Àwọn Ìwé Mímọ́
Abráhámù 5


Orí 5

Àwọn Ọlọ́run parí èrò wọn fún ṣíṣe ẹ̀dá ohun gbogbo—Wọ́n mú Ìṣẹ̀dá wá sí ìmúṣẹ gẹ́gẹ́bí àwọn èrò wọn—Ádámù fún gbogbo ẹ̀dá alàyè ní orúkọ.

1 Báyìí sì ni a ó parí àwọn ọ̀run àti ilẹ̀ ayé, àti gbogbo àwọn ẹgbẹ́ ogun inú wọn.

2 Àwọn Ọlọ́run sì wí láàrin ara wọn pé: Ní ìgbà keje ni a ó parí iṣẹ́ wa, èyítí a ti gbìmọ̀ràn rẹ̀; a ó sì sinmi ní ìgbà keje kúrò nínú iṣẹ́ èyítí a ti gbìmọ̀ràn rẹ̀.

3 Àwọn Ọlọ́run sì parí iṣẹ́ ní ìgbà keje, nítorí tí ó jẹ́ ní ìgbà keje ni wọn yíò sinmi kúrò nínú gbogbo àwọn iṣẹ́ wọn èyítí wọ́n (àwọn Ọlọ́run) ti gbìmọ̀ràn láàrin ara wọn láti ṣe; wọ́n sì yà á sí mímọ́. Báyìí sì ni àwọn ìpinnu wọn ní àkókò náà tí wọ́n gbìmọ̀ràn láàrin ara wọn láti dá àwọn ọ̀run àti ilẹ̀ ayé.

4 Àwọn Ọlọ́run sì sọ̀kalẹ̀ wá, wọ́n sì dá àwọn ìrandíran wọ̀nyí ti àwọn ọ̀run àti ti ilẹ̀ ayé, nígbàtí a dá wọ́n ní ọjọ́ náà tí àwọn Ọlọ́run dá ilẹ̀ ayé àti àwọn ọ̀run,

5 Ní ìbámu sí gbogbo èyítí wọ́n ti wí nípa olukúlùkù ewéko ìgbẹ́ ṣaájú kí ó tó wà ní orí ilẹ̀ ayé, àti olukúlùkù ewébẹ̀ ti inú ìgbẹ́ kí ó tó hù jáde; nítorí àwọn Ọlọ́run kò tíì mú kí òjò kí ó rọ̀ sí orí ilẹ̀ ayé nígbànáà tí wọ́n gbìmọ̀ràn láti dá wọ́n, wọn kò sì tíì dá ènìyàn láti ro ilẹ̀.

6 Ṣùgbọ́n ikũkũ kan lọ sókè láti ilẹ̀ ayé, ó sì bu omi rin gbogbo ojú ilẹ̀.

7 Àwọn Ọlọ́run sì dá ènìyàn láti inú erùpẹ̀ ilẹ̀, wọ́n sì mú ẹ̀mí rẹ̀ (èyíinì ni, ẹ̀mí ti ènìyàn náà), wọ́n sì fi sí inú rẹ̀; wọ́n sì mí èémí ìyè sí inú ihò imú rẹ̀, ènìyàn sì di alààyè ọkàn.

8 Àwọn Ọlọ́run sì gbin ọgbà kan, sí ìha ìlà oòrùn ní Édẹ́nì, níbẹ̀ ni wọ́n sì fi ènìyàn náà sí, ẹnití wọ́n ti fi ẹ̀mí rẹ̀ sí inú ara rẹ̀ èyítí wọ́n ti dá.

9 Láti inú ilẹ̀ ni àwọn Ọlọ́run sì ti mú kí olukúlùkù igi hù tí ó dára sí ojú àti tí ó dára fún oúnjẹ; igi ìyè, bákannáà, ní ààrin ọgbà náà, àti igi ìmọ rere àti búburú.

10 Odò kan nṣàn jáde ní Édẹ́nì, láti bu omi rin ọgbà náà, àti láti ibẹ̀ ó pínyà ó sì ya sí ipa ọ̀nà mẹ́rin.

11 Àwọn Ọlọ́run sì mú ènìyàn wọ́n sì fi òun sí inú Ọgbà Édẹ́nì, láti ro ó àti láti bójú tó o.

12 Àwọn Ọlọ́run sì pàṣẹ fún ènìyàn, wípé: Nínú olukúlùkù igi inú ọgbà ìwọ lè jẹ ní òmìnira,

13 Ṣùgbọ́n nínú igi ìmọ rere àti búburú, ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ nínú rẹ̀; nítorí ní àkókò tí ìwọ bá jẹ nínú èyí, ìwọ yíò kú dájúdájú. Nísisìyí èmi, Ábráhámù, rí i pé ó jẹ́ lẹ́hìn àkókò Olúwa ni, èyítí í ṣe lẹ́hìn àkókò Kólóbù; nítorí títi di àkókò yìí àwọn Ọlọ́run kò tĩ yan ìṣirò rẹ̀ fún Ádámù.

14 Àwọn Ọlọ́run sì wí: Ẹ jẹ́kí a wá olùrànlọ́wọ́ kan fún ọkùnrin náà, nítorí kò dára kí ọkùnrin náà kí ó nìkan wà, nítorínáà a ó ṣe olùrànlọ́wọ́ kan fún un.

15 Àwọn Ọlọ́run sì mú kí oorun àsùnwọra kan ó kun Ádámù; òun sì sùn, wọ́n sì mú ọ̀kan nínu eegun ìhà rẹ̀, wọ́n sì bo ẹran ara náà ní ipò ibẹ̀;

16 Àti pẹ̀lú eegun ìhà èyítí àwọn Ọlọ́run ti mú ní ara ọkùnrin, wọ́n dá obìnrin, wọ́n sì mú un tọ ọkùnrin náà wá.

17 Ádámù sì wí pé: Èyí ni egungun ti àwọn egungun mi, àti ẹran ara ti ẹran ara mi; nísisìyí a ó pèé ni Obìnrin, nítorí ti a mú jade láti ara ọkùnrin;

18 Nítorínáà ni ọkùnrin yíò ṣe fi bàbá àti ìyà rẹ̀ sílẹ̀, tí yío sì fi ara mọ́ ìyàwó rẹ̀, wọn yíò sì di ara kan.

19 Àwọ́n méjèjì sì wà ní ìhòhò, ọkùnrin náà àti ìyàwó rẹ̀, ojú kò sì tì wọ́n.

20 Lati inú ilẹ̀ sì ni àwọn Ọlọ́run ti dá olukúlùkù ẹranko igbẹ́, àti olukúlùkù ẹyẹ ojú ọ̀run, wọ́n sì mú wọn tọ Ádámù wá láti rí ohun tí yíò pè wọ́n; ohunkóhun tí Ádámù sì pè olukúlùkù ẹ̀dá alààyè, èyíinì ni yíó jẹ́ orúkọ rẹ̀.

21 Ádámù sì fi orúkọ fún gbogbo ẹran ọ̀sìn, fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run, fún olukúlùkù ẹranko ìgbẹ́; àti fún Ádámù, a sì rí olùrànlọ́wọ́ kan fún un.