Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Àwa Ni Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2022


Àwa Ni Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn

Ìjọ jẹ́ díẹ̀ síi ju àwọn ilé àti àwọn ìlànà oníwàásù; Ìjọ wà nínú wa, àwọn ọmọ ìjọ, pẹ̀lú Kristi ní orí àti wòlíì gẹ́gẹ́ bí agbẹnusọ Rẹ̀.

Lẹ́hìn gbígba ìpè láti “wá kí o sì ríi,”1 Mo lọ Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn fún ìgbà àkọ́kọ́ ní ọjọ́ orí kẹrìndínlọ́gbọ̀n. Mo yapa kúrò lọ́dọ̀ ọkọ mi àkọ́kọ́ láìpẹ. Mo ní omokùnrin ọmọ ọdún mẹ́ta. Àti pé mo ní ìmọ̀lára àìní agbára pẹ̀lú ìbẹ̀rù. Nígbà tí mo wọnú ilé náà, mo kún fún ìyári bí mo ṣe rí ìgbàgbọ́ àti ayọ̀ àwọn ènìyàn tó yí mi ká. Ní tòótọ́, ó jẹ́ “ibi ìsádi kúrò lọ́wọ́ ìjì.”2 Ọ̀sẹ̀ mẹ́ta lẹ́hìn náà, mo dá májẹ̀mú ìrìbọmi pẹ̀lú Bàbá Ọ̀run mo sì bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò mi gẹ́gẹ́ bí ọmọẹ̀hìn Krístì, bíótilẹ̀jẹ́pé ìgbé ayé mi kò pé ní-ọ̀nà ìrìnàjò náà.

Fún mi láti gba àwọn ìbùkún ayérayé wọnnì, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn èròjà ti ara àti ẹ̀mí ní láti wà. Ìhìnrere Jésù Krístì ni a ti mú padàbọ̀sípò tí a sí ti wàásù; ilé ìjọsìn ni a ti kọ́ tí a sì ti tọ́jú; ìlànà oníwàásù kan wà, láti orí wòlíì dé àwọn olórí ìbílẹ̀; àti ẹ̀ka kan tí ó kún fún àwọn ọmọ ìjọ onímájẹ̀mú ti múra láti gbàmí àti ọmọkùnrin mi mọ́ra bí a ti mú wa wá sọ́dọ̀ Olùgbàlà, “tí a bọ́ nípa ọ̀rọ̀ rere Ọlọ́run.”3 tí a sì fún ní àwọn ànfààní láti sìn.4

Láti ìbẹ̀rẹ̀, Ọlọ́run ti wá láti kójọ àti láti ṣètò àwọn ọmọ Rẹ̀5 “Láti mú àìkú àti ìyè ayérayé [wa] wá sí ìmúṣẹ.”6 Pẹ̀lú èrèdí náà lọ́kàn, Ó ti fún wa ní ìtọ́ni láti kọ́ àwọn ibi ìjọsìn7 níbití a ti gba ìmọ̀ àti àwọn ìlànà ti ìgbàlà àti ìgbéga; kí a dá kí a sì pa àwọn májẹ̀mú tí ó so wá pọ̀ mọ́ Jésù Krístì mọ́;8 gba ìfúnni-ní ẹ̀bùn “agbára ìwa-bi-Ọlọrun”;9 kí a sì kó wọn jọ léraléra láti rántí Jésù àti láti fún ara wọn lókun nínú Rẹ̀.10 Ìṣètò Ìjọ àti àwọn ilé rẹ̀ wà fún àǹfààní ti-ẹ̀mí wa. “Ìjọ… jẹ́ ìpayà tí a fi ngbé àwọn ẹbí ayérayé ga.”

Nígbà tí mo nbá ọ̀rẹ́ mi kan sọ̀rọ̀ nígbà ìṣòro, mo béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ bí ó ṣe nyè nípa owó. Nínú omijé, ó fèsì pé bíṣọ́ọ̀pù òun nràn òun lọ́wọ́ ní lílo owó ọrẹ-àwẹ̀. Ó fi kún un pé, “Mi ò mọ ibi tí èmi àti ẹbí mi ì bá wà tí kì í bá ṣe ti Ìjọ.” Mo dáhùn, “Ìjọ ni àwọn ọmọ ìjọ. Àwọn ni àwọn tí wọ́n nfi tìfẹ́tìfẹ́ àti tayọ̀tayọ̀ fi ọrẹ-àwẹ̀ ṣe ìrànlọ́wọ́ fún àwọn aláìní. Ẹ ngba àwọn èso ìgbàgbọ́ àti ìpinnu wọn láti tẹ̀lé Jésù Kristi.”

Àwọn ọmọẹ̀hìn Kristi ẹlẹgbẹ́ mi, ẹ má ṣe jẹ́ kí a fojú kéré iṣẹ́ àgbàyanu tí Olúwa nṣe nípa wa, Ìjọ Rẹ̀, pẹ̀lú àwọn àìpé wa. Nígbà míràn a jẹ́ olùfúnni àti nígbàmíràn a jẹ́ olùgbà, ṣùgbọ́n gbogbo wa jẹ́ ẹbí kan nínú Krístì. Ìjọ Rẹ̀ ni ìlànà tí Ó ti fi fúnni láti tọ́nisọ́nà àti láti bùkún wa bí a ṣe njọ́sìn Rẹ̀ tí a sì nsìn ara wa.

Àwọn arábìnrin kan ti tọrọ àforíjì lọ́wọ́ mi, ní ríronú pé àwọn kì í ṣe ọmọ Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ tó nwa déédé nítorí pé wọ́n nsìn ní Alákọbẹ̀rẹ̀ tàbí Àwọn Ọ̀dọ́mọbìnrin. Àwọn arábìnrin yẹn wà lára ​​àwọn ọmọ Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n nwa déédé jù lọ nítorí pé wọ́n nran àwọn ọmọdé àti ọ̀dọ́ iyebíye wa lọ́wọ́ láti fún ìgbàgbọ́ wọn lókun.

Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ ò lópin sí iyàrá kan nínú ilé kan, ẹ̀kọ́ ọjọ́ Ìsinmi, ṣíṣe ìṣe kan, tàbí àjọ ààrẹ ní ìpele ìbílẹ̀ tàbí gbogbogbò. Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ ni àwọn obìnrin májẹ̀mú ti Ìjọ; òun ni àwaẹnìkọ̀ọ̀kan wa àti gbogbo wa. Ó jẹ́ “agbègbè àgbáyé ti àánú àti ìsìn.”12 Níbikíbi àti níbigbogbo tí a bá lọ, a jẹ́ apákan ti Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ nígbàgbogbo bí a ṣe ntiraka láti mú ìpinnu tọ̀run rẹ̀ ṣẹ, èyítí ó wà fún àwọn obìnrin láti ṣe àṣepé iṣẹ́ Ọlọ́run nínú olúkúlùkù bákannáà bí àwọn ọ̀nà lápapọ̀13 nípa pípèsè ìrànlọ́wọ́: “ìrànlọ́wọ́ kúro nínú òṣì, ìrànlọ́wọ́ kúro nínú àìsàn; ìrànlọ́wọ́ kúrò nínú iyèméjì, ìrànlọ́wọ́ kúrò nínú àìmọ̀kan— ìrànlọ́wọ́ kúrò nínú gbogbo ohun ìdíwọ́ … ayọ̀ àti ìlọsíwájú.”14

Irú wíwà pẹ̀lú kannáà wà nínú àwọn iyejú alàgbà àti àwọn ìṣètò ti Ìjọ fún gbogbo ọjọ́-orí, pẹ̀lú àwọn ọmọde àti àwọn ọdọ wa. Ìjọ ju àwọn ilé àti àwọn ìlànà oníwàásù; Ìjọ ni àwa, ọmọ ìjọ Àwa ni Ìjọ ti Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́ Ìkẹhìn, pẹ̀lú Krístì ní orí àti wòlíì gẹ́gẹ́bí agbẹnusọ Rẹ̀. Olúwa ti wípé:

“Kíyèsíi, èyí ni ẹ̀kọ́ mi—ẹnikẹ́ni tí ó bá ronúpiwàdà tí ó sì wá sí ọ̀dọ̀ mi, òun kannáà ni ìjọ mi.…

“Àti pé … ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ ti ìjọ mi, tí ó sì dúró ti ìjọ mi títí dé òpin, òun ni èmi yíò fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ lórí àpáta mi.”15

Ẹ̀yin arabìnrin àti arakùnrin, ẹ jẹ́ kí a mọ bí a ti láyọ̀ tó láti wà nínú Ìjọ Jésù Krístì, níbi tí a ti lè so ìgbàgbọ́, ọkàn, agbára, èrò inú, àti ọwọ́ wa pọ̀ láti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu nlá Rẹ̀. “Nítorí ara [Ìjọ Kristi] kì í ṣe ẹ̀yà kanṣoṣo, bí kò ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀.”16

Ọ̀dọ́kùnrin kan sọ fún ìyá rẹ̀ pé, “Nígbà tí mo wà lọ́mọdé, gbogbo ìgbà tí mo bá san dọ́là kan fún ìdámẹ́wàá, mo máa nrò pé pẹ̀lú dọ́là kan a óò kọ́ gbogbo ìlé ìjọsìn. Ṣé ìyẹn kìí ṣe àìlọ́gbọ́n?”

Ní ìfọwọ́tọ́, ó dáhùn pé, “Ìyẹn jẹ́ ẹlẹ́wà! Ṣé o ya àwòrán wọn ní ọkàn rẹ?”

“Bẹ́ẹ̀ni!” ó kígbe. “Wọ́n rẹwà, ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù wọn sì wà!”17

Ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n, ẹ jẹ́ kí a ní ìgbàgbọ́ ti ọmọdé kí a sì yọ̀ ní mímọ̀ pé àní ìtiraka wa tí ó kéré jù lọ nmú ìyípadà pàtàkì kan wá nínú ìjọba Ọlọ́run.

Èrèdí wa nínú ìjọba Rẹ̀ ni láti mú ara wa wá sọ́dọ̀ Kristi. Bí a ṣe nkà nínú àwọn ìwé mímọ́, Olùgbàlà nawọ́ ìpè yìí sí àwọn ará Néfì:

“Njẹ́ ẹ̀yin ní aláìsàn lãrín yín? Ẹ mú wọn wá sí ọ̀dọ̀ mi. Njẹ́ ẹ̀yin ní ẹnikẹ́ni tí a … pọ́nlójú lọ́nàkọnà? Ẹ mú wọn wá sí ọ̀dọ̀ mi èmi yíò sì wò wọ́n sàn, nítorítí èmi ní ìyọ́nú sí yín; inú mi kún fún ãnú.

“… Mo ríi pé ìgbàgbọ́ rẹ ti tó pé kí èmi ó mú ọ láradá.”18

Njẹ́ gbogbo wa ní ìpọ́njú tí a lè mú wá sí ẹsẹ̀ Olùgbàlà? Nígbàtí díẹ̀ nínú wa ní àwọn ìpèníjà ti ara, ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ síi nbá ija ẹdun ọkàn jà, àwọn míràn ntiraka láti tọ́jú àwọn ìsopọ̀ àwùjọ, àti pé gbogbo wa nwá ìsinmi nígbàtí àwọn ẹ̀mí wa bá ní ìpèníjà. Gbogbo wa ni a nní ìpọ́njú lọ́nàkọnà.

A kà pé “àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn nã, pẹ̀lú ọkàn kan, jáde lọ pẹ̀lú àwọn aláìsàn wọn àti … pẹ̀lú gbogbo àwọn tí a pọn lójú ní ọ̀nàkọnà; ó wò olúkúlùkù wọ́n sàn bí wọn ṣe nmú wọn wá sí ọdọ rẹ̀.

“Wọ́n sì ṣe gbogbo ohun, àwọn méjèèjì tí a ti wò sàn àti àwọn tí ó wà ní pípé, wólẹ̀ sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀, wọ́n sì jọ́sìn rẹ̀.”19

Láti ọ̀dọ̀ ọmọdékùnrin tí ó san ìdámẹ̀wá pẹ̀lú ìgbàgbọ́ sí ìyá àdáwà tí ó nílò oore-ọ̀fẹ́ tó nfúnni lágbára Olúwa sí baba tí ó ntiraka láti pèsè fún ẹbí rẹ̀ sí àwọn baba nlá wa tí ó nílò àwọn ìlànà ti ìgbàlà àti ìgbéga sí olúkúlùkù wa tí ó tún àwọn májẹ̀mú pẹlu Ọlọ́run ṣe ní ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀, a nílò ara wa, àti pé a lè mú arawa wá sí ìwòsàn ìràpadà ti Olùgbàlà.

Ẹ̀yin arábìnrin àti arákùnrin mi ọ̀wọ́n, ẹ jẹ́ kí a tẹ̀lé ìpè Jésù Krístì láti mú ara wa àti àwọn ìpọ́njú wa wá sọ́dọ̀ Rẹ̀. Nígbàtí a bá wásí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ tí a sì mú àwọn tí a nífẹ̀ si wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ, Ó nrí ìgbàgbọ́ wa. Yìó sọ wọ́n di pípé, Òun yìó sì sọ wá di pípé.

Gẹ́gẹ́ bí “àwọn àtẹ̀lé Kristi tí ó ní àlàáfíà,”20 à ntiraka láti di “ọkàn kan àti èrò inú kan”21 àti láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀; onítẹriba; Onírẹlẹ; tó rọrun lati ṣe itẹwọgbà; tó kún fún sùúrù àti ìpamọ́ra; ìwà tútù ninu ohun gbogbo; aláápọn ní pípa àwọn òfin Ọlọrun mọ́ nígbà gbogbo; kún fún ìgbàgbọ́, ìrètí, àti ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́; tí ó sì pọ̀ sí i nínú àwọn iṣẹ́ rere.22 À ntiraka làti dàbíi Jésù Krístì.

Mo jẹ́rìí pé gẹ́gẹ́ bí Ìjọ Krístì, a jẹ́ ọ̀nà èyí tí “Olùgbàlà àti Olùràpadà wa, Jésù Krístì, yíò gbà láti ṣe díẹ̀ nínú àwọn iṣẹ́ alágbára Rẹ̀ nísisìyí àti nígbà tí Ó bá padà wa,”23

Olúwa ti wípé:

“Kiyesĩ, Emi o mú iṣẹ mi yá ni àkokò rẹ̀.

“Àti pé mo fún yín ní… òfin kan pé kí ẹ kó ara yín jọ papọ̀, kí ẹ sì ṣètò ara yín, kí ẹ múra arayín sílẹ̀, kí ẹ ṣe ara yín ni mímọ́; bẹ̃ni, sọ ọkàn nyin di mímọ́, kí ẹ sì wẹ ọwọ́ ati ẹsẹ̀ yín mọ́ níwájú mi, kí nlè sọ yín di mímọ́.”24

Njẹ́ kí á dáhùn sí ìpè àtọ̀runwá yii kí a sì fi ayọ̀ péjọ, ṣètò, múra, àti sọ ara wa di mímọ́ ni àdúrà ìrẹ̀lẹ̀ mi ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.