Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ṣé O Ṣì Nfẹ́
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2022


Ṣé O Ṣì Nfẹ́?

Fífẹ́ wa láti tẹ̀lé Jésù Krístì wà tààrà ní ìbámu sí iye àkokò tí a fisílẹ̀ láti wà ní àwọn ibi mímọ́.

Ní ọjọ́ Ìsinmi kan, nígbà tí mò nmúrasílẹ̀ láti jẹ oúnjẹ Olúwa lẹ́hìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀sẹ̀ ti àwọn yíyan-iṣẹ́ ìpàdé àpapọ̀ ti èèkàn, ìrònù alágbára wíwuni kan wá sí ọkàn mi.

Bí àlùfáà ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í bùkún búrẹ́dì náà, àwọn ọ̀rọ̀ tí mo ti gbọ́ ní ọ̀pọ̀ ìgbà ṣáájú tẹ̀ mí lọ́kàn ṣinṣin. “Kí a sì jẹ́rìí sí ọ, Ọlọ́run, Baba Ayérayé, pé wọ́n nfẹ́ láti gbé orúkọ Ọmọ rẹ lé ara wọn lórí, kí wọ́n sì máa rántí rẹ̀ nígbàgbogbo kí wọ́n sì pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́ tí ó ti fi fún wọn; kí wọ́n lè ní Ẹ̀mí rẹ̀ láti máa wà pẹ̀lú wọn nígbàgbogbo.”1 Ìgbà mélòó ni a ti jẹ́ríì fún Ọlọ́run pé à nfẹ́?

Bí mo ṣe nronú lórí ìjẹ́pàtàkì àwọn ọ̀rọ̀ mímọ́ wọ̀nyẹn, ọ̀rọ̀ náà nfẹ́ wú mi lórí ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Ìkún omi ti àwọn ìrírí dídùn àti mímọ́ kún ọkàn àti inú mi, pẹ̀lú ìfẹ́ àti ọpẹ́ fún ẹbọ ètùtù ti Olùgbàlà àti ojúṣe pàtàkì Rẹ̀ nínú ètò ìràpadà Baba fún ẹbí mi àti èmi. Lẹ́hìnnáà, mo gbọ́ mo sì ní ìmọ̀lára àwọn ọ̀rọ̀ àdúrà tí ó wọlé lórí omi: “Kí wọ́n lè jẹ́rìí sí ọ … pé wọ́n máa rántí rẹ̀ nígbàgbogbo.”2 Ó yé mi kedere ní àkokò yẹn pé pípa àwọn májẹ̀mù mi mọ́ gbọ́dò jẹ́ díẹ̀ síi ju àwọn èrò inú rere lọ.

Jíjẹ oúnjẹ Olúwa kìí ṣe àṣà ẹ̀sìn tí ó túmọ̀ ìfọkànsí wa lásán. Ó jẹ́ ìránnilétí alágbára ti òtítọ́ àti ìpìlẹ̀ ti Ètùtù àìlópin Krístì àti ìnílò láti rántí Rẹ̀ nígbàgbogbo kí a sì pa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́. Fífẹ́ láti dojúkọ Olùgbàlà jẹ́ pàtàkì tóbẹ́ẹ̀ tí ó jẹ́ gbùngbùn ọ̀rọ̀ àwọn ìwé-mímọ́ méjì tí a sọ jùlọ ní Ìjọ: àwọn àdúrà oúnjẹ Olúwa. Lílóye òtítọ́ ohun tí Baba Ọ̀run nfi tọkàntọkàn pèsè fún ẹnì kọ̀ọ̀kan wa nípasẹ̀ Ọmọ Bíbí Rẹ̀ Kanṣoṣo níláti ru ìtiraka wa gíga jùlọ láti ní ìfẹ́ nígbàgbogbo ní ìfèsì.

Njẹ́ a kọ́ ìpìlẹ̀ ti ẹ̀mí wa jinlẹ̀ lórí Jésù Kristi bí?

Bí ìpìlẹ̀ ti ẹ̀mí wa kò bá jìn tàbí tí kò fi bẹ́ẹ̀ jinlẹ̀, a lè ní ìtẹ̀sí láti gbé ìfẹ́-láti-ṣe wa lórí àyẹ̀wò iye owó láwùjọ tàbí atọ́ka àìrọrùn ti ara ẹni. Àti pé bí a bá faramọ́ ìtàn pé ìjọ pẹ̀lú kókó àwọn ìlànà àwùjọ ti ìgbà àtijọ́ tàbí ti ìṣèlú tí kò tọ́, àwọn ìhámọ́ araẹni tí kò dájú, àti àwọn ìfarasìn àkokò, lẹ́hìnnáà àwọn ìpinnu wa nípa fífẹ́ yìó di alábàwọ́n. Kí a máa retí ìpìlẹ̀ ìfẹ́-láti-ṣe láti àṣà dáradára pẹ̀lú àwọn olùdásíṣẹ́ ìbákẹ́gbẹ́ ìròhìn tàbí àwọn alárà TikTok. Ó ṣọ̀wọ́n kí àwọn ìlànà ènìyàn wà ní ìbámu pẹ̀lú òtítọ́ àtọ̀runwá.

Ìjọ jẹ́ ibi ìkójọpọ̀ fún àwọn ènìyàn aláìpé tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n sì nfẹ́ láti tẹ̀lé Jésù Krístì Olúwa. Ìfẹ́-láti-ṣe yẹn fìdí múlẹ̀ nínú òtítọ́ náà pé Jésù ni Kristi, Ọmọ Ọlọ́run alààyè. Òtítọ́ àtọ̀runwá yí ni a lè mọ̀ nípasẹ̀ agbára Ẹ̀mí Mímọ́ nìkan. Nítorínáà, ìfẹ́-láti-ṣe wa ní ìbámu tààràtà sí iye àkokò tí a yàn láti wà ní àwọn ibi mímọ́ níbi tí ipa ti Ẹ̀mí Mímọ́ wà.

A yíò ṣe dáadáa láti lo àkokò síi nínú àwọn ìbárasọ̀rọ̀ sísọ àwọn àníyàn wa pẹ̀lú olùfẹ́ni Baba ní Ọ̀run àti ní ìdínkù àkokò wíwá èrò àwọn ohùn míràn. Bákannáà a lè yàn láti yí ìròhìn ojojúmọ́ fífúnni padà sí ọ̀rọ̀ Krístì nínú ìwé mímọ́ àti sí ọ̀rọ̀ ti wòlíì àwọn wòlíì alààyè Rẹ̀.

Pàtàkì tí a fi lé ọjọ́ ìsinmi wa, sísan ìdámẹ́wàá òtítọ́, dídi ìdánimọ̀ tẹ́mpìlì kan mú, lílọ sí tẹ́mpìlì, àti bíbọ̀wọ̀ fún àwọn májẹ̀mú tẹ́mpìlì mímọ́ jẹ́ àwọn àmì tí ó lágbára ti Ìfẹ́-láti-ṣe àti ẹ̀rí ìfaramọ́ wa. Njẹ́ à nfẹ́ láti ṣe ju ìtiraka lásán láti fún ìgbàgbọ́ wa nínú Kristi lókun bí?

Baba Ọ̀run fẹ́ wa ní pípé, ṣùgbọ́n ìfẹ́ yẹn wá pẹ̀lú àwọn ìrètí nlá. Ó retí pé kí a fi tinútinú gbé Olùgbàlà sí àárín gbùngbùn ìgbésí ayé wa. Olùgbàlà ni àpẹrẹ pípé Ìfẹ́-láti-ṣe wa láti tẹríba fún Baba nínú ohun gbogbo. Òun ni, “ọ̀nà, òtítọ́, àti ìyè.”3 Ó fi tìfẹ́tìfẹ́ ṣe ètùtù fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa. Ó fi tìfẹ́tìfẹ́ mú ẹrù wa rọrùn, rọ àwọn ìnira wa, fún wa ní okun, ó nmú àlàáfíà àti òye wá sí ọkàn wa ní àkokò ìdààmú àti ìbànújẹ́.

Síbẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì jẹ́ yíyàn. “Bí [a] kò bá le ṣe ju ìfẹ́ láti gbàgbọ́”4 nínú àwọn ọ̀rọ̀ Rẹ̀, a ní ààyè ìbẹ̀ẹ̀rẹ̀ láti bẹ̀rẹ̀ tàbí láti tún ìrìn-àjò ìgbàgbọ́ wa padà. Àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀, bí a bá gbìn sínú ọkàn wa bí èso tí a sì ṣìkẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú ìtọ́jú nlà, yíò ta gbòngbò, ìgbàgbọ́ wa yíò sì dàgbà sínú ìdánilójú, yíò sì di ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ ti ìṣe àti agbára. Ìwé ti Mọ́mọ́nì jẹ́ ohun èlò alágbára júlọ fún dídàgbà àti mímúpadàbọ̀sípò ìgbàgbọ́ wa. Níní ìfẹ́ jẹ́ àmújáde ìgbàgbọ́.

Ayé ikú, nípasẹ̀ ọnà àtọ̀runwá, kò rọrùn àti pé nígbà míràn ó lè boni mọ́lẹ. Bí ó ti wù kí ó rí, “[a] wà, kí [a] lè ní ayọ̀”!5Fífi ojú sí Olùgbàlà àti àwọn májẹ̀mú mímọ́ wa nmú ayọ̀ pípẹ́ wá! Ìdí ayé ikú ni láti fi ìfẹ́-láti-ṣe wa hàn. “Iṣẹ́ nlá ti ìgbésí ayé, àti iye owo jíjẹ́-ọmọlẹ̀hìn, ni láti kọ́ ìfẹ́ Olúwa kí a sì ṣe é.”6 Jíjẹ́-ọmọlẹ̀hìn tòótọ́ nṣamọ̀nà sí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ayọ̀. Njẹ́ a nfẹ́ láti san ìdíyelé jíjẹ́-ọmọlẹ̀hìn bi?

Ọ̀nà májẹ̀mú kìí ṣe àkójọ àyẹ̀wo tí ó rọrùn; ó jẹ́ ìlànà ìdàgbàsókè ti ẹ̀mí àti ìfaramọ́ jíjinlẹ̀ sí Jésù Kristi. Ìdí pàtàkì gbogbo òfin, ìpilẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀kọ́, májẹ̀mú, àti ìlànà ni láti kọ́ ìgbàgbọ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Krístì. Nítorínáà, ìpinnu wa láti gbé ìgbésí ayé wa lé orí Krístì gbọ́dọ̀ wà déédéé—kì í ṣe àídájú, ipò, tàbí ti ara. A ò lè lo àkókò ìsinmi tàbí ìsinmi ara ẹni ti Ìfẹ́-láti-ṣe láti “dúró gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́rìí fún Ọlọ́run ní gbogbo ìgbà àti ní ohun gbogbo, àti ní gbogbo ibi.”7 Jíjẹ́-Ọmọlẹ́hìn kò rọrùn, nítorí íbákẹ́gbẹ́ Ẹmí Mímọ́ ko ni ìdíyelé.

Dájúdájú Olúwa nronú nípa ọjọ́ wa bí ó ti nkọ́ni ní òwe àwọn wúndíá mẹ́wàá náà. Nípa àwọn márùn tí wọ́n jẹ́ ọlọ́gbọ́n, Ó wípé: “Wọ́n ti gba Ẹ̀mí Mímọ́ fún amọ̀nà wọn, a kò sì tan wọ́n jẹ,”8 nígbà tí àtùpà aláìgbọ́n “ti kú lọ” nítorí àìsí òróró.9 Bóyá àwọn ọ̀rọ̀ Néfì ṣe àpèjúwe dáradára jùlọ àwọn ọmọ ìjọ olótítọ́ nígbà kan rí: “Àti pé àwọn míràn ni yíò rọ̀nínú, tí yíò sì mú wọn lọ sínú ààbò ti ara, tí wọn yíò wípé: Gbogbo rẹ̀ dára ní Síónì.”10

Aàbò ti ara ni wíwá àti gbígbẹ́kẹ̀lé àwọn ohun ti ayé dípo Krístì—ní àwọn ọ̀rọ̀ míràn, wíwo nípasẹ̀ lẹ́nsì ti ayé dípò ìwò ti ẹ̀mí. Ẹ̀mí Mímọ́ fún wa ní agbára láti rí “àwọn nkan bí wọ́n ṣe rí gan-an, àti… bí wọ́n ṣe máa rí.”11 Nípa “agbára Ẹ̀mí Mímọ́ nìkan [ni a] lè mọ òtítọ́ ohun gbogbo”12 kí a má ṣe tàn wá jẹ. A fi Krístì sí gbùngbùn ayé wa a sì jẹjẹ ìfẹ́ wa láti gbọ́ràn sí àwọn òfin Rẹ̀ kìí ṣe pé a fọ́jú ṣùgbọ́n nítorí pé a lè ríran.13

Báwo niti àwọn wúndíá aláìgbọ́n? Èé ṣe tí wọn kò fi fẹ́ gbé ohun èlò òróró ti ẹ̀mí? Ṣé wọ́n kàn sun síwájú ni? Bóyá, wọ́n jẹ́ aláìlẹ́tọ pẹ̀lú nítorí pé kòrọrùn tàbí ó dàbí ẹnipé kò wúlò? Ohun yòówù kí èrèdí náà jẹ́, a tàn wọ́n jẹ nípa ojúṣe pàtàkì tí Krístì kó. Èyí ni ìpìlẹ̀ ẹ̀tàn Sátánì àti ìdí tí àwọn fìtílà ẹ̀rí wọn ṣe kú nígbẹ̀hìn fún àìsí òróró ti ẹ̀mí. Àfiwé yìí jẹ́ òwe òde òní fún àkokò wa. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ fi Olùgbàlà àti àwọn májẹ̀mú wọn sílẹ̀ tipẹ́tipẹ́ kí wọ́n tó kúrò ní Ìjọ Rẹ̀.

A ngbé ní àwọn àkokò tí a kò tíì rí tẹ́lẹ̀ tipẹ́tipẹ́ tí àwọn wòlíì ìgbàanì ti sọ tẹ́lẹ̀, ọjọ́ kan nígbà tí Sátánì bínú “nínú ọkàn-àyà àwọn ọmọ ènìyàn, tí ó sì ru wọ́n sókè láti bínú sí ohun rere.”14 Púpọ̀ lára wa ngbé ní ayé lórí ìlà nínú ìṣeré àti ìsọ́rọ̀ líle sí ìdánimọ̀ àtọ̀runwá àti ìgbàgbọ́ nínú Krístì.

Ipa alágbára jùlọ ti ẹ̀mí ní ayé ọmọdé ní àpẹẹrẹ òdodo ti àwọn olùfẹ́ òbí àti àwọn òbí àgbà tí wọ́n pa àwọn májẹ̀mú mímọ́ tiwọn mọ́ pẹ̀lú òtítọ́. Àwọn òbí tó mọ̀ọ́mọ̀ nkọ́ àwọn ọmọ wọn ní ìgbàgbọ́ nínú Jésù Kristi Olúwa kí àwọn náà lè “mọ̀ orísun tí wọ́n lè máa wá ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ wọn.”15 Májẹ̀mú pípamọ́ àìròtẹ́lẹ̀ àti àìtẹramọ́ ndarí sí ìpalára ti ẹ̀mí. Ìbàjẹ́ ti ẹ̀mí nígbàgbogbo nga jùlọ lórí àwọn ọmọ àti awọn ọmọ-ọmọ wa. Àwọn òbí àti àwọn òbí àgbà, ṣé a ṣì nfẹ?

Ààrẹ Nelson ti kìlọ̀ fún wa pé “ní àwọn ọjọ́ tí nbọ̀, kò ní ṣeé ṣe láti wà láàyè nípa ti ẹ̀mí, láìsí ìtọ́nisọ́nà, dídarí, títùninínú àti ipa Ẹ̀mí Mímọ́ léraléra.”16 Èyí jẹ́ ìkìlọ̀ kedere tí kò sì ní àṣìṣe láti tún fìtílà wa ṣe, kí a sì mú òróró tẹ̀mí wa pa mọ́. Njẹ́ a ṣi nfẹ láti tẹ̀lé àwọn wòlíì alãye bi? Kíni ipele òróró ti ẹ̀mí nínú fìtílà yín? Kíni àwọn ìyípadà nínú ìgbé ayé araẹni yín yíò jẹ́ kí ẹ lè ní agbára Ẹmí Mímọ́ síi léraléra?

Lónìí, gẹ́gẹ́bí ó ti rí ní àwọn àkokò Jésù, àwọn kan yíò wà tí wọn yíò yí padà, tí wọn kò fẹ́ gba ìdíyelé jíjẹ́-ọmọlẹ̀hìn. Bí àríwísí líle àti ìkórìíra ti npọ̀ sí i ní Ìjọ Olùgbàlà àti àwọn tí wọ́n ntẹ̀lé E, jíjẹ́-ọmọlẹ́hìn wa yíò nílò ìfẹ́-láti-ṣe púpọ̀ láti tọ́ àti láti fún àwọn ẹ̀hìn ẹ̀mí wa lókun kí a má sì kọbi ara sí wọn.17

Bí ìpìlẹ̀ ti ẹ̀mí wa bá dá lórí Jésù Krístì gbọingbọin, a kò ní ṣubú a kò sì ní láti bẹ̀rù.

“Kíyèsí i, Olúwa nbèèrè ọkàn àti inú tí nfẹ́; àti àwọn tí ó nfẹ́ àti àwọn tí ó gbọ́ràn yíó jẹ ire ti ilẹ̀ Síónì ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn yìí.”18

Njẹ́ kí á ní ìfẹ́-láti-ṣe nígbàgbogbo. Ní orúkọ mímọ́ ti Olúwa Jésù Krístì, àmín