Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ìbáṣepọ̀ Wa Pẹ̀lú Ọlọ́run
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2022


Ìbáṣepọ̀ Wa Pẹ̀lú Ọlọ́run

Mo jẹ́ ẹ̀rí pé ohunkóhun tí ìrírí ara kíkú wa le jẹ́, a le gbẹ̀kẹ̀lé Ọlọ́run kí a sì rí ayọ̀ nínú Rẹ̀.

Bíi Jobù nínú Májẹ̀mu Láéláé, ní àkókò ìjìyà kan àwọn kan le ní ìmọ̀lára pé Ọlọ́run ti pa wọ́n tì. Nítorípé a mọ̀ pé Ọlọ́run ní agbára láti dènà tàbí mú èyíkéyi ìpọ́njú, a le jẹ́ dídánwò láti ṣàròyé bí Òun kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, bóyá ní bíbèèrè pé, “Bí Ọlọ́run kò bá ṣe ìrànlọ́wọ́ náà tí mo gbàdúrà fún, báwo ni èmi ó ṣe ní ìgbàgbọ́ nínú Rẹ̀?” Ní àkókò kan nínú àdánwò líle rẹ̀, Jobù olódodo sọ pé:

“Ẹ mọ̀ nígbànáà pé Ọlọ́run ti ṣe àìdára sí mi Òun sì ti na àwọ̀n rẹ̀ yí mi ká.

“Bí mo tilẹ̀ kígbe, ‘a ti ṣe àìdára sími!’ Èmi kò rí ìdáhùn; bí mo tilẹ̀ pè fún ìrànlọ́wọ́, kò sí ìdáláre.”2

Nínú ìdáhùn Rẹ̀ sí Jóbù, Ọlọ́run bèèrè pé: “Njẹ́ ìwọ ó dámi lẹ́bi pé kí ìwọ ó le jẹ́ olódodo bí?”2 Tàbí ní àwọn ọ̀rọ̀ míràn, “Àní njẹ́ ìwọ ó fi mí sínú àìdára náà bí? Njẹ́ ìwọ ọ́ dámi lẹ́bi kí ìwọ ó le jẹ́ dídáláre bí?”3 Jèhófà fi tipátipá rán Jóbù létí pé Òun ní gbogbo agbára àti gbogbo òye, àti pé Jóbù nínú ìrẹ̀lẹ̀ tó jìnlẹ̀ jùlọ gbà pé òun kò ní ohun kan àní tí ó súnmọ́ ìmọ̀, agbára, ài òdodo Ọlọ́run òun kò sì le dúró nínú ìdájọ́ Alágbára Jùlọ:

“Èmi mọ̀ pé ìwọ́ lè ṣe ohun gbogbo,” ni ó sọ, “àti pé kò sí èrò kan tí a lè fàsẹ́hìn kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.

“… Èmi sọ èyí tí èmi kò mọ̀; àwọn ohun tí o ṣe ìyanu jọjọ fún mi, tí èmi kò mọ̀. …

“Njẹ́ nítorínà èmi korira ara mí, mo sì ronúpìwàdà nínú èkuru àti eérú.”4

Ní ìgbẹ̀hìn, Jóbù ní ànfààní láti rí Olúwa, àti pé “Olúwa bùkún opin ìgbẹ̀hìn Jóbù ju ìbẹ̀rẹ̀ lọ.”5

O jẹ́ ìwà àìmoye fún wa pẹ̀lú ìriran kúkúrú ti-ara kíkú wa láti rò pé a le dá Ọlọ́run lẹ́jọ́, láti rò pé, fún àpẹrẹ, “Inú mi kò dún, nítorínáà ó nílati jẹ́ pé Ọlọ́run nṣe àìdára kan.” Sí wa, àwa ọmọ kíkú Rẹ̀ nínú ayé tó ti ṣubú, tí ó mọ ohun tó kéré púpọ̀ nípa ti ìkọjá, ti lọ́wọ́lọ́wọ́, àti ti ọjọ́ iwájú, Ó kéde, “Ohun gbogbo jẹ́ lọ́wọ́lọ́wọ́ pẹ̀lú èmi, nítorítí mo mọ gbogbo wọn.”6 Jákọ́bù fi ọgbọ́n kìlọ̀ pé: “Máṣe lépa láti gba Olúwa ní ìmọ̀ràn, ṣùgbọ́n láti gba ìmọ̀ràn ní ọwọ́ rẹ̀. Nítorí kíyèsi, ẹ̀yin tikara yín mọ̀ pé ó nfúnni ní ìmọ̀ràn nínú ọgbọn, àti nínú àìṣègbè, àti nínú ọ̀pọ̀ ãnú, lórí gbogbo àwọn iṣẹ́ rẹ̀.”7

Àwọn kan ní òye òdì sí àwọn ìlérí Ọlọ́run láti túmọ̀ sí pé ìgbọ́ràn sí Òun nmú àwọn àbájáde pàtó wa lóri ètò kan tí a ti làkalẹ̀. Wọ́n le rò pé, “Bí mo bá sìn bíi ìránṣẹ́ ìhìnrere ní kíkún pẹ̀lú aápọn, Ọlọ́run yío bùkún mi pẹ̀lú ìgbéyàwọ́ àti àwọn ọmọ ìdúnnú,” tàbí “Bí mo bá yẹra fún síṣe iṣẹ́ ilé ìwé ní Ọjọ́ Ìsinmi, Ọlọ́run yío bùkún mi pẹ̀lú àwọn èsì ìdánwò rere,” tàbí “Bí mo bá san ìdámẹ́wàá, Ọlọ́run yío bùkún mi pẹ̀lú iṣẹ́ tí mo ti nfẹ́ náà.” Bí ìgbé ayé kò bá rí bíi ọ̀nà yí gẹ́gẹ́ tàbí ní ìbámu sí ìrètí ìwọ̀n àkókò kan, wọn le ní ìmọ̀lára ìjákulẹ̀ láti ọwọ́ Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n àwọn nkan kò rí ohun èlò ẹ̀rọ tó bẹ́ẹ̀ nínú ètò ọ̀rọ̀ ajé ti ọ̀run. Kò yẹ kí a rò nípa ètò Ọlọ́run bíi ẹrọ ìtajà ti kọ́símíkì níbití a ti (i) nyan ìbùkún kan tí a ní ìfẹ́ inú sí, (ii) nfi iye àwọn iṣẹ́ rere tí a nílò sínú rẹ̀, àti (iii) tí ohun di gbígbà lójú ẹ̀sẹ̀.8

Nítòótọ́ Ọlọ́run yío bu ọlá fún àwọn májẹ̀mú àti àwọn ìlérí Rẹ̀ fún ẹnìkọ̀ọ̀kan wa. A kò nílò láti dààmú nípa èyí.9 Agbára ìṣètùtù ti Jésù Krístì—ẹnití ó sọ̀kalẹ̀ sí abẹ́ ohun gbogbo àti nígbànáà tí ó gùnkè lọ sókè10 àti ẹni tí ó ní gbogbo agbára ní ọ̀run àti ní ilẹ̀ ayé11—ríi dájú pé Ọlọ́run le ṣe yío sì mú àwọn ìlérí Rẹ̀ ṣẹ Ó ṣe kókó pé kí a bu ọlá fún kí a sì gbọ́ràn sí àwọn òfin Rẹ̀, ṣùgbọ́n kìí ṣe gbogbo ìbùkún tí a ti so mọ́ ìgbọràn sí òfin12 ni a ti ṣe, ya àwóràn rẹ̀, tàbí fi àkókò sí ní ìbámu sí àwọn ìrètí wa. A nṣe bí a ti lè ṣe dára tó ṣùgbọ́n a gbọdọ̀ fi àmójútó àwọn ìbùkún sílẹ̀ fún Òun, ní ti ara àti ti ẹ̀mí.

Ààrẹ Brigham Young ṣe àlàyé pé ìgbàgbọ́ òun kò jẹ́ kíkọ́ lé orí àwọn àbájáde tàbí àwọn ìbùkún kan pàtó ṣùgbọ́n lóri jíjẹ́ ẹ̀rí rẹ̀ nípa àti ìbáṣepọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú Jésù Krístì. Ó sọ pé: Ìgbàgbọ́ mi kò jẹ́ fífi lé orí iṣẹ́ síṣe Olúwa lórí àwọn erékùsù òkun, lórí pé ó mú àwọn ènìyàn náà wá síhĩn, … tàbí lórí àwọn ojúrere tí ó fifún àwọn ènìyàn yí tàbí lórí àwọn ènìyàn wọnnì, bẹ́ẹ̀ni kìí ṣe lórí bóyá a jẹ́ alábùkún fún tàbí a kò jẹ́ alábùkún fún, ṣùgbọ́n ìgbàgbọ́ mi jẹ́ fífi lé Olúwa Jésù Krístì, àti ìmọ̀ mi tí mo ti gbà láti ọ̀dọ̀ rẹ̀.”13

Ìrònúpìwàdà àti ìgbọràn wa, àwọn iṣẹ́-ìsìn àti ìrúbọ wa ṣe pàtàkì. A fẹ́ wà lára àwọn wọnnì tí Ether ṣe àpèjúwe wọn bíi “fífi ìgbà gbogbo pọ̀ síi nínú àwọn iṣẹ́ rere.”14 Ṣùgbọ́n púpọ̀ rẹ̀ kìí ṣe nítorí àwọn talí díẹ̀ tí a pamọ́ nínú àwọn ìwé ìṣirò sẹ̀lẹ́stíà. Àwọn nkan wọ̀nyí ṣe pàtàkì nítorípé wọ́n fi wá sí inú iṣẹ́ Ọlọ́run wọ́n sì jẹ́ ọ̀nà nípa èyítí a ndarapọ̀ pẹ̀lú Rẹ̀ nínú ìyípadà tiwa láti ènìyàn ẹlẹ́ran ara sí ẹni mímọ́.15 Ohun tí Baba wa Ọrun fi sílẹ̀ fúnwa ni Ara Rẹ̀ àti Ọmọ Rẹ̀, ìbáṣepọ̀ tímọ́tímọ́ àti pẹ́títí pẹ̀lú Wọn nípasẹ̀ oore ọ̀fẹ́ àti ìlàjà ti, Jésù Krístì, Olùràpadà wa.

Awa ni ọmọ Ọlọ́run, tí a yàsọ́tọ̀ fún àìkú àti ìyè ayérayé. Àyànmọ́ wa ni láti jẹ́ ajogún Rẹ̀, “àjùmọ̀ jogún pẹ̀lú Krístì.”15 Baba wa ṣetán láti tọ́ ẹnikọ̀ọ̀kan wa ní ipa ọ̀nà Májẹ̀mú Rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìgbésẹ̀ tí a ti yàwòrán rẹ̀ sí ìnílò ẹnìkọ̀ọ̀kan wa tí a sì so mọ́ ètò Rẹ̀ fún ìdùnnú ìgbẹ̀hìn wa pẹ̀lú Rẹ̀. A lè fojúsọ́nà fún ìgbẹ́kẹ̀lé àti ìgbàgbọ́ tó ndàgbà síi nínú Baba àti Ọmọ, àti pípọ̀síi ìmọ̀lára ìfẹ́ Wọn, àti léraléra ìtùnú àti ìtọ́ni ti Ẹmí Mímọ́.

Àní bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ipa ọ̀nà yí kò le rọrùn fún ẹnikẹ́ni wa. Àtúnṣe púpọ̀jù wà tí a nílò fún un láti rọrùn. Jésù wí pé:

“Èmi ni àjàra tòótọ́, Baba mi sì ni olúṣọ́gbà.

“Gbogbo ẹka nínú mi tí kò bá so èso [Baba] a mú un kúrò: àti gbogbo ẹka tí ó bá so èso, òun a wẹ̀ ẹ́ mọ́, kí ó le so èso púpọ̀ síi.”16

Àwọn ìlànà ìwẹ̀mọ́ àti ìsọdimímọ́ tí Ọlọ́run darí di dandan kí ó jẹ́ dídunni àti pẹ̀lú ìrora ní àwọn ìgbà míràn Ní rírántí ọ̀rọ̀ Paulù, àwa jẹ́ “àjùmọ̀-jogún pẹ̀lú Krístì; bíóbáṣepé àwa bá a jìyàkí a sì le ṣe wá lógo pẹ̀lú rẹ̀.”17

Nítorínáà, ní ààrin iná atúnniṣe náà, dípò ìbínú sí Ọlọ́run, súnmọ́ Ọlọ́run síi. Ké pe Baba ní orúkọ Ọmọ. Rìn pẹ̀lú Wọn nínú Ẹmí, ní ọjọ́ sí ọjọ́. Gbà Wọ́n láàyè láàrin àkókò láti fi ìṣòtítọ́ Wọn hàn sí ọ. Wá láti mọ̀ Wọ́n nítòótọ́ àti nítòótọ́ láti mọ ara rẹ.18 Jẹ́kí Ọlọ́run Borí.19 Olùgbàlà ti tún mu dáwalójú pé:

“Fetísílẹ̀ sí i ẹnití ó jẹ́ alágbàwí pẹ̀lú Bàbá, ẹnití ó nbẹ̀bẹ̀ èrò yín níwájú rẹ̀—

“Ó sọ pé: Bàbá, kíyèsí àwọn ìjìyà àti ikú rẹ̀ ẹni náà tí kò ní ẹ̀ṣẹ̀ rárá, ẹnití inú rẹ dùn sí gidigidi, kíyèsí ẹ̀jẹ̀ ọmọkùnrin rẹ èyí tí a ta sílẹ̀, ẹ̀jẹ̀ ẹni náà tí ìwọ fifúnni kí ìwọ fúnrarẹ lè jẹ́ síṣelógo;

Nítorínáà, Bàbá, dá àwọn arákùnrin mi [ati àwọn arábìnrin mi] wọ̀nyí tí wọ́n gbàgbọ́ ní orúkọ mi sí, kí wọ́n ó lè wá sí ọ́dọ̀ mi kí wọ́n ó sì ní ìyè ayérayé20

Ẹ rò àwọn àpẹrẹ díẹ̀ ti olódodo àwọn ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run, pẹ̀lú ìdánilójú pé àwọn ìbùkún Rẹ̀ tí a ṣèlérí yío wà lórí ní yíyè tàbí ní kíkú. Ìgbàgbọ́ wọn kò jẹ́ lórí ohun tí Ọlọ́run ṣe tàbí tí kò ṣe nínú ipò tàbí àkókò nínú ìgbà kan pàtó, ṣùgbọ́n lórí mímọ̀ Ọ bíi Baba wọn onínú rere àti Jésù Krístì bíi olódodo Olùràpadà wọn.

Nígbàtí a fẹ́ fi Abrahamù rúbọ láti ọwọ́ àlùfáà Ẹlikánà ará Egíptì náà, ó kígbe jáde sí Ọlọ́run láti gbà á là, Ọlọ́run sì ṣe bẹ́ẹ̀.22 Abrhámù gbé ìgbésí ayé láti di baba àwọn olódodo nípasẹ̀ irú ọmọ ẹnítí gbogbo àwọn ẹbí ti ilẹ̀ ayé yío di bíbùkún fún.23 Ṣaájú, lórí pẹpẹ yí kannáà gan, àlùfáà Ẹlikánà yi kannáà ti fi àwọn wúndía mẹ́ta rúbọ àwọn tí “nítorí ìwà rere wọn … kí yío foríbalẹ̀ láti sìn àwọn ọlọ́run igi tàbí ti òkúta.”24 Wọ́n kú níbẹ̀ bíi ajẹ́rìíkú.

Jósẹ́fù àtijọ́, tí a tà sí oko ẹrú bíi ọ̀dọ́ láti ọwọ́ àwọn arákùnrin rẹ̀, nínú ìrora rẹ̀ ó kọjú sí Ọlọ́run. Díẹ̀díẹ̀, ó gòkè sí ipò olókìkí nínú ilé ọ̀gá rẹ̀ ní Egíptì ṣùgbọ́n nígbànáà gbogbo ìtẹ̀síwájú rẹ̀ di gbígbà kúrò nítorí àwọn ẹ̀sùn irọ́ ti aya Pọ́tífà. Joseph ti lè rò pé, “Ẹ̀wọ̀n ni ohun tí mo wá rí gbà fún pípa àwọn òfin ìparaẹnimọ́ mọ́.” Dípò bẹ́ẹ̀ ó tẹ̀síwájú láti yípadà sí Ọlọ́run ó sì yege nínú ẹ̀wọ̀n. Jósẹ́fù jìyà ìjákulẹ̀ síwájú síi nígbàtí ara túbú tí ó bá ṣọ̀rẹ́, láìka ìlérí rẹ̀ sí Jósẹ́fù, gbàgbé ohun gbogbo nípa rẹ̀, lẹ́hìn tí a ti mú un padàbọ̀ sí ipò ìgbẹ́kẹ̀lé nínú kóòtù ti Fáráò. Ní ìgbẹ̀hìn, bí ẹ ti mọ̀, Olúwa dá síi láti fi Jósẹ́fù sí ipò gíga jùlọ ti ìgbẹ́kẹ̀lé àti agbára tí ó tẹ̀lé ti Fáráò, tí ó fún Jósẹ́fù ní agbára láti gba ìdílé Israẹlì là. Dájúdájú Jósẹ́fù le jẹ́rí, “pé ohun gbogbo nṣiṣẹ́ pọ̀ fún rere sí àwọn tí wọ́n fẹ́ Ọlọ́run.”25

Abínádì ní ẹ̀rò láti mú àṣẹ àtọ̀runwá rẹ̀ ṣe ní ọ̀nàkọnà. “Èmi parí ọ̀rọ̀ mi;” ni ó sọ, “àti nígbànáà kò já mọ́ ohun kan [ohunkóhun tó bá ṣẹlẹ̀ sí mi], bí ó bá rí bẹ́ẹ̀ pé mo di gbígbàlà.”26 A kò dá a sí lọ́wọ́ ikú ajẹ́ríkú, ṣùgbọ́n dájúdájú òun di gbígbàlà ní ìjọba Ọlọ́run, àti pé ẹni iyebíye kan tí ó yí lọ́kàn padà, Alma, yí ipa ìtàn àwọn ará Néfì padà ní dídarí sí títí dé wíwá Krístì.

Almà àti Amúlẹ́kì ni a tú sílẹ̀ kúrò nínú ẹ̀wọ̀n ní Ammonihà ní ìdáhùn sí ẹ̀bẹ̀ wọn, àwọn tó nṣe inúnibíni sí wọn ni a sì pa.27 Ṣùgbọ́n, ṣaájú, àwọn tó nṣe inúnibíni wọ̀nyí kannáà ti ju àwọn obìnrin onígbàgbọ́ àti àwọn ọmọ wọn sínú iná tí njó. Almà, bí ó ti nrí iran burúkú náà nínú ìrora, ni a dá lẹ́kun nípasẹ̀ Ẹmi láti máṣe lo agbára Ọlọ́run láti “gbà wọ́n kúrò nínú iná náà”25 pé kí a lè gbà wọ́n sókè sí Ọlọ́run nínú ògo.26

Wòlíì Joseph Smith jẹ̀rora nínú ẹ̀wọ̀n ní Liberty, Missouri, láìlágbára láti ran àwọn Ènìyàn Mímọ́ lọ́wọ́ bí wọ́n ti di kíkójọ àti lílé kúrò ní àwọn ibùgbé wọn nínú otútù kíkorò ti àkókò ọ̀rinrin. “Áà Ọlọ́run, níbo ni ìwọ wà?” Joseph kígbe. “Yíò ti pẹ́ tó tí ọwọ́ rẹ yíò jẹ́ dídá dúró?”31 Ní ìfèsì, Olúwa ṣe ìlérí: “Ọtá rẹ àti àwọn ìpọ́njú rẹ yíò wà ṣùgbọ́n fún àkókò kékeré; àti nígbànáà, bí ìwọ bá faradà á dáradára, Ọlọ́run yíò gbé ọ ga lókè. … Ìwọ kò tíì dàbí Jóbù síbẹ̀.”31

Ní ìparí, Joseph le kéde pẹ̀lú Jóbù, “Bí [Ọlọ́run] tilẹ̀ pa mí, síbẹ̀ ni èmi ó ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú rẹ̀.”33

Alàgbà Brook P. Hales sọ ìtàn Arábìnrin Patricia Parkinson ẹnití a bí pẹ̀lú ìríran ojú dáradára ṣùgbọ́n tí ó di afọ́jú ẹni ọdún mọ́kànlá.

Alàgbà Hales sọ pé: “Mo ti mọ Pat fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún mo sì sọ fún un láìpẹ́ yí pé mo fẹ́ràn bí ó ti máa nfi gbogbo ìgbà wà pẹ̀lú èrò rere àti ìdùnnú. Ó fèsì pé, ‘Ó dára, ìwọ kò tíì wà nílé pẹ̀lú mi, àbí o ti ṣe bẹ́ẹ̀? Mo ní àwọn àkókò mi. Mo ní ohun tí a le pè ní àwọn ìjakadì lile ti ìrẹ̀wẹ̀sì, mo sì ti sunkún púpọ̀. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ó fi kún, ‘Láti ìgbà tí mo ti bẹ̀rẹ̀ sí pàdánù ìriran ojú mi, ó ṣe àjèjì, ṣùgbọ́n mo mọ̀ pé Baba Ọrun àti Olùgbàlà wà pẹ̀lú ẹbí mi àti èmi. Sí àwọn tí wọn nbi mí lèèrè bí mo bá nbínú nítorípé èmi ò riran, mo nfèsì pé, ‘Tani èmi ó bínú sí? Baba Ọrun wà nínú èyí pẹ̀lú mi; èmi kò dá nikan wà. Ó wà pẹ̀lú mi ní gbogbo ìgbà.”34

Ní ìparí, ó jẹ́ pé ìbùkún ti ìbáṣepọ̀ tímọ́tímọ́ àti pẹ́títí pẹ̀lú Baba àti Ọmọ ni a nlépa. Ó nṣe gbogbo ìyàtọ̀ àti pé títí ayérayé ni ó yẹ fún iye rẹ̀. A ó jẹ́ri pẹ̀lú Páùlù “pé àwọn ìjìyà ti àkókò [kíkú] lọ́wọ́lọ́wọ́ yi kò yẹ láti ṣe àfiwé pẹ̀lú ògo èyí tí a ó fi hàn nínú wá.”35 Mo jẹ́ ẹ̀rí pé ohunkóhun tí ìrírí ara kíkú wa le jẹ́, a le gbẹ̀kẹ̀lé Ọlọ́run kí a sì rí ayọ̀ nínú Rẹ̀.

“Fi gbogbo àyà rẹ gbẹ́kẹ̀lé Olúwa; másì ṣe tẹ̀ sí ìmọ̀ ara rẹ.

“Mọ̀ọ́ ní gbogbo ọ̀nà rẹ, òun ó sì máa tọ ipa-ọ̀nà rẹ.”35

Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.