Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Sísúnmọ́ Olùgbàlà Síi
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2022


Sísúnmọ́ Olùgbàlà Síi

Ní wíwá áti mọ̀ àti láti nifẹ Olùgbàlà, à ya arawa sọ́tọ̀ kúrò nínú ayé nípasẹ̀ àwọn májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run, nípa jíjẹ́ títayọ, àìwọ́pọ̀, àti nípàtàkì bí a ti nbu ọlá fún Un àti àwọn ìkọ́ni Rẹ̀, láìsí pípa arawa tì kúrò lọ́dọ̀ àwọn míràn nínú ayé tí wọ́n gbàgbọ́ lọ́tọ̀ọ̀tọ̀.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, ní ìrọ̀lẹ́ yí mo nṣọ́rọ́ sí àwọn àtẹ̀lé onírẹ̀lẹ̀ àti olùfọkànsìn Jésù Krístì. Bí mo ti nrí ìwàrere ìgbé ayé yín àti ìgbàgbọ́ yín nínú Olúwa Jésù Krístì nihin ní orílẹ̀-èdè yí àti ní orílẹ̀-èdè káàkiri ayé, mo nifẹ gbogbo yín síi.

Ní òpin iṣẹ́ ìránṣẹ́ Rẹ̀, àwọn ọmọ-ẹ̀hìn Jésù ní kí Ó wí fún wọn nípa “àmì ti bíbọ̀ [Rẹ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì], àti ti òpin ayé.”1

Jésù wí fún wọn nípa àwọn ipò tí yíò ṣíwájú ìpadàbọ̀ Rẹ̀ àti píparí nípa kíkéde pé “Nígbàtí ẹ ó rí gbogbo àwọn ohun wọ̀nyí, [ẹ yío] mọ̀ pé [àkókò náà] nsúnmọ́.”2

Nínú ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò, mo fetísílẹ̀ típẹ́típẹ́ sí àwọn ọ̀rọ̀ Ààrẹ Henry B. Eyring: “Ẹnìkọ̀ọ̀kan lára wa,” ni ó wí “nibikíbi tí a wà, ẹ mọ̀ pé à ngbé nínú ìgbà àwọn ewu púpọ̀si. … Ẹnikẹ́ni pẹ̀lú ojú láti rí àwọn àmì àkokò àti etí láti gbọ́ ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì mọ̀ pé òtítọ́ ni.”3

Olùgbàlà gbóríyìn fún àwọn akọni ọmọ-ẹ̀hìn Rẹ̀: “Alábùkúnfún ni ojú yín, nítorí wọn ó rí: àti etí yín, nítorí wọn ó gbọ́.”4 Njẹ́ kí ìbùkún yí jẹ́ tiwa bí a ti nfetísílẹ̀ tímọ́tímọ́ sí àwọn ọ̀rọ̀ Olúwa nípasẹ̀ àwọn wòlíì Rẹ̀ nínú ìpàdé àpapọ̀ yí.

Àlìkámá àti Èpò

Olúwa ṣe àlàyé pé ní òpin àkokò yí ṣíwájú ìpadàbọ̀ Rẹ̀, “álìkámọ̀ náà,” tí Ó júwe bí “àwọn ọmọ ìjọba,”5 yíò dàgbà ní ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú “èpò náà,” tàbí àwọn wọnnì tí wọn kò nifẹ Ọlọ́run àti tí wọn kò pa àwọn òfin Rẹ mọ́. Àwọn méjèjì “yíò ó dàgbà papọ̀”6 ní ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́.

Èyí ni ayé wa títí ìpadàbọ̀ Olùgbàlà, pẹ̀lú ọ̀pọ̀ tí ó dára púpọ̀ tí ó sì jẹ́ ibi ní gbogbo ibi.7

Nígbà míràn ẹ lè má ní ìmọ̀lára bíi ẹyọ pòpórò àlìkámà tó lágbára, gbígbó kan. Ẹ ní sùúrù pẹ̀lú arayín! Olúwa wípé àlìkámà náà yío ní àwọn èhù tuntun tí ó nyọ jáde nínú.8 Àwa ni àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, àti bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kìí ṣe gbogbo ẹni ni ó fẹ́ láti jẹ́ bẹ́ẹ̀, a ní ìfẹ́ wa pàtàkì láti jẹ́ ọmọ-ẹ̀hìn Rẹ̀ nítòótọ́.

Fún Ìgbàgbọ́ Wa Nínú Jésù Krístì Lókun

A damọ̀ pé bí ibi ti npọ̀ si ní ayé, wíwàláàyè ti ẹ̀mí wa, àti wíwàláàyè ti ẹ̀mí àwọn wọnnì tí a nifẹ, yíò gbà pé kí a ṣìkẹ́ ní kíkún, múle, kí a sì fi okun fún ìfẹsẹ̀múlẹ̀ wa nípa ìgbàgbọ́ wa nínú Jésù Krístì. Àpóstélì Páùlù gbà wá lámọ̀ràn láti ní ìfẹsẹ̀múlẹ̀,8 jíjinlẹ̀, àti tí a fìkalẹ̀9 sínú ìfẹ́ wa fún Olùgbàlà àti ìpinnu wa láti tẹ̀lé E. Òní àti ní àwọn ọjọ́ iwájú gba ìdojukọ si àti ìtẹ̀mọ́ ìtiraka, tí ntọ́ni ní yíyàká àtàkò, àìbìkítà, àti àìkọbiarasí.10

Ṣùgbọ́n àní pẹ̀lú okun ti ayé tí ó npọ̀ si ní àyíká wa, a kò níláti bẹ̀rù. Olúwa kò ni fi àwọn ènìyàn májẹ̀mú Rẹ̀ sílẹ̀ láéláé. Agbára ẹ̀san kan wà nípa àwọn ẹ̀bùn ti ẹ̀mí àti ìdarí tọ̀run fún òdodo.11 Àfikún ìbùkún agbára ti ẹ̀mí yí, bákannáà, kò fidímúlẹ̀ sòrí wa lásán nítorí a jẹ́ ara ìran yí. Ó nwá bí a ti lè fún ìgbàgbọ́ wa nínú Olúwa Jésù Krístì lókun kí a sì pa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́, bí a ti nwá láti mọ̀ Ọ́ kí a sì ní ìfẹ́ Rẹ̀. “Ìyè àìnípẹ̀kun ni èyí,” Jésù gbàdúrà, “kí wọn kí ó lè mọ̀ ọ, ìwọ nìkan Ọlọ́run òtítọ́, àti Jésù Krístì, ẹnití ìwọ rán.”4

Jíjẹ́ ọmọ-ẹ̀hìn Jésù Krístì tòótọ́ àti níní ìgbàgbọ́ nínú Rẹ̀ si ju ìpinnu ìgbà-kan—ó ju ìṣẹ̀lẹ̀ igbà-kan lọ. Ó jẹ́ ètò mímọ́, ti mímúdàgbà àti mímú gbòòrò nípasẹ̀ àwọn àkokò ti ìgbé ayé wa, títẹ̀síwájú títí a ó fi kúnlẹ̀ ní ẹsẹ̀ Rẹ̀.

Bí àlìkámà tí ó ndàgbà ní àárín àwọn èpò nínú ayé, báwo ni a ó ti mú ìfarasìn wa jinlẹ̀ àti níní okun sí Olùgbàlà nínú àwọn ọjọ́ iwájú?

Nihin ni àwọn èrò mẹ́ta:

Kí A Ri Arawa Sínú Ìgbé Ayé ti Jésù

Àkọ́kọ́, a lè ri arawa sínú ayé ti Jésù síi pátápátá, sí ẹ̀kọ́ Rẹ̀, sí ọlánlá Rẹ̀, sí agbára Rẹ̀, àti sí ìrúbọ ètùtù Rẹ̀. Olùgbàlà wípé, “Wo mí nínú gbogbo èrò.”10 Jòhánnù wípé, “A nifẹ rẹ̀, nítorí ó kọ́ nifẹ wa.”14 Bí a ti nní ìrírí òfẹ́ Rẹ̀ dídára si, a nní ìfẹ́ Rẹ̀ àní pùpọ̀ si, pẹ̀lú ádánidá gidi, ní títẹ̀lé àpẹrẹ Krísti dáadáa síi nípa fífẹ́ni àti títọ́jú fún àwọn wọnnnì nínú àìní. Pẹ̀lú gbogbo rínrìn òdodo síwájú Rẹ̀, à nríi I kedere síi.16 A yìn Ín, a sì ngbìyànjú nínú àwọn ọ̀nà kékeré wa láti ṣe bíi Tirẹ̀.15

Dá Àwọn Májẹ̀mú Pẹ̀lú Olúwa

Títẹ̀le, bí a ti nmọ̀ tí a sì nní ìfẹ́ Olùgbàlà dáradára, àní à nfẹ́ si láti ṣèlérí ìtúbá àti ìgbẹ́kẹ̀lé wa fún Un. À ndá àwọn májẹ̀mú pẹ̀lú Rẹ̀. A bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìlérí wa níbi ìrìbọmi, a si fi ẹsẹ̀ àwọn ìlérí wọ̀nyí àti àwọn míràn múlẹ̀ ní ojojúmọ́ bí a ti nronúpìwàdà, bèèrè fún ìdáríjì, kí a sì fi ìwára gbèrò gbígba oúnjẹ Olúwa ní ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀. A jẹjẹ láti “rántí rẹ̀ nígbàgbogbo kí a sì pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́.”16

Nígbàtí a bá ṣetán, a ó gba àwọn ìlànà àti majẹ̀mú tẹ́mpìlì mọ́ra. Níní ìmọ̀lára agbára àìlòpin nínú àwọn àkokò jẹ́jẹ́, mímọ́ nínú ilé Olúwa, à nfi pẹ̀lú ìdùnnú dá májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run a sì nfi okun fún ìpinnu wa láti pa wọ́n mọ́.

Dídá àti pípa àwọn májẹ̀mú mọ́ nfi ààyè gbà ìfẹ́ Olùgbàlà láti wọnú ọkàn wa jinlẹ̀ si. Nínú oṣù yí LiahonaÀàrẹ Nelson wípé: “ (Àwọn) májẹ̀mú [wa] yíì ndarí wa súnmọ́ àti súnmọ́ Ọ si. … Ọlọ́run kò ní pa ìbáṣepọ̀ Rẹ̀ tì pẹ̀lú àwọn tí wọ́n ti fi irú ìsopọ̀ kan bẹ́ẹ̀ múlẹ̀ pẹ̀lú Rẹ̀.”17 Àti bí Ààrẹ Nelson ti fi pẹ̀lú ìrẹwà ṣe ìlérí, “Pẹ̀lú ìyàsímímọ tẹ́mpìlì titun kọ̀ọ̀kan, àníkún agbára ti ọ̀run nwá sínú ayé láti fún wa lókun kí a sì takò títẹramọ́ ìtiraka ọ̀tá.”20

Ṣe a lè rí ìdí tí Olúwa fi ndárí wòlíì Rẹ̀ láti mú àwọn ilé Olúwa súnmọ́ wa àti láti gbà wá láàyè láti wà ní ilé Rẹ̀ léraléra si?

Bí a ti nwọ ilé Olúwa, à ndi òmìnira kúrò nínu agbára ti ayé tí ó ntako wá mọ́lẹ̀, bí a ti nkọ́ nípa èrèdí wa nínú ayé àti àwọn ẹ̀bùn ayérayé tí a fún wa nípasẹ̀ Olùgbàlà wa, Jésù Krístì.

Dá Ààbò Bo Ẹ̀bùn ti Ẹ̀mí Mímọ́

Ní ìgbẹ̀hìn, èrò kẹ́ta mi: nínú ìwákiri mímọ́ yí, a ní ìṣura, ààbò, ìgbèjà, àti pípa ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́ mọ́ pẹ̀lú gbogbo ọkàn wa. Ààrẹ M. Russell Ballard ṣíwájú àti Alàgbà Kevin W. Pearson láìpẹ́ ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa ìkìlọ̀ ti wòlíì Ààrẹ Nelson tí èmi o´ túnsọ lẹ́ẹ̀kansi: “Kò ní ṣeéṣe láti yè níti ẹ`mí láìsí títọ́nisọ́nà, dídarí, títuni-nínú, àti agbára lemọ́lemọ́ ti Ẹ̀mí Mímọ́.”21 Ó jẹ́ ẹ̀bùn oye. À nsa ipá wa láti dá ààbò bo àwọn ìrírí ojojúmọ́ kí agbára Ẹmí Mímọ́ lè dúró pẹ̀lú wa. Àwà ni ìmọ́lẹ̀ ayé, àti pé nígbà tí ó bá yẹ, à nfi ìfẹ́ yàn láti yàtọ̀ sí àwọn ẹlòmíràn. Ààrẹ Dallin H. Oaks ní àìpẹ́ bèèrè lọ́wọ́ àwọn ọ̀dọ́ àgbà àdánìkan wa: “Ṣe [ẹ̀] ‘nwá láti di yíyàtọ̀? … [Nípàtàkì] àwọn àṣàyàn pàtàkì tí ẹ̀ nṣe nínú ìgbé ayé araẹni yín. … Ṣe ẹ̀ nlọ síwájú ní àtakò sí ìlòdì ti ayé”22

Ẹ Yan láti Jẹ́ Yíyàtọ̀ kúrò nínú Ayé

Nínú àlẹ̀mọ́ ìbákẹ́gbẹ́ ìròhìn àìpẹ́, mo bèèrè lọ́wọ́ akẹ́gbẹ́ àwọn ọmọ-ẹ̀hìn láti pín àwọn àṣàyàn tí wọ́n ti ṣe tí ó gba kí wọ́n yàtọ̀ kúrò nínú ayé. Mo gba àwọn ìdáhùn ọgọọgọ́rùn.20 Nihin ni àwọn díẹ̀:

Amanda: Nọ́ọ̀sì tí ó nṣe iṣẹ́ nínú ẹ̀wọ̀n ìbílẹ̀ ni mí. Mò ngbìyànjú láti tọ́jú àwọn ẹlẹ́wọ̀n bíi Krístì yíò ti ṣe.

Rachel: Èmi jẹ́ akọrin ópérà, a sì máa nfojúdimí nígbàkugbà pé èmi máa wọ aṣọ eyikeyi tí wọ́n fún mi, ní àìka ìwọ̀ntúnwọ̀nsì sí. [Nítorí mo ti gba ẹ̀bun tẹ́mpìlì,] mo wí fún [àwọn olùgbéjáde] pé aṣọ náà yíò nílò láti jẹ́ [ìwọ̀ntúnwọ̀sì]. Inú wọn kò dùn … ṣùgbọ́n wọ́n fi ìlọ́ra ṣe àtúnṣe. Èmi kò ní ta àláfíà tí ó nwá látinú dídúró bí ẹlẹri ti Krístì ní gbogbo ìgbà.

Chriss: Ọ̀mùtín ni mí (mo wà nínú imúpadà), yíyẹ tẹ́mpìlì, ọmọ Ìjọ. Èmi ko dákẹ́ nípa àwọn ìrírí mi pẹ̀lú ìwa bánbákú àti jíjèrè ẹ̀rí kan nípa Ètùtù [ti Jésù Krístì].

Lauren: Mo nṣiṣẹ́ lórí kíkọ síkítì pẹ̀lú akẹ́gbẹ́ kílásì mi ní ilé-ìwé gíga. Wọ́n nfẹ́ láti pa mí lẹ́nu mọ́, ìwà pípamọ́ ní ìtújáde ẹ̀sẹ̀kẹsẹ̀ ti àìmọ́. Wọ́n tẹramọ́ títẹ̀ mí mọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n mo kọ mo sì dira mi mú.

Adam: Àwọn ènìyàn púpọ̀ kò gbà mí gbọ́ nígbà tí mo wípé èmi yíò pa òfin ìmáradúró mọ́ kí nsì yàn láti máradúró kúrò nínú ponógíráfì. Wọn kò ní ìmọ̀ ire ti ayọ̀ àti àláfíà inú tí ó nfi fún mi.

Ella: Baba mi ni ọmọ ẹgbẹ́ ìletò ti LGBTQ. Mo máa ngbìyànjú láti pa ìmọ̀lára àwọn ènìyàn míràn mọ́ nínú ìrònú nígbàtí mo bá ndúró bí ẹlẹri Krístì àti jíjẹ́ olóòtítọ́ sí ohun tí mo gbàgbọ́.

Andrade: Mo pinnu láti tẹ̀síwájú láti lọ ilé ìjọsìn nígbàtí ẹbí mi pinnu pe wọn kò ní lọ mọ́.

Àti ní òpin, látọ̀dọ̀ Sherry: À nlọ síbi ìṣẹ̀lẹ̀ ní ibùgbé gómìnà. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí nmú ọtí lílé jádé láti fún “ìkíni.” Mo tẹnumọ omi, bíótilẹ̀jẹ́pé òṣìṣẹ́ wípé yíò di ẹ̀bi. A ṣe ìkíni gómìnà, mo sì di gílásì omi mi mú sókè! Gómìnà kò kàá sí ẹ̀bi.

Ààrẹ Nelson wípé, “Bẹ́ẹ̀ni, ẹ̀ ngbé inú ayé, ṣùgbọ́n ẹ ni òṣùwọ̀n tí ó yàtọ̀ nínú ayé láti ràn yín lọ́wọ́ láti yẹra fún àbàwọ́n ti ayé.”24

Anastasia, ìyá ọ̀dọ́ kan ní Ukraine tí ó wà ní ilé ìwòsàn tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ bímọ ọwọ́ ọkùnrin bí bọ́mbù bíbú ṣe bẹ̀rẹ̀ ní Kyiv ní Oṣù Kejì tó kọjá. Nọ́ọ̀sì kan ṣí ilẹ̀kùn yàrá ilé ìwòsàn ó sì wí pẹ̀lú ohun kánkán pé, “Gbé ọmọ ọwọ́ rẹ, yi mọ́ aṣọ òtútù, kí ó sì lọ sí gbàgede—nísisìyí!”

Lẹ́hìnnáà, Anastasia sọ̀rọ̀:

“Èmi kò le ro pé ọjọ́ ìkínní mi bí abiyamọ yíò le bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n èmi ndojúkọ àwọn ìbùkún àti iṣẹ́ ìyanu tí mo ti rí.

“Nísisìyí bayi, ó lè dàbí àìṣeéṣe láti dáríji àwọn wọnnì tí wọ́n ti fa irú ìparun àti ìpalára púpọ̀ bẹ́ẹ̀ láé … , ṣùgbọ́n bíi ọmọ-ẹ̀hìn Krístì, mo ní ìgbàgbọ́ pé èmi ó le [dáríji]. …

“Èmì kò mọ gbogbo ohun tí yíò ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ ọ̀la, ṣùgbọ́n mo mọ̀ pé pípa àwọn májẹ̀mú wa mọ́ yíò fi àyè gba Ẹ̀mí láti wà pẹ̀lú wa nígbàgbogbo, … ó nfí ààyè gbà wá láti nímọ̀lára ayọ̀ àti ìrètí, … àní ní ìgbà iṣòro.”21

Ìlérí Ìyè Ayérayé àti Ògò Sẹ̀lẹ́stíà

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, mo ti di alábùkún láti gba ọ̀pọ̀ ìfẹ́ ti àyànfẹ́ Olùgbàlà wa, Jésù Krístì. Mo mọ̀ pé Ó wà láàyè Ó sì ntọ́ iṣẹ́ mímọ́ Rẹ̀ sọ́nà. Èmi kò ní àwọn ọ̀rọ̀ kíkún tó láti fi ìfẹ́ mi hàn sí I.

Gbogbo wa ni “àwọn ọmọ májẹ̀mú” nínà káàkiri ilẹ̀ aye ní àwọn orílẹ̀ ayé àti àwọn ọ̀làjú ní gbogbo ayé, ní iye àwọn míllíọ́nù, bí a ṣe ndúró de ìpadàbọ̀ ológo ti Olúwa àti Olùgbàlà. Títàn bí ìmọ́lẹ̀ sí àwọn wọnnì ní àyíká wa, à nfi ìfura tún ìfẹ́, èrò, àṣàyàn, àti ìṣe wa. Wíwá pẹ̀lú gbogbo ọkàn wa láti mọ̀ àti láti nifẹ Olùgbàlà, à ya arawa sọ́tọ̀ kúrò nínú ayé nípasẹ̀ àwọn májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run, nípa jíjẹ́ títayọ, àìwọ́pọ̀, àti pàtàkì bí a ti nbu ọlá fún Un àti àwọn ìkọ́ni Rẹ̀, láìsí pípa arawa tì kúrò lọ́dọ̀ àwọn míràn nínú ayé tí wọ́n gbàgbọ́ lọ́tọ̀ọ̀tọ̀.

Ó jẹ́ ìrìnàjò oníyanu láti wà ní àárín àlìkámà àti èpò, nígbàmíràn tí ó kún fún ìrora ọkàn, ṣùgbọ́n tí a mú wálẹ̀ nípa ìdàgbà àti ìdánilójú ìgbàgbọ́ wa nígbaogbogbo. Bí ẹ ti nfi ààyè gba ìfẹ́ yín fún Olùgbàlà àti ìfẹ́ Rẹ̀ fún yín láti wọnú ọkàn yín jìnlẹ̀, mo ṣe ìlérí pé ẹ ó ní àfikún ìgbẹ́kẹ̀lé, àláfíà, àti ní pípàdé àwọn ìpènijà ti ìgbé ayé yín. Olùgbàlà sì ṣe ìlérí fún wa pé: “Èmi [yíò] kó àwọn ènìyàn mi jọpọ̀, gẹ́gẹ́bí òwe ti àlìkámà àti èpò, kí a lè dáàbò bo àlìkámà nínú àwọn àká láti gba ìyè ayérayé, àti kí a lè dé wọn ládé pẹ̀lú ògo sẹ̀lẹ́stíà.”23 Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́

  1. Máttéù 24:3.

  2. Máttéù 24:33.

  3. Henry B. Eyring, “Dídúróṣinṣin nínú àwọn Ìjì,” Liahona, May 2022.

  4. Máttéù 13:16; àfikún àtẹnumọ́.

  5. Máttéù 13:38.

  6. Máttéù 13:30.

  7. Alàgbà Neal A. Maxwell wípé: “Àwọn ọmọ Ìjọ yíò gbé nínú ipò a`lìkámà a`ti èpò yí títí di ẹgbẹ̀rún ọdún. Àwọn èpò lódodo ndáṣọbojú bí àlìkámà” (“Becometh as a Child,” Ensign, May 1996, 68).

  8. Wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 86:4, 6.

  9. Wo Lúkù 2:7

  10. Wo Colossians 1:23; bákannáà wo Ephesians 3:17; Neal A. Maxwell, “Grounded, Rooted, Established, and Settled” (Brigham Young University devotional, Sept. 15, 1981), speeches.byu.edu.

  11. In Matthew 13:22Jesus cautioned His disciples to not allow the cares of the world and the deceitfulness of riches to “choke the word” and stop his or her spiritual progress. Mo ní i`fẹ́ láti di gbólóhùn ọ̀rọ̀ “gún ọ`rọ̀ náà” sí orí ìkínní ti John, níbití John ti kéde ọ̀rọ̀ láti jẹ́ Jésù: “Ní ìbẹ̀rẹ̀ ni Ọ`rọ náà, Ọ̀rọ̀ náà sì wà pẹ̀lú Ọlọ́run. … “Nípasẹ̀ rẹ̀ ni a dá ohun gbogbo; lẹ́hìn rẹ̀ a kò sí dá ohunkan nínú óhun tí a dá” (John 1:1, 3). Ìgbàgbọ́ wa nínú Jésù Krístì, ìpinnu wa láti tẹ̀le E, ìfẹ́ wa fún Olùgbàlà lè gúnni, tàbí dẹ̀nà láti dàgbà, bí a ti ní ìdíwọ́ ìmọ́lẹ̀ ti ẹ̀mí àti títọ́jú (wo Alma 32:37–41

  12. Wo Neil L. Andersen, “A Compensatory Spiritual Power for the RighteousBrigham Young University devotional, Aug. 18, 2015), speeches.byu.edu.

  13. Jòhánnù17:3.

  14. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 6:36.

  15. 1 Jòhánnù 4:19.

  16. Alàgbà David B. Haight wí pé:

    “It is true that some have actually seen the Savior, but when one consults the dictionary, he learns that there are many other meanings of the word wosuch as coming to know Him, discerning Him, recognizing Him and His work, perceiving His importance, or coming to understand Him.

    Such heavenly enlightenment and blessings are available to each of us” (“Temples and Work Therein,” Ensign, Nov. 1990, 61).

  17. Wo Mòsíàh 5:13.

  18. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 20:77.

  19. Russell M. Nelson, “Májẹ̀mú Àìlópin Náà,” Liahona, Oct. 2022, 5.

  20. Russell M. Nelson, “Kíni Òtítọ́ Jẹ́?,” Liahona, Nov. 2022, 29.

  21. Russell M. Nelson, “Ìfihàn fún Ijọ, Ìfihàn fún Ìgbé Ayé Wa,” Liahona, May 2018, 96.

  22. Dallin H. Oaks, “Lílọ Síwájú Ní Sẹ́ntúrì Kejì” (Brigham Young University devotional, Sept. 13, 2022), speeches.byu.edu. Ààrẹ Oaks credited the phrase “dáṣà láti jẹ́ yíyàtọ̀” sí àtẹ̀kọ àìpẹ́ nínú Ìròhìn Deseret nípasẹ̀ Alàgbà Clark G. Gilbert,olùdarí Ètò Ilé-Ẹ̀kọ́ Ìjọ, lórí pípa ìdánimọ̀ ẹ̀sìn mọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ gíga (wo Clark G. Gilbert, “dáṣà láti jẹ́ yíyàtọ̀,” Ìròhìn DeseretSept. 2022, www.deseret.com).

  23. Bí ẹ bá fẹ́ láti ẹkọ látọ̀dọ̀ a`wọn míràn tí wọ́n sọ̀rọ̀ lórí bí wọ́n ti yàtọ̀ kúrò nínú ayé, ẹ lè ka a`wọn ọ̀rọ̀ wọn lórí Ojúìwé (wo Neil L. Andersen, Ojúìwé, Aug. 18, 2022, facebook.com/neill.andersen) or Instagram (see Neil L. Andersen, Instagram, Aug. 18, 2022, instagram.com/neillandersen).

  24. Russell M. Nelson, “Ìrètí Ísráẹ́lì” (worldwide youth devotional, June 3, 2018), HopeofIsrael.ChurchofJesusChrist.org.

  25. Anastasia K., “Dídojúkọ Ìja ní Ukraine, Wíwò Ìja Sàn nínú Ọkàn Mi,” YA Weekly, May 2022.

  26. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 101:65.