Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Nítorí Ọlọ́run Fẹ́ Wa Tó Bẹ́ẹ̀ Gẹ́
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2022


Nítorí Ọlọ́run Fẹ́ Wa Tó Bẹ́ẹ̀ Gẹ́

Ọlọ́run fẹ wa tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ tí Ó fi rán Ọmọ Bíbí Rẹ kanṣoṣo—kìí ṣe láti dá wa lẹ́bi bíkòṣe láti gbàwálà.

“Nítorí Ọlọ́run fẹ́ aráyé tóbẹ́ẹ́ gẹ́, tí ó fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kanṣoṣo fúnni, pé ẹnikẹ́ni tí ó bá gbàá gbọ́ má bàá ṣègbé, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun” (Jòhánnù 3:16). Ní ìgbà àkọ́kọ́ tí mo ṣàkíyèsí ẹsẹ yí, mi ò sí ní ìjọ tàbí ní ẹbí ilé ìrọ̀lẹ́. Mò nwo èto eré ìdárayá lórí amóhunmáwòràn. Èyíkeyi ibùdó tí mo wò, àti èyíkeyi eré tí ó jẹ́, ó kéré jù ènìyàn kan nmú àmì kan tí ó ka “Jòhánnù 3:16.”

Mo ti wá nífẹ̀ẹ́ ẹsẹ kẹtàdínlógún: “Nítorí Ọlọ́run kò rán Ọmọ Rẹ̀ sínú ayé láti dá ayé lẹ́bi; ṣùgbọ́n pé kí ayé nípa rẹ̀ lè ní ìgbàlà.”

Ọlọ́run rán Jésù Krístì, Ọmọ Rẹ̀ Kan ṣoṣo nínú ẹran ara, láti fi ayé Rẹ̀ sílẹ̀ fún ẹnikọ̀ọ̀kan wa. Ó ṣe èyí nítorí pé Ó nífẹ̀ẹ́ wa ó sì ṣe ètò kan fún ẹnìkọ̀ọ̀kan wa láti padà sílé lọ́dọ̀ Rẹ̀.

Ṣùgbọ́n èyí kìí ṣe ìbora, mú gbogbo rẹ̀, kọlù-tàbí-pàdánù irú ètò kan. Ó jẹ́ ti araẹni, tí a ti gbé kalẹ̀ láti ọwọ́ olùfẹ́ni Baba Ọ̀run, ẹnití ó mọ ọkàn wa, orúkọ wa, àti ohun tí Ó nílò wa láti ṣe. Kínì ìdí tá a fi gbà ìyẹn gbọ́? Nítorí a ti kọ́wà nínú àwọn ìwé-mímọ́.

Mósè gbọ́ léraléra tí Baba Ọ̀run sọ àwọn ọ̀rọ̀ náà “Mósè, ọmọ mi” (wo Mose 1:6; bákannáà wo àwọn ẹsẹ 7, 40). Ábráhámù kọ́ pé ọmọ Ọlọ́run ni òun, tí a yàn fún iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ àní kí a tó bí i (wo Ábráhámù 3:12, 23). Nípa ọwọ́ Ọlọ́run, a fi Ẹ́stérì sí ipò agbára láti gba àwọn ènìyàn rẹ̀ là (wo Ẹ́stérì 4). Ọlọ́run sì gbẹ́kẹ̀lé ọ̀dọ́mọbìnrin kan, ìránṣẹ́ kan, láti jẹ́rìí nípa wòlíì alààyè kan kí Náámánì lè rí ìwòsàn (wo 2 Àwọn Ọba 5).

Mo fẹ́ràn ọkunrin rere náà nípàtàkì, kúkúrú ní ìwọ̀n ara, ẹnití ó gun igi kan láti rí Jésù. Olùgbàlà mọ̀ pé ò wà níbẹ̀, ó dúró, ó gbé ojú sókè sí àwọn ẹ̀ka náà, ó sì sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí: “Sákéù, … sọ̀kalẹ wá” (Lúkù 19:5 A kò sì lè gbàgbé ọmọdékùnrin ọdún mẹ́rìnlá tó lọ sí inú igbó igi ṣúúrú kan tó sì kọ́ nípa bí ètò náà ṣe jẹ́ ti araẹni sí lotitọ: “[Joseph,] èyí ni Àyànfẹ́ Ọmọ Mi. Gbọ Ọ!” (Ìtàn—Josefu Smith 1:17).

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, àwa ni àfojúsùn ti ètò Baba wa Ọ̀run àti ìdí fún iṣẹ́ ìránṣẹ́ Olùgbàlà wa. Ẹnìkọ̀ọ̀kan wa, ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, ni iṣẹ́ Wọn àti ògo Wọn.

Sí èmi, kò sí ìwé mímọ́ tó ṣe àkàwé èyí lọ́nà tó ṣe kedere ju bí àṣàrò mi nínú Májẹ̀mú Láéláé lọ. Orí lẹ́hìn orí a ṣe àwárí àwọn àpẹẹrẹ bíi Baba Ọ̀run àti Jèhófà ṣe ní ipa tímọ́tímọ́ nínú ìgbésí-ayé wa.

Láìpẹ́ yìí, a ti nṣe àṣàrò nípa Joseph, àyànfẹ́ ọmọkùnrin Jákọ́bù. Láti ìgbà èwe rẹ̀, Joseph ti rí ojú rere gíga lọ́dọ̀ Olúwa, síbẹ̀ ó ní ìrírí àdánwò nlá lọ́wọ́ àwọn arákùnrin rẹ̀. Ní ọ̀sẹ̀ méjì sẹ́hìn, púpọ̀ nínú wa ní ìwúrí nípa bí Joseph ṣe dárí ji àwọn arákùnrin rẹ̀. Nínú Wá, Tẹle Mi a kà pé: “Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀nà, ìgbésí-ayé Joseph jọra pẹ̀lú ti Jésù Krístì Àní bíótilẹ̀jẹ́pé àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa fa ìjìyà nlá fún Un, Olùgbàlà fi ìdáríjì lélẹ̀, ní gbígba gbogbo wa sílẹ̀ lọ́wọ́ àyànmọ́ tí ó burú ju ìyàn lọ. Bóyá a nílò láti gbà ìdáríjì tàbí kí a fi í fúnni—ní àwọn ààyè kan gbogbo wa nílò láti ṣe méjèèjì—àpẹẹrẹ Joseph tọ́ka wa sí Olùgbàlà, orísun tòótọ́ ti ìwòsàn àti ìlàjà.”1

Ẹ̀kọ́ kan tí mo nífẹ̀ẹ́ sí nínú ìtàn náà wá láti ọ̀dọ̀ Júdà arákùnrin Joseph, ẹni tó kópa nínú ètò ara ẹni ti Ọlọ́run fún Joseph Nígbàtí a dalẹ̀ Joseph láti ọwọ́ àwọn arákùnrin rẹ̀, Júdà yí wọn lọ́kàn padà láti máṣe gba ẹ̀mí Joseph ṣùgbọ́n kí wọ́n tà á sí oko ẹrú (wo Gẹ́nẹ́sísì 37:26–27).

Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́hìnnáà, Júdà àti àwọn arákùnrin rẹ̀ nílò láti mú arákùnrin wọn kékeré jùlọ, Bẹ́njámínì, lọ sí Egypt. Ní ìbẹ̀ẹ̀rẹ̀ baba wọn kọ̀. Ṣùgbọ́n Júdà ṣe ìlérí kan fún Jákọ́bù pé òun yíò mú Bẹ́njámínì wá sí ilé.

Ní Egypt, a fi ìlérí Júdà sínú ìdánwò. Wọ́n fi ẹ̀sùn kan ọ̀dọ́mọkùnrin Benjamin lọ́nà àìtọ́. Júdà, ní tòótọ́ sí ìlérí rẹ̀, ó yọ̀nda láti ṣe ẹ̀wọ̀n ní ipò Bẹ́njámínì. “Nítorí,” ó wí pé, “báwo ni èmi yíò ṣe gòkè lọ sí ọ̀dọ̀ baba mi, tí ọ̀dọ́ ọmọ náà kò sì sí pẹ̀lú mi?” (Wo Gẹ́nẹ́sísì 44:33–34). Júdà pinnu láti mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ, kí ó sì dá Bẹ́njámínì padà ní àlàáfíà. Njẹ́ ẹ ti ní ìmọ̀lára rí láé nípa àwọn ẹlòmíràn bí Júdà ti ní ìmọ̀lára fún Bẹnjamin?

Njẹ́ báyí kọ́ ni àwọn òbí ṣe nní ìmọ̀lára nípa àwọn ọmọ wọn? Bí àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere ṣe ní ìmọ̀lára nípa àwọn ènìyàn tí wọ́n nsìn? Bí àwọn olórí Alákọbẹ́rẹ̀ àti ọ̀dọ́ ṣe nní ìmọ̀lára nípa àwọn tí wọ́n nkọ́ tí wọ́n sì fẹ́ràn?

Ẹni tí ó wù kí ẹ jẹ́ tàbí àwọn ipò yín lọ́wọ́lọ́wọ́, ẹnikan ní ìmọ̀lára ní ọ̀nà yí gan an nípa yín. Ẹnìkan fẹ́ láti padà sí ọ̀dọ̀ Baba Ọ̀run pẹ̀lú yín.

Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn tí kò jáwọ́ lọ́rọ̀ wa, tí wọ́n ntẹ̀síwájú láti tú ọkàn wọn jáde nínú àdúrà fún wa, tí wọ́n sì ntẹ̀síwájú láti kọ́ni tí wọ́n sì nràn wá lọ́wọ́ láti di yíyẹ láti padà sílé lọ́dọ̀ Bàbá wa ní Ọ̀run.

Láìpẹ́ yí ọ̀rẹ́ ọ̀wọ́n kan lo àwọn ọjọ́ 233 ní ile´-ìwòsàn pẹ̀lú COVID-19. Láàrin àkokò náà, baba rẹ̀ tó ti kú bẹ̀ ẹ́ wò, ó ní kí a fi iṣẹ́ kan jẹ́ fún àwọn ọmọ-ọmọ rẹ̀. Ání ní ìkọjá ìkelè, baba-àgbà rere yí fẹ́ láti ran àwọn ọmọ-ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́ láti padà sí ilé wọn ti ọ̀run.

Ní púpọ̀si, àwọn ọmọ ẹ̀hìn Krístì nrántí “àwọn ará Bẹ́njámínì” nínú ìgbésí-ayé wọn. Ní gbogbo àgbáyé wọ́n ti gbọ́ ìpè sí iṣẹ́ wòlíì alààyè Ọlọ́run, Ààrẹ Russell M. Nelson. Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin nṣiṣẹ́ nínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀dọ́ ti Olúwa. Àwọn ẹ̀nìkọ̀ọ̀kan àti àwọn ẹbí nnawọ́ jáde nínú ẹ̀mí síṣe iṣẹ́-ìránṣẹ́—nínú ìfẹ́, ní pínpín fúnni, àti pípè àwọn ọ̀rẹ́ àti àwọn aladugbo láti wá sí ọ̀dọ̀ Krístì. Àwọn ọ̀dọ́ àti àwọn àgbàlagbà nrántí wọ́n sì ntíraka láti pa àwọn májẹ̀mú wọn mọ́—ní kíkún inú àwọn tẹ́mpìlì Ọlọ́run, wíwá àwọn orúkọ àwọn ọmọ ẹbí tí wọ́n ti kú, àti gbígba àwọn ìlànà fún wọn.

Kíni ìdí tí ètò àdáni Baba Ọ̀run fún wa ṣe ní ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti padà sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ nínú? Nítorípé bẹ́ẹ̀ ní a ṣe le dàbíi Jésù Krístì. Ní ìgbẹ̀hìn, ìtàn Júdà àti Bẹ́njámínì kọ́ wa nípa ìrúbọ Olùgbàlà fún wa. Nípasẹ̀ Ètùtù Rẹ̀, Ó fi ẹ̀mí Rẹ̀ lélẹ̀ láti mú wa wá sílé. Àwọn ọ̀rọ̀ Júdà fi ìfẹ́ Olùgbàlà hàn: “Báwo ni èmi yíò ṣe gòkè lọ sọ́dọ̀ baba mi, tí [ìwọ] kò sì sí pẹ̀lú mi?” Bíi àwọn olùkójọ Ísráẹ́lì, ìwọ̀nyí lè jẹ́ àwọn ọ̀rọ̀ wa pẹ̀lú.

Májẹ̀mú Láéláé kún fún àwọn iṣẹ́ ìyanu àti àwọn ìrọ́nú àánú tí ó jẹ́ àmì ètò Baba Ọ̀run. Ninú 2 Àwọn Ọba 4, gbólóhùn náà “ó bọ́ sí ọjọ́ kan” ni a lò ní ìgbà mẹ́ta láti tẹnumọ pé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì ṣẹlẹ̀ ní ìbámu sí àkokò Ọlọ́run àti pé kò sí àlàyé tí ó kéré jù fún Un.

Ọ̀rẹ́ mi tuntun Páùlù jẹ́rìí nípa òtítọ́ yìí. Páùlù dàgbà nínú ilé kan tó máa nlo ìlòkulò nígbà míràn, tí ó sì fi ìgbàgbogbo ṣe àìfaramọ́ ẹ̀sìn. Nígbàtí ó nlọ sí ilé ẹ̀kọ́ ní ibùdó àwọn ológun kan ní Germany, ó kíyèsí àwọn arábìnrin méjì kan tó dà bíi pé wọ́n ní ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí. Bíbéèrè ìdí tí wọ́n fi yàtọ̀ mú ìdáhùn wá pé wọ́n jẹ́ ti Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn.

Láìpẹ́ Paulù bẹ̀rẹ̀ ìpàdé pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere a sì pè é sí ijọ. Ní ọjọ́ Ìsinmi tó tẹ̀lé e, bí ó ṣe sọ̀kalẹ̀ nínú ọkọ̀ èrò náà, ó ṣe àkíyèsí àwọn ọkùnrin méjì kan tí wọ́n wọ àwọn ẹ̀wù funfun àti táì. Ó béèrè lọ́wọ́ wọn bóyá alàgbà ìjọ ni wọ́n. Wọ́n dáhùn pé bẹ́ẹ̀ ni, Páùlù sì tẹ̀ lé wọn.

Lákokò ìsìn, oníwàásù kan nawọ́ sí àwọn ènìyàn láarín àpéjọ náà o sì pè wọ́n láti jẹ́rìí Ní òpin ìjẹ́rìí kọ̀ọ̀kan, onílù á lu ìlù kan, àpéjọ náà á sì kígbe pé, “Àmín.”

Nígbàtí oníwàásù náà tọ́ka sí Páùlù, ó dìde ó sì sọ pé, “Mo mọ̀ pé Joseph Smith jẹ́ wòlíì kan àti pé Ìwé ti Mọ́mọ́nì jẹ́ òtítọ́.” Kò sí ìkíni ìlù tàbí àwọn àmín. Páùlù wá mọ̀ pé òun ti lọ sí ìjọ tí kò tọ́. Láìpẹ́, Páùlù wá ọ̀nà rẹ̀ sí ibi tó tọ́, a sì rì í bọmi.

Ní ọjọ́ ìrìbọmi Páùlù, àjèjì kan sọ fún un pé, “Ìwọ gba ẹ̀mí mi là.” Ní ọ̀sẹ̀ díẹ̀ ṣaájú, ọkùnrin yìí ti pinnu láti wá ìjọ míràn ó sì lọ sí ìsìn kan pẹ̀lú ìlù àti àwọn àmín. Nígbàtí ọkùnrin náà gbọ́ tí Páùlù njẹ́rìí nípa Joseph Smith àti Ìwé ti Mọ́mọ́nì, ó mọ̀ pé Ọlọ́run mọ̀ òun, ó mọ àwọn ìjàkadì rẹ̀, ó sì ní ètò kan fún òun. Fún àwọn méjèèjì Páùlù àti ọkùnrin náà, “ó bọ́ sí ọjọ́ kan,” nítòótọ́!

Àwa náà mọ̀ pé Baba Ọ̀run ní ètò ìdùnnú ti ara ẹni fún ẹnì kọ̀ọ̀kan wa. Nítorípé Ọlọ́run rán Ọmọ Rẹ̀ Àyànfẹ́ fún wa, àwọn iṣẹ́ ìyanu tí a nílò yíò “bọ́ sí ọjọ́ náà gan-an” tí ó ṣe pàtàkì fún ètò Rẹ̀ láti di mímúṣẹ.

Mo jẹ́rìí pé ní ọdún yii a lè kọ́ ẹ̀kọ́ síi nípa ètò Ọlọ́run fún wa nínú Májẹ̀mú Láéláé. Àkópọ̀ mímọ́ náà nkọ́ni ní ojúṣe tí àwọn wòlíì nkó ní àwọn àkókò àìdánilójú àti ọwọ́ Ọlọ́run nínú ayé kan tí ó ndàrú tí ó sì sábà nṣe àríyànjiyàn. Ó tún jẹ́ nípa àwọn onírẹ̀lẹ̀ onìgbàgbọ́ tí wọ́n fi ìṣòtítọ́ fojú sọ́nà fún bíbọ̀ Olùgbàlà wa, gẹ́gẹ́ bí a ṣe nfojú sọ́nà tí a sì nmúra sílẹ̀ fún Bíbọ̀ Rẹ̀ Lẹ́ẹ̀kejì ìpadàbọ̀ ológo Rẹ̀—tí Ó ti sọtẹ́lẹ̀ tipẹ́.

Títí di ọjọ́ náà, a lè ma ri, pẹ̀lú àwọn ojú àdánidá wa, àwòrán ètò Ọlọ́run fún gbogbo àwọn abala ìgbé-ayé wa (wo Ẹ̀kọ́ ati Àwọn Májẹ̀mú 58:3). Ṣùgbọ́n a lè rántí ìdáhùn Néfì nígbàtí ó dojú kọ ohun kan tí kò lóye rẹ̀: nígbàtí kò mọ ìtumọ̀ ohun gbogbo, ó mọ̀ pé Ọlọ́run fẹ́ràn àwọn ọmọ Rẹ̀ (wo 1 Néfì 11:17).

Èyí ni ẹ̀rí mi ní ọ̀wúrọ̀ Ìsinmi rírẹwà yi. Njẹ́ kí a le kọ ọ́ sí ọkàn wa kí a sì fi ààyè gbà á láti kún ẹ̀mí wa pẹ̀lú àlááfíà, ìrètí, àti ayọ̀ ayérayé: Ọlọ́run fẹ wa tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ tí Ó fi rán Ọmọ Bíbí Rẹ kanṣoṣo—kìí ṣe láti dá wa lẹ́bi bíkòṣe láti gbàwálà. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Àkọsílẹ̀ Ránpẹ́

  1. Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún olúkúlùkù àti àwọn Ẹbí: Májẹ̀mú Láéláé 2022, 51.