Àwọn Ìwé Mímọ́
Àwòrán 1


Àwòrán láti inú Ìwé Ábráhámù

Ònkà kínní

Àwòrán
Àwòrán 1

Àsọyé

Àwòrán 1. Ángẹ́lì Olúwa Náà.

Àwòrán 2. A so Ábráhámù mọ́ pẹpẹ kan.

Àwòrán 3. Àlùfáà abọ̀rìṣà Ẹlkẹ́nà ngbìdánwò láti fi Ábráhámù rú ẹbọ.

Àwòrán 4. Pẹpẹ fún ẹbọ rírú láti ọwọ́ àwọn àlùfáà abọ̀rìṣa, tí wọ́n dúró níwájú àwọn òrìṣà Ẹlkẹ́nà, Líbnà, Mámákrá, Kóráṣì, àti Fáráò.

Àwòrán 5. Òrìṣà Ẹlkẹ́nà.

Àwòrán 6. Òrìṣà Líbnà.

Àwòrán 7. Òrìṣà Mámakrà.

Àwòrán 8. Òrìṣà Kóràṣì.

Àwòrán 9. Òrìṣà Fáráò.

Àwòrán 10. Ábráhámù ní Égíptì.

Àwòrán 11. A yà á láti dúró fún àwọn ọ̀wọ̀n ọ̀run, bí ó ṣe yé àwọn ará Égíptì.

Àwòrán 12. Raukeeyang, tí ó dúró fún ojú ọ̀run, tàbí òfurufú tí ó wà ní òkè orí wa; ṣùgbọ́n nínú ọ̀rọ̀ yìí, bí ó ti jẹ mọ́ àkòrí yìí, àwọn ará Égíptì ní i lọ́kàn láti tọ́ka sí Ṣáúmáù, bíi èyí tí ó ga, tàbí àwọn ọ̀run, ní bíbáramu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Hébérù, Ṣáúmáyéemù.