Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ìmúdúró àwọn Aláṣẹ Gbogbogbò, Àádọ́rin Agbègbè, àti Olóyè Gbogbogbò
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2022


Ìmúdúró àwọn Aláṣẹ Gbogbogbò, Àádọ́rin Agbègbè, àti Olóyè Gbogbogbò.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, bí a ti kede, nísisìyí èmi yíò gbé àwọn Aláṣẹ Gbogbogbò, àwọn Àádọ́rin Agbègbè, àti àwọn Olóyè Gbogbogbò Ìjọ kalẹ̀ fún ìbò ìmúdúró yín.

Ẹ jọ́wọ́ e fi àtìlẹhìn yín hàn bí ẹ ti nṣe níbikíbi tí ẹ lè wà. Bí a bá rí àwọn wọ̀nni tí wọń tako eyikeyi nínú àwọn àbá, a bèèrè pé kí ẹ kàn sí ààrẹ èèkàn yín.

A dalaba pé kí a ṣe ìmúdúró Russell Marion Nelson bí wòlíì, aríran, àti olùfihàn àti Ààrẹ Ìjọ Jésù Kristì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn; Dallin Harris Oaks bí Olùdámọ̀ràn Kínní; àti Henry Bennion Eyring bí Olùdámọ̀ràn Kejì nínú Àjọ Ààrẹ Ìkinní.

Àwọn wọnnì tó bá faramọ lè fihàn.

Àwọn wọnnì tó bá tàkòó, tí ẹnikẹ́ni bá wà, lè fihàn.

A dalaba pé kí a ṣe imúdúró Dallin H. Oaks bí Ààrẹ Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá àti M. Russell Ballard bí Aṣojú Ààrẹ Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá.

Àwọn to bá faramọ, jọ̀wọ́ ṣàpẹrẹ.

Alátakò kankan tó bá wa lè fihàn.

A dalaba pé kí a ṣe imúdúró àwọn wọ̀nyí bí ọmọ Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá: M. Russell Ballard, Jeffrey R. Holland, Dieter F. Uchtdorf, David A. Bednar, Quentin L. Cook, D. Todd Christofferson, Neil L. Andersen, Ronald A. Rasband, Gary E. Stevenson, Dale G. Renlund, Gerrit W. Gong, àti Ulisses Soares.

Àwọn tó bá faramọ, jọ̀wọ́ fihàn.

Alátakò kankan lè fihàn bẹ́ẹ̀.

A dalaba pé kí a ṣe ìmúdúró àwọn olùdámọ̀ràn nínú Àjọ Ààrẹ Ìkínní àti Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá bí àwọn wòlíì, aríran, àti olùfihàn.

Gbogbo ẹni tó bá faramọ, jọ̀wọ́ fihàn.

Ìlòdì, bí èyíkéyi bá wá, nípa irú àmì kannáà.

A ti dá àwọn Alàgbà Weatherford T. Clayton, LeGrand R. Curtis Jr., Randy D. Funk, Christoffel Golden, Walter F. González, Larry S. Kacher, Lynn G. Robbins, àti Joseph W. Sitati sílẹ̀ bí Aláṣẹ Gbogbogbò Àádọ́rin a sì fún wọn ní ipò ìfẹ̀hìntì.

Àwọn wọnnì tí wọ́n fẹ́ láti darapọ̀ mọ́ wa ní fífi ìmoore hàn sí àwọn arákùnrin wọ̀nyí àti ìyàwó wọn àti ẹbí wọn fún iṣẹ́-ìsìn ìfọkànsìn wọn lè ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ìnawọ́ sókè.

Bákannáà a kíyèsi pẹ̀lú ìdúpẹ́ àwọn Àádọ́rin Agbègbè tí wọ́n ti parí iṣẹ́-ìsìn wọn ní ọdún tí ó kọjá yí àti àwọn tí a lè rí orúkọ́ wọn ní newsroom.ChurchofJesusChrist.org.

Àwọn wọnnì tí wọ́n fẹ́ láti darapọ̀ mọ́ wa ní fífi ìmoore hàn sí àwọn arákùnrin wọ̀nyí fún iṣẹ́ ìsin títayọ lè fihàn.

A dá àbá pé kí a ṣe ìmúdúró àwọn Aláṣẹ Gbogbogbò àti àwọn Àádọ́rin Agbègbè míràn, pẹ̀lú àwọn Àádọ́rin Agbègbè titun mẹfà tí a kéde ṣíwájú ní ọ̀sẹ̀ yí ní newsroom.ChurchofJesusChrist.org, àti àwọn Olóyè Gbogbogbò bí a ti gbé wọn kalẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́.

Gbogbo ẹni tó bá faramọ lè ṣe bẹ́ẹ̀ nípa nínawọ́ sọ́kè.

Àwọn alátakò, to báwa.

A dúpẹ́ lọ́wọ́ yín, ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin fún ìtẹ̀síwájú ìgbàgbọ́ yín àti àdúrà ní ìtìlẹhìn àwọn olórí Ìjọ.

Àwọn Ìyípadà sí Àwọn Àádọ́rin Agbègbè

Àwọn Àádọ́rin Agbègbè wọ̀nyí ni a ṣe ìmúdúró fún nínú abala àwọn olórí kan tí a ṣe bí ara ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò:

Ricardo J. Battista, Willy Binene, Bernhard Cziesla, Nathan R. Emery, Sione Tuione, Yves S. Weidmann.

Àwọn Àádọ́rin Agbègbè wọ̀nyí ni a dásílẹ̀ ní Ọjọ́ Kínní Oṣù Kẹ́jọ, 2021:

Luis R. Arbizú, Michael V. Beheshti, David A. Benalcázar, Berne S. Broadbent, Kevin E. Calderwood, Luciano Cascardi, Ting Tsung Chang, Ariel E. Chaparro, Pablo H. Chavez, Raymond A. Cutler, José L. Del Guerso, Alessandro Dini Ciacci, Carlos R. Fusco Jr., Jorge A. García, Gary F. Gessel, Karl D. Hirst, Ren S. Johnson, Jay B. Jones, Paul N. Lekias, Artur J. Miranda, Elie K. Monga, A. Fabio Moscoso, Yutaka Nagatomo, Juan C. Pozo, Anthony Quaisie, Martin C. Rios, Sandino Roman, Johnny F. Ruiz, Rosendo Santos, Gordon H. Smith, K. Roy Tunnicliffe.

Alàgbà Levi W. Heath àti Elder ‘Inoke F. Kupu, tí wọ́n nsìn bi Àádọ́rin agbegbè, ti kú ní 2022.