Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Agbára Ipa Ti-Ẹ̀mí
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2022


Agbára Ipa Ti-Ẹ̀mí

Èmi yíò fẹ́ láti dá kókó àbá àwọn ìṣe marun tí a lè ṣe láti ràn wá lọ́wọ́ láti mú ipa dídára ti-ẹ̀mí dúró.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, mo nifẹ yín. Mo ṣìkẹ́ ànfàní yí láti sọ̀rọ̀ pẹ̀lú yín ní òní Mo ngbàdúrà lójojúmọ́ pé ẹ ó ní ààbò kúrò nínú àwọn ìkọlù líle ti ọ̀tá àti níní agbára láti tẹ̀ síwájú nínú eyikeyi àwọn ìpènijà tí a lè kojú.

Àwọn àdánwò jẹ́ àwọn àjàgà ìjìnlẹ̀ ìkọ̀kọ̀ tí ẹnìkẹ́ni kò lè rí. Àwọn ẹlòmíràn nṣe eré jáde lórí ìtàgé ayé. Ìjà ogun ní ìlà-òòrùn Europe ni ọ̀kan lára ìwọ̀nyí. Mo ti lọ sí Ukraine àti Russia ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà. Mo nifẹ àwọn ilẹ̀ wọnní, àwọn ènìyàn, àti àwọn èdè wọn. Mo sọkún mo sì gbàdúrà fún gbogbo ẹnití ó farapa nípasẹ̀ ìjà yí. Bí Ìjọ à nṣe gbogbo ohun tí a lè ṣe lati ran àwọn wọnnì tí wọ́n njìyà tí wọ́n sì nlàkàkà láti yè lọ́wọ́. A pe gbogbo ènìyàn láti tẹ̀síwájú láti gbàwẹ̀ àti láti gbàdúrà fún gbogbo àwọn wọnnì tí ó ní ìpalára nípa àjálù yí. Ogun jẹ́ ìbẹ̀rù ìpayà ti ohungbogbo tí Olúwa Jésù Krístì kọ́ni tí ó si dúró fún.

Kò sí ẹnìkankan lára wa tí ó lè ṣàkóso àwọn orílẹ̀-èdè tàbí àwọn ìṣe ẹlòmíràn àní tàbí àwọn ọmọ ti ẹbí arawa. Ṣùgbọ́n a lè ṣe àkòso arawa. Ìpè mi ní òní, ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, ni láti parí àwọn ìjà tí ó njà nínú ọkàn yín, ilé yín, àti ayé yín. Ẹ ri ohunkóhun àti gbogbo ìrò láti pa àwọn ẹlòmíràn lára mọ́lẹ̀—bóyá iro láti bínú, ahọ́n mímú, tàbí ìkorira fún ẹnìkan tí ó ti pa yín lára. Olùgbàlà pàṣẹ fún wa láti yí ẹ̀rẹ̀kẹ́ míràn,1 láti fẹ́ràn àwọn ọ̀tá wa, àti láti gbàdúrà fún àwọn wọnnì tí wọ́n nlò wá nílókulò.2

Ó lè le ní dídunni láti fi ìbínú tí ó dàbí ìdáláre sílẹ̀. Ó lè dàbí àìṣeéṣe láti dáríji àwọn wọnnì tí àwọn ìṣe ìpanirun wọn ti pa aláìmọ̀kan lára. Àti síbẹ̀síbẹ̀, Olùgbàlà kìlọ̀ fún wa láti “dáríjì gbogbo ènìyàn.”3

Àwa ni àtẹ̀lé Aládé Àlááfíà. Nísisìyí ju bẹ́ẹ̀ láéláé, a nílò àlááfíà tí Òun lè múwá nìkan. Báwo ni a ṣe lè retí àláfíà láti wà nínú ayé nígbàtí ẹnìkọ̀ọ̀kan wa kò wá àláfíà araẹni àti ìrẹ́pọ̀? Ẹyin arákùnrin àti arábìnrin, mo mọ pé ohun tí èmi ndá àbá kò rọrùn. Ṣùgbọ́n àwọn àtẹ̀lé Jésù Krístì níláti gbé àpẹrẹ kalẹ̀ fún gbogbo ayé láti tẹ̀lé. Mo bẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú yín láti ṣe gbogbo ohun tí ẹ lè ṣe láti parí àwọn ìjà araẹni tí ó njà nínú ọkàn àti ayé yín.

Njẹ́ kí nfi ìpè yí sábẹ́ ìṣe nípa sísọ èrò kan tí a rán mi létí láìpẹ́ nígbàtí mò nwo ere bọ́ọ̀lù àfọwọ́gbá.

Nínú eré náà, ìlàjì àkọ́kọ́ jẹ́ ogun rírí, síwájú àti sẹ́hìn. Lẹ́hìnnáà, ní ìgbà ìṣẹ́jú akàn márun ti ìlàjì àkọ́kọ́, aṣọ́nà kan níínú ẹgbẹ́ ṣe jíjù àmì-mẹ́ta dídára. Pẹ̀lú ìṣẹ́jú akàn kan tí ó kù, àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ jí bọ́ọ̀lù tí ó nkọjá gbé wọ́n sì ṣe apẹ̀rẹ̀ míràn sí bússà! Kí ẹgbẹ́ náà lọ sínú yàrá àpótí àwọn àmì mẹ́rin ṣíwájú pẹ̀lú ìfọwọ́kàn ìyára ríru. Wọ́n ní ànfàní làti gbé ipa náà sínú ìlàjì kejì àti borí eré náà.

Ìyára jẹ́ èrò alágbára kan. Gbogbo wa ti ní ìrírí rẹ̀ ní ọ̀nà kan tàbí òmíràn—fún àpẹrẹ, nínú ọkọ̀ tí ó nsáré sókè tàbí pẹ̀lú àìfaramọ́ tí ó nyípada lọ́gán sínú èdèàiyedè.

Nítorínáà mo bèèrè, “Kíni ó lè mú ipa ti-ẹ̀mí tagìrì? A ti rí àwọn àpẹrẹ ti méjèèjì ipa dídára àti àìdára. A mọ̀ àwọn àtẹ̀lé Jésù Krístì tí wọ́n di olùyípadà tí wọ́n sì dàgbà nínú ìgbàgbọ́. Ṣùgbọ́n bákannáà a mọ̀ nípa olùfarasìn onígbàgbọ́ tẹ́lẹ̀rí tí wọ́n ṣáko lọ. Ipa lè yí ní ọ̀nàkọnà.

A kò nílò ipa dídára ti-ẹ̀mí ju bí a ti nṣe ní òní láéláé, láti tako ìyára pẹ̀lú irú ibi àti àwọn àmì dúdújù ti àkokò tí ó nle si. Ipa dídára ti-ẹ̀mí yíò tẹramọ́ mímú wa rìn síwájú ní àárín ẹ̀rù àti àìní-ìdánilójú tí a dá sílẹ̀ nípa àjàkálẹ̀ àrùn, tsunamis, bíbú-gbàm fólkánó, àti ìjà-gbangba ológun. Ipa ti-ẹ̀mí lè rànwálọ́wọ́ láti kojú àìnísimi, ìkọlù ìwà-ìkà ọ̀tá àti láti ta àwọn ìtiraka rẹ̀ dànù láti mú ìpìlẹ̀ araẹni ti-ẹ̀mí wa kúrò.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìwà lè mú ìyára dídára ti-ẹ̀mí jí girì. Ìgbọ́ran, ìfẹ́, ìrẹ̀lẹ̀, iṣẹ́-ìsìn, àti ìmoore4 wà ṣùgbọ́n díẹ̀ ni.

Ní òní, èmi yíò fẹ́ láti dá kókó àbá àwọn ìṣe marun tí a lè ṣe láti ràn wá lọ́wọ́ láti mú ipa dídára ti-ẹ̀mí dúró.

Àkọ́kọ́: Ẹ lọ sí ipá-ọ̀nà májẹ̀mú kí ẹ sì dúró níbẹ̀.

Láipẹ̀ sẹ́hìn, mo lá àlá híhàn-kedere kàn nínú èyí tí mo ti pàdé ẹgbẹ́ àwọn ènìyàn Wọ́n bèèrè ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbèèrè lọ́wọ́ mi,èyí tó tẹ̀léra jùlọ jẹ́ nípa ipá-ọ̀nà májẹ̀mú àti ìdí tí í fi ṣe pàtàkì.

Nínú àlá mi, mo ṣe àlàyé pé à nwọnú ipá-ọ̀nà májẹ̀mú nípa ṣíṣe ìrìbọmi àti dídá májẹ̀mú wa àkọ́kọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run.5 Ìgbà kọ̀ọ̀kan tí a bá ṣe àbápín oúnjẹ Olúwa, a nṣe ìlérí lẹ́ẹ̀kansi láti gba orúkọ Olùgbàlà sí orí arawa, láti rántí Rẹ̀, àti láti pa àwọn ofin Rẹ̀ mọ́.6 Ní ìpadàbọ̀, Ọlọ́run nmu dá wá lójú pé a lè ní ẹ̀mí Olúwa pẹ̀lú wa nígbàgbogbo.

Lẹ́hìnwá a nṣe àfikún àwọn májẹ̀mú nínú tẹ́mpìlì, àní níbití a ti ngba àwọn ilérí títóbijù Àwọn ìlànà àti májẹ̀mú nfún wa ní ààyè sí agbára ti ọ̀run. Ipá ọ̀nà májẹ̀mú ni ipá ọ̀nà kanṣoṣo tí ó ndarí sí ìgbéga àti ìye ayérayé.

Nínú àlá mi, obìnrin kan bèèrè pé báwo ni ẹnìkan tí wọ́n ti já májẹ̀mú lọ́kùnrin tàbí lóbìnrin fi lè padà sí ipá-ọ̀nà. Ìdáhùn sí irú ìbèerè rẹ̀ ndarí sí àbá mi kejì:

ayọ̀ ìrònúpìwàdà ojojúmọ́ rí.

Báwo ni ìrònúpìwàdà ṣe jẹ́ pàtàkì tó? Álmà kọ́ni pé a kò níláti “wàásù ohunkóhun bíkòṣe ìrònúpìwàdà àti ìgbàgbọ́ nínú Olúwa.”7 Ìrònúpìwàdà ni a nílò láti ọ̀dọ̀ gbogbo ẹni tí ó njíyìn tí ó si nfẹ́ ògo ayérayé.8 Àwọn ayọkúrò kankan kò sí. Nínú ìfihàn sí Wòlíì Joseph Smith, Olúwa bá àwọn olórí Ìjọ wí nítorí wọn kò kọ́ àwọn ọmọ wọn ní ìhìnrere.9 Ríronúpìwàdà ni kọ́kọ́rọ́ sí ìlọsíwájú. Ìgbàgbọ́ mímọ́ npa wá mọ́ ní rírìn síwájú lórí ipá ọ̀nà májẹ̀mú.

Ẹ jọ̀wọ́ ẹ máṣe bẹ̀rù tàbí dẹ́kun ríronúpìwàdà. Sátánì ní ayọ̀ nínú ìbànújẹ́ yín. Ké e kúrú. Ẹ ti ipa rẹ̀ jáde kúrò nínú ayé yín. Ẹ bẹ̀rẹ̀ ní òní láti ní ìrírí ayọ̀ ti mímú ènìyàn ẹlẹ́ran ara kúrò.10 Olùgbàlà fẹ́ràn wa nígbàgbogbo ṣùgbọ́n nípàtàkì nígbàtí a bá ronúpìwàdà. Ó ṣe ìlérí pé bíótilẹ̀jẹ́pé “òkè yíò ṣí nidi, tí òkè gíga sì ṣí kúrò … inúrere mi kò ní kúrò lọ́dọ̀ yín.”11

Bí ẹ bá nímọ̀lára pé ẹ ti ṣìnà kúrò ní ipá ọ̀nà májẹ̀mú jìnnà gan tàbí gígùn gan tí kò sì ọ̀nà láti padà, ìyẹn kìí ṣe òtítọ́ rárá.12 Ẹ jọ̀wọ́ ẹ farakan bíṣọ́ọ̀pù tàbí ààrẹ ẹ̀ká yín. Òun ni aṣojú Olúwa yíò sì ràn yín lọ́wọ́ láti ní ìrírí ayọ̀ àti àtìlẹ́hìn ríronúpìwàdà.

Nísisìyí, ìkìlọ̀ kan: Pípadà sí ipá ọ̀nà májẹ̀mú túmọ̀ sí pé ìgbé ayé yíò rọrùn. Ipá ọ̀nà yí le àti pé nígbàmíràn a ó nímọ̀lára bíi gígun ibi gẹ́rẹ́gẹ̀rẹ́ kan.13 Ìgòkè yí, bákannáà, ni a ṣe láti dánwò àti láti kọ́ wa, láti tún ìwà-ẹ̀dá wa ṣe, àti láti ràn wá lọ́wọ́ láti di Ènìyàn Mímọ́. Ó jẹ́ ipá-ọ̀nà kanṣoṣo tí ó ndarí sí ìgbéga. Wòlíì kan14 júwe “ipò ìbùkún àti ìdùnnú ti àwọn tí ó pa àwọn òfin Ọlọ́run. Nítorí kíyèsi, wọ́n di alábùkúnfún nínú ohun gbogbo , níti-ara àti níti-ẹ̀mí méjèèjì; àti pé bí wọ́n bá dìí mú lódodo dé òpin a ó gbà wọ́n sí ọ̀run … [a ó sì] gbé pẹ̀lú Ọlọ́run nínú ipò ìdùnnú àìlópin.”15

Rírìn ní ipá ọ̀nà májẹ̀mú, papọ̀ pẹ̀lú ìrònúpìwàdà ojojúmọ́, nrú àkokò dídára ti-ẹ̀mí jáde.

Àbá mi kẹta: Ẹ kọ́ nípa Ọlọ́run àti bí Ó ti nṣiṣẹ́.

Ọ̀kan lára àwọn ìpènijà wa títóbijùlọ ní òní ni mímọ ìyàtọ̀ ní àárín òtítọ́ Ọlọ́run àti ayédèrú Sátánì. Ìyẹn ni ìdí tí Olúwa fi kìlọ̀ fún wa láti “gbàdúrà nígbàgbogbo, …ki [a] lè borí Sátánì, àti … kí a bọ́ lọ́wọ́ àwọn ìránṣẹ́ Sátánì tí ó ndi iṣẹ́ rẹ̀ mú.”16

Mósè pèsè àpẹrẹ bí a ti lè ní ìdámọ̀ ní àárín Ọlọ́run àti Sátánì. Nígbàtí Sátánì wá dán Mósè wò, ó rí ẹ̀tàn náà nítorí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ní ìbáṣe ojú-kojú pẹ̀lú Ọlọ́run. Báyìí, Mósè tètè mọ ẹni tí Sátánì jẹ́ ó sì pàṣẹ fún un láti kúrò.17 Nígbàtí Sátánì tẹnumọ, Mósè mọ bí òun yíò ti ké pe Ọlọ́run fún ìrànlọ́wọ́ síi. Mósè gba okun àtọ̀runwá ó sì bá ẹni ibi wí lẹ́ẹ̀kansi, ó wípé, “Kúrò lọ́dọ̀ mi, Sátánì, nítorí Ọlọ́run nìkanṣoṣo ni kí ìwọ ó foríbalẹ̀ fún.”18

A níláti tẹ̀lé àpẹrẹ náà. Ẹ ti ipa Sátánì jáde kúrò nínú ayé yín. Ẹ jọ̀wọ́ ẹ maṣe tẹ̀le lọ sí “ọ̀gbun ìbánújẹ́ àti ìparun àìlópin.”19

Pẹ̀lú ìyára ẹ̀rù, ẹ̀rí tí kò bá gba ìtọ́jú ojojúmọ́ “nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ rere Ọlọ́run”20 lè ṣubú. Báyìí, ẹ̀rọ̀ sí ète Sátánì hàn kedere: A nílò àwọn ìrírí ojojúmọ́ jíjọ́sìn Olúwa àti ṣíṣe àṣàrò ìhìnrere Rẹ̀. Mo bẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú yín láti jẹ́kí Ọlọ́run Borí nínú ayé yín. Ẹ fún Olúwa ní ìpín dáadáa ti àkokò yín. Bí ẹ ti nṣe é, ẹ kíyèsí ohun tí yíò ṣẹlẹ̀ sí ipa dídára ti-ẹ̀mí.

Àbá nọmba kẹ́rin: Ẹ wá kí ẹ sì retí àwọn iṣẹ́ ìyanu.

Mórónì mu dá wa lójú pé “Ọlọ́run ko dáwọ́dúró láti jẹ́ Ọlọ́run iṣẹ́ ìyanu.”21 Gbogbo ìwé mímọ́ júwe bí Olúwa ti ní ìfẹ́ láti dásí ìgbé ayé àwọn tí wọ́n gbàgbọ́ nínú Rẹ̀.22 Ó pín Òkun Pupa níyà fún Mósè, Ó ran Néfì lọ́wọ́ láti gba àwo idẹ, Ó sì mú Ìjọ Rẹ̀ padàbọ̀sípò nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith. Ọ̀kọ̀ọ̀kan lára àwọn iṣẹ́ ìyanu wọ̀nyí gba àkokò ó sì lè má jẹ́ déédé ohun tí àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan wọnnì bèèrè tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Olúwa.

Ní ọ̀nà kannáà, Olúwa yíò bùkún yín pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ẹ nílò ẹ bá gbàgbọ́ nínú Rẹ̀, “láìṣiyèméjì kankan.”23 Ẹ ṣe iṣẹ́ ti-ẹ̀mí láti wá iṣẹ́-ìyanu. Pẹ̀lú àdúrà ẹ bèèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run láti ràn yín lọ́wọ́ láti lo irú ìgbàgbọ́ náà. Mo ṣe ìlérí pé ẹ lè ní ìrírí fún arayín pé Jésù Krístì “fi agbára fún àwọn aláìlera, àti sí àwọn tí kò ní okun ní Ó nmú pọ̀ si ní agbára.”24 Àwọn ohun díẹ̀ yíò mú àkokò ti-ẹ̀mí yín yára si ju dídámọ̀ pé Olúwa nràn yín lọ́wọ́ láti ṣí òkè nínú ayé yín.

Àbá nọmba karun: Ẹ fi òpin sí ìjà nínú ayé arayín.

Mo tún ìpè mi sọ pé kí ẹ fi òpin sí àwọn ìjà nínú ayé yín. Ẹ lo ìrẹ̀lẹ̀, ìgboyà, àti okun tí ó yẹ láti darìjì àti láti wá ìdáríjì pẹ̀lú. Olùgbàlà ti ṣe ìlérí pé “bí [a] bá darí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn jì wọ́n, Baba [wa] ọ̀run yíò dàríjì [wa] bákannáà.”25

Ọ̀sẹ̀ mejì láti òní lọ a ó ṣe Ọdún Àjínde. Ní àárín ìsisìyí àti nígbànáà, mo pè yín láti wá òpin sí ìjà araẹni tí ó bò yín mọ́lẹ̀. Ṣé ìbámu ìṣe ìmoore sí Jésù Krístì fún Ètùtù Rẹ ṣì lè wà? Bí ìdáríjì bá dàbí àìṣeéṣe lọ́wọ́lọ́wọ́, ẹ bẹ̀bẹ̀ fún agbára nípasẹ̀ ètùtù ẹ̀jẹ̀ ti Jésù Krístì láti ràn yín lọ́wọ́. Bí ẹ ti nṣe bẹ́ẹ̀, mo ṣe ìlérí àlááfíà araẹni àti ìtújade ipa ti-ẹ̀mí.

Nígbàtí Olùgbàlà ṣe ètùtù fún gbogbo aráyé, Ó ṣí ọ̀nà kan tí àwọn tí ó bá tẹ̀lé E lè fi lè ní ààyè sí ìwòsàn, ìfúnlókun, àti agbára ìràpadà. Àwọn ànfàní ti-ẹ̀mí wọ̀nyí wà fún gbogbo ẹnití ó nwá láti gbọ́ Tirẹ̀ àti láti tẹ̀lé E.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin ọ̀wọ́n, pẹ̀lú gbogbo ẹ̀bẹ̀ ọ̀kàn mi, mo rọ̀ yín láti lọ sórí ipá-ọ̀nà májẹ̀mú kí ẹ sì dúró níbẹ̀. Ní ìrírí ayọ̀ ti ríronúpìwàdà ojojúmọ́. Ẹ kọ́ nípa Ọlọ́run àti bí Ó ti nṣiṣẹ́. Ẹ wá kí ẹ sì retí àwọn iṣẹ́ ìyanu. Ẹ tiraka láti mú ìjà wá sí òpin nínú ayé yín.

Bí ẹ ti nṣe iṣé lórí àwọn ìlépa wọ̀nyí, mo ṣe ìlérí okun fún yín láti rìn síwájú lórí ipá-ọ̀nà májẹ̀mú pẹ̀lú ipa púpọ̀si, pẹ̀lú eyikeyi àwọn ìdènà tí ẹ lè kojú. Mo sì ṣe ìlérí agbára títóbijù fún yín láti tako àdánwò, àlááfíà inú síi àti òmìnira kúrò nínú ẹ̀rù, àti ìrẹ́pọ̀ títóbijù nínú ẹbí yín.

Ọlọ́run wà láàyè! Jésù ni Krístì! Ó wà láàyè! Ó ní ifẹ́ wa yíò sì ránwálọ́wọ́. Nípa Èyí ni mo jẹrí ni orúkọ mímọ́ ti Olùràpadà wa, Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́

  1. Wo 3 Néfì 12:39.

  2. Wo 3 Néfì 12:44.

  3. Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 64:10; bákannáà wo ẹsẹ 9.

  4. As the Apostle Paul said, “In every thing give thanks” (1 Thessalonians 5:18). One of the surest antidotes for despair, discouragement, and spiritual lethargy is gratitude. Kíni àwọn ohun fún èyí tí a lè fi ọ̀pẹ́ fún Ọlọ́run? Ẹ dúpẹ́ fún lọ́wọ́ Rẹ̀ fún ẹwà ayé, fún ìmúpadàbọ̀sípò ti ìhìnrere, àti fún àìlónkà àwọn ọ̀nà tí Òun àti Ọmọ Rẹ̀ fi nmú agbára wọn wà fún wa ní ihin lórí ilẹ̀-ayé yí. Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ Rẹ̀ fún àwọn ìwé mímọ, fún àwọn ángẹ́lì tí wọ́n nfèsì sí àwọn ẹ̀bẹ̀ wa sí Ọlọ́run fún ìrànlọ́wọ́, fún ìfihàn, àti fún àwọn ẹbí ayérayé. Ati parí gbogbo rẹ̀, ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún ẹ̀bùn Ọmọ Rẹ̀ apti Ètùtù Jésù Krístì, èyítí ó nmu ṣeéṣe fún wa láti mú àwọn iṣẹ́ ìránṣẹ́ ṣẹ fún èyí tí a rán wá wá sí ilẹ̀-ayé.

  5. Láti ní òye ipá-ọ̀nà májẹ̀mú, ó ṣe pàtàkì láti ní òye pé májẹ̀mú ní ọ̀nà-méjì ìfarasìn ní àárín Ọlọ́run àti ọ̀kan lára àwọn ọmọ Rẹ̀. Nínú májẹ̀mú, Ọlọ́run gbé àwọn ọ̀ràn kalẹ̀, a sì faramọ́ àwọn ọ̀ràn wọnnì. Ní ìrọ́pò, Ọlọ́run ṣe àwọn ìlérí sí wa. Ọ̀pọlọpọ̀ àwọn májẹ̀mú bá àwọn àmì ìta wá—tàbí àwọn ìlànà mímọ́—nínú èyí tí à nkópa pẹ̀lú àwọn ẹlẹri ní ijoko. Fún àpẹrẹ, ìrìbọmi jẹ́ àmì kan sí Olúwa pé ẹni náà tí ó nṣe ìrìbọmi ti dá májẹ̀mú láti pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́.

  6. Mórónì 4:35:2Ẹkọ́ àti àwọn Májẹ̀mú20:77, 79

  7. Mòsíàh 2:17

  8. Wo Lúkù 10:30–37

  9. Wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 78:50–70

  10. Wo Mòsíàh 3:19

  11. Isaiah 54:10, àfikún àtẹnumọ́; bákannáà wo 3 Nefi 22:10 Inúrere is translated from the Hebrew term hesed, a powerful word with deep meaning that encompasses kindness, mercy, covenant love, and more.

  12. Ó sì ṣeéṣe láti ṣe ìdápadà fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ṣùgbọ́n kìí ṣe àwọn míràn. Bí ẹnìkan bá ṣe ìwaàimọ́ sí ẹlòmíràn, tàbí bí ẹnìkan bá gba ẹ̀mí ẹlòmíràn, a kò lè ṣe ìdápadà kíkún. Ẹlẹ́ṣẹ̀ nínú àwọn nkan wọ̀nyí kàn lè ṣe púpọ̀ gan, àti pé púpọ̀ ìyókù ni a fi sílẹ̀ fún gbèsè. Nítorí ìfẹ́ Olúwa láti dárí èyí tó kù jì, a lè wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ láìka bí a ti ṣáko lọ tó. Nígbàtí a bá ronúpìwàdà lódodo, Òun yíò dáríjì wá. Ìyókù gbèsè kankan ní àárín àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa àti okun wa láti ṣe ìdápadà ni a lè san nípa lílo Ètùtù Jésù Krístì, ẹnití ó lè ṣe ẹ̀bùn àánú. Ìfẹ́ Rẹ̀ láti dárí ìyókù jì wá ni ẹ̀bùn àìlóye.

  13. Wo 2 Néfì 31:18–20.

  14. The Nephite prophet King Benjamin.

  15. Mòsíàh 2:41.

  16. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 10:5; àfikún àtẹnumọ́.

  17. Wo Moses 1:16; bàkannáà wo ẹsẹ 1–20.

  18. Mósè1:20.

  19. Hẹ́lámánì 5:12.

  20. Mórónì 6:4.

  21. Mórónì 9:15; bákannáà wo ẹsẹ 19.

  22. John the Apostle declared that he recorded the Savior’s miracles so “that [we] might believe that Jesus is the Christ” (Jòhánnù 20:31).

  23. Mọ́mọ́nì 9:21.

  24. Isaiah 40:29.

  25. Máttéù 6:14.