹ̀ sì kú. O sì ṣe ti Kímù kò jọba nínú òdodo, nítorí eyi kò sì rí ojú rere Olúwa.

14 Arákùnrin rẹ̀ sì dìde ọ̀tẹ̀ síi, nínú èyítí ó mũ ní ìgbèkùn; ó sì wà nínú igbèkùn ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀; ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin nínú ìgbèkùn, àti nínú ọjọ́ ogbó rẹ̀ ní ó bí Léfì; ó sì kú.

15 O sì ṣe tí Léfì sì sìn nínú ìgbèkùn lẹ́hìn ikú bàbá rẹ̀, fún ìwọ̀n ọdún méjìlélógójì. O sì gbé ogun tì ọba ilẹ̀ nã, nínú èyítí ó gbà ìjọba nã fún ìní ara rẹ̀.

16 Àti lẹ́hìn tí ó ti gbà ìjọba nã fún ìní ara rẹ̀ ó ṣe èyítí ó tọ́ ní ojú Olúwa; àwọn ènìyàn nã sì ṣe rere ní ilẹ̀ nã; ó sì dàgbà púpọ̀, ó sì bí awọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin, ó sì bí Kórómù pẹ̀lú, ẹnití ó fí àmì òróró yàn lọ́ba ní ìrọ́pọ̀ ara rẹ̀.

17 O sì ṣe tí Kórómù ṣe èyítí ó dara níwájú Olúwa ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀; ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin tí ó pọ̀; àti lẹ́hìn tí ó ti rí ọjọ púpọ̀ ó sì kú, àní gẹ́gẹ́bí àwọn ara ayé; Kísì sí jọba ní ìrọ́pò rẹ̀.

18 O sì ṣe tí Kíṣì kú pẹ̀lú, Líbù sì jọba ní ìrọ́pò rẹ̀.

19 Ó sì ṣe tí Líbù pẹ̀lú ṣe ohun èyítí ó dára níwájú Olúwa. Àti ní ọjọ́ ayé Líbù wọ́n pa àwọn ejò olóró nã run. Nítorí eyi wọ́n lọ sínú ilẹ̀ tí ó wà ní apá gũsù, látí lọ ṣe ọdẹ fun onjẹ fún àwọn ènìyàn ilẹ̀ nã, nítorítí àwọn ẹranko igbó bò ilẹ̀ nã. Líbù pẹ̀lú fúnrarẹ̀ sì di ọdẹ nla.

20 Wọ́n sì kọ́ ìlú nlá kan sí ẹ̀bá ilẹ̀ tõró tí ó wa ní ibití òkun tí pín ilẹ̀ nã yà.

21 Wọ́n si pa ilẹ̀ tí ó wà ni apá gũsù aginjù mọ́ láti mã rí àwọn ẹran ọdẹ. Gbogbo orí ilẹ tí ó sì wà ní apá àríwá ni àwọn ènìyàn ngbé inú rẹ̀.

22 Wọ́n sì jẹ́ ènìyàn tí ó tẹpámọ́ṣẹ́, wọ́n sì nṣe kárà-kátà wọn sì nṣòwò pẹ̀lú ara wọn, láti lè rí èrè.

23 Wọ́n sì nlò onírúurú irin láti ṣiṣẹ́, wọn sì nyọ́ wúra, àti fàdákà, àti irin, àti idẹ, àti onírúuru àwọn irin; wọ́n sì nwà wọ́n jáde láti inú ilẹ̀; nítorí eyi wọ́n sì wà àwọn òkítì èrùpẹ̀ jáde láti ri àwọn irin àìpò tútù, ti wúrà, àti ti fàdákà, àti ti irin, àti ti bàbà. Wọ́n sì rọ àwọn onírúurú iṣẹ́ dáradára.

24 Wọ́n sì ní àwọn aṣọ sẹ́dà, àti àwọn aṣọ ọ̀gbọ̀ tí ó jọjú; wọ́n sì nhun àwọn onírúurú aṣọ, kí wọn ó lè wọ asọ̀ láti fi bò ìhòhò wọn.

25 Wọ́n sì rọ onírúuní àwọn ohun èlò láti roko, àti láti túlẹ̀ àti láti gbìn, láti kórè àti láti ro, àti láti pakà pẹ̀lú.

26 Wọ́n sì rọ onírũru àwọn ohun èlò pẹ̀lú èyítí wọn mú àwọn ẹranko wọn ṣiṣẹ́.

27 Wọ́n sì rọ onírúurú àwọn ohun ìjà ogun. Wọ́n sì nṣe onírúurú iṣẹ́ tí wọn ṣe iṣẹ́ ọnà sí lára.

28 Kò sì sí bí àwọn ènìyàn ti lè jẹ olùbùkún tó bí wọn ti jẹ́, àti kí ó mú wọn ṣe rere. Wọ́n sì wà nínú ilẹ̀ èyítí ó jẹ́ àṣàyàn jù gbogbo ilẹ̀ lọ, nítorítí Olúwa ni ó ti wí i.

29 Ó sì ṣe tí Líbù gbé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ómọbìnrin; ó sì bí Héátómì pẹ̀lú.

30 Ó sì ṣe tí Héátọ́mù jọba ní ìrọ́pò bàbá rẹ̀. Nígbàtí Héátómì sì ti jọba fún ọdún mẹ́rìnlélógún, ẹ kíyèsí i, wọ́n gbà ìjọba nã lọ́wọ́ rẹ̀. O sì lò ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún nínú ìgbèkùn, bẹ̃ni, àní gbogbo èyítí ó kù nínú ọjọ́ ayé rẹ̀.

31 O sì bí Hẹ́tì, Hẹ́tì sì gbé nínú ìgbèkùn ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀. Hẹ́tì sì bí Áárọ́nì, Áárọ́nì sì gbé nínú ìgbèkùn ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀; ó sì bí Ámnígádà, Ámnígádà pẹ̀lú sì gbé nínú ìgbèkùn ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀; ó sì bí Koríántúmù, Koríántúmù sì gbé nínú ìgbèkùn ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀; ó sì bí Kọ́mù.

32 Ó sì ṣe ti Kọ́mù fà ìdájì àwọn ènìyàn inú ìjọba nã lọ. Ó sì jọba lórí ìdaji ìjọba nã fún ọdún méjìlélógójì; ó sì lọ láti bá ọba Ámgídì jagun, wọ̀n sì jà fún ìwọ̀n ọdún tí ó pọ̀ nínú àkókò èyítí Kọ́mù gbà agbára lórí Ámgídì, ó sì gbà agbárá lórí èyítí ó kù nínú ìjọba nã.

33 Ní ọjọ́ ayé Kọ́mù sì ni àwọn ọlọ́ṣà bẹ̀rẹ̀sí wà nínú ilẹ̀ nã; wọ́n sì mú àwọn ìlànà àtijọ́ lò, wọ́n sì ṣe àwọn ìbúra bí àwọn ará àtijọ́ ti nṣe, wọ́n sì wá ọ̀nà láti pa ìjọba nã run.

34 Nísisìyí Kọ́mù sì bá wọn jà púpọ̀; bíótilẹ̀ríbẹ̃, kò borí wọn.