Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Jésù Nṣe Ìwòsàn Èyíinì Tí O ti Fọ́
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2022


Jésù Nṣe Ìwòsàn Èyíinì Tí O ti Fọ́

Ó le wo àwọn ìbáṣepọ̀ bíbàjẹ́ pẹ̀lú Ọlọ́run sàn, àwọn ìbáṣepọ̀ bíbàjẹ́ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, àti àwọn apákan bíbàjẹ́ ti arawa.

Ní àwọn ọdún díẹ̀ sẹ́hìn, nígbàtí a wà níbi àpéjọ ẹbí kan, ọmọkùnrin ẹ̀gbọ́n ẹni ọdún mẹ́jọ nígbànáà William béèrè lọ́wọ́ ọmọkùnrin wa àgbà, Briton, bí yío bá fẹ́ láti gbá bọ́ọ̀lù pẹ̀lú òun. Briton fi ìtara fèsì pé, “Bẹ́ẹ̀ni! Èmi yío fẹ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀!” Lẹ́hìn tí wọ́n ti ngba fún ìgbà díẹ̀, bọ́ọ̀lù kan kúrò ní ọ̀dọ̀ Briton ó sì ṣèèsì fọ́ ọ̀kan lára àwọn apẹ àtijọ ti àwọn obí rẹ̀ àgbà.

Briton ní ìmọ̀lára burúkú. Bí ó ti bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀ tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kó àwọn èrúnrún fífọ́ náà, William rìn lọ sí ọ̀dọ̀ ìbátan rẹ̀ ó sì fi pẹ̀lú ìfẹ́ni gbá ẹ̀hìn rẹ̀ pẹ́pẹ́. Lẹ́hìnnáà ó tùú nínú, “Máṣè yọnu, Briton. Mo ti fọ́ nkan kan ní ilé Ìyá Àgbà àti Bàbá Àgbà lẹ́ẹ̀kan rí, Ìyá Àgbà sì fi apá rẹ̀ yíká mi ó sì wípé, ‘O dára, William. Ọdún márũn péré ni ọ́.’”

Sí èyítí Briton fèsì pé, “Ṣùgbọ́n, Wíllíam, ọdún mẹ́tàlélógún ni èmi!”

A le kọ́ ẹ̀kọ́ púpọ̀ láti inú àwọn ìwé mímọ́ nípa bí Olùgbàlà wa, Jésù Krístì, yío ṣe ràn wá lọ́wọ́, yanjú àwọn nkan inú ìgbé ayé wa tó ti fọ́ ní àṣeyọrí, láìka ọjọ́ orí wa sí. Ó le wo àwọn ìbáṣepọ̀ bíbàjẹ́ pẹ̀lú Ọlọ́run sàn, àwọn ìbáṣepọ̀ bíbàjẹ́ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, àti àwọn apákan bíbàjẹ́ ti arawa.

Àwọn Ìbáṣepọ̀ bíbàjẹ́ pẹ̀lú Ọlọ́run

Nígbàtí Olùgbàlà nkọ́ni nínú tẹ́mpìlì, a gbé obìnrin kan wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ láti ọwọ́ àwọn akọ̀wé àti àwọn Farisí. A kò mọ ìtàn rẹ̀ ní kíkún, ju pé wọ́n “mú un nínú ìwà panṣágà.”1 Léraléra ni àwọn ìwé mímọ́ nsọ kékeré díẹ̀ nìkan nínú ìgbé ayé ẹnìkan, àti pé lórí díẹ̀ náà, àwa nígbàmíràn nṣe láti gbéga tàbí dá lẹ́bi. Kò sí ìgbé ayé ẹnìkan tí a le ní òye rẹ̀ nípa àkókò títóbi kan tàbí àbámọ̀ ìjákulẹ̀ ìta gbangba kan. Èrèdí àwọn àkọsílẹ̀ inú ìwé mímọ́ wọ̀nyí ni láti ràn wá lọ́wọ́ láti ríi pé Krístì ni ìdáhùn nígbànáà, Òun sì ni ìdáhùn nísisìyí. Ó mọ ìtàn wa ní pípé àti ohun tí njẹwá níyà, àti pẹ̀lú àwọn agbára àti àwọn àìlera wa.

Ìfèsì Krístì sí ọmọbìnrin iyebíye ti Ọlọ́run yi ni “Bẹ́ẹ̀ni èmi kò dá ọ lẹ́bi: lọ, kí o má sì ṣe dẹ́ṣẹ̀ mọ́.”2 Ọnà míràn láti sọ pé “lọ, kí o má sì ṣe dẹ́ṣẹ̀ mọ́” le jẹ́ “jáde lọ kí o sì yípadà.” Olùgbàlà npè é láti ronúpìwàdà, láti yí ìhùwàsí rẹ̀, àwọn ìbákẹ́gbẹ́ rẹ̀, irú ìmọ̀lára tí ó ní nípa ara rẹ̀, ọkàn rẹ̀ padà

Nítorí Jésù Krístì, ìpinnu wa láti “jáde lọ kí a sì yípadà” le gbàwá láàyè bákannáà láti “jáde lọ kí a sì wòsàn,” nítorí Òun ni orísun ìwòsàn gbogbo ohun tí ó ti bàjẹ́ nínú ìgbésí ayé wa. Bí Onílàjà àti Alágbàwí nlá pẹ̀lú Baba, Krístì nṣe ìyàsímímọ́ àti ìmúpadàbọ̀sípò àwọn ìbáṣepọ̀ tó ti bàjẹ́—ní pàtàkì jùlọ àwọn ìbáṣepọ̀ wa pẹ̀lú Ọlọ́run.

Iyírọ̀padà Joseph Smith mú un ṣe kedere pé obìnrin náà ṣe títẹ̀lé ìmọ̀ràn Olùgbàlà ó sì yí ìgbé ayé rẹ̀ padà: “Obinrin náà sì yin Ọlọ́run lógo láti wákàtí náà lọ, ó sì gbàgbọ́ nínú orúkọ rẹ̀.”3 Ó ṣeni láànú pé a kò mọ orúkọ rẹ̀ tàbí àwọn ọ̀rọ̀ míràn nípa ayé rẹ̀ lẹ́hìn àkókò yí nítorípé yío jẹ́ pé ó ti gba ìpinnu, ìrẹ̀lẹ̀, àti ìgbàgbọ́ nlá nínú Olúwa Jésù Krístì fún un láti ronúpìwàdà kí ó sì yípadà. Ohun tí a mọ̀ ni pé ó jẹ́ obìnrin kan tí ó “gbàgbọ́ nínú orúkọ rẹ̀” pẹ̀lú níní òye pé òun kò tayọ àrọ́wọ́tó sí ìrúbọ Rẹ̀ àìlópin àti ti ayérayé.

Àwọn Ìbáṣepọ̀ bíbàjẹ́ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn

Nínú Luku ori 15 a ka òwe kan nípa ọkùnrin kan ẹnití ó ní àwọn ọmọkùnrin mejì. Ọmọkùnrin kékeré béèrè lọ́wọ́ baba rẹ̀ fún ogún ìní rẹ̀ ó sì mú ìrìn àjò rẹ̀ lọ sí orílẹ̀ èdè jíjìnnà kan, ó sì fi ohun ìní rẹ̀ ṣòfò pẹ̀lú ìgbé ayé aláriwo.4

“Nígbàtí ó sì ba gbogbo rẹ̀ jẹ́ tán, ìyàn nlá wá mú ní ilẹ̀ náà; ó sì bẹ̀rẹ̀ sí di aláìní.

“O sì lọ, ó sì da ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ ọlọ́rọ̀ kan ní ilẹ̀ náà; òun sì rán an lọ sí oko rẹ̀ lati tọjú ẹlẹ́dẹ̀.

“Ayọ ni ibá fi jẹ ounjẹ tí àwọn ẹlẹ́dẹ̀ njẹ ní àyẹyó: ẹnikẹ́ni kò sì fi fún un.

Ṣùgbọ́n nígbàtí ojú rẹ̀ wálẹ̀, ó ní, àwọn alágbàṣe baba mi melomelo ni ó ní oúnjẹ àjẹyó àti àjẹtì, èmi sì nkú fún ebi níhin!

Emi ó dìde, èmi ó sì tọ baba mi lọ, emi ó sì wí fún un pé, Baba, èmi ti dẹ́ṣẹ̀ sí ọ̀run, àti níwájú rẹ,

“Emi kò sì yẹ ní ẹnití a bá máa pè ní ọmọ rẹ mọ́: fi mi ṣe bí ọ̀kan nínú àwọn alágbàṣe rẹ.

“O sì dìde, ó sì tọ baba rẹ̀ lọ. Ṣùgbọ́n nígbàtí ó sì wà ní òkèrè, baba rẹ̀ rí i, àánú ṣe é, ó sì sáré, ó rọ̀ mọ́ ọ ní ọrùn, ó sì fẹnu kò ó ní ẹnu.”5

Òtítọ́ pé baba náà sáré sí ọmọ rẹ̀, mo gbàgbọ́, ṣe pàtàkì. Ìrora ti ara ẹni tí ọmọkùnrin náà ti mú bá baba rẹ̀ jinlẹ̀ ó sì jẹ́ ìjìnlẹ̀ dájúdájú. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ó ṣeéṣe kí baba náà ti ní ìtìjú gidi nípa àwọn ìṣe ọmọkùnrin rẹ̀.

Nítorínáà, kínníṣe ti baba náà kò dúró fún ọmọ rẹ̀ láti tọrọ àforíjì? Kínniṣe tí òun kò dúró fún ọrẹ ìmúpadà àti ìlàjà kan kí ó to nawọ́ ìdáríjì àti ìfẹ́? Èyí jẹ́ ohun kan ti mo máa nrò jinlẹ̀ nígbà púpọ̀.

Olúwa nkọ́wa pé dídaríji àwọn ẹlòmíràn jẹ́ òfin gbogbo àgbáyé: “Èmi, Olúwa, yíò dáríji ẹnití èmi yíò dáríjì, ṣùgbọ́n ní tiyín ó jẹ́ dandan láti dáríji gbogbo ènìyàn.”6 Láti nawọ́ ìdáríjì le gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgboyà àti ìrẹ̀lẹ̀. Ó le gba àkókò bákannáà Ó gba pé kí a fi ìgbàgbọ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé wa sínú Olúwa bí a ṣe fi inú ro ìjíhìn fún ipò ọkàn wa. Níhin ni pàtàkì àti agbára òmìnira wa láti yàn wà.

Pẹ̀lú àpẹrẹ baba yí nínú òwe ọmọ onínákunàá, Olùgbàlà ṣe àtẹnumọ́ pé ìdáríjì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀bùn tí ó lọ́lá jùlọ tí a le fifún ẹ̀nìkan sí ẹlòmíràn ara wa àti ní pàtàkì jùlọ àwa fúnra wa. Gbígbé ẹrù kúrò lórí ọkàn wa nípasẹ̀ ìdáríjì kìí ṣe ohun tí ó fi ìgbà gbogbo rọrùn, ṣùgbọ́n nípasẹ̀ agbára ìgbéniró ti Jésù Krístì, ó ṣeéṣe.

Fífọ́ àwọn apákan ti Arawa

Nínú Iṣe Àwọn Àpóstélì ori 3 a kọ́ nípa ọkùnrin kan tí a bí ní arọ, “tí nwọ́n sì ímá gbé kalẹ̀ ní ojoójumọ́ ní ẹnu-ọ̀nà tẹ́mpìlì tí à npè ní Dáradára, láti máa ṣagbe lọ́wọ́ àwọn tí nwọ inú tẹ́mpìlì lọ.”7

Arọ alágbe náà ti ju ẹni ogójì ọdún lọ8 ó sì ti lo gbogbo ayé rẹ̀ nínú ipò tó dàbí pé kò ní dópin náà ti síṣe àìní àti dídúró, nítorítí ó gbaralé àtìlẹ́hìn àti inú rere àwọn ẹlòmíràn.

Ní ọjọ́ kan ó rí “Pétérù òun Jòhánnù bí wọ́n ti fẹ́ wọ inú tẹ́mpìlì, ó [sì] ṣagbe.

“Pétérù, ní títẹjúmọ́ ọ pẹ̀lú Jòhánnù, ó ní, Wò wá.

“Ó sì fiyèsí wọn, ó nretí àti rí nkan gbà lọ́wọ́ wọn.

“Nígbà náà Pétérù wípé, Fàdákà àti wúrà èmi kò ní; ṣùgbọ́n ohun tí mo ní èyínì ni mo fifún ọ: Ní orúkọ Jésù Krístì ti Násárẹ́tì dìde kí o sì máa rìn.

“Ó sì fà á lí ọwọ́ ọ̀tún, ó sì gbé e dìde: lí ojúkannà ẹsẹ̀ rẹ̀ àti egungun kókósẹ́ rẹ̀ sì mókun.

“Ó sì nfò sókè, ó dúró, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí rìn,ó sì bá wọn wọ inú tẹ́mpìlì lọ, ó nrìn, ó sì nfò, ó sì nyin Ọlọ́run.”9

Ní àwọn ìgbà púpọ̀ jákèjádò ìgbé ayé wa a le rí ara wa, bíi arọ alágbe náà ní ẹnu ọ̀nà tẹ́mpìlì, pẹ̀lú sùúrù—tàbí nígbà míràn láìsí sùúrù—”ní dí[dúró] de Olúwa.”10 Ní dídúró láti di wíwòsàn ní ti àfojúrí àti ẹ̀dùn ọkàn. Ní dídúró fún àwọn ìdáhùn tí ó wọlé sí abala jíjìn jùlọ inú ọkàn wa. Ní dídúró fún iṣẹ́ ìyanu kan.

Dídúró de Olúwa lè jẹ́ ibi mímọ́—ibi ìmúdára àti ìtúnṣe kan níbití a le wá láti mọ Olùgbàlà náà ní ọ̀nà ti araẹni jíjinlẹ̀ kan. Dídúró de Olúwa bákannáà lè jẹ́ ibì kan tí a ti nrí arawa ní bíbééré pé, “Ah Ọlọ́run, níbo ni ìwọ wà?”11—ibìkan tí ìfaradà ti-ẹmí nfẹ́ kí a lo ìgbàgbọ́ nínú Krístì nípa mímọ̀ọ́mọ̀ yàn Án lẹ́ẹ̀kansi àti lẹ́ẹ̀kansi àti lẹ́ẹ̀kansi. Èmi mọ ìhín yí, mo sì ní òye irú dídúró yi

Mo lo àwọn wákàtí àìlónkà ní ibi ìtọ́jú àrùn jẹjẹrẹ kan, ní ìrẹ́pọ̀ nínú ìjìyà mi pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹnití wọ́n npòngbẹ láti di wíwòsàn. Àwọn kan yè; àwọn míràn kò yè. Mo kọ́ ẹ̀kọ́ ní ọ̀nà ìjìnlẹ̀ kan pé ìtúsílẹ̀ kúrò nínú àwọn àdánwò wa yàtọ̀ fún ẹnìkọ̀ọ̀kan wa, àti nítorínáà ìfojúsùn wa níláti dínkù nípa ọ̀nà tí a fi di títúsílẹ̀ àti púpọ̀ síi nípa Olùdandè Fúnrarẹ̀. Ìtẹnumọ́ wa nílati fi gbogbo ìgbà jẹ́ lórí Jésù Krístì!

Lílo ìgbàgbọ́ nínú Krístì túmọ̀ sí àìgbẹ́kẹ̀lé ìfẹ́ Ọlọ́run nìkan ṣùgbọ́n bákannáà nínú àkokò Rẹ̀. Nítorí Ó mọ déédé ohun tí a nílò àti ìgbà tí a nílò rẹ̀. Nígbàtí a bá jọ̀wọ́ ara sí ìfẹ́ Olúwa, ní ìgbẹ̀hìn àwa ó gbà ọ̀pọ̀lọpọ̀ síi ju èyí tí a ti ní ìfẹ́ inú lọ.

Ẹyin ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n, gbogbo wa ní ohun kan nínú ayé wa tí ó ti fọ́ tí ó nílò láti di títúnṣe, fi sí ipò, tàbí wò sàn. Bí a ti nyípadà sí ọ̀dọ̀ Olùgbàlà, bí a ti nmú ọkàn àti iyè wa wà ní ìbámu pẹ̀lú Rẹ̀, bí a ti nronúpìwàdà, Ó nwá sí ọ̀dọ̀ wà “pẹ̀lú ìwòsàn ní ìyẹ́ apá rẹ̀,”12 Ó nfi apá rẹ̀ yí wá ká pẹ̀lú ìfẹ́ni, Ó sì nwí pé, “Ó dára. Ìwọ jẹ́ ẹni ọdún marun péré—tàbí mẹrindinlogun, mẹ́tàlélógún, méjìdínláadọ́ta, ọgọ́tàlémẹ́rin, mọ̀kànléláàdọ́rún. A le jùmọ̀ tún èyí ṣe papọ̀!”

Mo jẹ́ri sí yín pé kò sí ohunkóhun nínú ìgbé ayé yín tí ó ti bàjẹ́ tí ó kọjá agbára wíwòsàn, gbígbàlà, àti agbára alèṣe ti Jésù Krístì. Ní orúkọ ọ̀wọ̀ àti mímọ́ ti Ẹni náà tí ó lágbára láti wòsàn, Jésù Krístì, àmín.