Àwọn Ìwé Mímọ́
Mórónì 2


Orí 2

Jésù fún àwọn ọmọ ẹ̀hìn ara Nífáì méjìlá nnì ní agbára láti fi ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́ fún ni. Ní ìwọ̀n ọdún 401 sí 421 nínú ọjọ́ Olúwa.

1 Àwọn ọ̀rọ́ Krístì, èyítíi ọ́ sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀hìn rẹ̀, àwọn méjìlá tí ó ti yàn, bí ó ti gbé ọwọ́ rẹ̀ lé wọn—

2 O sì fi orúkọ wọn pè wọ́n, wípé: Ẹyin yíò ké pè Bàbá ni orukọ mi, nínú àdúrà nlá; àti lẹ́hin tí ẹ̀yin bá ti ṣe eleyĩ ẹ̀yin yíò ní gbára pe ẹnití ẹ̀yin yíò gbe ọwọ yín le, ẹyin yíò fi Ẹ̀mí Mímọ́ fún un; àti ní orúkọ mi ni ẹ̀yin yíò fi fún ni, nítorí báyĩ ni àwọn àpóstélì mi yíò ṣe.

3 Nísisìyí Krístì sọ àwọn ọ̀rọ̀ yĩ fún wọn ní ìgbà tí ó kọ́kọ́ farahàn sí wọn; àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn kò sì gbọ́ ọ, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ẹ̀hìn gbọ́ ọ; àti pe gbogbo iye àwọn tí wọ́n gbé ọwọ́ wọn lé, ni ó gbà Ẹ̀mí Mímọ́.