Orí 1Ọlọ́run fi ara Rẹ̀ hàn sí Mósè—A pa Mósè lára dà—A kò ó lójú láti ọwọ́ Sátánì—Mósè rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ayé tí àwọ̀n ẹ̀dá ngbé—A ṣe ẹ̀dá àwọn ayé tí wọn kò ní ònkà láti ọwọ́ Ọmọ—Iṣẹ́ àti ògo Ọlọ́run ni láti mú àìkú àti ìyè ayérayé ènìyàn wá sí ìmúṣẹ. Orí 2Ọlọ́run dá àwọn ọ̀run àti ilẹ̀ ayé—Gbogbo àwọn onírúurú ẹ̀yà ni a dá—Ọlọ́run dá ènìyàn Ó sì fún un ní ìjọba lórí ohun gbogbo tí ó kù. Orí 3Ọlọ́run dá ohun gbogbo ní ti ẹ̀mí ṣíwájú kí wọ́n ó tó wà ní àdánidá lorí ilẹ̀ ayé—Ó dá ọkùnrin, ènìyàn àkọ́kọ́, ní orí ilẹ̀ ayé—Obìnrin jẹ́ olùrànlọ́wọ́ fún ọkùnrin. Orí 4Bi Sátánì ṣe di èṣù—Ó dán Éfà wò—Ádámù àti Éfà ṣubú, ikú sì wọ inú ayé. Orí 5Ádámù àti Éfà bí àwọn ọmọ—Ádámù rú ẹbọ ó sì sin Ọlọ́run—A bí Káínì àti Ábẹ́lì—Káínì ṣe ọ̀tẹ̀, ó fẹ́ràn Sátánì ju Ọlọ́run lọ, ó sì di Ègbé—Ìpànìyàn àti ìwa búburú tànká—Ìhìnrere ni a wàásù láti ìbẹ̀rẹ̀. Orí 6Irú ọmọ Ádamù ṣe ìpamọ́ ìwé ìrántí kan—Àwọn olódodo irú ọmọ rẹ̀ wàásù ironúpìwàdà—Ọlọ́run fi ara Rẹ̀ hàn sí Énọ́kù—Énọ́kù wàásù ìhìnrere—A fi ètò ìgbàlà hàn sí Ádámù—Òun gba ìrìbọmi àti oyè àlùfáà. Orí 7Énọ́kù kọ́ni, ó ṣaájú àwọn ènìyàn, ó ṣí àwọn òkè nídìí—Ìlú Síónì ni a gbé kalẹ̀—Énọ́kù rí ìran bíbọ̀ Ọmọ Ènìyàn, ẹbọ-ọrẹ ètùtù Rẹ̀, àti àjínde ti àwọn Ènìyàn Mímọ́—Ó rí ìran Ìmúpadàbọ̀ sípò, Àkójọpọ̀ náà, Bíbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì, àti ìpadàbọ̀ Síónì. Orí 8Mẹ̀túsẹ́là sọ̀tẹ́lẹ̀—Nóà àti àwọn ọmọ rẹ̀ wàásù ìhìnrere—Ìwà búburú púpọ̀ tànkálẹ̀—Ìpè sí ironúpìwàdà di àìkàsí—Ọlọ́run pinnu ìparún sí gbogbo ènìyàn nípa Ìkún-omi.