Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Gbé Ọkàn Rẹ Sókè Kí O sì Yọ̀
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2022


Gbé Ọkàn Rẹ Sókè Kí O sì Yọ̀

A bí wa ní àkókò yìí fún èrèdí àtọ̀runwá kan, ìkójọpọ̀ Ísráẹ́lì

Ní bíbá Thomas B. Marsh sọ̀rọ̀, ẹnití ó yí ọkàn padà láìpẹ́, Olúwa sọ pẹ̀lú ìgbani-níyànjú pé, “Gbé ọkàn rẹ sókè kí o sì yọ̀, nítorí wákàtí iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ ti dé” ((Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 31:3)).

Mo gbàgbọ́ pé ìfipè yí lè ṣiṣẹ́ bíi ìmísí fún gbogbo àwọn ọmọ Ìjọ. Lẹ́hìnnáà, ọ̀kọ̀ọ̀kan wa ti gbà láti ọ̀dọ̀ Bàbá wa Ọ̀run iṣẹ́ ìránṣẹ́ ti kíkójọpọ̀ Ísráẹ́lì ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì ìbòjú náà.

“Apejọ náà,” Ààrẹ Russell M. Nelson ti sọ, “jẹ́ ohun tó ṣe pàtàkì jùlọ tó nṣẹlẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé lónìí. Kò sí ohun míràn tí a lè fi wé títóbi rẹ̀, kò sí ohun míràn tí a lè fi wé pàtàkì rẹ̀, kò sí ohun míràn tí a lè fi wé ọlánlá rẹ̀.”1

Dájúdájú, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìdí yíyẹ wà ní àgbáyé. Kò ṣeéṣe láti dárúkọ gbogbo wọn. Ṣùgbọ́n njẹ́ ìwọ kì yíò fẹ́ láti kópa nínú ìdí nlá kan láarin àrọ́wọ́tó rẹ àti níbití ìlọ́wọ́sí rẹ ti mú ìyàtọ̀ pàtàkì wá? Ìkójọ náà mú ìyàtọ̀ ayérayé wá sí gbogbo ènìyàn. Àwọn ènìyàn ní gbogbo ọjọ́-orí lè kópa nínú iṣẹ́ yi láìbìkítà àwọn ipò wọn àti ibi tí wọn ngbé. Kò sí iṣẹ́ miràn ní àgbáyé tí ó kónipọ̀ jùlọ.

Ní sísọ̀rọ̀ nípàtó sí àwọn ọ̀dọ́, Ààrẹ Nelson sọ pé: “Baba Wa Ọrun ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹ̀mí Rẹ̀ tó lọ́lá jùlọ pamọ́—bóyá… àwọn ikọ̀ Rẹ̀ tí ó dára jùlọ—fún ipele ìparí yi. Àwọn ọlọ́lá ẹ̀mí wọnnì—àwọn òṣèré tí wọ́n dára jùlọ wọnnì, àwọn akíkanjú wọnnì—ni ẹ̀yin!”2

Bẹ́ẹ̀ni, a ti pèsè yín sílẹ̀ ṣáájú ìgbà ayé yìí, a sì bí yín nísisìyìí láti kópa nínú iṣẹ́ nlá ti ìkójọ Ísráẹ́lì ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì ìbòjú ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn wọ̀nyí (wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 138:53–56).

Kinníṣe ti iṣẹ́ yí ṣe pàtàkì? Nítorípé ìtóye àwọn ẹ̀mí jẹ́ títóbi ní ojú Ọlọ́run” (Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 18:10). Nítorì ẹnìkẹ́ni tí ó bá sì gbàgbọ́ nínú mi, tí a sì rì bọmi, òun ni a ó gbàlà; àti … yíò sì jogún ìjọba Ọlọ́run” (3 Nèfì 11:33). Síwájú sí i, “gbogbo ohun tí Baba ní ni a ó fi fún ” àwọn tí wọ́n gba àwọn ìlànà Rẹ̀ tí wọ́n sì pa àwọn májẹ̀mú Rẹ̀ mọ́.Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 84:38 Ní àfikún, “àwọn alágbàṣe kò tó nkan”Lúkù 10:2

Nínú Ìjọ ti Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́ Ìkẹhìn nìkan ni a ti rí agbára, àṣẹ, àti ọ̀nà láti fi irú ìbùkún bẹ́ẹ̀ fún àwọn ẹlòmíràn, yálà alààyè tàbí òkú.

Bí Ààrẹ Nelson ti sọ: “Ìgbàkugbà tí ẹ bá ṣe ohunkóhun tí ó ran ẹnìkan lọ́wọ́—ní èyíkéyí ẹ̀gbẹ́ ti ìbòjú—gbé ìgbésẹ̀ kan sí ìhà dídá àwọn májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run àti gbígba àwọn ìlànà ìrìbọmi àti ti tẹ́mpìlì tó ṣe kókó sí wọn, o nṣe ìrànwọ́ láti kó Ísráẹ́lì jọ. Ó jẹ́ rírọrùn bí èyí.”3

Nígbàtí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀nà wà láti ṣèrànwọ́ nínú ìkójọ náà, mo fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa ọ̀kan ní pàtàkì: sísìn bíi ìránṣẹ́ ìhìnrere ìgbà-kíkún. Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ yín, èyí yíò túmọ̀ sí jíjẹ́ ìránṣẹ́ ìhìnrere tó ńkọ́ni. Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹlòmíràn, yíò túmọ̀ sí jíjẹ́ ìránṣẹ́ ìhìnrere tó nṣe iṣẹ́ ìsìn. Ṣùgbọ́n ayé ngbìyànjú láti dààmú ọkàn àwọn ọ̀dọ́ kúrò nínú ojúṣe mímọ́ jùlọ yi ní lìlo ìbẹ̀rù àti àìláàbò.

Díẹ̀ nínú àwọn ìdààmú-ọkàn miran lè jẹ́ nípa ìrírí àjàkálẹ̀-àrùn kan, fífi iṣẹ́ tó dára sílẹ̀, pípa ètò ẹ̀kọ́ tì, tàbí níní ìfẹ́ ní pàtó sí ẹnìkan pẹ̀lú ìfẹràn ìfaramọ́ra. Gbogbo ènìyàn yíò ní ètò àwọn ìpèníjà tirẹ̀. Irú àwọn ìdààmú-ọkàn bẹ́ẹ̀ lè wáyé ní àkokò gan-an tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe iṣẹ́ ìsìn Olúwa, àwọn yíyàn tó dà bíi pé ó ṣe kedere lẹ́hìnwá kì í fi bẹ́ẹ̀ rọrùn ní àkokò náà.

Mo mọ̀ ìdààmú ọkàn irú ọ̀dọ́ kan bẹ́ẹ̀ láti inú ìrírí. Nígbàtí mò nmúra láti lọ fún iṣẹ́ ìránṣẹ́ mi, àwọn ipa ìyàlẹ́nu díẹ̀ gbìyànjú láti mú mi rẹ̀wẹ̀sì. Ọ̀kán jẹ́ dókítà ehín mi. Nígbàtí ó mọ̀ pé yíyàn mí ni láti jẹ́ ìránṣẹ́ ìhìnrere, ó gbìyànjú láti yí mi lọ́kàn-padà kúrò ní sísìn. Èmi kò ti ní èrò tó kéré jù pé dókítà ehín mi lòdì sí Ìjọ.

Ìdádúró ti ètò ẹ̀kọ̀ mi tún díjú bákannáà. Nígbàtíi mo bèèrè fún gáfárà àìsinílé ọdún mèji kúrò nínú ètò-ẹ̀kọ́ gíga unifásítì mi, a sọ fún mi pé kò ṣeéṣe. Èmi yíó pàdánù ààyè mi ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga yunifásítì náà ti èmi kò bá padà lẹ́hìn ọdún kan. Ní Brazil, èyí ṣe pàtàkì nítorípé òsùnwọ̀n kanṣoṣo fún ìgbaniwọlé nínú ètò ẹ̀kọ́ unifásítì ni ìdánwò kan tí ó nira púpọ̀ tí ó sì jẹ́ ìfigagbága.

Lẹ́hìn àtẹnumọ́ léraléra, wọ́n sọ fún mi pẹ̀lú ìlọ́ra pé lẹ́hìn àìsínílé fún ọdún kan, mo lè béèrè fún ìyọ̀nda lórí àwọn èrèdí àrà ọ̀tọ̀ kan. Ó ṣeéṣe kí ó jẹ́ fífọwọsi tabi bẹ́ẹ̀kọ́. Ẹ̀rú bà mí gidigidi ní ti èrò títún ìdánwò ìgbàniwọlé tí ó nira náà ṣe lẹ́hìn ọdún méjì kíkúrò níbi àwọn ẹ̀kọ́ mi.

Bákannáà mo ní ìfệ pàtàkì sí ọ̀dọ́mọbìnrin kan. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn ọ̀rẹ́ mi ni wọ́n pín irú ìfẹ́ kanáà. Mo ro nínú ara mi pé, “Tí mo bá lọ sí míṣọ̀n, mo nṣe nkan tó léwu.”

Ṣùgbọ́n Jésù Krístì Olúwa ni ìmísí mi nlá láti máṣe bẹ̀rù ọjọ́ iwájú bí mo ṣe tiraka láti sìn Ín pẹ̀lu gbogbo ọkàn mi.

Bákannáà Ó ní ojúṣe kan láti múṣẹ. Nínú ọ̀rọ̀ Rẹ̀, Ó ṣàlàyé pé, “Nítorí èmi sọ̀kalẹ̀ wá láti ọ̀run, kì í ṣe láti ṣe ìfẹ́ ti èmi tìkárami, bíkòṣe ìfẹ́ ti ẹnití ó rán mi” (Jòhánnù 6:38). Iṣẹ-iranṣẹ Rẹ ha sì rọrun bi? Dájúdájú bẹ́ẹ̀kọ́. Ìjìyà Rẹ̀, èyítí ó jẹ́ ipa-pàtàkì nínú iṣẹ́ ìránṣẹ Rẹ̀, mú Òun tìkárarẹ̀, àní Ọlọ́run, tí ó tóbi ju ohun gbogbo lọ, láti gbọn-rìrì nítorí ìrora, àti láti ṣẹ̀jẹ̀ nínú gbogbo ihò ara, àti láti jìyà ní ara àti ẹ̀mí—àti láti fẹ́ pé kí [Òun] máṣe mu nínú ago kíkorò náà, kí Ó sì fàsẹ́hìn—

“Bíótilẹ̀ríbẹ́ẹ̀, ògo ni fún Baba, àti pé [Òun] kópa Ó sì ṣe àṣeparí ìmúrasílẹ̀ [Rẹ̀] fún àwọn ọmọ ènìyàn” (Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 19:18–19).

Sísìn iṣẹ́ ìránṣẹ́ ní kíkún lè dàbí ohun tí ó ṣòro sí wa. Bóyá ó nbéèrè pé kí a fi àwọn ohun pàtàkì sílẹ̀ fún ìgbà dìẹ̀ kan. Dájúdájú Olúwa mọ èyí, Òun yíò sì wà ní ẹ̀gbẹ́ wa nígbà gbogbo.

Nítòótọ́, nínú ọ̀rọ̀ wọn sí àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere nínú Wàásù Ìhìnrere Mi, Àjọ Ààrẹ Ìkínní ṣèlérí, “Olúwa yíò san èrè yíò sì bùkún yín lọ́pọ̀lọpọ̀ bí ẹ ṣe ńfi ìrẹ̀lẹ̀ àti pẹ̀lú àdúràsìn Ín.”4 Òtítọ́ ni pé gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run ni a bùkúnfún, lọ́nà kan tàbí òmíràn, ṣùgbọ́n ìyàtọ̀ wà láàrin jíjẹ́ alábùkúnfún àti jíjẹ́ alábùkúnfún lọ́pọ̀lọpọ̀ nínú iṣẹ́ ìsìn Rẹ̀.

Rántí àwọn ìpèníjà tí mo rò pé mo kojú ṣáájú iṣẹ́ ìránṣẹ́ mi? Dókítà ehín mi? Mo rí òmíràn. Ilé-ẹ̀kọ́ unifásítí mi? Wọ́n ṣe ìyọ̀nda fún mi. Rántí ọ̀dọ́mọbìrin náà? Ó fẹ́ ọ̀kan lára ​​àwọn ọ̀rẹ́ mi àtàtà.

Ṣùgbọ́n Ọlọ́run bùkún fúnmi lọ́pọ̀lọpọ̀ nítọ̀ọ́tọ́. Mo sì kọ́ ẹ̀kọ́ pé àwọn ìbùkún Olúwa lè wá ní àwọn ọ̀nà tí ó yàtọ̀ sí bí a ti nretí. Lẹ́hìn gbogbo rẹ̀, àwọn èrò Rẹ̀ kìí ṣe àwọn èrò wa (wo Ìsàíàh 55:8–9).

Lára ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìbùkún tí Ó ti fifún mi fún sísìn Ìn bíi ìránṣẹ́ ìhìnrere ní kíkún ni ìgbàgbọ́ títóbi síi nínú Jésù Krístì àti Ètùtù Rẹ̀ àti ìmọ̀ àti ẹ̀rí tí ó lágbára síi nípa àwọn ìkọ́ni Rẹ̀, kí èmi ó má di fífi ìrọ̀rùn gbá sọnù nípasẹ̀ “gbogbo ẹ̀fúùfù ẹ̀kọ́” (Éfésù 4:14). Mo sọ ẹ̀rù mi nípa ìkọ́ni nù. Agbára mi láti kojú àwọn ìpèníjà pẹ̀lú ìrètí pọ̀ si. Nípa kíkíyèsí àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan àti àwọn ẹbí tí mo bá pàdé tàbí tí mo kọ́ bíi ìránṣẹ́ ìhìnrere, mo kẹ́kọ̀ọ́ pé àwọn ìkọ́ni Ọlọ́run jẹ́ òtítọ́ nígbàtí Ó sọ pé ẹ̀ṣẹ̀ kì í mú ayọ̀ tòótọ́ wá àti pé ìgbọràn sí àwọn òfin Ọlọ́run nràn wá lọ́wọ́ láti ṣe rere nípa ti ara àti nípa tẹ̀mí (wo Mòsíàh 2:41; Álmà 41:10). Mo sì kọ́ ẹ̀kọ̀ fún ara mi pé Ọlọ́run jẹ́ Ọlọ́run àwọn iṣẹ́ ìyanu (wo Mómónì 9).

Gbogbo nkan wọ̀nyi jẹ́ ohun èlò nínú ìgbáradì mi fún ìgbésí ayé àgbàlagbà, pẹ̀lú ìgbeyàwó tí ó ṣeéṣe àti ìṣe òbi, ìsìn ìjọ, àti ìgbésí aye iṣẹ́ àyànṣe àti ti agbègbe.

Lẹ́hìn iṣẹ́ ìránṣẹ́ mi, mo jẹ àǹfààní láti inú ìgboyà mi tí ó pọ̀ sí i láti fi ara mi hàn bí olõtọ́ atẹ̀lé Jésù Krístì àti Ìjọ Rẹ̀ ní gbogbo ipò àti sí gbogbo ènìyàn, àní ní ṣíṣe àjọpín ìhìnrere pẹ̀lú obìnrin arẹwà kan tí yíò di oníwà rere, ọlọ́gbọ́n, ìgbádùn, àti olufẹ ojúgbà ayeraye, ìtànsán oòrùn ti ìgbésí-ayé mi.

Bẹ́ẹ̀ni, Ọlọ́run ti bùkún mi lọ́pọ̀lọpọ̀, jìnnà rékọjá ohun tí mo fi inú rò, gẹ́gẹ́bí Òun yíò ti ṣe sí gbogbo àwọn tó bá “fi ìrẹ̀lẹ̀ àti pẹ̀lú àdúrà sìn Ín.” Mo dúpẹ́ títíayé sí Ọlọ́run fún ire Rẹ̀.

Iṣẹ́ ìránṣẹ́ mi tún ìgbésí ayé mi ṣe patapata. Mo kọ́ ẹ̀kọ́ pé ó yẹfún aápọn láti ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Ọlọ́run, láti ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ọgbọ́n àti àánú Rẹ̀ àti nínú àwọn ìlérí Rẹ̀. Lẹ́hìn gbogbo rẹ̀, Òun ni Baba wa, àti láìsí iyèméjì kankan, Ó fẹ́ ohun tí ó dára jùlọ fún wa.

Ẹ̀yin èwe jákèjádò àgbáyé, mo nawọ́ ìpè kannáà tí wòlíì wa, Ààrẹ Nelson, ti ṣe sí gbogbo yín “láti forúkọ sílẹ̀ nínú ẹgbẹ́ ológun ọ̀dọ́ ti Olúwa láti ṣèrànwọ́ láti kó Ísráẹ́lì jọ.” Ààrẹ Nelson sọ:

“Kò sí ohunkóhun ti àbájáde tí ó ga jùlọ. Pátápátá ohunkóhun.

“Àpéjọ eléyí yóò tumọ ohun gbogbosí yín. Èyí ni èrèdí tí a fi rán yín wá sí ilé áyé.”5

A bí wa ní àkókò yìí fún èrèdí àtọ̀runwá kan, ìkójọ Ísráẹ́lì Nígbàtí a bá sìn bíi ìránṣẹ́ ìhìnrere ní kíkún, aó máa pe wá níjà nígbàmíràn, ṣùgbọ́n Olúwa Fúnrarẹ̀ ni àwòkọ́ṣe àti amọ̀nà nlá wa nínú irú àwọn ipò bẹ́ẹ̀. Ó lóye ohun tí iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí ó nira jẹ́. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Rẹ̀, a le ṣe àwọn ohun líle. Òun yíò wà ní ẹ̀gbẹ́ wa (wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 84:88), Òun yíò sì bùkún wa púpọ̀ bí a ṣe nsìn Ìn pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀.

Nítorí gbogbo àwọn ìdí wọ̀nyí, kò yà mí lẹ́nu pé Olúwa sọ fún Thomas B. Marsh àti fún gbogbo wa pé, “Ẹ gbé ọkàn yín sókè kí ẹ sì yọ̀, nítorí wákàtí iṣẹ́ ìránṣẹ́ yín ti dé.” Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́

  1. Russell M. Nelson, “Hope of Israel” (worldwide youth devotional, June 3, 2018), HopeofIsrael.ChurchofJesusChrist.org.

  2. Russell M. Nelson, ”Ìrètí ti Ísráẹ́lì.“

  3. Russell M. Nelson, ”Ìrètí ti Ísráẹ́lì.“

  4. Wàásù Ìhìnrere Mi: Atọ́nà kan sí Iṣẹ́ Ìránṣẹ́ Ìhìnrere2019), v.

  5. Russell M. Nelson, ”Ìrètí ti Ísráẹ́lì.“