Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Búrẹ́dì Wà
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2020


Búrẹ́dì Wà

Bí a ṣe nwá láti múrasílẹ̀ niti ara, a lè kojú àwọn àdánwò ayé pẹ̀lú ìgbẹ́kẹ̀lé púpọ̀ si.

Ṣáájú sí àwọn ìhámọ́ àwọn ìrìnàjò nípasẹ̀ àjàkálẹ̀ àrun lọ́wọ́lọ́wọ́, mo npadàbọ̀ nílé látibi iṣẹ́ ìyànsílẹ̀ káríayé èyítí, ó mú kí ndúró di ọjọ́-ìsinmi, nítorí àwọn ìlàsílẹ̀ àwọn ọ̀ràn. Mo ní àkokò líle ní àárín fífò lọ sí ìpàdé ìbílẹ̀ oúnjẹ Olúwa, níbi tí mo ti lè ṣe àbápín ọ̀rọ̀ ránpẹ́ kan. Lẹ́hìn ìpàdé náà, díákónì onítara kan dé ọ̀dọ̀ mi ó sì bèèrè tí mo bá mọ Ààrẹ Nelson àti bí mo bá ti ní ààye láti bọ̀ọ́ lọ́wọ́ rí. Mo dáhùn pé mo mọ̀ ọ́, pé mo ti bọ̀ọ́ lọ́wọ́ rí àti pé, bí ọmọ àjọ̀ Alakoso Bìṣọ́ọ́pù, mo ti ní ànfàní láti padé Ààrẹ Nelson àti àwọn olùdámọ̀ràn rẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ìgbà ní ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀.

Nígbànáà díákónì ọ̀dọ́ náà joko lórí àgà, ó ju ọwọ́ rẹ̀ sí afẹ́fẹ́, ó kígbe pé, “Èyí ni ọjọ́ gígajùlọ nínú ayé mi!” Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, èmì lè má ju ọwọ́ mi sí afẹ́fẹ́ kí nsì kígbe, ṣùgbọ́n mo fi ìmoore ayérayé hàn fún wòlíì alààyè kan àti fún ìdarí tí a ngbà látọ̀dọ̀ àwọn wòlíì, aríran, àti olùfihàn, nípàtàkì ní àkokò ìpènijà.

Láti ìbẹ̀rẹ̀ àkokò, Olúwa ti pèsè ìdarí fún àwọn ènìyàn Rẹ̀ láti ṣèrànwọ́ fún wọn láti múrasílẹ̀ níti ẹ̀mí àti níti ara ní ìlòdì sí àwọn àjálù tí Ó mọ̀ pé yíò wá bí ara ìrírí ayé ikú yí. Àwọn àjálù wọ̀nyí lè jẹ́ ti araẹni tàbí gbogbogbò ní ẹ̀dá, ṣùgbọ́n ìtọ́nisọ́nà Olúwa yíò pèsè ààbò àti àtìlẹhìn dé ibi tí a bá gbọ́ tí a sì ṣe ìṣe lórí àmọ̀ràn Rẹ̀. Àpẹrẹ ìyanilẹ́nu ni a pèsè nínú àkọsílẹ̀ látinú ìwé ti Gẹ́nẹ́sísì, níbití a ti kọ́ nípa Joseph ní Égyptì àti ìtumọ̀ ìmísí rẹ nípa àlá Fáráò.

“Jósẹ́fù wí fún Fáráò pé, … Ọlọ́run ti fi ohun tí ò mbọ̀wá ṣe hàn fún Fáráò. …

“Kíyèsi, ọdún méje ọ̀pọ̀ mbọ̀ já gbogbo ilẹ̀ Egypt:

“Lẹ́hìn wọn ọdun meje iyan sì mbọ̀; gbogbo ọ̀pọ̀ ni a ó sì gbàgbé ní ilẹ̀ Égyptì.”1

Fáráò fetísílẹ̀ sí Jósẹ́fù, ó sì fèsì sí ohun tí Ọlọ́run ti fihàn án nínú àlá kan tí a sì gbé imurasílẹ̀ rẹ̀ kalẹ̀ lọ́gán fún ohun tó mbọ̀ . Àwọn ìwé-mímọ́ kọ́sílẹ̀ pé:

“Ní ọdún méje ọ̀pọ̀ ni ilẹ̀ sì so èso ní ìkúnwọ́-ìkúnwọ́.

“Ó sì kó gbogbo oúnjẹ ọdún méje nì jọ. …

“Jósẹ́fù sì kó ọkà jọ bí iyanrìn òkun lọ́pọ̀lọpọ̀, … títí ó fi dẹ́kun àti má ṣírò; nítorí tí kò ní iye.”2

Ní ìgbàtí ọdún méje ọ̀pọ̀ sì kọjá “ọdún meje ìyàn si bẹ̀rẹ̀ sí dé, gẹ́gẹ́ bí Joseph ti wí: ìyàn náà sì mú ní ilẹ̀ gbogbo; ṣùgbọ́n ní gbogbo ilẹ̀ Égyptì ni óunjẹ gbé wà.”3

Ní òní, a di alábùkúnfún láti gba ìdárí nípasẹ̀ àwọn wòlíì tí ó ní ìmọ̀ ìnilò fún wa láti múrasílẹ̀ ní ìlòdi sí àwọn àjálù “èyítí yíò wà”4 àti pé ẹní tí ó bá dá ìdẹ́kun tàbí ìdíwọ́ mọ̀ bákannáà tí a lè bá pàdé ní ìlàkàkà wa láti tẹ̀lé àmọ̀ràn wọn.

Ìmọ̀ kedere wà pé àbájáde COVID-19, bákannáà pẹ̀lú ìparun àjálù àdánidá, tí kìí ṣe olùbọ̀wọ̀fún àwọn ẹnikẹ́ni káàkiri ẹ̀yà, àwùjọ, àti ààlà ẹ̀sìn ní gbogbo àgbàyé. A ti sọ àwọn iṣẹ́ nù tí owó ọya sì ti dínkù bí ànfàní sí iṣẹ́ ti ṣe faragbá nípasẹ̀ àwọn ìdánidúró àti pé agbára láti ṣiṣẹ́ ni a ti nípalára nípasẹ̀ àwọn ìpènijà ìlera àrùn-kòrónà.

Sí gbogbo ẹni tí wọ́n tí faragbá, a fi ímọ̀ hàn àti àníyàn fún ipò yín, bákannáà gẹ́gẹ́bí ìdánilójú pé àwọn ọjọ́ dídára si wà níwájú. Ẹ ti di alábùkúnfún pẹ̀lú awọn bíṣọ́ọ̀pù àti ààrẹ ẹ̀ka tí wọ́n nwá ọmọ ìjọ tí wọ́n sì nṣàtìlẹhìn gbogbo ìjọ wọn pẹ̀lú awọn àìní ti ara tí wọ́n sì ní ààyè sí awọn ohun èlò ati irinṣẹ́ tí ó lè ṣèrànwọ́ láti tún ayé yín ṣe ati láti gbé yín sí ipa ọ̀nà sí ìgbẹ́kẹ̀lé-araẹni bí ẹ ṣe nlo awọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ ìmúrasílẹ.

Ní àyíká òde-òní, pẹ̀lú àjàkálẹ̀ àrùn tí ó ti pa gbogbo ọrọ̀ ajé àti ìgbé ayé olúkúlùkù run, kò ní wà ní ìbámu pẹ̀lú aláàánú Olùgbàlà láti pa òdodo ti pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ntiraka kí ó sì ní kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìkójọ oúnjẹ àti owó lọ́gán. Bákannáà, ìyẹn kò túmọ̀ sí pé a ó pa àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ nípa ìmúrasílẹ̀ ti pátápátá—ó kàn jẹ́ pé àwọn ẹ̀kọ́ ìpìnlẹ̀ wọ̀nyí yẹ kó wúlò “nínú ọgbọ́n àti ètò,”5 ki a lè wí ní ọjọ́ ọ̀là pé, bí Joseph ní Egypti ti ṣe, “búrẹ́dì wà.”6

Olúwa ko retí wa láti ṣe ju bí a tìlè ṣe, ṣùgbọ́n O nretí kí a ṣe ohun tí a lè ṣe, nígbàtí a lè ṣe é. Àarẹ Nelson rán wa létí nínú ìpàdé àpapọ̀ tó kọjá pé, “Oluwa nifẹ ìtiraka.”7

Àwòrán
Ìwé Ìṣúna Araẹni nínú oríṣiríṣi èdè

Àwọn olórí Ìjọ ti gba àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn níyànjú léraléra “láti múrasílẹ̀ fún ìpọ́njú nínú ayé nípa níní kókó ìpèsè oúnjẹ àti omi àti owó díẹ̀ nínú ìpamọ́.”8 Ní ìgbà kannáà, a gbàwánìyànjú láti “gbọ́n” àti pé “kí a má kọjá àyè”9 nínú ìtiraka wa láti gbé ìpèsè ìkójọ ilé àti ìpamọ́ ìṣúná-owó kalẹ̀. Ohun èlò kan tí a pè ní Ìṣúná-owó Araẹni, ti a tẹ̀ jáde ní 2017 tí ó sì wà lọ́wọ́lọ́wọ́ lórí wẹ́ẹ̀bù Ìjọ ní èdè mẹrindinlogojì, bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ kan láti ẹnu Ajọ Ààrẹ Ìkínní, èyí tí ó wípé:

“Olúwa ti kéde, ‘Ó jẹ́ èrèdí mi láti pèsè fún àwọn ènìyàn mímọ́ mi’ [Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 104:15]. Ìfihàn yí ni ìlérí kan látọ̀dọ̀ Olúwa pé Òun yíò pèsè awọn ìbùkún ti ara òun yíò si ṣí ilẹ̀kùn ìgbẹ́kẹ̀lé-araẹni. …

“…Títẹ́wọ́ gba àti gbígbé àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ wọ̀nyí yíò jẹ́ kí ẹ gba àwọn ìbùkún ti ara tí a ṣe ileri láti ẹnu Olúwa.

“A pè yín láti fi taratara ṣe àṣàrò kí ẹ sì kọ́ wọn sí àwọn ọmọ ẹbí yín. Bí ẹ ti nṣe bẹ́ẹ̀, a ó bùkún ìgbé ayé yín … [Nítorí] ẹ jẹ́ ọmọ Baba wa ní Ọ̀run. Ó fẹ́ràn yín òun kò sì ní pa yín ti. Ó mọ̀ yín ó sì ṣetán láti nawọ́ awọn ìbùkún ti ara ati ti ẹ̀mí ìgbẹ́kẹ̀lé-araẹni sí yín.”10

Ohun-èlò yí pẹ̀lú àwọn orí tí a fifún dídásílẹ̀ àti gbígbé ní àárín ètò-ìnáwó kan, kí a dá ààbò bo ẹbí wa ní ìlòdì sí ìṣòrò, ṣíṣe àkóso aáwọ̀ ìṣúná-owó, àti ìfipamọ́ fún ọjọ́-ọ̀la, àti pé púpọ̀ si ni ó sì wà fún gbogbo ènìyàn lórí wẹ́ẹ̀bù Ìjọ tàbí nípasẹ̀ àwọn olórí ìbílẹ̀ yín.

Nígbàtí a bá nronú ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ ìmúrasílẹ̀, a lè wẹ̀hìnwò sí Joseph ní Egypt fún ìmísí. Ní mímọ ohun tí yíò ṣẹlẹ̀ kì bá ti gbé wọn tó nínú àwọn ọdún “ìyàn” láìsí ipele ìrúbọ nígbà àwọn ọdún ọ̀pọ̀. Sànju kí wọ́n jẹ gbogbo ohun tí àwọn òṣìṣẹ́ Fáráò mú jáde, wọ́n dín ìgbékalẹ̀ kù, wọ́n sì tẹ̀lé, pípèsè ohun ti ó tó fún àwọn, àìní lọ́wọ́lọ́wọ́, bákannáà sí ọjọ́-ọ̀là. Kò tó láti mọ̀ pé àwọn igbà ìpènijà yíò wá. Wọ́n níláti gbé ìgbésẹ̀ àti, nítorí ìtiraka wọn, “búrẹ́dì wà.”11

Èyí darí sí ìbèerè pàtàkì, “Nítorínáà, kíni?” Ibi rere láti bẹ̀rẹ̀ ni láti ní ìmọ̀ pé ohun gbogbo jẹ́ ti ẹ̀mí sí Olúwa, “kò sì sí àkokò kankan” tí Ó fúnni ní “òfin èyí tí ó jẹ́ ti-ara.”12 Gbogbo ohun, nígbànáà, nawọ́ sí Jésù Krístì bí ìpìnlẹ̀ lórí èyí tí a gbọ́dọ̀ kọ́ lé àní ìmúrasílẹ̀ ti ara wa.

Ìmúrasílẹ̀ ti-ara àti ìgbẹ́kẹ̀lé-araẹni túmọ̀ sí “ìgbàgbọ́ nípasẹ̀ oore-ọ̀fẹ́, tàbí níní agbára, nípa Jésù Krístì àti ìtiraka ara wa, ni a fi lè gba gbogbo ìní ti-ẹ̀mí àti ti ara ìgbé ayé tí a nílò fún ara wa àti àwọn ẹbí wa”13

Àwọn ara ìpìnlẹ̀ afikún ti ẹ̀mí fún ìmúrasílẹ̀ ti ara wà pẹ̀lú ṣíṣe ìṣe “nínú ọgbọ́n àti àṣẹ,”14 èyí túmọ̀ sí kíkó oúnjẹ jọ́ àti ìfowó pamọ́, fún ìgbà kan, ati ní àárín agbára wa, àti èkejì, kí a gba níní “ohun kékeré àti ìrọ̀rùn” mọ́ra,15 èyí tí ó jẹ́ ìfihàn ìgbàgbọ́ pé Olúwa yíò gbé ìtiraka kékeré ṣùgbọ́n títẹramọ́ wa ga.

Pẹ̀lú ìpìnlẹ̀ ti ẹ̀mí ní ipò, nígbànáà a lè fi ìyege lo àwọn ohun èlò méjì ti ìmùrasílẹ̀ ti ara—ṣe àkóso ìṣúná-owó àti ìkópamọ́ ilé.

Àwọn kókó ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ ṣíṣe àkóso ìṣúná-owó pẹ̀lú sísan idamẹwa àti ọ̀rẹ, mímúkúrò àti yíyẹra fún gbèsè, mímúrasílẹ̀ àti gbígbé nínú ètò ìṣúná-owó wa, àti pípamọ́ fún ọjọ́ ọ̀la.

Kókó ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ ìkópamọ́ ilé pẹ̀lú ìkópamọ́ oúnjẹ, ìkópamọ́ omi, níbi tí ó ti ṣeéṣe, bákannáà bí àwọn ìní míràn tí ó dálé àwọn àìní olúkúlùkù àti ẹbí, gbogbo rẹ̀ nítorí “ilé-ìṣura tó darajùlọ”16 ni ilé, ibi èyí “tí a lè tètè dé nígbà àìní.”17

Bí a ti ngba àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ mọ́ra tí a sì nwá ìmísí láti ọ̀dọ̀ Olúwa, a ó gba ìtọ́nisọ́nà láti mọ ìfẹ́ Olúwa fún wa, bí olúkúlùkù àti bí ẹbí, àti bí a ṣe lè lo àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ dáradára nípa mímúrasílẹ̀ níti ara. Ìgbésẹ̀ tó ṣe pàtàkì julọ nínú gbogbo rẹ̀ ni láti bẹ̀rẹ̀.

Alàgbà Bednar kọ́ ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ yí nígbàtí ó wípé: “Ṣíṣe ìṣe ni lílo ìgbàgbọ́. … Ìgbàgbọ́ òtítọ́ ní ìdojúkọ nínú àti lórí Olúwa Jésù Krístì tí ó ndarí sí ìṣe nígbàgbogbo.”18

Ẹ̀yin arábìnrin àti arákùnrin, nínú ayé tí ó nyípada-lemọ́lemọ́, a gbọ́dọ̀ múrasílẹ̀ fún àwọn àìnídánilójú. Àní pẹ̀lú àwọn ọjọ́ dídára níwájú, a gbọ́dọ̀ múrasílẹ̀ fún àwọn àìnídánilójú. Bí a ṣe nwá láti múrasílẹ̀ níti ara, a lè kojú àwọn àdánwò ayé pẹ̀lú ìgbẹ́kẹ̀lé púpọ̀, àláfíà nínú ọkàn wa, àti, bíi ti Joseph ní Egypti, a ó lè wí, àní nínú awọn ipò rírẹni pé “Búrẹ́dì wà”.19 Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.