Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Nípa Ìṣọ̀kan ti Ìmọ̀lára A Gba Agbára pẹ̀lú Ọlọ́run
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2020


Nípa Ìṣọ̀kan ti Ìmọ̀lára A Gba Agbára pẹ̀lú Ọlọ́run

Bí a ṣe nwá ìrẹ́pọ̀ ti ìmọ̀ ara, a ó pe agbára Ọlọ́run láti mú àwọn ìtiraka wa dára si.

Ìyá Gordon wí fun pé bí ó bá ṣe iṣẹ́ rẹ̀ tán, òun ó ṣe àkàrà dídùn fun. Irú èyí tí ó fẹ́ràn jùlọ. Fún òun nìkan. Gordon lọ ṣiṣẹ́ bí ó ti pari iṣẹ́ náà, ìyá rẹ gbé àkàrà dídùn náà jáde. Arábìnrin rẹ̀ àgbà wọnú ilé wá pẹ̀lú ọ̀rẹ́ kan. Ó rí àkàrà dídùn ó sì bèèrè bí òun àti ọ̀rẹ́ òun bá lè ní ọkan.

“Rárá,” ni Gordon wí, “àkàrà dídùn mi ni. Ìyá ló yan an fún mi, mo si ṣiṣẹ́ fun ni.”

Kathy ké mọ́ arákùnrin rẹ̀ kékeré. O fi ìwà ìmọtaraẹni-nìkan àti àìní-ìwàrere hàn. Báwo ni ó ṣe lè pa gbogbo èyí mọ́ fúnra rẹ̀?

Àwọn wákàtí lẹ́hìnnáà nígbàtí Kathy ṣí ilẹ̀kùn ọkọ̀ rẹ̀ láti gbé ọ̀rẹ́ rẹ̀ lọ sílé, níbẹ̀ ní wọ́n gbé ìnuwọ́ méjì tí wọ́n ká dáadáa sí, fọ́ọ̀kì méjì wà lórí rẹ̀, àti ẹyọ àkàrà dídùn méjì nla nínú àwo. Kathy sọ ìtàn yí níbi ìsìnkú Gordon láti fi bí ó ṣe nifẹ láti yípadà àti láti fi inúrere hàn sí àwọn ẹni tí kò tọ́ sí.

Ní 1842, àwọn Ènìyàn Mímọ́ nṣiṣẹ́ kárakára láti kọ́ Tẹ́mpìlì Nauvoo. Lẹ́hìn dídá Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ sílẹ̀ ní Oṣù Kẹta, Wòlí Joseph nwá sí ìpàdé wọn léraléra láti múra wọn sílẹ̀ fún àwọn ìrẹ́pọ̀ májẹ̀mú mímọ́, tí wọn ó ṣe nínú tẹ́mpìlì.

Ní Ọjọ́ Kẹsan Oṣù Kẹfà, Wòlí “wípé òun nlọ wàásù àánú[.] Bí Jésì Krístì àti àwọn ángẹ́lì [náà] bá tako wá lórí àwọn ohun àìkàsí, kíni yíò ṣẹlẹ̀ sí wa? A gbọ́dọ̀ jẹ́ aláàánú kí a sì gbójúkúrò nínú ohun kékèké.” Ààrẹ Smith tẹ̀síwájú, “Ó bà mí nínú jẹ́ pé kò sí ijọsìn kíkún si—tí ọmọ ìjọ kan bá jìyà gbogbo wọn a mọ̀ọ́ lára—nípa ìrẹ́pọ̀ ìmọ̀lára ni a fi ngba agbára pẹ̀lú Ọlọ́run.”1

Gbólóhùn kékeré náà wọ̀ mí lọ́kan bí ìṣáná. Nípa ìrẹ́pọ̀ ìmọ̀lára ni à ngba agbára pẹ̀lú Ọlọ́run Ayé yí kìí ṣe ohun tí a fẹ́ kí ó jẹ́. Àwọn ohun púpọ̀ wà tí mo fẹ́ kí ó fún wa lágbára láti mú wa dára si. Lódodo, ọ̀pọ̀ àtakò ni ó wà sí ohun tí a nretí, àti pé ìgbàmíràn mò nní ìmọ̀lára àìlágbára. Láìpẹ́, mo bi ara mi ní ìbéèrè àtinúwá: Báwo ni mo ṣe lè ní òye àwọn tí ó wà ní àyíká mi dáradára si Báwo ni mo ṣe máa dá “ìmọ̀lára ìrẹ́pọ̀” sílẹ̀ nígbàtí gbogbo wa yàtọ̀ síra gan? Agbára wo látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni mo lè ní ààyè sí bí èmi bá kan ní ìrẹ́pọ̀ díẹ̀ si pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn? Látinú ẹ̀mí-ìwákiri mi, mo ní àwọn àbá mẹta. Bóyá wọn a ràn yín lọ́wọ́ bákannáà.

Ní Àánú

Jacob 2:17 reads, “Ẹ rònú nípa [àwọn arákùnrin àti arábìnrin] nyín gẹ́gẹ́bí ara yín, kí ẹ sì fifúnni nínú ohun ìní nyín, kí nwọ́n lè ní ọrọ̀ bí ẹ̀yin.” Ẹ jẹ́ kí a rọ́pò ọ̀rọ̀ ohun ìní pẹ̀lú àánú—kí ẹ fúnni ní àánú yín kí wọ́n lè ní ọrọ̀ bí ẹ̀yin.

A máa nronú nípa ohun ìní bí oúnjẹ tàbí owó, ṣùgbọ́n bóyá ohun tí a nílò jùlọ nínú iṣẹ́ ìránṣẹ wa ni àánú.

Ààrẹ Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ ti ara mi láìpẹ́ wípé: “Ohun tí èmi … ṣe ìlérí fún … yín ni pé èmi ó pa orúkọ yín mọ́ ní ààbò. … Èmi ó rí yín fún ẹni tí ẹ jẹ́ ní ibi dídára jùlọ yín. … Èmi kò ní sọ ohunkan nípa yín tí kò dára, tí kò ní gbé yín sókè. Mo bèèrè lọ́wọ́ yín láti ṣe bákannáà fún mi nítorí èmi níbẹ̀rù, lótítọ́, nípa jíjá yín kulẹ̀.”

1842:Joseph Smith wí fún àwọn arábìnrin ní ọjọ́ Oṣù Kẹfa náà ní

“Nígbàtí àwọn ẹnìkan fi àìní inúrere àti ìfẹ́ han sí mi, Áà irú agbára tí ó ní ní ọkàn mi. …

“… Bí a ṣe nsún mọ́ Baba wa ní ọ̀run si, bẹ́ẹ̀ ni a o ṣe ní àánú lórí àwọn ọkàn tí ó nṣègbé —[a ní ìmọ̀lára pé a fẹ́ láti] gbé wọn sí èjìká wa, kí a sì ju àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn sí ẹ̀hìn wa. [Ọ̀rọ̀ mi wà fún] gbogbo àwùjọ—tí ẹ bá fẹ́ kí Ọlọ́run ní àánú lórí yín, ẹ ní àánú lorí ara yín.”2

Èyí ni àmọ̀ràn tí ó wà nípàtàkì fún Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́. Ẹ máṣe dá ara wa lẹ́jọ́ tàbí kí a jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wa panilàra. Ẹ jẹ́ kí a pa orúkọ arawa mọ́ ní ààbò àti kí a fúnni ní ẹ̀bùn àánú.3

Ẹ Mú Kí Ọkọ̀ Ojú Omi Yín Máa Yí

Ní 1936, ẹgbẹ́ ìyíká tó ṣókùnkùn láti Unifásitì Washington rin ìrìnàjò lọ sí Germany láti kópa nínú Eré-ìdárayá Olympic. Ó jẹ́ àárín Ìrẹ̀wẹ̀sì Nlá. Ìwọ̀nyí ni kíláàsì-òṣìṣẹ́ àwọn ọkùnrin tí àwọ́n ìlú kékeré tí wọ́n nwalẹ̀ dá owó díẹ̀ kí wọ́n lè rin ìrìnàjò lọ sí Berlin. Gbogbo ara ìdíje náà dàbí ó wà ní ìlòdi sí wọn, ṣùgbọ́n ohunkan ṣẹlẹ̀ nínú ìje náà. Nínú ayé tó nyílọ, wọ́n pèé ní “yíyí.” Ẹ fi etí sílẹ̀ sí ìjúwe tí ó dá lé ìwé Àwọn ọkùnrin nínú Ọkọ̀ Ojú-omi:

Ohun kan wà tí ó máa nṣẹlẹ̀ nígbàmíràn tí ó le láti ṣe àṣeyege tí ó sì le láti túmọ̀. Wọ́n pèé ní “yíyí.” Ó nṣẹlẹ̀ nìkan nígbàtí gbogbo wa bá wà nínú irú ìrẹ́pọ̀ pípé tí ìṣe kankan kò lòdì sí.

Àwọn Olùyí gbọ́dọ̀ jọba nínú òmìnira olóró wọn àti ní ìgbà kannáà kí wọ́n di òtítọ́ mú sí àwọn agbára olúkúlùkù wọn. Àwọn kílónù kìí borí olùsárá. Àwọn òṣìṣẹ́ dídára dára láti wà ní ìbámu—ẹnìkan láti darí àṣẹ, ẹnìkan láti di ohunkan mú ní ìpamọ́, ẹnìkan láti ja ìjà, ẹnìkan láti mú àláfíà wá. Kò sí olùyí tí ó níyì ju òmíràn, gbogbo wọn jẹ́ ohun ìní sí ọkọ̀-ojú omi, ṣùgbọ́n bí wọ́n bá yíi dáadáa papọ̀, ẹnìkọ̀ọ̀kan gbọ́dọ̀ ṣe àtúntò sí àìní àti agbára àwọn ẹlòmíràn—ẹni ọlọ́wọ́-kúkúrú nde ibi jíjìn díẹ̀ si, ẹni alápá-gígùn ntìí díẹ̀ díẹ̀.

Àwọn ìyàtọ̀ lè yípadà sí dídára dípò àìdára. Igbànáà nìkan ni a ó ní ìmọ̀ bí ọkọ̀-ojú omi ti nrìn fúnra rẹ̀. Ìgbànáà nìkan ni gbogbo ìrora nfi ọ̀nà fún ìgbéga. “Yíyí” rere dàbí ewì.4

Ní ìlòdi sí àwọn àtakò tó nyíká, ẹgbẹ́ yí rí ìyíkiri pípé wọ́n sì ṣẹ́gun. Olympic wùra ngbọ̀nni, ṣùgbọ́n ìrẹ́pọ tí olùyí kọ̀ọ̀kan ní ìrírí ní ọjọ́ náà jẹ́ àkokò mímọ́ tí ó dúró pẹ̀lú wọn nínú ìgbé ayé wọn títí.

Nu Búburú Kúrò Kíákíá kí Rere Lè Dàgbà

Nínú àfiwé títayọ ní Jákọ́bù 5, Olúwa ọgbà-àjàrà gbin igi rere ní ilẹ̀ rere, ṣùgbọ́n ó díbàjẹ́ ní ìgbàkan ó sì mú èso líle jáde. Olúwa ọgbà-àjàrà wípé: “Ó sì bà mí nínú jẹ́ [láti] pàdánù igi yí.”

Ìránṣẹ́ nã sọ fún Olúwa ọgbà-àjàrà nã pé: “Ẹ dáa [igi náà] sí fún ìgbà díẹ̀ síi. Olúwa sì wípé: Bẹ́ẹ̀ni, èmi o da sí fún ìgbà díẹ̀ si.”

Nígbànáà ni àṣẹ tí ó lè wúlò sí gbogbo wa ní ìgbìyànjú láti gbẹ́lẹ̀ yíká kí a sì wá èso rere nínú ọgbà-àjàrà kékeré ti ara wa: “Ẹ̀yin ó gbá búburú kúrò gẹ́gẹ́bí rere yíò ti dàgbà.”6

Ìrẹ́pọ̀ kìí fi ìdíbọ́n ṣẹlẹ̀; ó gba iṣẹ́. Ó jẹ́ ìdọ̀tí, ìgbàmíràn kò tunilára, ó sì nṣẹlẹ̀ díẹ̀díẹ̀ nígbàtí a bá gbá bùburú kúrò kíákíá kí rere lè dàgbà.

A kò dá wà nínú ìtiraka wa láti dá ìrẹ́pọ̀ sílẹ̀. Jákọ́bù 5 tẹ̀síwájú, “Àwọn ìránṣẹ́ náà lọ ṣiṣẹ́ pẹ̀lú agbára wọn; Olúwa ọgbà-àjàrà sì ṣiṣẹ́ pẹ̀lú wọn.”7

Ọ̀kọ̀ọ̀kan lára wa nlọ láti ní ìjìlẹ̀ ìyípo àwọn ìrírí, ohun tí kò yẹ kó ṣẹlẹ̀ láé. Olúkúlukú wa yíò tún, ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àkókò, gba ìgbéraga àti agbéraga láti ba èso tí a so jẹ́. Ṣùgbọ́n Jésù Krístì ni Olùgbàlà nínú ohun gbogbo. Agbára Rẹ̀ nà dé ìsàlẹ̀ gan an ó sì wà nìbẹ̀ fún wa dáadáa nígbàtí a bá pè É. Gbogbo wa bẹ̀bẹ̀ fún àánú fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ àti ìkùnà wa. O fúnni ní ọ̀fẹ́. Ó sì bèèrè lọ́wọ́ wa tí a bá lè fún ní irú àánú kannáà kí a sì ní òye sí ara wa.

Jésù sọ ọ́ ṣáká: Ẹ jẹ́ ọ̀kan; tí ẹ kò bá jẹ́ ọ̀kan ẹ kìí ṣe tèmi.”8 Ṣùgbọ́n tí ẹ bá jẹ́ ọ̀kan—tí ẹ bá lè fúnni ní ẹyọ páì wa kan tàbí tún ẹ̀bùn olúkúlùkù ṣe kí ọkọ̀ ojú omi wa lè yí nínú ìṣọ̀kan pípé—ìgbànáà ni a jẹ́ Tirẹ̀. Òun ó ràn wá lọ́wọ́ láti gbá búburú kúrò kíákíá bí rere ti ndàgbà.

Àwọn Ìlérí ti Wòlí

Síbẹ̀síbẹ̀ a lè má tilẹ̀ tí dé ibi tí a bá dé, a kò sí nibi tí a ó wọ̀ nísisìyí. Mo gbàgbọ́ pé ìyípadà tí a nwá nínú arawa àti ní ẹgbẹ́ tí a wà pẹ̀lú yíò wá ní ìdínkù nípa ìwà-ṣíṣe si àti nínú ìṣe ìgbìyànjú lojojúmọ́ láti ní òye ara wa. Kínìdí? Nítorí a ngbé Síónì ga—àwọn ènìyàn “pẹ̀lú ọkàn kan àti inú kan.”9

Gẹ́gẹ́bí àwọn obìnrin májẹ̀mú, a ní agbára tó gbòòrò. Agbára náà wúlò ní àwọn àkokò lójojumọ́ nígbàtí a bá nṣe àṣàrò pẹ̀lú ọ̀rẹ́ kan, gbígbé àwọn ọmọ sí ibùsùn, bíbá olùjokopọ̀ nínú ọkọ̀ sọ̀rọ̀, mímúra ìgbékalẹ̀ kan pẹ̀lú ẹlẹgbé kan. A ní agbára láti mú ìkórira kúrò kí a kọ́ ìṣọ̀kan.

Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ àti Ọ̀dọ́mọbìnrin kìí ṣe àwọn kíláàsì lásán. Bákannáà wọ́n lè di ìrírí àìlègbàgbé nibití gbogbo àwọn obìnrin tó yàtọ̀ gan an tí nwọnú ọkọ̀-ojú omi kannáà tí à nyí títí tí a ó fi rí ìyípo wa. Mo funni ní ìpè yí: ẹ jẹ́ ara ìsopọ̀ ipa tí yíò yí ayé padà fún rere. Iṣẹ́ májẹ̀mù yíyàn wa ni láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́, láti gbé ọwọ́ tí ó rẹ̀ sílẹ̀ ga, láti gbé àwọn ènìyàn tó ntiraka sẹ́hìn wa tàbí apá wa kí a sì gbé wọn. Kò ṣòro láti mọ ohun tí a ó ṣe, ṣùgbọ́n ó má ndí àwọn ifẹ́ ìmọtaraẹni-nìkan wa lọ́wọ́, a sì níláti gbìyànjú. Àwọn obìnrin Ìjọ yí ti ní agbára tí kò lópin láti yí àwùjọ padà. Mo ní ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún ti ẹ̀mí pé, bí a ṣe nwá ìrẹ́pọ̀ ti ìmọ̀ ara, a ó pe agbára Ọlọ́run láti mú àwọn ìtiraka wa dára si.

Nígbàtí Ìjọ ṣe ayẹyẹ ìfihàn lórí oyèàlùfáà, Ààrẹ Russell M. Nelson nawọ́ ìbùkún alágbára ti wòlíì: “Àdúrà àti ìbùkún mi ni mo fi sílẹ̀ sórí gbogbo ẹni tí ó nfi etí sílẹ̀ kí a lè borí àjàgà èyíkéyìí ẹ̀tanú kí a sì rìn ní ọ̀nà títọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run—àti pẹ̀lú ara wa—ní àláfíà pípé àti ìbámu.”10

Njẹ́ kí a fàlé orí ìbùkún ti wòlíì yí kí a sì lo ìtiraka olúkúlùkù àti ìsopọ̀ láti mú ìrẹ́pọ̀ wa ní ayé pọ̀si. Mo fi ẹ̀rí mi sílẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ Olúwa Jésù ní ìrẹ̀lẹ̀, àìlónkà àdúrà: “Pé kí wọ́n lè jẹ́ ọ̀kan; bí ìwọ, Baba, ti wà nínú mi, àti èmi ní inú rẹ, bákannáà kí wọ́n lè jẹ́ ọ̀kan nínú wa.”11 Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.