Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Díduróṣinṣin nínú àwọn Ìjì
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2022


Díduróṣinṣin nínú àwọn Ìjì

Nígbàtí àwọn ìjì inú ayé bá wá, ẹ lè dúróṣinṣin nítorí ẹ ndúró lórí àpàta ìgbàgbọ́ yín nínú Jésù Krístì.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìrnin mi ọ̀wọ́n, a ti di alábùkúnfún ní òní láti gbọ́ tí àwọn ìránṣẹ́ onímísí tí Ọlọ́run fúnni ní àmọ̀ràn àti ìyànjú. Ẹ̀nìkọ̀ọ̀kan wa, ibikíbi tí a wà, mọ̀ pé à ngbé ní ìgbà ewu púpọ̀si. Àdúrà mi ni pé kí èmi lè ràn yín lọ́wọ́ láti dúróṣinṣin nínú àwọn ìjì tí à nkojú, pẹ̀lú ọkàn àlááfíà1

Ibi láti bẹ̀rẹ̀ ni láti rántí pé ọ̀kọ̀ọ̀kan wa jẹ́ olùfẹ́ ọmọ Ọlọ́run àti pé Ó ní àwọn ìránṣẹ́ onímísí. Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ti rí àwọn àkokò nínú èyí tí à ngbé ṣíwájú. Àpóstélì Páùlù kọ̀wé sí Timothy, “Èyí ni kí o mọ̀ bákannáà, pé ní ọjọ́ ìkẹhìn àwọn ìgbà ewu yíò dé.”1

Ẹnikẹ́ni pẹ̀lú ojú láti rí àwọn àmì àkokò àti etí láti gbọ́ ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì mọ̀ pé òtítọ́ ni. Àwọn ewu ti ìjàmbá títóbijùlọ nwá sọ́dọ̀ wa látinú àwọn agbára ìwà búburú. Àwọn agbára wọnnì npọ̀si. Nítorínáà yíò sì di líle si, kìí rọrùn, láti bú-ọlá fún àwọn májẹ̀mú tí a gbọdọ̀ dá kí a sì pamọ́ láti gbé ìgbé ayé ìhìnrere Jésù Krístì.

Fún àwọn wọnnì lára wa tí à nní àníyàn fún arawa àti fún àwọn wọnnì tí a nifẹ, ìrètí wà nínú ìlérí tí Ọlọ́run ti ṣe nípa ibi ààbò nínú àwọn ìjì ọjọ́-iwájú.

Nihin ni àwòrán ọ̀rọ̀ kan nípa ibi náà. Ó ti di àpèjúwe lẹmọ́lemọ́ nípasẹ̀ àwọn wòlíì. Fún àpẹrẹ, bí a ti kọsílẹ̀ nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì, baba olùfẹ́ni àti ìmísí wí fún àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ bí wọ́n ṣe nfún arawọn lókun làti dúróṣinṣin nínú àwọn ìjì iwájú wọn: “Àti nísisìyí, ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ rántí, ẹ rántí pé lórí àpáta Olùràpadà wa, ẹnití íṣe Krístì, Ọmọ Ọlọ́run, ni ẹ̀yin níláti kọ́ ìpìlẹ̀ nyín lé, pé nígbàtí èṣù bá sì fẹ́ ẹ̀fũfù líle rẹ̀ wá, bẹ̃ni, ọ̀pá rẹ̀ nínú ìjì, bẹ̃ni, nígbàtí gbogbo àwọn òkúta yìnyín rẹ̀ àti ìjì líle rẹ̀ bá rọ̀ lé yín kò lè ní agbára lórí yín láti fà yín sínú ọ̀gbun òṣì àti ègbé aláìlópin, nítorí àpáta èyítí a kọ́ yín lé lórí, èyítí íṣe ìpìlẹ̀ tí o dájú, … èyítí ènìyàn kò lè ṣubú lórí rẹ̀ bí nwọ́n bá kọ́ lé e lórí.”2

Ìbànújẹ́ àti ìparun àìlópin nípa èyí tí ó sọ̀rọ̀ jẹ́ àbájáde olóró ti àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí a kò bá ronúpìwàdà nípa wọn ní kíkún. Àwọn ìjì tí ó ndàgbà si ni àwọn àdánwò àti àwọn àtakò ti Sátáni tó npọ̀si. Kò ì tí jẹ́ pàtàkì rí ju bí ó ti wà nísisìyí láti ní òye bí a ó ti kọ́ lé ìpìlẹ̀ dídájú. Fún mi, kò sí ibi dídarajùlọ láti wò ju inú ìwàásù Ọba Benjamin, bákannáà bí a ṣe kọ́sílẹ̀ nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì.

Àwọn ọ̀rọ̀ ti-wòlíì Benjamin wúlò sí wa ní ọjọ́ wa. Òun mọ̀ ìjayà ogun látinú ìrírí ti ararẹ̀. Ó ti dáààbò bo àwọn ènìyàn rẹ̀ ní kíkojú, gbígbara lé agbára Ọlọ́run. Ó rí agbára ìbẹ̀rù Lúsífà láti dànniwò kedere, láti gbìyànjú láti borí, àti láti mú ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn ọmọ Ọlọ́run.

Ó pe àwọn ènìyàn rẹ̀ àti àwa láti kọ́ lé orí àpàta dídájú ààbò nìkan, ẹnití iṣe Olùgbàlà. Ó fi han kedere pé a ní ominira láti yàn ní àárín títọ́ àti àṣìṣe àti pé a kò lè yẹra fún àyọrísí àwọn àṣàyàn wa. Ó sọ̀rọ̀ tààrà àti kíákíá nítorí ó mọ ìkorò tí yíò wá sọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n lè má tilẹ̀ gbọ́ àti láti gbọ́ àwọn ìkìlọ̀ rẹ̀.

Nihin ni bí a ṣe júwe àwọn àyọrísí tí yíò tẹ̀lé yíyàn wa bóyá láti tẹ̀lé ìṣílétí Ẹ̀mí tàbí láti tẹ̀lé àwọn ọ̀rọ̀ ibi tí ó nwá láti ọ̀dọ̀ Sátánì, ẹnití èrò-inú rẹ̀ jẹ́ láti dánwò àti láti pa wá run.

“Ẹ kíyèsĩ, a ti fi ègún gún lórí ẹnìkẹ́ni tí ó bá ṣe ìfẹ́ ẹ̀mí [ibi] nã; nítorítí bí ó bá ṣe ìfẹ́ rẹ̀, tí ó wà bẹ̃ tí ó sì kú nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, èyĩyí ni ó mu ègbé sórí ẹ̀mí ara rẹ̀; nítorítí ó ti gba èrè ìyà títí ayé, nítorípé ó rékọjá sí òfin Ọlọ́run ní ìlòdì si ìmọ̀ èyítí ó ní. …

“Nítorínã, tí ẹní nã kò bá ronúpìwàdà, tí ó sì wà bẹ̃, tí ó sì kú gẹ́gẹ́bí ọ̀tá Ọlọ́run, ìbẽrè fún àìṣègbè ti Ọlọ́run yíò ta ẹ̀mí àìkú rẹ̀ jí sí ẹ́bi ara rẹ̀, tí yìó jẹ́ kí ó súnkì kúrò níwájú Olúwa, tí yíò sì kún àyà rẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀bi, àti ìrora, àti àròkàn, èyítí ó dàbí iná tí a kò lè pa, èyítí ẹ̀là-iná rẹ̀ nrú sókè, títí láéláé.”

Ọba Bẹnjamin tún wí pé: “A, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ ti gbó, àti ẹ̀yin ọ̀dọ́, àti ẹ̀yin ọmọ wẹ́wẹ́ tí ẹ lè gbọ́ ọ̀rọ̀ mi yé, nítorítí èmi ti sọ̀rọ̀ ní kedere sí i yín kí ó lè yé nyín, èmi bẹ̀bẹ̀ pé kí ẹ lè tají sí ìràntí àwọn ipò búburú tí àwọn tí ó ti ṣubú sínú ìwà irékojá wa.”3

Fún mi, agbára ìkìlọ̀ náà láti ronúpìwàdà dá àwòrán kan nínú ọkàn mi nípa àkokò dídájú nígbàtí ẹ̀yin àti èmi yíò dúró síwájú Olùgbàlà lẹ́hìn ayé yí. Pẹ̀lú gbogbo ọkàn wa a kò fẹ́ hunjọ ṣùgbọ́n jùbẹ́ẹ̀ láti wò Ó, rí I tí ó rẹrin kí a sì gbọ́ Ọ ní wíwí pé “Kú iṣẹ́, ìwọ ọmọ ọ̀dọ̀ rere: … wọlé[síhin].”4

Ọba Benjamin mu hàn kedere bí a ṣe lè gba ìrètí láti gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ wọnnì bí a bá rí ọ̀nà nínú ayé láti jẹ́ kí àwọn ìwà-ẹ̀dá wa yípadà nípasẹ̀ Ètùtù Jésù Krístì. Ìyẹn ni ọ̀nà kanṣoṣo tí a fi lè kọ́ lé ìpìlẹ̀ dídájú kí a sì dúróṣinṣin ní ìgbà àwọn ìjì àdánwò àti ìdánwò iwájú. Ọba Bẹnjamin júwe pé ìyípadà náà nínú ìwà-ẹ̀dá wa pẹ̀lú àfiwé rírẹ̀wà tí ó wọ ọkàn mi. A lòó nípasẹ̀ àwọn wòlíì fún mìllẹ́níà àti nípasẹ̀ Olúwa Fúnrarẹ̀. Òun ni èyí: a gbọ́dọ̀ dà bí ọmọ kan—ọmọ kékeré kan.

Fún àwọn díẹ̀. tí kò ní rọrùn láti tẹ́wọ́gbà. Púpọ̀ lára wa nfẹ́ láti jẹ́ alágbára. A lè rí dídà bíi ọmọ kan ní jíjẹ́ aláìlera. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn òbí nfojúsọ́nà fún ọjọ́ náà nígbàtí àwọn ọmọ wọn yíò dínkù ní híhùwà bí-èwe. Ṣùgbọ́n Ọba benjamin, ẹnití ó ní òye bàkànnáà bí eyikeyi ara-ikú kankan ohun tí ó túmọ̀ sí láti jẹ́ ènìyàn alágbára àti ìgboyà, nmu hàn kedere pé láti jẹ́ ọmọ kan kìí ṣe láti ṣe bí èwe. Ó jẹ́ láti dàbí Olùgbàlà, ẹnití ó gbàdúrà sí Baba Rẹ̀ fún agbára láti lè ṣe ìfẹ́ Baba Rẹ̀ àti láti ṣe ètútù fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo àwọn ọmọ Baba Rẹ̀ nígbànáà ó sì ṣe é. Àwọn ìwà-ẹ́dá wa gbọ́dọ̀ yípada láti dà bíi ọmọ kan láti jèrè agbára a gbọ́dọ̀ dúróṣinṣin àti ní àlááfíà ní àwọn ìgbà ewu.

Nihin ni ìjúwe ìròpọ̀ Ọba Benjamin nípa bí ìyípadà ṣe nwá: “Nítorítí ènìyàn ẹlẹ́ran ara jẹ ọ̀tá Ọlọ́run, ó sì ti wà bẹ̃ láti ìgbà ìṣubú Ádámù, yíò sì wà bẹ̃ títí láéláé, bíkòṣepé ó jọ̀wọ́ ara rẹ̀ sílẹ̀ fún ònfà Ẹ̀mí Mímọ́, tí ó sì gbé ìwà ti ara sílẹ̀, tí ó sì di ènìyàn mímọ́ nípasẹ̀ ètùtù Krístì Olúwa, tí ó sì dà bí ọmọdé, onítẹríba, oníwá-tútù, onírẹ̀lẹ̀, onísũrù, kíkún fún ìfẹ́, tí ó fẹ́ láti jọ̀wọ́ ara rẹ̀ fún ohun gbogbo èyítí Olúwa ríi pé ó tọ́ láti fi bẹ̃ wò, àní gẹ́gẹ́bí ọmọdé ṣe jọ̀wọ́ ara rẹ̀ fún bàbá rẹ̀.”5

Á ngba ìyípadà náà bí a ti ndá tí a sì ntún àwọn májẹ̀mú wa ṣe pẹ̀lú Ọlọ́run. Ìyẹn nmú agbára Ètùtù Krístì wá láti fi ààyè gbà wá láti yípadà nínú ọkàn wa. A lè nímọ̀lára rẹ̀ ní gbogbo ìgbà tí a bá jẹ́ oúnjẹ Olúwa, ṣe ìlànà tẹ́mpìlì fún babanla tó ti kú, jẹri bí ẹlẹri Olùgbàlà, tàbí ṣe ìtọ́jú ẹnìkan nínú àìní bí ọmọẹ̀hìn Krístì.

Nínú àwọn ìrírí wọnnì, a ndà bí ọmọdé ní ìgbà pípẹ́ nínú okun wa láti nifẹ àti láti gbọ́ran. A nwá láti dúró lórí ìpìlẹ̀ dídájù. Ìgbàgbọ́ wa nínú Jésù Krístì nmú wa ronúpìwàdà àti láti pa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́. À ngbọ́ran, a sì njèrè agbára láti takò àdánwò, kí a sì jèrè ìlérí ojúgbà Ẹ̀mí Mímọ́.

Àwọn ìwà-ẹ̀dá wa nyípadà láti dàbí ọmọ kékeré, gbọ́ran sí Ọlọ́run àti jíjẹ́ olùfẹ́ni si. Ìyípadà ìyẹn yíò mú wa yege láti gbádùn àwọn ẹ̀bùn tí ó nwá nípasẹ̀ Ẹ̀mí Miḿọ. Níní ojúgbà ti Ẹ̀mí yíò tùní-nínú, tọ́sọ́nà, àti fún wa lókun.

Mo ti wá mọ àwọn ohun kan tí Ọba Benjamin rò nígbàtí ó wípé a lè dàbí ọmọ kékeré níwájú Ọlọ́run. Mo kẹkọ látinú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìrírí pé Ẹ̀mí Mímọ́ nsọ̀rọ̀ nígbàkugbà jùlọ nínú ohùn jẹ́jẹ́, tí a gbọ́ ní ìrọ̀rùn jùlọ nígbàtí ẹnìkan bá jẹ́ ọlọ́kàn-tútù àti onítẹríba, bíi ti ọmọ kan. Nítòótọ́, àdúrà tí ó nṣiṣẹ́ ni “Mo fẹ́ ohun tí Ẹ fẹ́ nìkan. Kàn wí fún mi ohun tí ìyẹn jẹ́. Èmi yíò ṣe é.”

Nígbàtí àwọn ìjì inú ayé bá wá, ẹ lè dúróṣinṣin nítorí ẹ ndúró lórí àpàta ìgbàgbọ́ yín nínú Jésù Krístì. Ìgbàgbọ́ náà yíò darí yín sí ìrònúpìwàdà ojojumọ àti pipa májẹ̀mú mọ́ léraléra. Nígbànáà ẹ ó rántí Rẹ̀ nígbàgbogbo. Àti nípasẹ̀ àwọn ìjì ikorira àti iwa-buburú, ẹ ó ní ìmọ̀lára ìdúróṣinṣin àti níní-ìrètí.

Ju ìyẹn lọ, ẹ lè rí arayín ní nínawọ́ jáde láti gbé àwọn ẹlòmíràn sókè sí ààbò ní orí àpàta pẹ̀lú yín. Ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì nígbàgbogbo ndarí sí ìrètí títóbijù àti àwọn ìmọ̀lára ìfẹ́-àìlẹ́gbẹ́ síwájú àwọn ẹlòmíràn, èyítí ó jẹ́ ìfẹ́ òtítọ́ Krístì.

Mo jẹ́ ẹ̀rí ọ̀wọ̀ mi pé Olúwa Jésù Krístì ti fún yín ní ìpè “Wá sọ́dọ̀ mi.”6 Mo pè yín, látinú ìfẹ́ fún yín àti fún àwọn wọnnì tí ẹ fẹ́ràn, láti wá sọ́dọ̀ Rẹ̀ fún àlááfíà nínú ayé yí àti ìyè ayérayé nínú ayé tó nbọ̀. Óun mọ àwọn ìjì tí ẹ ó kojú nínú ìdánwò yín bí ara ètò ìdùnnú ní pípé.

Mo bẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú yín láti tẹ́wọ́gba ìpè Olùgbàlà. Bíi ti ọlọ́kàntútù àti olùfẹ́ni ọmọ kan, ẹ tẹ́wọ́gba ìrànlọ́wọ́ Rẹ̀. Ẹ dá kí ẹ sì pa àwọn májẹ̀mú tí Ò fúnni nínú Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn mọ́. Wọn yíò fún yín lókun. Olùgbàlà mọ àwọn ìjì àti ibi ààbò ní ọ̀nà sí ilé lọsí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ àti sí ọ̀dọ̀ Baba wa Ọ̀run. Ó mọ ọ̀nà náà. Òun ni ọ̀nà náà. Ní mo jẹ́ ẹ̀rí bẹ́ẹ̀ ní orúkọ mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín.