Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ǎwọn Májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run Nfúnni Lókun, Ndáàbò bò, ó sì Nmúra Wa sílẹ̀ fún Ògo Ayérayé.
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2022


Ǎwọn Májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run Nfúnni Lókun, Ndáàbò bò, ó sì Nmúra Wa sílẹ̀ fún Ògo Ayérayé.

Bí a ti nyàn láti dá àwọn májẹ̀mú àti láti pa wọ́n mọ́, a ó di alábùkún fún pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ìdùnnú síi nínú ayé yi àti ìyè ayérayé ológo tó nbọ̀.

Ẹyin arábìnrin, ó ti jẹ́ ayọ̀ tó láti péjọ nínú ìdàpọ̀ àwọn obìnrin káríayé. Bí àwọn obìnrin tí ó ndá tí ó sì npa àwọn májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run mọ́, a npín àwọn ìsopọ̀ ti ẹ̀mí tí ó nrànwá lọ́wọ́ láti pàdé àwọn ìpèníjà ti ọjọ́ wa tí ó sì npèsè wa fún Ìpadàbọ̀ Ẹẹ̀kejì ti Jésù Krístì. Àti pé, pípa àwọn májẹ̀mú wọnnì mọ́ ngbà wá láàyè láti jẹ́ obìnrin tó ní ipá, ẹnití ó le fa àwọn ẹlòmíràn sí ọ̀dọ̀ Olùgbàlà.

Àwọn tí wọ́n ti ṣe ìrìbọmi dá májẹ̀mú ní ọjọ́ mánigbàgbé náà láti gba orúkọ Jésù Krístì sí orí wọn nípa dída ọmọ Ìjọ Rẹ̀ tí a múpadàbọ̀ sípò, láti máa rántí Rẹ̀ nígbàgbogbo, pa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́, àti láti sìn Ín dé òpin. Nígbàtí a bá ṣe àwọn ohun wọ̀nyí, Baba Ọrun ṣe ìlérí láti dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì àti láti fúnwa ní ojúgbà Ẹmí Mímọ́ nípasẹ̀ ìlànà ti ìfẹsẹ̀múlẹ̀. Àwọn ìbùkún wọ̀nyí mú wa bẹ̀rẹ̀ ní ipa ọ̀nà náà tí, a bá tẹ̀síwájú láti máa lọ síwájú kí a sì fi orí tìí dé òpin, yío fi ààyè gbà wá láti gbé pẹ̀lú Òun àti Ọmọ Rẹ̀ Jésù Krístì, nínú ijọba sẹ̀lẹ́stíà. Gbogbo ènìyàn tí a ti rìbọmi ní ìlérí àwọn ìbùkún àti ànfààní wọ̀nyí bí obìnrin tàbí ọkùnrin náà bá pa àwọn májẹ̀mú tí wọ́n ti ṣe ní ọjọ́ pàtàkì náà mọ́.

Àwọn tí wọ́n dá àwọn májẹ̀mú síwájú síi nínú tẹ́mpìlì ngba àwọn ìlérí tó lágbára tí ó dá lórí ìṣòtítọ́ araẹni. Pẹ̀lú ọ̀wọ̀ a nṣe ìlérí láti gbọ́ràn sí àwọn òfin Ọlọ́run, gbé ìgbé ayé ìhìnrere Jésù Krístì, jẹ́ oníwà mímọ́, àti pé a ó ya àkókò àti àwọn ẹ̀bùn wa sọ́tọ̀ sí Olúwa. Ní ìpadà, Ọlọ́run ṣe ìlérí àwọn ìbùkún ìyanu ní ayé yi àti ànfààní láti padà láti gbé pẹ̀lú Rẹ̀ títíláé.1 Nínú ìṣètò náà, a nfifúnni, tàbí fúnni-ní ẹ̀bùn pẹ̀lú, agbára láti mọ ìyàtọ̀ láàrin òtítọ́ àti àṣìṣe, láàrin títọ́ àti àìtọ́, nínú ọ̀gọ̀rọ̀ àwọn ohùn òdì tí ó sì ndani láàmú tó nrọ́ sí ọ̀dọ̀ wa láti gbogbo ìhà. Ó ti jẹ́ alágbára ẹ̀bùn kan tó!

Ní ìmúrasílẹ̀ fún ìṣẹ̀lẹ̀ náà, ìyá mi àti àwọn arábìnrin Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n ti ní ìrírí rànmí lọ́wọ́ láti ṣe àṣàyàn àwọn ohun èlò tí èmi ó nílò, pẹ̀lú aṣọ ayẹyẹ rírẹwà kan. Ṣùgbọ́n ìmúrasílẹ̀ pàtàkì jùlọ ti wá àní ṣaájú kí a tó mọ ohun tí mo fẹ́ wọ̀. Lẹ́hìn fífi ọ̀rọ̀ wámi lẹ́nuwò láti pinnu bí mo bá yẹ, bíṣọ́pù mi ṣe àlàyé àwọn májẹ̀mú tí wọ́n nretí mi láti dá nínú ile Olúwa náà. Àláyé pẹ̀lẹ́kùtù rẹ̀ fúnmi ní ààyè láti ronú nípa àti láti múrasílẹ̀ láti tẹ́wọ́gba ojúṣe náà ti dídá àwọn májẹ̀mú wọnnì.

Nígbàtí ọjọ́ náà dé, mo kópa nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀wọ̀ náà pẹ̀lú ìmọ̀lára ìmoore àti àlàáfíà. Àní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi kò ní òye kíkún ti ṣíṣe pàtàkì àwọn májẹ̀mú tí mo dá ní ọjọ́ náà, mo mọ̀ pé mo jẹ́ sísopọ̀ mọ́ Ọlọ́run nípasẹ̀ àwọn májẹ̀mú wọnnì, a sì ṣe ìlérí àwọn ìbùkún kan fún mi tí èmi kò ní òye rẹ̀ tó bí mo bá pa àwọn májẹ̀mú náà mọ́. Láti ìgbà ìrírí àkọ́kọ́ náà nínú ilé Olúwa, a ti tẹ̀síwájú láti fi dámilójú pé pípa àwọn májẹ̀mú tí a ṣe pẹ̀lú Ọlọ́run mọ́ ngbà wá láàyè láti fà lé agbára Olúgbàlà, èyítí nfún wa lókun nínú àwọn àdánwò wa tí kò ṣeé yẹra fún, tí ó npèsè ààbò kúrò lọ́wọ́ ipá ọ̀tá, tí ó sì npèsè wa fún ògo ayérayé ti ọjọ́ iwájú.

Àwọn ìrírí ayé le yí láti pípani lẹ́rin sí bíba ọkàn jẹ́, láti inú ìkorò sí ológo. Ìrírí kọ̀ọ̀kan nrànwá lọ́wọ́ láti ní òye síi nípa ìfẹ́ àkótán ti Baba wa àti agbára wa láti yípadà nípasẹ̀ ẹ̀bùn oore ọ̀fẹ́ ti Olugbàlà. Pípa àwọn májẹ̀mú wa mọ́ nfi ààyè gba agbára Olùgbàlà láti wẹ̀ wá mọ́ bí a ti nkọ́ ẹ̀kọ́ nípasẹ̀ ìrírí—bóyá ó jẹ́ àṣìṣe ìdájọ́ kékeré tàbí ìkùnà nlá. Olùràpadà wa wà níbẹ̀ láti gbé wa nígbàtí a bá ṣubú a bá yípadà sí ọ̀d\\ Rẹ̀.

Àwòrán
Sísọ̀kalẹ̀ láti orí Òkè

Njẹ́ o ti dúró ní orí bèbè okúta gíga kan rí pẹ̀lú àwọn ìka ẹsẹ̀ rẹ ní bíbà lé ẹ̀gbẹ́ etí rẹ̀ àti ẹhìn rẹ sí ibi ọ̀gbun nísàlẹ̀? Nínú eré fífi okùn fò sọ̀kalẹ̀, àní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ mọ pé o wà ní sísopọ̀ pẹ̀lú ààbò mọ́ ètò àwọn okùn yíyi àti irinṣẹ́ kan tí yío gbé ọ kalẹ̀ láìléwu sí ìsàlẹ̀ ọ̀gbun náà, dídúró níbi ẹ̀gbẹ́ etí níbẹ̀ ṣì jẹ́ ìrírí tí ndààmú ọkàn. Gbígbé ẹsẹ̀ sọ́nà ẹ̀hìn kúrò lórí òkúta àti fífì dirodiro sí inú afẹ́fẹ́ nílò ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ìdákọ̀ró náà, èyítí a ti sopọ̀ mọ́ ohun èlò kan tí kò le yẹ̀. Ó gba ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ẹni náà tí yío ṣe àmúlò ìfàle sí okùn náà bí o ti nsọ̀kalẹ̀. Àti bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé irinṣẹ́ náà pèsè agbára díẹ̀ fún ọ láti darí àkókò ìsọ̀kalẹ̀ rẹ, o gbọdọ̀ ní ìfọkànbalẹ̀ pé ẹnìkejì rẹ kò ní jẹ́ kí o ṣubú.

Àwòrán
Sísọkalẹ̀ láti inú ìdákòró
Àwòrán
Ọ̀dọ́mọbìnrin nsọ̀kalẹ̀ láti orí òkè

Mo rántí kedere ṣíṣe eré fífi okùn fò sọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú ẹgbẹ́ àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin kan. Èmi ni àkọ́kọ́ nínú ẹgbẹ́ náà láti lọ. Bí mo ṣe gbé ẹsẹ̀ sẹ́hìn kúrò lórí òkúta, lójijì mo bẹ̀rẹ̀ sí ṣubú láì sí ìdarí. Pẹ̀lú ìmoore, okùn náà jáàkì ìsọ̀kalẹ̀ mi tó ti yárajù sì dá dúró. Bí mo ṣe mì dirodiro ní ìlàjì ọ̀nà ojú apáta págunpàgun ti okúta náà, mo fi ìtara gbàdúrà fún ẹnikẹ́ni tàbí ohunkóhun tí ó ndènà mí ní sísọ̀kalẹ̀ sí orí àwọn okúta náà nísàlẹ̀.

Lẹ́hìnwá, mo gbọ́ pé bóòtù ìdákọ̀ró kò dè dáradára, àti pé bí mo ṣe gbé ẹsẹ̀ kúrò ní etí bèbè náà, a jáàkì ẹnití ó nrẹ̀mísílẹ̀ láti ẹ̀hìn ó sì di fífà kíákíá sí ọ̀nà ibi etí bèbè okúta náà. Bákanbákan, ó sáré fi ẹsẹ̀ rẹ̀ mú àwọn òkúta kan. Ní gbígbé ara dúró ní ipò náà, òun le fi pẹ̀lú iṣẹ́ àṣekára rẹ̀ mí sílẹ̀, ọwọ́ lórí ọwọ́, pẹ̀lú okùn náà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi kò le rí i, mo mọ̀ pé ó nṣiṣẹ́ pẹ̀lú gbogbo agbára rẹ̀ láti gbàmí là kúrò nínú ewu síi níwájú. Ọrẹ́ míràn wà ní ìsàlẹ̀ ọ̀gbun náà, ní ìmúrasílẹ̀ láti gbé mi bí okùn náà bá kọ̀ láti dúró. Bí mo ṣe dé ibi àrọ́wọ́tó, ó gbá ìjánu mi mú ó sì rẹ̀ mí sílẹ̀ ní ìyókù ọ̀nà náà dé ilẹ̀.

Pẹ̀lú Jésù Krístì bíi ìdákọ̀ró àti ẹnìkejì wa pípé, a ní ìdánilójú ti okun ìfẹ́ni Rẹ̀ ní àwọn àkókò àdánwò àti ìtúsílẹ̀ mípasẹ̀ Rẹ̀ ní ìgbẹ̀hìn. Bí Ààrẹ M. Russell Ballard ti kọ́ni: “Ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run àti nínú Ọmọ Rẹ̀. Olúwa Jésù Krístì, ni … ìdákọ̀ró tí a gbọdọ̀ ní nínú ayé wa láti dì wá mú ṣinṣin ní àwọn àkókò ìdarúdàpọ̀ àti ìwà ibi ti ìbákẹ́gbẹ́. … Ìgbàgbọ́ wa … gbọdọ̀ wà nínú Jésù Krístì, ayé rẹ̀ àti ètùtù rẹ̀, àti nínú ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere rẹ̀ ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn.”2

Irinṣẹ́ ti ẹ̀mí tí ó npawámọ́ kúrò nínú kí a jẹ́ fífọ́ lórí àwọn òkuta ti ọ̀tá ni àwọn ẹ̀rí wa nípa Jésù Krístì àti àwọn májẹ̀mú tí a dá bíi ọmọ Ìjọ ti Olúwa. A lè gbáralé àwọn àtìlẹ́hìn wọ̀nyí láti tọ́ wa àti láti gbé wa dé ibi àìléwu. Bíi ẹnìkejì wa tí ó ṣetán, Olùgbàlà kò níi jẹ́kí a ṣubú kọjá àrọ́wọ́tó Rẹ̀. Àní nínú àwọn àkókò ìjìyà àti ìbànújẹ́ wa, Òun wà níbẹ̀ láti gbé wa sókè àti láti gbà wá níyànjú. Agbára Rẹ̀ bákannáà ma nrànwá lọ́wọ́ rí ìtúsílẹ̀ kúrò nínú ipá àwọn yíyàn ẹlòmíràn tí í ṣe ìparun. Ṣùgbọ́n, ọ̀kọ̀ọ̀kan wa gbọdọ̀ wọ ìjánu kí a sì ríi dájú pé àwọn kókó náà jẹ́ síso dáradára. A gbọdọ̀ yàn láti jẹ́ dídákọ̀ró sí ọ̀dọ̀ Olùgbàlà, láti jẹ́ sísopọ̀ mọ́ Òun nípa àwọn májẹ̀mú wa.3

Báwo ni a ṣe nfún ìdákọ̀ró náà lókun? A ngbàdúrà pẹ̀lú ọkàn ìrẹ̀lẹ̀ tó nwákiri, nṣe àṣàrò àti ronú jinlẹ̀ lórí àwọn ìwé mímọ́, ngba oúnjẹ Olúwa ní ọ̀sẹ̀-ọ̀sẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀mí ìrònúpìwàdà àti ọ̀wọ̀, ntiraka láti pa àwọn òfin mọ́, à sì ntẹ̀lé àwọn ìmọ̀ràn wòlíì. Bí a sì ti nmú àwọn iṣẹ́ ojúmọ́ wa ṣe nínú àwọn ọ̀nà “gígajù àti mímọ́jù” náà4 a ti sọ fún wa láti lọ́wọ́sí, a nní ìfarakọ́ra síi pẹ̀lú Olùgbàlà àti pé, ní àkókò kannáà, a nran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀.

Báwo ni “ọ̀nà gígajù àti mímọ́jù” náà ṣe rí? A ngbìyànjú láti gbé ìgbé ayé ìhìnrere nínú gbogbo ìbáṣepọ̀ wa pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. A nṣe ìtọ́jú fún àwọn tí wọ́n wà nínú àìní nípa síṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ ní tòótọ́, fífi ìfẹ́ hàn nípasẹ̀ iṣẹ́ ìsìn tó rọ̀rùn. A npín ìròhìn ayọ̀ ti ìhìnrere pẹ̀lú àwọn tí wọ́n nílò àlàáfíà àti okun nínú ayé wọn tí wọn kò sì “mọ ibití wọ́n ti le rí i.”5 A nṣiṣẹ́ láti mú àwọn ẹbí rẹ́pọ̀ fún ayérayé ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì ìkelè. Àti fún àwọn tí wọ́n ti dá àwọn májẹ̀mú nínú ilé Olúwa, bí Ààrẹ Russell M. Nelson ti ṣàláyé, “Olukúlùkù àgbàlagbà tí ó ti lọ sí tẹ́mpìlì yio máa wọ gámẹ́ntì mímọ́ ti oyè àlùfáà, [èyítí] … ó nránwa létí … láti rìn ní ipa ọ̀nà májẹ̀mú ní ojojúmọ́ ní ọ̀nà gígajù àti mímọ́jù kan.”6 Àwọn ìgbésẹ̀ wọ̀nyí kìí ṣe ohun síṣ ẹ̀kọ̀ọ̀kan ṣùgbọ́n wọ́n ṣe kókó sí ìdùnnú wa ojojúmọ́—àti ayọ̀ ayérayé.

Kò sí ohun tó ṣe pàtàkì jùlọ sí ìtẹ̀síwájú ayérayé ju pípa àwọn májẹ̀mú wa pẹ̀lú Ọlọ́run mọ́. Nígbàtí àwọn májẹ̀mú tẹ́mpìlì wa mímọ́ bá nṣiṣẹ́, a le ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ìdàpọ̀ aláyọ̀ pẹ̀lú àwọn olùfẹ́ ní ẹ̀gbẹ́ kejì ìbòjú. Ọmọ náà tàbí òbí tàbí ẹnìkejì tí ó ti fi ayé kíkú sílẹ̀ nretí pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ̀ lọ́kùnrin tàbí lóbìnrin pé ìwọ ó jẹ́ olõtọ́ sí àwọn májẹ̀mú èyítí ó sò yín papọ̀ títíláé. Bí a kò bá kọbi ara sí tàbí fi ọwọ́ yẹpẹrẹ mú àwọn májẹ̀mú wa pẹ̀lú Ọlọ́run, a nfi àwọn ìsopọ̀ ayérayé wọnnì sínú ewu. Ìsisìyí ni àkókò láti ronúpìwàdà, ṣe àtúnṣe, kí a sì gbìyànjú lẹ́ẹ̀kansíi.

Ìdùnnú máa nṣófo bí a bá ṣe pàṣípààrọ̀ àwọn ìbùkún ayọ̀ ayérayé fún ìtura ìgbà díẹ̀. Ohun tó wù kí ọjọ́ orí wa jẹ́, èyí jẹ́ òtítọ́ pátápátá: kọ́kọ́rọ́ sí ìdùnnú pípẹ́-títí ni gbígbé ìgbé ayé ìhìnrere Jésù Krístì àti pípa àwọn májẹ̀mú tí a ti dá mọ́. Wòlíì wa, Ààrẹ Nelson, ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé “ààbò wa ìgbẹ̀hìn àti ìdùnnú wa pípẹ́-títí kanṣoṣo wà nínú dídi ọ̀pá irin ti ìhìnrere Jésù Krístì tí a mú padàbọ̀ sípò mú, ní pípé pẹ̀lú àwọn májẹ̀mú àti àwọn ìlànà rẹ̀. Nígbàtí a bá ṣe bẹ́ẹ̀, a le lọ kiri la àwọn omi rírú já láìléwu nítorípé a ní ọ̀nà ìwọlé sí agbára Ọlọ́run.”7

Púpọ̀ lára wa nní ìrírí àwọn omi rírú. Bí a ti ndi títì kiri nípasẹ̀ àwọn ìgbì ọ̀tá tí a sì nfi ìgbàmíràn di fífọjú nípasẹ̀ ìṣàn àwọn omijé tí ó máa nwá nínú àwọn ìṣoro wọnnì, a le má mọ ìhà ibi tí a le darí ọkọ̀ ayé wa sí tàbí kí a rò pàapàa pé a kò ní okun láti dé èbúté. A tilẹ̀ le má ní èrò pé a ní okun láti mú wa dé èbúté. Rírántí ẹnití o jẹ́—àyànfẹ́ ọmọ Ọlọ́run kan—ìdí tí o fi wà lórí ilẹ̀ ayé, àti ìlépa rẹ ti gbígbé pẹ̀lú Ọlọ́run àti àwọn olólùfẹ́ rẹ nínú ayé sẹ̀lẹ́stíà le tún ìríran rẹ ṣe kí ó sì tọ́ka rẹ sí ìhà tí ó tọ́. Àní ní ààrin ìjì náà, ìmọ́lẹ̀ dídán kan wà láti fi ọ̀nà hàn wá. “Èmi ni ìmọ́lè náà tí ó ntàn nínú òkùnkùn,” ni Jésù kéde.8 A ní ìdánilójú ààbò nígbàtí a bá wò sí ìmọ́lẹ̀ Rẹ̀ tí a sì dúró lórí jíjẹ́ olõtọ́ sí àwọn májẹ̀mú wa.

Ó ti jẹ́ ànfààní láti pàdé àwọn obìnrin ti gbogbo ọjọ́ orí láti àyíká agbáyé tí wọ́n ngbé ní oríṣiríṣi àwọn ipò tí wọn npa àwọn májẹ̀mú wọn mọ́. Ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan, wọ́n nwò Olúwa àti wòlíì Rẹ̀ fún ìtọ́ni, dípò wíwò ìròhìn tó gbajúmọ̀. Láìka àwọn ìpèníjà olúkulùkù wọn sí àti àwọn ẹ̀kọ́ ti ayé tó ní ìpalára tí ó ngbìyànjú láti yí wọn lọ́kàn padà kúrò ní pípa àwọn májẹ̀mú wọn mọ́, wọ́n pinnu láti dúró ní ipa ọ̀nà tí ó darí sí ìyè ayérayé pẹ̀lú àwọn olùfẹ́ wọn. Wọ́n gbáralé ìlérí ti “gbogbo ohun tí Baba [náà] ní.”9 Àti ohunkóhun tí ọjọ́ orí yín jẹ́, olukúlùkù obìnrin tí ó ti dá àwọn májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run ní agbára láti gbé ìmọ́lẹ̀ Olúwa sókè kí ó sì darí àwọn ẹlòmíràn sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ nípa àpẹrẹ yín.10 Nípasẹ̀ pípa àwọn májẹ̀mú yín mọ́, Òun yío bùkún yín pẹ̀lú agbára oyè àlùfáà Rẹ̀ yío sì mú kí ó ṣeéṣe fún yín láti ní ipá ìjìnlẹ̀ lóri gbogbo àwọn tí ẹ bá ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú. Bí Ààre Nelson ti sọ, ẹ̀yin ni obìnrin tí yío mú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí wọ́n ti sọ ṣaájú ṣẹ!11

Ẹyin arábìnrin ọ̀wọ́n, ju gbogbo ohun míràn lọ, ẹ dúró ní ipa ọ̀nà májẹ̀mú sí Jésù Krístì! A ti jẹ́ alábùkúnfún láti wá sí ilẹ̀ ayé ní àkókò tí àwọn tẹ́mpìlì pọ̀ ní àgbáyé. Dídá àti pípa àwọn májẹ̀mú tẹ́mpìlì mọ́ wà ní àrọ́wọ́tó sí gbogbo ọmọ Ijọ tó yẹ. Ẹyin ọ̀dọ́ àgbà, ẹ kò nílò láti dúró di ìgbà ìgbéyàwó tàbí sísìn ní míṣọ̀n kan láti dá àwọn májẹ̀mú mímọ́ wọnnì. O le múrasílẹ̀ bíi ọ̀dọ́mọbìnrin láti gba ààbò àti okun tí àwọn májẹ̀mú tẹ́mpìlì nfúnni ní kété lẹ́hìn ọjọ́ orí ọdún méjìdínlógún bí o bá ti ṣetan tí o sì ní ìmọ̀lára ìfẹ́ inú láti bu ọlá fún àwọn májẹ̀mú tẹ́mpìlì wọnnì,11 Ẹyin tí ẹ ti gba àwọn ìbùkún tẹ́mpìlì tẹ́lẹ̀, ẹ máṣe jẹ́kí àwọn adaniláàmú tàbí àwọn ìdáámú fà yín kúrò nínú àwọn òtítọ́ ayérayé wọ̀nyí Ẹ ṣe àṣàrò kí ẹ sì béèrè lọ́wọ́ orísun tó ṣeé gbẹ́kẹ̀lé fún òye títóbi síi nípa bí síṣe-pàtàkì àti àwọn ìbùkún ti àwọn májẹ̀mú tí ẹ ti dá ṣe jẹ́ mímọ́ sí. Ẹ lọ sí tẹ́mpìlì déédé bí ẹ ti le ṣe sí kí ẹ sí fetísílẹ̀ sí Ẹmí. Ẹ ó ní ìmọ̀lára ọ̀tun ìdánilójú dídùn pé ẹ wà ní ipa ọ̀nà tí Olúwa. Ẹ ó rí ọ̀tun ìdánilójú dídùn pé ẹ wà ní ipa ọ̀nà tí Olúwa, ní fífún yín ní ìgboyà láti tẹ̀síwájú àti pẹ̀lú láti mú àwọn míràn wá pẹ̀lú yín.

Mo jẹ́ri pé bí a ṣe nyàn láti dá àwọn májẹ̀mú pẹ̀lú Baba Ọrun tí a sì ngba agbára Olùgbàlà láti pa wọ́n mọ́, a ó di alábùkún fún pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ìdùnnú nínú ayé yi ju bí a ti le rò nísisìyí lọ àti ìyè ayérayé ológo nínú ayé tó nbọ̀.12 Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.