Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ọ̀rọ̀ Ìṣaájú
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2022


Ọ̀rọ̀ Ìṣaájú

A bu ọlá fún àwọn ọmọbìnrin Ọlọ́run nínú abala pàtàkì yí nípa títẹjúmọ́ àwọn àníyàn wọn àti ti àwọn ìṣètò wọn.

Bí a ti bẹ̀rẹ̀ àìwọ́pọ̀ abala àwọn obìnrin yi ti ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò, inú mi dùn láti fi ọ̀rọ̀ ìṣaájú yí fúnni láti ọ̀dọ̀ Àjọ Ààrẹ Kinní.

Àwọn abala Sátidé wa ní ìtàn oríṣiríṣi àwọn èrèdí àti oríṣiríṣi àwọn èrò olùgbọ́. Ní ìrọ̀lẹ́ yi a fikún ìtàn náà bí a ti ndáwọ́lé èrèdí àti ìlànà titun kan fún ìfojúrí ọjọ́ iwájú. Ìhìnrere Jésù Krístì kìí yípadà. Ẹkọ́ ìhìnrere kìí yípadà. Àwọn májẹ̀mú ti araẹni wa kìí yípadà. Ṣùgbọ́n bí ọdún ti nyípo, àwọn ìpàdé tí a nṣe láti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wa máa nyípadà, ó sì ṣeéṣe pé yío tẹ̀síwájú láti máa yípadà bí ọdún ti nyípo.

Fún ìsisìyí, ìpàdé ìrọ̀lẹ́ Sátidé yi jẹ́ abala kan ti ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò, kìí ṣe abala ìṣètò amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ kankan. Bíi ti gbogbo àwọn abala ti ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò, ṣíṣeètò, àwọn olùsọ̀rọ̀, àti orin ni a ti yàn láti ọwọ́ Àjọ Ààrẹ Kinní.

A ti sọ fún Ààrẹ Jean B. Bingham, Ààrẹ Gbogbogbò Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́, láti darí abala yi. Àwọn abala ìrọ̀lẹ́ Sátidé ní ọjọ́ iwájú le jẹ́ dídarí láti ọwọ́ ọ̀kan lára àwọn Òṣìṣẹ́ Gbogbogbò míràn ti Ìjọ, bí irú ọmọ àwọn Àjọ Ààrẹ ti Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́, Àwọn Ọdọ́mọbìnrin, àti Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀, tí a ti yàn láti ọwọ́ Àjọ Ààrẹ Kinní.

Ní àṣàlẹ́ yí, abala ìrọ̀lẹ́ Sátidé yi ti ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò yío dúró lórí àwọn àníyàn àwọn obìnrin Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn. Èyí yío pẹ̀lú ẹ̀kọ́ Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, àwọn ìlàna ti Ìjọ tí ó jẹmọ́ àwọn obìnrin ní pàtó, àti àwọn ojúṣe àti iṣẹ́ gbogbogbò ti àwọn amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ eyítí ó pẹ̀lú àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé-bìnrin Ìjọ. Bíótilẹ̀jẹ́pé a mọ̀ọ́mọ̀ ṣe ìtànkiri rẹ̀ sí àwọn èrò olùgbọ́ jákèjádò agbáyé bíi ti gbogbo àwọn abala ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbòò, àwọn èrò olùgbọ́ tí a pè láti wà nínú Gbàgede Ìpàdé fún abala yi ni àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé-bìnrin ẹni ọdún méjìlá sókè A ti fi àwọn olùdarí olóyè àlùfáà díẹ̀ síi tí wọ́n nṣe àkóso lórí àwọn ẹgbẹ́ tí nkópa.

Ohun ti a nfi lọ́lẹ̀ níhin jẹ́ bíi ìdáhùn sí àwọn ohun èlò ìbárasọ̀rọ̀ tí ó wà lọ́wọ́lọ́wọ́ ní àrọ́wọ́tó sí àwọn ọmọ-ijọ àti àwọn olórí Ìjọ agbáyé ti Olúwa. Ẹkọ́ ìhìnrere ti Jésù Krístì jẹ́ ti gbogbo ènìyàn, nítorínáà èyínì ni kókó èrò inú wa àti bí a ti ṣe ìfọ́nkiri tó. A bu ọlá fún àwọn ọmọbìnrin Ọlọ́run nínú abala pàtàkì yí nípa títẹjúmọ́ àwọn àníyàn wọn àti ti àwọn ìṣètò wọn.

A dúpẹ́ pé ìmọ̀ ẹ̀rọ ìkéde ti nfún àwọn olùdarí Ìjọ ní agbára nísisìyí láti ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tó péye nípa bíbá àwọn èrò olùgbọ́ kan pàtó sọ̀rọ̀ ní orí pápá. Bákannáà a tẹ́wọ́gba òtítọ́ pé àwọn ohun èlò ìrìnàjò lọ́wọ́lọ́wọ́ npọ̀ síi. Èyínì fúnwa ní ààyè láti rán àwọn olórí Ìjọ jáde láti ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ aṣáájú-ọ̀nà ojúkojú lóòrèkóòrè fún àwọn olórí ní pápá.

Èyí ni iṣẹ́ ti Jésù Krístì Olúwa. Ìránṣẹ́ Rẹ̀ ni àwa jẹ́, tí Ẹ̀mí Mímọ́ Rẹ̀ ndarí. A pe àwọn ìbùkún Olúwa wá sórí àwọn olórí ti àwọn ìṣètò wọ̀nyí àti sórí àwọn obìnrin àti àwọn ọmọbìrin olótítọ́ tí wọn nṣe ìránṣẹ́ Olúwa nínú àwọn ìṣètò wọ̀nyi àti ní ìgbésí ayé olúkúlukú wọn. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.