Àwọn Ìwé Mímọ́
Mórónì 4


Orí 4

A ṣe àlàyé lórí bí àwọn àgbàgbà àti àwọn àlùfã ṣé nfi àkàrà àmì májẹ̀mú fún ni. Ní ìwọ̀n ọdún 401 sí 421 nínú ọjọ́ Olúwa wa.

1 Ọ̀nà tí àwọn àgbàgbà wọn àti àwọn àlùfã wọn gbà nfi ara àti ẹ̀jẹ̀ Krístì fún ìjọ; wọ́n sì nfi fún ni ní ìbámu pẹ̀lú òfin Krístì; nítorí èyí, àwa mọ̀ pé òtítọ́ ni ọ̀nà nã, alàgbà tabi àlùfã ní ó sì fifún ni—

2 Wọ́n sì kúnlẹ̀ pẹ̀lú ìjọ, wọ́n sì gbàdúrà sí Bàbá ní orukọ Krístì, wípé:

3 A! Olọ́run, Bàbá Ayérayé, àwa bẽrè lọ́wọ́ yín ní orúkọ Ọmọ yín, Jésù Krístì, pé kí ẹ bùkún kí ẹ sì yà àkàrà yĩ sí mímọ́ fún ọkàn gbogbo àwọn tí ó jẹ́ alábãpín nínú rẹ̀; láti lè jẹ ní ìrántí ara ti Ọmọ yín, kí wọ̀n ó sì jẹ̃rí sí yín, A! Ọlọ́run, Bàbá Ayéráyè, pé wọ́n ní ìfẹ́ láti gbà orúkọ ọmọ yín sórí wọn, wọn sì rántí rẹ̀ nígbàgbogbó, wọn sì npá òfin rẹ̀ mọ́ èyítí ó ti fi fun wọn, kí wọn ó lè ni Ẹ̀mi rẹ̀ pẹ̀lú wọn nígbàgbogbo. Àmín.