Àwọn Ìwé Mímọ́
Abráhámù 1


Ìwé ti Ábráhámù

Tí a túmọ̀ láti inú àwọn ohun kíkọ igbàanì kan tí a pè ní Pápírúsì, láti ọwọ́ Joseph Smith

Ìyírọ̀padà kan ti díẹ̀ nínú àwọn Àkọsílẹ̀ ìgbàanì tí ó ti bọ́ sí ọwọ́ wa láti inú àwọn ihò ilẹ̀ ní Égíptì. Àwọn ohun kíkọ ti Ábráhámù nígbàtí ó wà ní Égíptì, tí a pè ní Ìwé ti Ábráhámù, tí ó kọ pẹ̀lú ọwọ́ rẹ̀, sí orí ohun ìkọ̀wé kan tí a pè ní pápírúsì.

Orí 1

Ábráhámù wá àwọn ìbùkún tí ètò pátríákì—A ṣe inúnibíni sí i láti ọwọ́ àwọn àlùfáà èké ní Káldéà—Jèhófàh gbà á là—Àwọn orísun àti ìjọba Égíptì ni a ṣe àtúnyẹ̀wò wọn.

1 Ní ilẹ̀ ti àwọn ara Káldéà, ní ibùgbé ti àwọn bàbá mi, èmi, Ábráhámù, rí pé mo nílò láti gba ibi ibùgbé míràn;

2 Àti, ní ríríi pé ìdùnnú àti àlãfíà àti ìsìnmi púpọ̀jù wà fún mi, mo wá ọ̀nà fún ìbùkún àwọn bàbá, àti ẹ̀tọ́ sí èyítí èmi yíò jẹ́ yíyàn láti mójútó ọ̀kannáà, nítorí tí èmi tìkárami jẹ́ àtẹ̀lé ti òdodo, tí ó ní ìfẹ́ inú bákannáà láti jẹ́ ẹni náà tí ó ní ìmọ̀ púpọ̀, àti láti jẹ́ àtẹ̀lé ti òdodo púpọ̀jù síi, àti láti ní ìmọ̀ púpọ̀jù síi, àti láti jẹ́ bàbá ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn orílẹ̀ ède, ọmọ aláde àlãfíà, àti tí ó ní ìfẹ́ inú láti gba àwọn ẹ̀kọ́, àti láti pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́, èmi di ajógún tí ó tọ́, Àlùfáà Gíga, tí ó di ẹ̀tọ́ mú èyí ti ó jẹ́ ti àwọn bàbá.

3 A fi í fún mi láti ọ̀dọ̀ àwọn bàbá; ó sọ̀kalẹ̀ wá láti ọwọ́ àwọn bàbá, láti ìpìlẹ̀sẹ̀ àkókò, bẹ́ẹ̀ni, àní láti àtètèkọ́ṣe, tàbí ṣaájú ìpilẹ̀sẹ̀ ilẹ̀ ayé, títi sí àkókò yìí, àní ẹ̀tọ́ ti àkọ́bí, tàbí ọkùnrin àkọ́kọ́, ẹnití í ṣe Ádámù, tàbí bàbá àkọ́kọ́, nípasẹ̀ àwọn bàbá sí mi.

4 Mo lépa fún yíyàn tèmi sí Oyè Àlùfáà ní ìbámu pẹ̀lú yíyàn ti Ọlọ́run sí àwọn bàbá nípa ti irú ọmọ.

5 Àwọn bàbá mi, nítorití wọ́n yípadà kúrò nínú òdodo wọn, àti kúrò nínú àwọn òfin mímọ́ èyí tí Olúwa Ọlọ́run wọn ti fún wọn, sí sísin àwọn òrìṣà kèfèrí, kọ̀jálẹ̀ pátapáta láti fetísílẹ̀ sí ohùn mi;

6 Nítorí ọkàn wọ́n ti múra tán láti ṣe búburú, ó sì ti yípadà pátápátá sí òrìṣà Ẹ́likẹ́nà, àti òrìṣà Líbnà, àti òrìṣà Mámákrà, àti òrìṣà Kóráṣì, àti òrìṣà Fáráò, ọba Égíptì;

7 Nítorínáà wọ́n yí ọkàn wọn padà sí ìrúbọ àwọn kèfèrí ní fífi àwọn ọmọ wọn rú ẹbọ-ọrẹ sí àwọn ère tí wọn kò le sọ̀rọ̀, wọ́n kò sì fetísílẹ̀ sí ohùn mi, ṣùgbọ́n wọ́n gbìyànjú láti pa mí láti ọwọ́ àlùfáà Ẹ́lkẹ́nà. Àlúfáà Ẹ́lkẹ́nà ni àlùfáà Fáráò bákannáà.

8 Nísisìyí, ní àkókò yìí ó jẹ́ àṣà ti àlùfáà Fáráò, ọba Égíptì, láti rú ẹbọ-ọrẹ ní orí pẹpẹ náà èyítí a ṣe ní ilẹ̀ Káldéà, fún ẹbọ-ọrẹ sí àwọn àjèjì òrìṣà wọ̀nyí, ọkùnrin, obìnrin, àti àwọn ọmọdé.

9 Ó sì ṣe tí àlùfáà náà ṣe ẹbọ-ọrẹ kan sí òrìṣà Fáráò, àti pẹ̀lú sí òrìṣà Ṣagrẹ́lì, àní gẹ́gẹ́bí ìwà àwọn ará Égíptì. Nísisìyí òrìṣà Ṣágrẹ́lì ni oòrùn.

10 Àní ẹbọ ọpé ọmọdé kan ni àlùfáà Fáráò rú ní orí pẹ́pẹ náà èyítí ó dúró ní ẹ̀bá òkè kékeré tí wọ́n pè ní Òkè Pọ́tífárì, ní ìbẹ̀rẹ̀ ibi pẹ̀tẹ́lẹ̀ ti Ólíṣémù.

11 Nísisìyí, àlùfáà yìí ti rú ẹbọ àwọn wúndíá mẹ́ta ní ìgbà kannáà ní orí pẹpẹ yìí, tí wọ́n jẹ́ àwọn ọmọbìnrin Ónítà, ọ̀kan nínú àwọn ìran ọba láti ìhà ti Hámù. Àwọn wúndíá wọ̀nyí ni wọ́n fi rúbọ nítorí ti ìwà rere wọn; wọ́n kò fi orí balẹ̀ láti jọ́sìn fún àwọn òrìṣà igi tàbí ti òkúta, nítorínáà wọ́n pa wọ́n ní orí pẹpẹ yìí, wọ́n sì ṣe èyí gẹ́gẹ́bí ìṣe àwọn ará Égíptì.

12 Ó sì ṣe tí àwọn àlùfáà náà fi ọwọ́ ipá mú mi, pé kí wọ́n ó lè pa èmi náà pẹ̀lú, bí wọ́n ti ṣe àwọn wúndíá wọnnì ní orí pẹpẹ yìí; àti pé kí ẹ̀yin ó lè ní ìmọ̀ nípa pẹpẹ yìí, èmi yíò tọ́ka yín sí àworán tí ó wà ní ìbẹ̀rẹ̀ àkọsílẹ̀ yìí.

13 A ṣe é gẹ́gẹ́bí ẹ̀yà ibùsùn kan, irú èyí tí wọ́n ní lààrin àwọn ará Káldéà, ó sì dúró níwájú àwọn òrìṣà Ẹ́lkẹ́nà, Líbna, Mámakrà, Kóráṣì, àti bákannáà òrìṣa kan tí ó dàbí ti Fáráò, ọba Égíptì.

14 Kí ẹ̀yin ó lè ní òye àwọn òrìṣà wọ̀nyí, mo ti fún yín ní àpèjúwe wọn nínú àwọn àwòrán ní ìbẹ̀rẹ̀, àwọn àwòrán irú èyítí àwọn ará Káldéà npè ní Rahalínósì, èyítí ó túmọ̀ sí àwọn àmì àpẹrẹ.

15 Bí wọ́n sì ṣe gbé ọwọ́ wọn sókè sí mi, pé kí wọ́n lè fi mí rúbọ kí wọ́n ó sì gba ẹ̀mí mi, kíyèsíi, mo gbé ohùn mi sókè sí Olúwa Ọlọ́run mi, Olúwa sì fetísílẹ̀ ó sì gbọ́, òun sì kún inú mi pẹ̀lú ìran Alágbára Jùlọ, ángẹ́lì ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ sì dúró tì mí, ó sì tú ìdè mi lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀;

16 Ohùn rẹ̀ sì tọ̀ mí wá: Ábráhámù, Ábráhámù, kíyèsíi, orúkọ mi ni Jèhófàh, èmi sì ti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ, mo sì ti sọ̀kalẹ̀ láti gbà ọ́, àti láti mú ọ lọ kúrò ní ilé bàbá rẹ, àti kúrò ní ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn ìbátan rẹ, sí ilẹ̀ àjèjì kan èyítí ìwọ kò mọ̀ nipa rẹ̀;

17 Àti èyí nítorítí wọ́n ti yí ọkàn wọn kúrò ní ọ̀dọ̀ mi, láti sin òrìṣà Ẹ́lkẹ́nà, àti òrìṣà Líbnà, àti òrìṣà Mamákrà, àti òrìṣà Kórásì, àti òrìṣà Fáráò, ọba Égíptì; nítorínáà èmi ti sọ̀kalẹ̀ wá láti bẹ̀ wọ́n wò, àti láti pa ẹni náà run tí ó gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè sí ọ, Ábráhámù, ọmọ mi, láti mú ẹ̀mí rẹ kúrò.

18 Kíyèsíi, èmi yíò saájú rẹ nípa ọwọ́ mi, èmi yíò sì mú ọ, láti fi orúkọ mi sí orí rẹ, àní Oyè Àlùfáà ti bàbá rẹ, agbára mi yíò sì wà ní orí rẹ.

19 Bí ó ti wà pẹ̀lú Nóà bẹ́ẹ̀ ni yíò wà pẹ̀lú rẹ; ṣùgbọ́n nípasẹ̀ iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ orúkọ mi yíò di mímọ̀ ní ilẹ̀ ayé títí láé, nítorí èmi ni Ọlọ́run rẹ.

20 Kíyèsíi, Òkè Pọ́tífárì wà ní ilẹ̀ Urì, ti Káldéà. Olúwa sì wó pẹpẹ Ẹ́lkẹ́nà lulẹ̀, àti ti àwọn òrìṣà ilẹ̀ náà, ó sì pa wọ́n run pátápátá, ó sì kọlu àlùfáà náà tí òun sì kú; ọ̀fọ̀ púpọ̀ sì wà ní Káldéà, àti bákannáà ní àfin Fáráò; Fáráò èyí tí ó túmọ̀sí jíjẹ́ ọba nípa ẹ̀jẹ̀ ìran.

21 Nísisìyí ọba Égíptì yìí jẹ́ àtẹ̀lé láti ìhà Hámù, ó sì jẹ́ alábàápín ẹ̀jẹ̀ ti àwọn ará Kénánì nípa ìbí.

22 Láti àtẹ̀lé ìran yìí ni gbogbo àwọn ará Égíptì ti dìde, báyìí ni a sì pa ẹ̀jẹ̀ àwọn Kénáánì mọ́ ní ilẹ̀ náà.

23 Ìlẹ̀ Égíptì ni a kọ́kọ́ ṣe àwárí rẹ̀ nípasẹ̀ obìnrin kan, ẹnití ó jẹ́ ọmọbìnrin Hámù, tí ó sì jẹ́ ọmọbìnrin Égíptù, èyítí ó túmọ̀ sí Égíptì sí àwọn ará Káldéà, tí ó túmọ̀ sí èyíinì tí í ṣe èèwọ̀;

24 Nígbàtí obìnrin yìí ṣe àwárí ilẹ̀ náà, ó wà ní abẹ́ omi, lẹ́hìnnáà tí ó sì tẹ̀ àwọn ọmọ rẹ̀ dó sínú ibẹ̀; àti báyìí, láti Hámù, ni ìran náà dìde èyítí ó pa ègún mọ́ ní ilẹ̀ náà.

25 Nísisìyí ìjọba àkọ́kọ́ ti Égíptì ni a gbé kalẹ̀ láti ọwọ́ Fáráò, ọmọkùnrin Égíptù tí ó dàgbàjùlọ, ọmọbìnrin Hámù, ó sì jẹ́ bí ìṣe ìjọba ti Hámù, èyítí í ṣe ti pátríakì.

26 Fáráò, nítorí tí ó jẹ olódodo ènìyàn, ṣe àgbékalẹ̀ ìjọba rẹ̀ ó sì ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ pẹ̀lú ọgbọ́n àti òtítọ́ ní gbogbo àwọn ọjọ́ rẹ̀, ní fífi ìtara lépa láti ṣe àfiwé ètò náà tí àwọn bàbá gbé kalẹ̀ ní àwọn ìran àkọ́kọ́, ní àwọn ọjọ́ ìṣèjọba àkọ́kọ́ ti pátríákì, àní nínú ìṣèjọba ti Ádámù, àti bákannáà ti Nóà, bàbá rẹ̀, ẹnití ó bùkún fún un pẹ̀lú àwọn ìbùkún ti ilẹ̀ ayé, àti pẹ̀lú àwọn ìbùkún ti ọgbọ́n, ṣùgbọ́n tí ó fi bú nípa Oyè Àlùfáà.

27 Nísisìyí, nítorítí Fáráò jẹ́ ti ìran náà nípa èyítí òun kò lè ní ẹ̀tọ́ sí Oyè Àlùfáà, bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀ àwọn Fáráò ní ìfẹ́ inú lati fi ìtara gbà á láti orí Nóà, nípasẹ̀ Hámù, nítorínáà a darí bàbá mi lọ kúrò nípa ìbọ̀rìṣa wọn;

28 Ṣùgbọ́n èmi yíò gbìyànjú, léhìnwá, láti fi àmì sí àkójọpọ̀ àwọn ìṣẹlẹ̀ lọ sẹ́hìn láti ọ̀dọ̀ èmi tìkara mi sí ìbẹ̀rẹ̀ ìṣẹ̀dá, nítorí àwọn àkọsílẹ̀ náà ti wá sí ọwọ́ mi, èyítí mo dìmú títí di àkókò yìí.

29 Nísisìyí, lẹ́hìn tí a ti kọlu àlùfáà Ẹ́lkẹ́nà tí ó sì kú, nígbànáà ni ìmúṣẹ àwọn ohun wọnnì wá èyítí a ti sọ fúnmi nípa ilẹ Káldéà, pé ìyàn kan yíò mú ní ilẹ̀ náà.

30 Bẹ́ẹ̀gẹ́gẹ́ ìyàn kan gbòde jákèjádò gbogbo ilẹ̀ Káldéà, a sì dá bàbá mi lóró gidigidi nítorí ìyàn náà, òun sì ronúpìwàdà ti búburú èyítí ó ti pinnu sí mí, láti gba ẹ̀mí mi.

31 Ṣùgbọ́n àwọn àkọsílẹ̀ ti àwọn bàbá, àní àwọn pátríákì, nípa ẹ̀tọ́ ti Oyè Àlùfáà, ni Olúwa Ọlọ́run mi pa mọ́ sí ọwọ́ mi; nítorínáà ìmọ̀ ti ìbẹ̀rẹ̀ ìṣẹ̀dá, àti bákannáà ti àwọn ohun tí nyípo oòrun, àti ti àwọn ìràwọ̀, bí a ṣe sọ wọ́n di mímọ̀ fún àwọn bàbá, ni èmi ti pamọ́ àní titi di òní yìí, èmi yíò sì gbìyànjú láti kọ díẹ̀ nínú àwọn ohun wọ̀nyí sí orí àkọsílẹ̀ yìí, fún ire ìran mi tí yíò wá lẹ́hìn mi.