Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
A Lè Ṣe Àwọn Ohun Líle Nípasẹ̀ Rẹ̀
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2022


A Lè Ṣe Àwọn Ohun Líle Nípasẹ̀ Rẹ̀

Mo jẹ́ ẹ̀rí pé a dàgbà nínú jíjẹ́-ọmọlẹ̀hìn wa nígbàtí a lò ìgbàgbọ́ nínú Olúwa ní àwọn ìgbà ìṣòrò.

Ní ìgbà iṣẹ́ ìránṣẹ́ ti-ayé Olùgbàlà, Ó ṣe àkíyèsí ọkùnrin kan tí ó fọ́ lójú. Àwọn ọmọẹ̀hìn Jésù bií léèrè wípé, “Olùkọ́ni, tani dẹ́ṣẹ̀, ọkùnrin yí, tàbí àwọn òbí rẹ̀, tí a fi bi ní afọ́jú?

Ìdáhún gbọingbọin, ìfẹ́ni, àti òdodo ti Olùgbàlà fi dá wa lójú pé Òun nífura àwọn ìlàkákà wa: “Kìí ṣe nítorítí ọkùnrin yí dẹ́ṣẹ̀, tàbí àwọn òbí rẹ̀: ṣùgbọ́n kí a lè fi iṣẹ́ Ọlọ́run hàn lára rẹ̀.”1

Nígbàtí àwọn ìpènijà kan lè wá nítorí àìgbọ́ran ṣíṣetinúẹni, a mọ̀ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìpènijà ti ayé nwá nítorí àwọn èrèdí míràn. Eyikeyi orísun àwọn ìpènijà wa, wọ́n lè jẹ́ ànfàní iyebíye kan láti dàgbà.

A kò dá ẹbí wa sí nínú àwọn ìpọ́njú ayé. Ní dídágbà sóké, mo nifẹsi àwọn ẹbí títóbi. Irú àwọn ẹbí bẹ́ẹ̀ máà ndàbí bíbójúmu sí mi, nípàtàkì nígbàtí mo bá Ìjọ pàdé ní ìgba-èwè mi nípasẹ̀ arákùnrin mi àgbà ní apá-ìyá mi, Sarfo, àti ìyàwó rẹ̀ ní Takoradi, Ghana.

Nígbàtí Hannah àti èmi ṣe ìgbeyàwó, a nifẹ láti ṣe ìmúṣẹ àwọn ìbùkún ti-bàbánlá wa, èyí tí ó fihàn pé a ò di alábùkún pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ. Bàkannáà, ṣíwájú ìbí ọmọkùnrin wa ìkẹ́ta, ó hàn kedere níti-ìlera pé Hannah kò ní lè bí ọmọ míràn. Pẹ̀lú ìmoore, bí ó tilẹ̀ jẹpé a bí Kenneth nínú ipò èwu-ìyè sí òun àti ìyá rẹ̀ méjèèjì, ó dé láìléwu, ara ìyá rẹ̀ sì yá. Òun sì bẹ̀rẹ̀ láti kópa ní kíkún nínú ìgbé-ayé ẹbí wa—pẹ̀lú lílọ sí ilé ìjọsìn, àwọn àdúrà ẹbí ojojúmọ́, àṣàrò ìwé-mímọ́, ilé ìrọ̀lẹ́, àti àwọn ṣíṣe ìdárayá alárinrin.

Àwòrán
Ọmọkùnrin Alàgbà Morrison

Bíótilẹ̀jẹ́pé a níláti tún ìrètí ti ẹbí wa títóbi ṣe, ó jẹ́ ayọ̀ láti fi àwọn ìkọ́ni látinú, “Ẹbí Náà: Ìkéde sí Àgbáyé” sí ìṣe pẹ̀lú àwọn àyànfẹ́ ọmọ wa mẹ́ta. Títẹ̀lé àwọn ìkọ́ni wọnnì fi ìtumọ̀ púpọ̀ kún dídàgbà ìgbàgbọ́ mi.

Bí ìkéde ti sọ: “Ìgbeyàwó ní àárín ọkùnrin àti obìnrin ṣe pàtàkì sí ètò ayérayé Rẹ̀. Àwọn ọmọ ní ẹ̀tọ́ sí ìbí nínú ìsopọ̀ ìgbeyàwó, àti láti di títọ́jú ní ọwọ́ baba àti ìyá tí wọ́n bọ̀wọ̀ fún àwọn ẹ̀jẹ́ ìgbeyàwó pẹ̀lú ìwà-mímọ́ pípé.”2 Bí a ti nfi àwọn ẹ̀kọ́-ìpìlẹ̀ wọ̀nyí sínú ìṣe, à ndi alábùkún.

Bákannáà, ní òpin ọ̀sẹ̀ kan nínú iṣẹ́-ìsìn mi bí ààrẹ èèkàn, a ní ìrírí àdánwò bóyá tí ó burújùlọ tí àwọn òbí lè dojúkọ. Ẹbí wa padàdé láti ṣiṣe Ìjọ kan a sì kórajọ fún oúnjẹ-ọ̀sàn. Lẹ́hìnnáà àwọn ọmọkùnrin wa mẹ́ta jáde lọ ṣeré nínú àgbo-ilé wa.

Ìyàwó mi nímọ̀lára ìtẹ̀mọ́ra léraléra pé àṣìṣe ohunkan lè wà. Ó ní kí èmi lọ wo àwọn ọmọ nígbàtí a nfọ àwọn àwò. Mo ní ìmọ̀lára pé wọ́n wà láìléwu nítorì a lè gbọ́ àwọn ohùn ìdùnnú láti ibi iṣeré wọn.

Nígbàtí a jíjọ lọ wo àwọn ọmọkùnrin wa, sí ìyanu wa, a rí Kenneth kékeré ọmọ oṣù méjìdínlógún láìlèmíra nínú bọ́kẹ́tì omi, tí àwọn arákùnrin rẹ̀ kò ri. A sáré gbe lọ sí ilé-ìwòsàn, ṣùgbọ́n gbogbo ìgbìyànjú láti ji já sí pàbó.

Inú wa bàjẹ́ pé a kò ní ní ànfàní láti tọ́jú ọmọ iyebíye wa nínú ayé ikú yí. Bíótilẹ̀jẹ́pé a mọ pé Kenneth yíò jẹ́ ara ẹbí ayérayé wa, mo rí arami ní bíbèèrè ìdí tí Ọlọ́run yíò fi jẹ́ kí àjálù yí ṣẹlẹ̀ nígbàtí mò nṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe láti gbe ìpè mi ga. Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ dé ilé láti ibí mímú ọkàn lára àwọn ojúṣe mi ṣẹ ní ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí àwọn Ènìyàn Mímọ́ ni. Kínìdí tí Ọlọ́run kò fi wo iṣẹ́ ìsìn mi kí ó sì gba ọmọkùnrin wa là àti ẹbí wa kùrò nínú àjálù yí? Bí mo ti nronú síi nípa rẹ̀, ni mò nní ìkorò síi.

Ìyàwó mi kò dá mi lẹ́bi rí fún àìlèfèsì sí àwọn ìṣílétí rẹ̀, ṣùgbọ́n mo kọ́ ẹ̀kọ́ ìyípadà-ìgbé ayé kan mo sì ṣe àwọn òfin méjì, tí nkò gbọ́dọ̀ já láéláé.

Òfin 1: Ẹ fetísílẹ̀ sí kí ó sì gbọ́ àwọn ìṣílétí ìyàwó yín.

Òfin 2: Bí kò bá dáa yín lójú fún èrèdí kankan, ẹ tọ́ka sí òfin nọ́mbà 1.

Bíótilẹ̀jẹ́pé ìrírí náà jẹ́ wíwọnilára, tí a sì tẹ̀síwájú láti ṣọ̀fọ̀, àjàgà bíbonimọ́lẹ̀ wa ní ó rọrùn nígbẹ̀hìn.3 Ìyàwó mi àti èmi kọ́ àwọn kókó ẹ̀kọ́ látinú àdánù wa. A wá ní ìmọ́lára ìrẹ́pọ̀ àti ìsopọ̀ nípa àwọn májẹ̀mú tẹ́mpìlì wa; a mọ̀ pé a lè gba Kenneth bíi tiwa nínú ayé tí ó nbọ̀ nítorí òun ni a bí sínú májẹ̀mú. Bákannáà a jèrè ìrírí tó ṣeéṣe láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí àwọn ẹlòmíràn àti láti kaanu pẹ̀lú ìrora wọn. Mo jẹ́ ẹ̀rí pé ìkorò wa ti kúrò làtigbànáà bí a ṣe nlo ìgbàgbọ́ nínú Olúwa. Ìrírí wa tẹ̀síwájú láti jẹ́ líle, ṣúgbọ́n a ti kẹkọ pẹ̀lú Àpóstélì Páùlù pé a “lè ṣe ohun gbogbo nípasẹ̀ Krístì èyí tí ó [nfún wa lókun]” bí a bá dojúkọ Ọ́.4

Ààrẹ Russell M. Nelson kọ́ni pé “Nígbàtí ìdojúkọ ti ìgbé ayé wa bá wà lórí ètò ìgbàlà Ọlọ́run … àti Jésù Krístì àti ìhìnrere Rẹ, a lè ní ayọ̀ láìkà ohun tó nṣẹlẹ̀ sí—tàbí tí kò ṣẹlẹ̀—nínú ìgbé ayé wa. Ó tẹ̀siwájú sí wípé, “Ayọ̀ nwá láti àti nítorí Rẹ̀.”5

A lè tújúká kí a sì kún fún àláfíà ní àwọn ìgbà ìnira wa. Ìfẹ́ tí a ní ìmọ̀lára nítorí Olùgbàlà àti Ètùtù Rẹ̀ ndi ohun-èlò alágbára fún wa ní àwọn àkokò ìgbìyànjú wa. “Gbogbo ohun tí kò dára nípa ìgbé-ayé ni a lè mú yẹ nípasẹ̀ Ètùtù Jésù Krístì.”6 Ó pàṣẹ pé, “Nínú ayé ẹ̀yin ó ní ìpọ́njú: ṣùgbọ́n ẹ tújúká; mo ti ṣẹ́gun ayé.”7 Òun lè ràn wá lọ́wọ́ láti ní ìfaradà eyíkeyi ìrora, àìsàn, àti àwọn àdánwò tí a dojúkọ nínú ayé ikú.

A rí àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìtàn ti-ìwé mímọ́ nípa àwọn olórí nlá àti akọni, bí i Jeremiah, Job, Joseph Smith, àti Néfì, àwọn ẹni tí a kò dá sí kúrò nínú àwọn ìlàkàkà àti ìpènijà ti ayé ikú. Wọ́n jẹ́ ara-ikú tí wọ́n kọ́ láti gbọ́ràn sí Olúwa nínú àwọn ipò líle.8

Ní ìgbà àwọn ọjọ́ olóró Ẹ̀wọ̀n Liberty, Joseph Smith kígbe jáde: “Ah Ọlọ́run, níbo ni ìwọ wà? Àti pé níbo ni àgọ́ ti o bo ibi ìpamọ́ rẹ?”9 Olúwa kọ́ Joseph láti “forítì í dáradára”10 ó sì ṣe ìlérí pé tí ó bá ṣe é, gbogbo ohun wọ̀nyí yíò fún ní ìrírí yíò sì jẹ́ fún ire rẹ̀.11

Ríronú lórí àwọn ìrírí ti ara mi, mo damọ̀ mo sì ti kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ dídárajùlọ mi ní àwọn ìgbà lílejùlọ, àwọn ìgbà tí ó mú mi jáde nínú ibi ìtura mi. Àwọn ìṣòrò tí mo bá pàdé gẹ́gẹ́bí ọ̀dọ́ kan, nígbàtí mò nkọ́ nípa Ìjọ nípasẹ̀ ìdánilẹ́kọ́, bí olùyípadà-ọkàn àìpẹ́, àti bí ìránṣẹ́-ìhìnrere ìgbà-kíkún àti àwọn ìpènijà tí mo dojúkọ nínú ikẹkọ mi, ní títiraka láti gbé àwọn ìpè mi ga, àti ní títọ́ ẹbí kan ti múra mi sílẹ̀ fún ọjọ́ ọ̀là. Bí mo tí nfi títúraká fèsì sí àwọn ipò líle síi pẹ̀lú ìgbàgbọ́ nínú Olúwa, bẹ́ẹ̀ ni mó ndàgbà síi ní jíjẹ́ ọmọlẹ̀hìn.

Àwọn ohun líle nínú ayé wa kò níláti wá bí ìyàlẹ́nú níwọ̀n bí a bá ti wọnú ọ̀nà híhá ati tóóró.12 Jésù Krístì kọ́ “ìgbọràn nípa àwọn ohun èyí tí ó ti jìyà.”13 Bí a ti ntẹ̀lé É, nípàtàkì ní àwọn ìgbà ìṣòrò, a lè dàgbà láti dà bíi Rẹ̀ síi.

Ọ̀kan lára àwọn májẹ̀mú tí a dá pẹ̀lú Olúwa nínú tẹ́mpílì ni láti gbé ìgbé òfin ìrúbọ. Ìrúbọ ti jẹ́ ara ìhìnrere ti Jésù Krístì nígbágbogbo. Ó jẹ́ ìrántí kan nípa ìrúbọ ètùtù nlá ti Jésù Krístì fún gbogbo ẹni tí ó ti gbé tàbí tí yíò gbé ní orí ilẹ̀ ayé.

Àwòrán
Ọmọkùnrin Alàgbà Morrison

Mo mọ̀ pé Olúwa nsan-ẹ̀san àwọn ìfẹ́ òdodo wa nígbàgbogbo. Ẹ Rántí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ tí a ṣe ìlérí fún mi nínú ìbùkún ti-babanlá mi? Ìbùkún náà ni à nmú ṣẹ. Ìyàwó mi àti èmi sìn pẹ̀lú àwọn onírurú ọgọ́ọ̀rún ìránṣẹ́-ìhìnrere, láti àwọn orílẹ̀-èdè tí ó pọ̀ju mẹẹdọgbọn, ní Míṣọ̀n Ghana Cape Coast. Wọ́n ṣọ̀wọ́n sí wá bíì pé wọ́n jẹ́ àwọn ọmọ arawa gan an.

Mo jẹ́ ẹ̀rí pé a dàgbà nínú jíjẹ́-ọmọlẹ̀hìn wa nígbàtí a lò ìgbàgbọ́ nínú Olúwa ní àwọn ìgbà ìṣòrò. Bí a ti nṣe bẹ́ẹ̀, Òun yíò fi àánú fún wa ní okun yíò sì rànwá lọ́wọ́ láti gbé àwọn ẹrù wa. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.