Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ogún Ìgbani-níyànjú
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2022


Ogún Ìṣírí

Mo gbà yín níyànjú láti tẹ̀síwájú ní ìlàkàkà láti yẹ láti padà sí ọ̀dọ̀ Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, mo ní ìmoore láti wà pẹ̀lú yin nínú ìpàdé àpapọ̀ ti Ìjọ ti Jésù Krístì tí Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́ Ìkẹhìn. A ti nímọ̀lára ìgbàgbọ́ yín àti ìfẹ́ yín níbikíbi tí ẹ bá wà. A ti di alábùkúnfún nípa ẹ̀kọ́ onímisi, àwọn ẹ̀rí alágbára, àti orin oníyìn.

Mo gbà yín níyànjú láti tẹ̀síwájú ní ìlàkàkà láti yẹ láti padà sí ọ̀dọ̀ Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì. Níbikíbi tí ẹ bá wà ní ọ̀nà májẹ̀mú, ẹ ó rì ìjàkadì lòdì sí àwọn ìdánwò ti ara ti ikú tàbí àtakò Sàtánì.

Gẹ́gẹ́bí ìyá mi ṣe sọ fún mi nígbà tí mo ṣàròyé nípa bí nkan ṣe le tó, “Ah, Hal, dájúdájú ó le. Ó yẹ kó lè. Ìgbé-ayé jẹ́ ìdánwó ránpẹ́ kan.”

Ó lè sọ iyẹn pẹ̀lú ìdákẹ́rọ́rọ́, pàápàá pẹ̀lú ẹ̀rín, nítorí ó mọ ohun méjì. Láìbìkítà ìjàkadì, ohun tí yìó ṣe pàtàkì jùlọ ni láti dé ilé láti wà pẹ̀lú Baba rẹ̀ Ọ̀run. Ó sì mọ̀ pé òun lè ṣe é nípa ìgbàgbọ́ nínú Olùgbàlà rẹ̀.

Ó nímọ̀lára pé Ó sún mọ́ ọ. Ní àwọn ọjọ́ tí ó mọ̀ pé òun kò ní pẹ́ kú, ó sọ̀rọ̀ pẹ̀lú mi nípa Olùgbàlà bí ó ti dùbúlẹ̀ nínú yàrá rẹ̀. Ilẹ̀kùn kan wà lọ sí yàrá míràn nítòsí ibùsùn rẹ̀. Ó rẹ́ẹ̀rín músẹ́ ó sì wo ẹnu-ọ̀nà nígbàtí ó sọ̀rọ̀ ní ìdákẹ́rọ́rọ́ ní ti rírí I láìpẹ́. Mo ṣì rántí wíwo ẹnu-ọ̀nà tí mo sì nfojú inú wo yàrá tí ó wà lẹ́hìn rẹ̀.

Bayi ó wà ní ayé ti ẹ̀mí. Ó lè tẹ ojú rẹ̀ mọ́ ìdíyelé tí ó fẹ́ pẹ̀lú àwọn ọdún àdánwò ti ara àti ti araẹni.

Ogún ìgbàni-níyànjú tí ó fi sílẹ̀ fún wa ni a ṣe àpèjúwe rẹ̀ dáradára nínú Mórónì 7, níbi tí Mọ́mọ́nì ti gba ọmọ rẹ̀ Mórónì níyànjú àti àwọn ènìyàn rẹ̀. Ó jẹ́ ogún ìgbàni-níyànjú fún àtẹ̀lé ọmọ bíbí ti ìyá mi sí ẹbí rẹ̀. Mọ́mọ́nì darí ogún ìgbàni-níyànjú yẹn sí gbogbo àwọn tí wọ́n ní ìpinnu láti yege, nínú gbogbo ìdánwò ayè ikú wọn, fún ìyè ayérayé.

Mọ́mọ́nì bẹ̀ẹ̀rẹ̀ ní àwọn ẹsẹ àkọ́kọ́ ti Mórónì 7 pẹ̀lú ẹ̀rí ti Jésù Krístì, ti àwọn áńgẹ́lì, àti ti Ẹ̀mí Krístì, èyítí ó jẹ́ kí a mọ ohun rere kúrò nínú ibi, kí a sì lè yan èyí tí ó tọ́.

Ó fi Jésù Krístì sípò àkọ́kọ́, gẹ́gẹ́bí gbogbo àwọn tí wọ́n ṣàṣeyọrí ní fífi ìyànjú fún àwọn wọnnì tí wọ́n ntiraka síwájú ní ipa ọ̀nà sí ilé wọn ti ọ̀run:

“Nítorítí a kò lè gbà ẹnikẹ́ni là, gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ Krístì, àfí bí wọ́n bá ní ìgbàgbọ́ nínú orúkọ rẹ̀; nítorí èyí, bí àwọn ohun wọ̀nyí bá ti dáwọ́dúró, nígbànã ní ìgbàgbọ́ ti dáwọ́dúró pẹ̀lú; ìpò búburú sì ni ènìyàn wà, nítorítí wọ́n wà bí èyítí a kò ṣe ìràpadà fún wọn.

“Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, ẹ̀yin arákùnrin mí àyànfẹ́, mo ṣe ìdájọ́ nípa èyítí ó dára jù fún yín, nítorítí èmi ṣe ìdájọ́ pé ẹ̀yin ní ìgbàgbọ́ nínú Krístì nitori ìwà tútù yín; nítorítí bí ẹ̀yin kò bá ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ nígbànã ní kò tọ́ kí a kà yín mọ́ àwọn ènìyàn ìjọ rẹ̀.”1

Mọmọnì rí ìwà tútù gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí okun ìgbàgbọ́ wọn. Ó rí i pé wọ́n nímọ̀lára ìgbẹ́kẹ̀lé lé Olùgbàlà. Ó fún wọn ní ìgbìyànjú nípa kíkíyèsí ìgbàgbọ́ náà. Mọ́mọ́nì tẹ̀síwájú ní fífún wọn ní ìgbìyànjú nípa ríràn wọ́n lọ́wọ́ láti rí i pé ìgbàgbọ́ àti ìwà tútù wọn yíò gbé ìdánilójú wọn sókè àti ìgbẹ́kẹ̀lé àṣeyọrí wọn nínú ìjàkadì wọn:

“Àti pẹ̀lú, ẹ̀yin àyànfẹ́ arákùnrin mi, emí yíò bá yín sọ̀rọ̀ nípa ìrètí. Báwo ní ẹ̀yin ṣe lè ri ìgbàgbọ́ gbà, bíkòṣepé ẹ̀yin ní ìrètí?

“Kí sì ni ẹ̀yin yíò ní ìrètí fún? Ẹ́ kíyèsĩ mo wí fún yín pe ẹ̀yin yio ní ìrètí nípasẹ̀ ètùtù Krístì àti agbára àjínde rẹ̀, kí a gbé yín dìde sí ìyè tí kò nípẹ̀kun, èyítí ó sì rí bẹ̃ nítorí ìgbàgbọ́ yín nínú rẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ìlérí rẹ̀.

“Nítorí èyí, bí ẹnikẹ́ni bá ní ìgbàgbọ́ ó gbọ́dọ̀ ní ìrètí; nítorí láìsí ìgbàgbọ́ kò lè sí ìrètí rárá.

“Àti pẹ̀lú, ẹ̀ kíyèsĩ mo wí fún yín pé òun kì yíò ní ìgbàgbọ́ àti ìrètí, àfi bí ó bá jẹ́ oníwàtútù ènìyàn, àti onírẹ̀lẹ̀-ọkàn ènìyàn.”2

Mọ́mọ́nì lẹ́hìn náà fún wọn ní ìgbìyànjú nípa jíjẹ́rìí pé wọ́n wà lójú ọ̀nà láti gba ẹ̀bùn tí ọkàn wọn ní kíkún fún ìfẹ́ mímọ́ ti Krístì. Ó kó àwọn ìbáṣepọ̀ ti ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì, ìwà tútù, ìrẹ̀lẹ̀, Ẹ̀mí Mímọ́, àti ìrètí tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀ ti gbígba ẹ̀bùn ìyè ayérayé papọ̀ fún wọn. Ó gba wọn níyànjú lọ́nà yìí:

“Nítorítí ẹnikẹ́ni kò jẹ́ ìtẹ́wógbà níwájú Ọlọ́run àfi oníwà tútù àti onírẹ̀lẹ́-ọkàn ènìyàn; bí ẹnikẹ́ni bá sì jẹ́ oníwàtútù àti onírẹ̀lẹ̀ ọkàn, tí ó sì jẹ́wọ́ nípa agbara Ẹ̀mí Mímọ́ pé Jésù ni Krístì nã, ó nílàti ní ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́; nítorítí bí kò bá ní ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ asán ní í ṣe; nítorí èyí ó níláti ní ìfẹ́ áìlẹ́gbẹ́.”3

Ní wíwo ẹ̀hìn, mo rí i nísisìyí bí ẹ̀bùn ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́—ìfẹ́ mímọ́ ti Krístì—ti fún-lókun, tọ́nisọ́nà, múnidúró, tí ó sì yí ìyá mi padà nínú ìtiraka ní ọ̀nà rẹ̀ sí ilé.

“Ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́ a máa mú sũrù, a sì máa ṣeun, kì í sì íṣe ìlara, kì í sì í fẹ̀, kì íwá ohun tí ara rẹ̀, a kĩ múu bínú, kĩ gbèrò ohun búburú, kì í sì í yọ̀ nínú àìṣedẽdé, ṣùgbọ́n a máa yọ̀ nínú òtítọ́, a máa faradà ohun gbogbo, a máa gbà ohun gbogbo gbọ́, a máa retí ohun gbogbo, a sì máa farada ohun gbogbo.

“Nítorí èyí, ẹ̀yin ará mi olùfẹ́, bí ẹ̀yin kò bá ní ìfẹ́, ẹ̀yin kò jẹ́ nǹkan kan, nítorí ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́ kì í kùnà láé. Nítorí èyí, ẹ rọ̀mọ́ ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́, èyítí ó tóbi jù ohun gbogbo, nítorítí ohun gbogbo gbodọ̀ kùnà---

“Ṣùgbọ́n ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́ ní ìfẹ́ Krístì tí kò ní àbàwọ́n, ó sì wà títí láe; ẹnikẹ́ni tí a bá sì rí ti ó ní i ní ọjọ́ ìkẹhìn, yíò dára fún un.

“Nítorí èyí, ẹ̀yin àyànfẹ́ arákùnrin mi, ẹ gbàdúrà sí Bàbá pẹ̀lú gbogbo agbára tí ó wà nínú yín, pé kí ìfẹ́ yì í ó kún inú yín, èyítí ó ti fi jínkí gbogbo àwọn tí wọn jẹ́ olùtẹ̀lé Ọmọ rẹ̀, Jésù Krístì; kí ẹ̀yin ó lè dì ọmọ Ọlọ́run; pé nígbàtí o bá fi ara hàn, a ó dàbí rẹ̀, nítorí àwa yio ríi àní bí ó ti ri; kí àwa ó lè ní ìrètí; kí Ọlọ́run ó lè sọ wá di mímọ́ àní bí òun ti mọ́.”4

Mo fi ìmoore hàn fún ìgbani-níyànjú ti àpẹrẹ àti ẹ̀kọ́ Mormon. Mo ti jẹ́ alábùkún fún nípasẹ̀ ogún ìyá mi. Àwọn wòlíì láti Adam títí di òní, nípasẹ̀ kíkọ́ àti àpẹẹrẹ, ti fún mi lókun.

Ní ìtara sí àwọn tí mo mọ̀ tìkalárami àti àwọn ẹbí wọn, mo ti yàn láti máa wá láti ríi àlàyé àwọn ìjàkadì wọn dájú tàbí láti sọ ti àwọn ẹ̀bun nla wọn ní gbangba. Síbẹ̀ ohun tí mo rí ti fún mi ní ìgbìyànjú ó sì yí mi padà sí rere.

Nínú ewu ti ìkọlù ìkọ̀kọ̀ rẹ̀, èmi yíò ṣàfikún ìjábọ̀ kúkúrú kan ti ìgbìyànjú ìyàwó mi. Mo ṣe bẹ́ẹ̀ ní ìfarabalẹ̀. Ó jẹ́ ènìyàn aládàní ti kìí wá tàbí kí ó mọyì ìyìn.

A ti ṣe ìgbéyàwó fún ọgọ́ta ọdún. Nítorí ìrírí yẹn ni mo ṣe lóye ìtumọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ inú Ìwé Mímọ́ wọ̀nyí báyìí: ìgbàgbọ́, ìrètí, ìwà tútù, ìfaradà, àìwá ti ara wa, yíyọ̀ nínú òtítọ́, láìrònú ibi, àti ju gbogbo rẹ̀ lọ, ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́.5 Lórí ìrírí náà, mo lè jẹ́ ẹ̀rí pé àwọn ẹ̀dá ènìyàn lè mú gbogbo àwọn èrò àgbàyanu wọnnì sínú ìgbé ayé ojojúmọ́ wọn bí wọ́n ṣe ń dìde nínú àwọn ìgbòkègbodò ìgbésí ayé.

Mílíọ̀nù yín tí ó nfetísílẹ̀ mọ irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀. Púpọ̀ nínú yín ni irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀. Gbogbo wa la nílò irú àpẹrẹ ìgbìyànjú bẹ́ẹ̀ àti àwọn ọ̀rẹ́ olùfẹ́ni.

Nígbàtí ẹ bá jókòó pẹ̀lú ẹnìkan gẹ́gẹ́ bí arábìnrin tàbí arákùnrin ojíṣẹ́ ìránṣẹ́ wọn, ẹ̀ nṣe aṣojú Olúwa. Ẹ ronú ohun ti Òun yìó ṣe tàbí sọ. Òun yìó pè wọ́n láti wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Òun yìó gbà wọ́n níyànjú. Òun yìó ṣàkíyèsí yìó sì yìn ìbẹ̀ẹ̀rẹ̀ ti àwọn ìyípadà tí wọn yìó nílò láti ṣe. Òun yìó sì jẹ́ àpẹrẹ pípé fún wọn láti ṣàfarawé.

Síbẹ̀síbẹ̀ kò sí ẹni tí ó lè ṣe èyí tán pátápátá, ṣùgbọ́n nípa fífetísílẹ̀ ní ìpàdè àpapọ̀ yí, ẹ lè mọ̀ pé ẹ wà ní ọ̀nà. Olùgbàlà mọ àwọn ìpènijà yín kíníkíní. O mọ ìlèṣe nlá yín láti dàgbà nínú ìgbàgbọ́, ìrètí, àti ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́.

Àwọn òfin àti májẹ̀mú tí Ó fún yín kìí ṣe àwọn ìdánwò láti ṣàkóso yín. Wọ́n jẹ́ ẹ̀bùn láti gbé yín sókè sí gbígba gbogbo àwọn ẹ̀bùn Ọlọrun àti láti padà sí ilé sọ́dọ̀ Baba Ọ̀run àti Olúwa, ẹni tí ó nífẹ̀ẹ́ yín.

Jésù Krístì San ìdíyelé fún Ẹ̀ṣẹ̀ Wa. A lè sọ pé ìbùkún ìyè àìnípẹ̀kun bí a bá ní ìgbàgbọ́ nínú Rẹ̀ tó láti ronúpìwàdà kí a sì dàbí ọmọdé, ní mímọ́ àti ṣíṣetán láti gba èyí tó tóbi jù lọ nínú gbogbo ẹ̀bùn Ọlọ́run.

Mo gbàdúrà pé ẹ ó gba ìpè rẹ̀ àti pé ẹ ó fi fún àwọn míràn ọmọ Baba wa Ọ̀run.

Mo gbàdúrà fún àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere wa káàkiri àgbáyé. Njẹ́ kí wọ́n ní ìmísí láti gba ẹnì kọ̀ọ̀kan níyànjú láti fẹ́ kí wọ́n sì gbàgbọ́ pé ìpè náà wá láti ọ̀dọ̀ Jésù Krístì nípasẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ Rẹ̀ tí wọ́n ti gba orúkọ Rẹ̀ lé orí ara wọn.

Mo jẹ́ríì pé Ó wà láàyè Ó sì ndarí Ìjọ Rẹ̀. Èmi ni ẹlẹ́rìí Rẹ. Ààrẹ Russell M. Nelson jẹ́ wòlíì Ọlọ́run alààyè fún gbogbo ayé. Mo mọ̀ pé èyí jẹ́ òtítọ́. Ní orúkọ mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín.